Sáàmù
Sí olùdarí. Orin Dáfídì.
20 Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà.
Kí orúkọ Ọlọ́run Jékọ́bù dáàbò bò ọ́.+
3 Kó rántí gbogbo ọrẹ ẹ̀bùn rẹ;
Kó fi ojú rere gba ẹbọ sísun rẹ.* (Sélà)
Kí Jèhófà dáhùn gbogbo ohun tí o béèrè.
6 Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ń gba ẹni àmì òróró rẹ̀ sílẹ̀.+
7 Àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn míì sì gbẹ́kẹ̀ lé ẹṣin,+
Àmọ́, àwa ń ké pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.+
8 Wọ́n ti kọsẹ̀, wọ́n sì ti ṣubú lulẹ̀,
Àmọ́ àwa ti dìde, a sì ti kọ́fẹ pa dà.+
9 Jèhófà, gba ọba sílẹ̀!+
Yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́.+