Sáàmù
Sí olùdarí; kí a yí i sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì.
12 Gbà mí Jèhófà, nítorí kò sí ẹni ìdúróṣinṣin mọ́;
Àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàárín àwọn èèyàn.
3 Jèhófà máa gé gbogbo ètè tó ń pọ́nni kúrò
Àti ahọ́n tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga,+
4 Àwọn tó ń sọ pé: “Ahọ́n wa la máa fi ṣàṣeyọrí.
Bó ṣe wù wá ni à ń lo ètè wa;
Ta ló máa jẹ ọ̀gá lé wa lórí?”+
5 “Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ,
Nítorí ìkérora àwọn aláìní,+
Màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀,” ni Jèhófà wí.
“Màá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.”*
6 Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́;+
Wọ́n dà bíi fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú iná ìléru tí wọ́n fi amọ̀ ṣe,* èyí tí a yọ́ mọ́ ní ìgbà méje.
7 Jèhófà, wàá máa ṣọ́ wọn;+
Wàá dáàbò bo kálukú wọn lọ́wọ́ ìran yìí títí láé.
8 Àwọn ẹni burúkú ń rìn káàkiri fàlàlà
Nítorí pé àwọn ọmọ èèyàn ń gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ.+