Sáàmù
Sí olùdarí. Orin Dáfídì.
2 O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́,+
Ìwọ kò sì fi ohun tó béèrè dù ú. (Sélà)
5 Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ fún un ní ògo ńlá.+
O fi iyì àti ọlá jíǹkí rẹ̀.
8 Ọwọ́ rẹ á tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ á tẹ àwọn tó kórìíra rẹ.
9 Wàá ṣe wọ́n bí ohun tí a jù sínú iná ìléru ní àkókò tí o yàn láti fiyè sí wọn.
Jèhófà máa gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, iná á sì jó wọn run.+
10 Wàá pa àtọmọdọ́mọ* wọn run kúrò ní ayé,
Àti ọmọ wọn kúrò láàárín àwọn ọmọ èèyàn.
13 Dìde nínú agbára rẹ, Jèhófà.
A ó fi orin yin* agbára ńlá rẹ.