Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Èé Ṣe Tí Ó Fi Ń Jẹ́ Ẹ̀bi Mi Nígbà Gbogbo?
“Dádì mi ní àwọn èèwọ̀ ara, ó sì ní láti máa bá àwọn ènìyàn tí ń mu sìgá ṣiṣẹ́. Bí ó bá darí délé, nígbà míràn, ó máa ń dààmú púpọ̀. Yóò sọ nǹkan nù, yóò sì dá mi lẹ́bi rẹ̀. Tí mo bá sọ fún un pé òun ló sọ ọ́ nù, inú rẹ̀ yóò ru, yóò sì sọ fún mi pé n kì bá tí sọ àṣìṣe òun fún òun.” —Ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba kan.
ÌWỌ ha máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé ìwọ ni a ń di gbogbo ẹ̀bi rù nínú ìdílé bí? Ó ha jọ pé ohun yòó wù kí ó ṣàìtọ́, ìwọ ni a ń dá lẹ́bi bí? Ó jọ bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn ọmọ ọlọ́dún 14 tí ń jẹ́ Joy. Ó wà nínú ìdílé olóbìí kan, ó sì máa ń fìgbà gbogbo bójú tó àwọn àbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Joy ṣàròyé pé: “Èmi máa ń wà nísàlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Wọ́n ń hùwà àìnírònú àti àìdàgbàdénú, ṣùgbọ́n nígbà tí Dádì bá dé, ó máa ń ké rara mọ́ mi nítorí pé n kò sí níbẹ̀ láti là wọ́n.”
Bí àwọn òbí rẹ bá ń sọ pé o bà jẹ́, o yọ̀lẹ, tàbí pé o kò ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ tàbí tí wọ́n ń pè ọ́ lóríṣiríṣi orúkọ tó jọ pé ó ń mú kí o dà bí ẹni tí kì í gbẹ̀kọ́, nígbà míràn, ó tilẹ̀ lè dà bíi pé wọ́n retí pé kí o kùnà. Ìdílé Ramon ń pè é ní ọ̀jọ̀gbọ́n aláìláfọkàn-sí, ìnagijẹ kan tí ó fìbínú kórìíra gidigidi. Lọ́nà kan náà, o lè fìbínú kórìíra ìnagijẹ kan tàbí ìpenilórúkọ kan tí ń tẹnu mọ́ àwọn àléébù rẹ, kódà bí a bá ń sọ ọ́ tìfẹ́nitìfẹ́ni. Kàkà kí ìpenilórúkọ-kórúkọ náà mú kí o ṣàtúnṣe, ó wulẹ̀ lè fún ìmọ̀lára pé ìwọ ni a ń dá lẹ́bi nígbà gbogbo lókun.
Ìdálẹ́bi lè dunni gan-an nígbà tí ó bá jọ pé ó jẹ́ nítorí ojúsàájú. Ọ̀dọ́langba kan tí ń jẹ́ Frankie sọ pé: “Èmi ni ọmọ tí ó wà láàárín, èmi ni mo sì sábà máa ń gba ìpín tí ó burú jù lọ nínú ìhùwàsí náà.” Ó lè jọ pé àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ kì í lẹ́bi ṣùgbọ́n pé ìwọ ni a máa ń dá lẹ́bi ní gbàrà tí nǹkan búburú kan bá ti ṣẹlẹ̀.
Ìdí Tí Àwọn Òbí Fi Ń Dáni Lẹ́bi
Dájúdájú, ó wulẹ̀ jẹ́ ohun wíwọ́pọ̀ fún àwọn òbí láti bá àwọn ọmọ wọn wí nígbà tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe. Ó ṣe tán, fífúnni ní ìbáwí gbígbámúṣé, tí ó ṣeé mú lò, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí àwọn òbí olùbẹ̀rù-Ọlọ́run gbà ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, àwọn òbí dídára jù lọ pàápàá lè hùwà pa dà lọ́nà àṣejù tàbí kí wọ́n tilẹ̀ yára dórí ìpinnu tí kò tọ́. Rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yí, a wá Jésù tì. Ó wá já sí pé ó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, ó ń ṣe ìjíròrò Bíbélì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ pàápàá, nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ìyá rẹ̀ béèrè pé: “Ọmọ, èé ṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yí? Wò ó báyìí baba rẹ àti èmi ti ń wá ọ nínú wàhálà èrò orí.”—Lúùkù 2:48.
Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni pípé, kò sí ìdí láti bẹ̀rù pé ó lè máa hùwà pòkíì. Ṣùgbọ́n bíi ti gbogbo òbí onífẹ̀ẹ́, ìyá rẹ̀ nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe síhà ọmọ rẹ̀, ó sì hùwà pa dà lọ́nà líle, bóyá ní bíbẹ̀rù pé ire dídára jù lọ ti ọmọ náà wà nínú ewu. Lọ́nà kan náà, àwọn òbí rẹ lè hùwà pa dà lọ́nà àṣejù nígbà míràn, kì í ṣe nítorí pé wọ́n ń gbìyànjú láti máa mú ọ bínú tàbí láti rorò mọ́ ọ, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ jẹ́ nítorí pé wọ́n bìkítà nípa rẹ ní gidi.
Tún mọ̀ pẹ̀lú pé a ń gbé nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (Tímótì Kejì 3:1) Ní ṣíṣiṣẹ́ àti bíbójútó ilé rẹ, àwọn òbí rẹ wà lábẹ́ másùnmáwo púpọ̀, èyí sì lè nípa lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá ọ lò. (Fi wé Oníwàásù 7:7.) Òṣìṣẹ́ ìlera ọpọlọ kan sọ pé: “Nínú àwọn ìdílé kan, nígbà tí ìṣòro kan bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn òbí lè bínú, kí wọ́n sì fi ìkùgbù ṣe àwọn ìpinnu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lábẹ́ ipò tí ó wà déédéé, wọn kì í ṣe ojúsàájú.”
Ní pàtàkì ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ lè ní ìtẹ̀sí láti fi ìjákulẹ̀ tí wọ́n ní lórí àwọn ọmọ wọn hàn lọ́nà lílágbára, kìkì nítorí pé wọn kò ní alábàá-ṣègbéyàwó tí wọ́n lè bá jíròrò ọ̀ràn. Láìṣeésẹ́, fífaragbá apá púpọ̀ nínú ìjákulẹ̀ ara ẹni tí òbí kan ní kì í ṣe ohun amóríyá. Ọmọ ọdún 17 tí ń jẹ́ Lucy sọ pé: “Bí mo bá ṣe nǹkan, tí ó sì yẹ kí n jìyà, ìyẹn dára. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá ń jìyà nítorí pé ìyá mi ní ìmọ̀lára búburú kan, ìyẹn kò dára rárá.”
Ṣíṣe ojúsàájú tún jẹ́ kókó mìíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òbí kan sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọmọ rẹ̀, kò ṣàìwọ́pọ̀ pé kí ó ní ìfàmọ́ àrà ọ̀tọ̀ fún ọmọ kan.a (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 37:3.) Níní ìmọ̀lára pé ìwọ ni ọmọ tí a kò fẹ́ràn tó bẹ́ẹ̀ máa ń dunni fúnra rẹ̀. Àmọ́ bí ó bá jọ pé a kò ka àwọn àìní rẹ sí tàbí pé a sábà máa ń dá ọ lẹ́bi nítorí ohun tí àwọn alájọbí rẹ ṣe, ó dájú pé ìkórìíra yóò tẹ̀ lé e. Roxanne ọ̀dọ́ wí pé: “Mo ní àbúrò ọkùnrin kan, Darren. Mọ́mì rò pé kò lè ṣe àṣìṣe kankan. . . . Èmi ló sábà máa ń dá lẹ́bi, kì í dá Darren lẹ́bi.”
Àwọn Ìdílé Tí Ó Níṣòro
Nínú àwọn ìdílé tí kò níṣòro, dídánilẹ́bi láìtọ́ lè máa ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ìdílé tí ó níṣòro, ó ṣeé ṣe kí ó máa ṣẹlẹ̀ léraléra pé àwọn òbí ń dáni lẹ́bi, wọ́n ń dójú tini, wọ́n sì ń tẹ́ni lógo. Nígbà míràn, a máa ń fi “ìkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” kún ìdánilẹ́bi náà.—Éfésù 4:31.
A ha lè dá èwe kan lẹ́bi fún irú ìbújáde bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ òbí bí? Òtítọ́ ni pé ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan tí ó ya aláìgbọ́ràn lè jẹ́ “ìbìnújẹ́” fún òbí kan. (Òwe 17:25) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn òbí ni Bíbélì ń bá wí pé: “Ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú [ní olówuuru, “sún sí ìrunú”].” (Éfésù 6:4, NW) Bí ó ti rí fún gbogbo Kristẹni, òbí kan gbọ́dọ̀ lo ìkóra-ẹni-níjàánu, “tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.” (Tímótì Kejì 2:24) Nítorí náà, bí òbí kan bá ṣàìní ìkóra-ẹni-níjàánu, kò lè di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn àìkúnjú-ìwọ̀n ọmọ rẹ̀.
Èébú lè jẹ́ ẹ̀rí pé òbí kan ń jìyà wàhálà ní ti ìmọ̀lára, ìsoríkọ́, tàbí iyì ara ẹni tí kò tó nǹkan. Ó tún lè tọ́ka sí àwọn ìṣòro wàhálà ìdè ìgbéyàwó tàbí ìmukúmu ọtí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtọ́kasí kan ṣe sọ, àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ní àṣà bárakú sábà máa ń fara gbá ibi. “Kò sí ohun tí wọ́n ṣe tí í tọ̀nà. A lè máa pè wọ́n ní ‘arìndìn,’ ‘ènìyànkénìyàn,’ ‘onímọtara-ẹni-nìkan,’ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé wá dájú sọ ọmọ (tàbí àwọn ọmọ) yẹn bí ‘ìṣòro’ tí a ti fi hàn náà, ó sì ń pín ọkàn wọn níyà kúrò lára àwọn ìmọ̀lára àìfararọ àti àwọn ìṣòro ti ara wọn.”
Kíkojú Ìdálẹ́bi Tí Kò Yẹ
Dókítà Kathleen McCoy sọ pé: “Pípe ọmọ [kan] lórúkọ, títẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ àti ṣíṣàríwísí ìwà rẹ̀ . . . lè jẹ́ kókó abájọ kan fún iyì ara ẹni tí ó kéré, ìsoríkọ́ àti àìbánisọ̀rọ̀ tí ọ̀dọ́langba kan ń fi hàn.” Tàbí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì fúnra rẹ̀ ṣe sọ ọ́, ìbálò lílekoko lè “dá” àwọn ọmọdé “lágara,” kí ó sì mú kí wọ́n “sorí kodò.” (Kólósè 3:21) O lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé o jẹ́ aláìwúlò tí kì í ṣàṣeyọrí. O tilẹ̀ lè mú ìmọ̀lára òdì dàgbà nípa àwọn òbí rẹ. O lè parí èrò sí pé kò sí ohun kankan tí o lè ṣe láti tẹ́ wọn lọ́rùn, àti pé kò sí ìdí fún ọ láti máa gbìyànjú. Ìbínú àti ìkórìíra lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú, tí ń mú kí o kọ ìbáwí èyíkéyìí sílẹ̀—kódà, àríwísí tí ń mú nǹkan sunwọ̀n.—Fi wé Òwe 5:12.
Báwo ni o ṣe lè kojú rẹ̀? Púpọ̀ yóò sinmi lórí ipò rẹ gan-an. O kò ṣe dúró kí o sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ bí ó ti rí gan-an? Bí àpẹẹrẹ, ó ha jẹ́ òótọ́ gidi pé ìwọ ni a ń dá lẹ́bi nígbà gbogbo? Tàbí ó ha lè wulẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ ní ìtẹ̀sí láti ṣàríwísí kọjá ààlà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì ń sọ ohun tí kò tọ́? Bíbélì wí pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà,” ìyẹn sì ní àwọn òbí nínú. (Jákọ́bù 3:2) Nítorí náà, bí àwọn òbí rẹ bá ń hùwà pa dà lọ́nà àṣejù díẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwọ pẹ̀lú ha ní láti hùwà pa dà lọ́nà àṣejù bí? Ìmọ̀ràn Bíbélì nínú Kólósè 3:13 lè bá a mu gan-an pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífara dà á fún ara yín lẹ́nìkíní kejì kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nìkíní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”
Níní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fún àwọn òbí rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Òwe 19:11 (NW) wí pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Bí ó bá jọ pé dádì rẹ máa ń bínú lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nígbà tí ó bá ti ibi iṣẹ́ dé, tí ó sì ń dá ọ lẹ́bi lórí ohun tí o kò ṣe, ìdí kankan ha wà láti sọ ọ́ di nǹkan bàbàrà kan bí? Mímọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ti tán an lókun kí ó sì ti rẹ̀ ẹ́ wulẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “gbójú fo ìrélànàkọjá” rẹ̀.
Ṣùgbọ́n, bí dídánilẹ́bi láìtọ́ kì í bá ṣe ọ̀ràn ìbínú ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ léraléra tí kò sì dẹwọ́ ńkọ́? Àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú yóò jíròrò àwọn ọ̀nà tí o lè fi mú ipò rẹ dára sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Awọn Ọ̀dọ́ Beere Pe . . . Eeṣe Tí Ó Fi Nira Tobẹẹ lati Gbé Papọ Bí Ọ̀rẹ́ Pẹlu Arakunrin ati Arabinrin Mi?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti January 22, 1988.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Kì í ṣe ohun tí kò tọ́ fún òbí kan láti fúnni nímọ̀ràn atúnǹkanṣe nígbà tí a bá nílò rẹ̀