Sáàmù
Orin Ìgòkè.
123 Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí,+
Ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.
2 Bí ojú àwọn ìránṣẹ́ ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn
Àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ṣe ń wo ọwọ́ ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,
Bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa,+
Títí á fi ṣojú rere sí wa.+
3 Ṣojú rere sí wa, Jèhófà, ṣojú rere sí wa,
Nítorí wọ́n ti kàn wá lábùkù dé góńgó.+
4 Àwọn ajọra-ẹni-lójú ti fi wá ṣẹ̀sín dé góńgó,*
Àwọn agbéraga sì ti kàn wá lábùkù gidigidi.