-
Ohun Tó Fa Ẹjọ́ NáàJí!—2003 | January 8
-
-
Ohun Tó Fa Ẹjọ́ Náà
STRATTON, NÍ ÌPÍNLẸ̀ OHIO, LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ jẹ́ àgbègbè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi. Ìtòsí Odò Ohio, èyí tó ya Ìpínlẹ̀ Ohio kúrò lára ìpínlẹ̀ West Virginia, ló wà. Abúlé ni wọ́n kà á sí, ó sì ní baálẹ̀ kan. Àgbègbè kékeré táwọn olùgbé ibẹ̀ kò tó ọ̀ọ́dúnrún yìí ṣàdédé di ojúkò àríyànjiyàn lọ́dún 1999 nígbà táwọn aláṣẹ ibẹ̀ sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àtàwọn mìíràn, gbọ́dọ̀ lọ gba àṣẹ kí wọ́n tó lè máa ṣèbẹ̀wò sí ilé àwọn èèyàn láti sọ ìhìn Bíbélì tí wọ́n ń jẹ́ fún wọn.
Kí nìdí tí ọ̀ràn yìí fi ṣe pàtàkì? Bó o ti ń kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ, wàá rí i pé láìsí àní-àní, irú òfin tí ìjọba àgbègbè náà ṣe yìí yóò dín ẹ̀tọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira kù, àmọ́ kì í ṣe tiwọn nìkan o, á tún dín ẹ̀tọ́ gbogbo olùgbé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kù pẹ̀lú.
Bí Wàhálà Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú Ìjọ Wellsville lábúlé Stratton ti ń wàásù dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé abúlé náà, àmọ́ ọdún 1979 ni àwọn aláṣẹ kan níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ si fa ìṣòro fún àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí látàrí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé tí wọ́n ń ṣe. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní 1990, ọlọ́pàá ìlú Stratton kan lé àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan jáde kúrò nínú ìlú náà. Ó sọ pé: “Kò sí nǹkan kan tó kàn mí pẹ̀lú ẹ̀tọ́ yín.”
Ọdún 1998 gan-an ni iná wá jó dórí kókó, nígbà tí baálẹ̀ abúlé Stratton fúnra rẹ̀ ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin lójú. Jẹ́jẹ́ wọn ni wọ́n ń wa ọkọ̀ jáde kúrò lábúlé náà lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn olùgbé ibẹ̀ tó ti fìfẹ́ hàn sí ìjíròrò Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí baálẹ̀ náà kò lójú ti sọ, baálẹ̀ náà sọ pé, ká ní ọkùnrin ni wọ́n ni, ńṣe lòun ò bá jù wọ́n sẹ́wọ̀n.
Ohun tó wá dá wàhálà tuntun yìí sílẹ̀ ni òfin kan tí wọ́n gbé jáde ní abúlé náà, èyí tó dá lórí ọ̀ràn “Ọjà Títà àti Yíyajúlékiri.” Ohun téyìí ń béèrè ni pé kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ máa lọ láti ilé-dé-ilé kọ́kọ́ lọ gbàṣẹ, láìsan kọ́bọ̀, lọ́dọ̀ baálẹ̀ ná. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka òfin yìí sí títẹ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, òmìnira ìsìn, àti òmìnira ìwé títẹ̀ lójú. Nítorí náà, nígbà táwọn aláṣẹ abúlé náà kọ̀ láti ṣàtúnṣe sí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo òfin náà, àwọn Ẹlẹ́rìí gbé ọ̀ràn náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga.
Ní July 27, 1999, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà níwájú adájọ́ ilé ẹjọ́ kan ní àgbègbè Apá Ìhà Gúúsù ìpínlẹ̀ Ohio nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Adájọ́ náà ṣèdájọ́ pé àṣẹ tí abúlé náà pa bá òfin orílẹ̀-èdè mu. Lẹ́yìn náà, ní February 20, 2001, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó wà ní Wọ́ọ̀dù Kẹfà náà tún sọ pé àṣẹ tí abúlé náà pa bá òfin mu.
Láti yanjú ọ̀ràn ẹjọ́ náà, àjọ kan tí a fòfin gbé kalẹ̀ láti máa bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn Watchtower Bible and Tract Society of New York, pa pọ̀ pẹ̀lú Ìjọ Wellsville ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Stratton bẹ̀bẹ̀ pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún ẹjọ́ náà gbọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Los Angeles
New York
OHIO
Stratton
-
-
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tẹ́wọ́ Gba Ẹjọ́ NáàJí!—2003 | January 8
-
-
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Tẹ́wọ́ Gba Ẹjọ́ Náà
LÁWỌN ỌDÚN ÀÌPẸ́ YÌÍ, gbogbo ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń tẹ́wọ́ gbà lọ́dún kan fún àyẹ̀wò kì í ju ọgọ́rin sí àádọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ̀rún méje ẹjọ́ lọ—díẹ̀ ni èyí sì fi lé ní ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún!
Ní May 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi Ìwé Ẹ̀bẹ̀ Láti Ṣàtúnyẹ̀wò Ẹjọ́ náà ránṣẹ́ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, kí wọ́n lè gbé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré ti kọ́kọ́ dá yẹ̀ wò. Ohun tó wà nínú ìwé náà rèé: “Lábẹ́ òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ǹjẹ́ ohun kan náà ni àwọn òjíṣẹ́ tó ń ṣe iṣẹ́ tó ti wà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá, tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu, ìyẹn ni iṣẹ́ sísọ nípa ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn èèyàn láti ilé dé ilé, ń ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń ta ọjà láti ojúlé dé ojúlé? Ǹjẹ́ ó sì pọn dandan fún wọn láti ṣègbọràn sí òfin ìjọba ìbílẹ̀ tó sọ pé kí wọ́n kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ kí wọ́n tó lè sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì tàbí kí wọ́n tó lè fi àwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì lọ àwọn èèyàn láìgba owó kankan?”
Ní October 15, 2001, wọ́n jẹ́ kí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní Ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà mọ̀ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti tẹ́wọ́ gba ẹjọ́ tí wọ́n pè, ìyẹn ẹjọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., pẹ̀lú Abúlé Stratton. Èyí túmọ̀ sí pé Ilé Ẹjọ́ náà ti gbà láti ṣàtúnyẹ̀wò ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré ti kọ́kọ́ dá!
Ìṣòro pàtàkì kan tó so mọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ló mú kí Ilé Ẹjọ́ náà tẹ́wọ́ gba ẹjọ́ ọ̀hún. Ìyẹn ni pé, bóyá Àtúnṣe Òfin Kìíní nínú ìwé òfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó fàyè gba òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kan ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn pàtàkì kan láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ lọ fi ara hàn lọ́dọ̀ ìjọba.
Ní báyìí, ẹnu làwọn agbẹjọ́rò tó wà fún ìhà kọ̀ọ̀kan máa fi ṣàlàyé ẹjọ́ yìí níwájú àwọn adájọ́ mẹ́sàn-án tó wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò ní àwọn agbẹjọ́rò tiwọn; Abúlé Stratton tó jẹ́ alátakò wọn náà á sì ní àwọn agbẹjọ́rò tirẹ̀. Ibo ni àpérò yìí máa wá já sí o?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
ÈWO NI WỌ́N Ń PÈ NÍ ÀTÚNṢE ÒFIN KÌÍNÍ?
“ÀTÚNṢE ÒFIN KÌÍNÍ (DÍDÁ ÌSÌN SÍLẸ̀; ÒMÌNIRA ÌSÌN, ÒMÌNIRA Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ, ÒMINIRA LÁTI TẸ̀WÉ JÁDE, ÒMINIRA LÁTI PÉJỌ PỌ̀, ÒMINIRA LÁTI KỌ̀WÉ Ẹ̀BẸ̀ SÍ ÌJỌBA) Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kò ní ṣe òfin kankan lórí ìdásílẹ̀ ìsìn, tàbí kó ka ìgbòkègbodò ìsìn ní fàlàlà léèwọ̀, tàbí kó fi òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ti kíkọ ìròyìn jáde du ẹnì kankan; bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn láti péjọ pọ̀ láìsí wàhálà, àti ẹ̀tọ́ láti kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí Ìjọba láti gbani lọ́wọ́ ìyà dù wọ́n.”—Ìwé Òfin Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
“Àtúnṣe Òfin Kìíní ni ìpìlẹ̀ fún ètò ìjọba tiwa-n-tiwa Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àtúnṣe Òfin Kìíní yìí kò fàyè gba Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti ṣe òfin tó máa ka òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, títẹ ìwé jáde, ṣíṣe ìpàdé tí kò mú wàhálà lọ́wọ́, tàbí kíkọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba nípa ohun tó ń dunni léèwọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ka òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ sí òmìnira tó ṣe pàtàkì jù lọ àti pé òun ni ìpìlẹ̀ fún gbogbo òmìnira yòókù. Bákan náà, Àtúnṣe Òfin Kìíní yìí kò fàyè gba Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti ṣe òfin pé ìsìn kan ní pàtó ni ìjọba tì lẹ́yìn, tàbí kó fi òmìnira ìsìn duni.” (The World Book Encyclopedia) Ó dùn mọ́ni pé, nínú ẹjọ́ kan tó ti wáyé ṣáájú, ìyẹn ti Cantwell pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Connecticut, tí nọ́ńbà rẹ̀ jẹ́ 310 U.S. 296 (1940), Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà dá ẹjọ́ mánigbàgbé kan tó ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn. Ilé Ẹjọ́ náà dájọ́ pé kì í ṣe “Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin” (ìjọba àpapọ̀) nìkan ni àwọn ìpinnu tó wà nínú Àtúnṣe Òfin Kìíní náà ká lọ́wọ́ kò láti má ṣe ṣe àwọn òfin tó lè tẹ àwọn ẹ̀tọ́ tó wà nínú Àtúnṣe Òfin Kìíní náà lójú, àmọ́ pé èyí tún kan àwọn ìjọba àgbègbè kọ̀ọ̀kan (ìyẹn àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀).
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn ohun tí ẹjọ́ náà ní nínú kan oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ láti ilé dé ilé
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Photograph by Franz Jantzen, Collection of the Supreme Court of the United States
-
-
Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́—Àwọn Agbẹjọ́rò Rojọ́ Níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù LọJí!—2003 | January 8
-
-
Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́—Àwọn Agbẹjọ́rò Rojọ́ Níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
FEBRUARY 26, 2002 ni ọjọ́ tí wọ́n dá, tí àwọn agbẹjọ́rò yóò ro ẹjọ́ náà níwájú Adájọ́ Àgbà, William Rehnquist àtàwọn adájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́jọ mìíràn. Àwọn agbẹjọ́rò mẹ́rin ló ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ẹni tó jẹ́ aṣáájú àwọn agbẹjọ́rò ti àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn kan tó gba àfiyèsí gbogbo àwọn tó wà nínú ilé ẹjọ́ náà, ó sọ pé: “Déédéé aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ni lọ́jọ́ Sátidé ní Abúlé Stratton. [Lẹ́yìn náà, ó fọwọ́ lu tábìlì iwájú rẹ̀ ko, ko, ko.] ‘Ẹ káàárọ̀ o. Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, mo ti sapá gidigidi láti wá sí ẹnu ọ̀nà yín láti wá bá yín sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Wòlíì Aísáyà tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ohun kan tó sàn ju àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí lọ. Ìyẹn ni ìhìn rere tí Kristi Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.’”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní Abúlé Stratton, ìwà ọ̀daràn ni wọ́n kà á sí pé kí ẹnì kan máa lọ láti ẹnu ọ̀nà kan dé òmíràn láti sọ ìhìn yẹn fún àwọn èèyàn láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ abúlé náà kó tó ṣe bẹ́ẹ̀.”
‘Ṣé Ẹ Kì Í Béèrè Owó?’
Adájọ́ Stephen G. Breyer béèrè àwọn ìbéèrè kan tó sojú abẹ níkòó lọ́wọ́ agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí. Ó béèrè pé: “Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí kì í béèrè owó kankan, ì báà má ju táṣẹ́rẹ́ lọ, àti [pé] ṣé wọn kì í ta Bíbélì, ṣé wọn kì í sì í ta ohunkóhun? Ṣé gbogbo ohun tí wọ́n kàn máa ń sọ kò ju, ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ìsìn’?”
Agbejọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí dá a lóhùn pé: “Olúwa Mi, kò sẹ́ni tí kò mọ̀ ní gbogbo Abúlé Stratton pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í béèrè owó. Bákan náà ló jẹ́ pé láwọn àgbègbè mìíràn, òtítọ́ tó ṣe kedere ni pé nígbà míì, wọ́n máa ń sọ fún àwọn èèyàn pé bí wọ́n bá fẹ́, wọ́n lè ṣe ìdáwó . . . . Kì í ṣe pé ńṣe là ń lọ láti tọrọ owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ńṣe la kàn ń gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.”
Ǹjẹ́ Ó Pọn Dandan Láti Gba Ìyọ̀ǹda Ìjọba?
Adájọ́ Antonin Scalia wá béèrè ìbéèrè olóye kan pé: “Ìyẹn ni pé, lójú tìrẹ, ko pọn dandan kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sọ́dọ̀ baálẹ̀ láti lọ gba àṣẹ kó tó lè bá aládùúgbò rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan kan tó ṣe pàtàkì?” Agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí wá dá a lóhùn pé: “A ò rò pé ó yẹ kí Ilé Ẹjọ́ yìí fọwọ́ sí òfin Ìjọba kan tó máa sọ pé aráàlú kan ní láti lọ gba ìwé àṣẹ kó tó lè bá aráàlú ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nínú ilé ẹni náà.”
Ọ̀rọ̀ Yí Padà, Ìmọ̀lára Yí Padà
Àwọn agbẹjọ́rò Abúlé Stratton lọ̀rọ̀ kàn báyìí láti sọ tẹnu wọn. Ẹni tó jẹ́ aṣáájú àwọn agbẹjọ́rò náà ṣàlàyé ìdí tí Abúlé náà fi ṣe òfin náà, ó sọ pé: “Ńṣe ni Abúlé Stratton ń lo agbára tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ kí àwọn kan má bàa máa yọ wọ́n lẹ́nu, ó sì ń gbìyànjú láti dènà ìwà ọ̀daràn. Òfin tí wọ́n gbé kalẹ̀ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ jíròrò nǹkan kan tàbí lọ tọrọ nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn nínú ilé wọn wulẹ̀ ń béèrè pé kí àwọn èèyàn kọ́kọ́ lọ forúkọ sílẹ̀ ni, kí wọ́n sì máa mú ìwé tí wọ́n fi fún wọn láṣẹ dání nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ lílọ láti ilé dé ilé.”
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Adájọ Scalia lọ sórí ohun tó pilẹ̀ ẹjọ́ náà nípa bíbéèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin adájọ́ yòókù mọ̀ bóyá ẹjọ́ kankan tiẹ̀ wà tó jọ èyí tí a [ìyẹn Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ yìí] ti bójú tó rí, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú lílọ bá èèyàn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan kan, kì í ṣe láti lọ tọrọ owó o, kì í ṣe láti lọ ta ọjà o, àní sẹ́, bí àpẹẹrẹ, bíi kéèyàn sọ pé, ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi,’ tàbí ‘Mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè dáàbò bo àyíká wa?’ Ǹjẹ́ a ti ní irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ rí?”
Adájọ́ Scalia wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mi ò rò pé wọ́n gbé irú ẹjọ́ tó jọ bẹ́ẹ̀ wá láti ohun tó lé ní igba ọdún sẹ́yìn.” Èyí mú kí Adájọ́ Àgbà, Rehnquist dápàárá pé: “O ò tíì dáyé ní gbogbo ìgbà yẹn kẹ̀.” Ni gbogbo àwọn tó wà nínú ilé ẹjọ́ náà bá kú sẹ́rìn-ín. Adájọ́ Scalia ò dákẹ́ o, àmọ́ ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ohun tuntun gbáà lèyí jẹ́ sí mi.”
Ṣé Èrò Yẹn Bọ́gbọ́n Mu?
Adájọ́ Anthony M. Kennedy ni tiẹ̀ béèrè ìbéèrè kan tó sojú abẹ níkòó, o sọ pé: “Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí n kọ́kọ́ lọ gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ Ìjọba kí n tó lè lọ sí ilé kan ládùúgbò mi, níbi tí mi ò ti mọ gbogbo ẹni tó ń gbébẹ̀, kí n [sì] sọ pé, Mo fẹ́ bá ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń gbé níbí yìí sọ̀rọ̀ nípa gbígbé àwọn pàǹtírí tẹ́ ẹ dá jọ, tàbí pé, mo fẹ́ bá yín sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin wa, tàbí irú ohun kan tó jọ bẹ́ẹ̀? Ṣé mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ sọ fún Ìjọba kí n tó lè ṣe ìyẹn ni?” Ó wá fi kún un pé, “Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí jẹ́ sí mi.”
Lẹ́yìn èyí ni Adájọ́ Sandra Day O’Connor dá sí ìjiyàn náà, ó béèrè pé: “Ó dáa, àwọn ọmọ tó máa ń lọ sílé àwọn èèyàn lásìkò ọdún láti lọ tọrọ nǹkan ńkọ́? Ṣé wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ gba àṣẹ?” Adájọ́ O’Connor àti Adájọ́ Scalia tún ń bá àlàyé wọn lọ lórí kókó yìí. Adájọ́ O’Connor bá tún gba ibòmíràn yọ, ó sọ pé: “Ká sọ pé èèyàn fẹ́ lọ yá ṣúgà kọ́ọ̀bù kan lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀ ńkọ́? Ṣé mo ní láti lọ gba àṣẹ kí n tó lè lọ yá ṣúgà kọ́ọ̀bù kan lọ́wọ́ aládùúgbò mi?”
Ṣé Ẹni Tó Ń Wá Ìtìlẹyìn Àwọn Èèyàn Kiri Làwọn Ẹlẹ́rìí Ni?
Adájọ́ David H. Souter béèrè pé: “Kí ló dé tó jẹ́ pé orí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ̀rọ̀ yìí dá lé ná? Ṣé ẹni tó ń lọ bẹ̀bẹ̀ fún ìtìlẹyìn àwọn èèyàn ni wọ́n ni, àbí nǹkan ni wọ́n ń tọrọ kiri, àbí ọjà ni wọ́n ń kiri, àbí ó ní iṣẹ́ tí wọ́n ń lọ ṣe fáwọn èèyàn nílé wọn ni? Wọn kì í ṣe ọ̀kankan lára èyí, àbí?” Lọ́yà tó ń ṣojú Abúlé Stratton náà wá ka púpọ̀ lára ohun tí òfin náà sọ, ó sì wá fi kún un pé ilé ẹjọ́ kékeré ti sọ pé ẹni tó ń wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn kiri làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí ló mú kí Adájọ́ Souter dá a lóhùn pé: “A jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀ lo ní fún lílọ wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn kiri, tó o bá ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”
Adájọ́ Breyer bá ka ìtumọ̀ tó wà fún lílọ wá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn jáde látinú ìwé atúmọ̀ èdè láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà kò bá àwọn Ẹlẹ́rìí mu. Ó tún fi kún un pé: “Mi ò tíì rí nǹkan kan nínú ìwé ẹjọ́ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ síbí tó ṣàlàyé ète tẹ́ ẹ fi ṣòfin pé kí àwọn èèyàn yìí [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] máa lọ sí gbọ̀ngàn ìlú láti lọ forúkọ sílẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé kì í ṣe pé torí owó ni wọ́n ṣe ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn, tí kì í ṣe torí àtilọ tajà, tí kì í sì ṣe pé wọ́n ń lọ polongo ìbò. Kí nìdí tí ìlú náà fi ṣòfin yìí gan-an ná?”
Ìyẹn Ni Pé “Àǹfààní” Ló Jẹ́ Láti Báni Sọ̀rọ̀
Lọ́yà Abúlé náà wá sọ pé, “ìdí tí ìlú yìí fi ṣe òfin náà ni pé wọn ò fẹ́ ohun tó máa fa ìbínú àwọn onílé.” Ó tún ṣàlàyé síwájú sí i pé, wọ́n ṣòfin náà torí àtilè dáàbò bo àwọn tó ń gbébẹ̀ lọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀ àtàwọn ọ̀daràn. Adájọ́ Scalia fa ọ̀rọ̀ kan yọ nínú òfin náà láti fi hàn pé baálẹ̀ náà tún lè béèrè ìsọfúnni síwájú sí i lẹ́nu ẹni tó wá forúkọ sílẹ̀ náà àti ète tó fi wá, kó bàa lè “ṣeé ṣe láti mọ ohun tó fẹ́ lo àǹfààní náà fún.” Ó wá là á mọ́lẹ̀ pé: “Ìyẹn ni pé, níbàámu pẹ̀lú òfin yín, àǹfààní lẹ̀yín kà á sí fún ẹnì kan láti lọ bá aráàlú ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan—èmi ò tiẹ̀ rò pé ìyẹn bọ́gbọ́n mu rárá.”
Adájọ́ Scalia tún béèrè pé: “Ṣé pé gbogbo ẹni tó bá fẹ́ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé kan gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ tẹ̀ka ní ọ́fíìsì ìjọba [kó] tó ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé ìbẹ̀rù pé kí ìwà ọ̀daràn má ṣẹlẹ̀ tó ohun téèyàn á fi sọ pé kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé kan lọ máa forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò tóyẹn.”
Ṣé Lóòótọ́ Ni Òfin Yẹn Dáàbò Bo Àwọn Aráàlú?
Nígbà tí ogún ìṣẹ́jú tí wọ́n fún agbẹjọ́rò Abúlé náà láti sọ̀rọ̀ pé, ó fa ọ̀rọ̀ lé amòfin àgbà fún ìpínlẹ̀ Ohio lọ́wọ́. Amòfin àgbà náà sọ pé, òfin máà-lọ-tọrọ-nǹkan-nílé-èèyàn yìí dáàbò bo àwọn ará abúlé náà lọ́wọ́ ìbẹ̀wò àwọn àjèjì, “dájúdájú, àjèjì ni èèyàn kan tí mi ò ké sí, [ẹni] tó wá sí ilé mi . . . látàrí èyí, mo rò pé abúlé náà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé, ‘Irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ kò fi wá lọ́kàn balẹ̀.’”
Adájọ́ Scalia wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Ìyẹn ni pé ohun tí abúlé náà ń sọ ni pé, ká tiẹ̀ ní àwọn èèyàn tí wọ́n á fẹ́ tẹ́wọ́ gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wà nínú ilé wọn láìrẹ́ni bá sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì fẹ́ kẹ́nì kan wá bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun, síbẹ̀, dandan ni kí àwọn èèyàn yìí [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] lọ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ baálẹ̀ kí wọ́n tó lè ní àǹfààní láti lọ tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.”
“Ìkálọ́wọ́kò Yẹn Kò Le Jù Rárá”
Láàárín àkókò tí àríyànjiyàn yẹn ń lọ lọ́wọ́, Adájọ́ Scalia, sọ kókó kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó sọ pé: “Gbogbo wa la gbà pé àwọn àgbègbè tó bọ́ lọ́wọ́ ewu jù lọ láyé làwọn ibi tí ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ ti ń ṣàkóso. Ìwà ọ̀daràn kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nírú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ bẹ́ẹ̀, àti pé, lára àwọn ìṣòro tí òmìnira máa ń dá sílẹ̀, dé ìwọ̀n àyè kan, ni ìwàkiwà tó máa ń pọ̀ gan-an. Kókó tó wá wà níbẹ̀ ni pé, bóyá ìwà ọ̀daràn tí òfin yìí máa jẹ́ kó dín kù tó nǹkan téèyàn ń lọ fọwọ́ síwèé kó tó lè ní àǹfààní láti tẹ aago ẹnu ọ̀nà ilé ẹnì kan.” Amòfin àgbà dá a lóhùn pé “ìkálọ́wọ́kò yẹn kò le jù rárá.” Bẹ́ẹ̀ ni Adájọ́ Scalia fèsì padà pé, kò le jù rárá lóòótọ́, ìyẹn náà “la ò fi rí ẹyọ ẹjọ́ kan ṣoṣo tí wọ́n tíì gbé wá síbí tó fi hàn pé ìjọba ìbílẹ̀ kan ṣe irú òfin bẹ́ẹ̀ jáde rí. Èmi ò gbà pé ìkálọ́wọ́kò yẹn kò le jù rárá.”
Níkẹyìn, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn adájọ́ náà tún sọ irú ohun kan náà, ni amòfin àgbà bá juwọ́ sílẹ̀, ó sì sọ pé: “Mi ò jẹ́ fara mọ́ ọn pé kí ẹnì kan ṣe òfin tó máa sọ pé àwọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ lọ tẹ aago ẹnu ọ̀nà tàbí kan ilẹ̀kùn ilé ẹlòmíràn.” Gbólóhùn tó sọ yìí ló fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí ń ta ko ohun tí agbẹjọ́rò Abúlé Stratton náà sọ, ó sọ pé, òfin náà kò ní ohun tí wọ́n lè fi mọ̀ bóyá ohun tẹ́nì kan pe ara rẹ̀ ló jẹ́ lóòótọ́. Ó ní: “Mo lè lọ sí ọ́fíìsì àwọn aláṣẹ abúlé náà kí n sì sọ pé, ‘Orúkọ mi ni [báyìí-báyìí],’ kí wọ́n sì fún mi láṣẹ láti máa lọ láti ojúlé dé ojúlé.” Ó tún sọ pé baálẹ̀ náà lágbára láti kọ̀ láti fún ẹni tó bá sọ pé òun kì í ṣe ara ẹgbẹ́ kan ní ìyọ̀ǹda. Ó wá sọ pé: “A gbà pé èyí kò yàtọ̀ sí lílo agbára tó wà ní ìkáwọ́ ẹni láti pinnu ohun téèyàn fẹ́ fún ẹlòmíràn,” ó sì fi kún un pé: “Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni mo fi sọ pé, iṣẹ́ àwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà] bá ohun tí Àtúnṣe Òfin Kìíní sọ mú dáadáa.”
Kété lẹ́yìn èyí, Adájọ́ Àgbà Rehnquist fòpin sí atótónu àwọn agbẹjọ́rò náà, ó sì sọ pé: “Ọwọ́ [Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ] ni ẹjọ́ náà kù sí.” Gbogbo àkókò tí àríyànjiyàn náà gbà kò ju wákàtí kan ó lé díẹ̀ lọ. Àmọ́, ìdájọ́ tí wọ́n kéde rẹ̀ lóṣù June ló máa fi bí wákàtí kan yẹn ṣe ṣe pàtàkì tó hàn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Adájọ́ Àgbà Rehnquist
Adájọ́ Breyer
Adájọ́ Scalia
[Àwọn Credit Line]
Rehnquist: Collection, The Supreme Court Historical Society/Dane Penland; Breyer: Collection, The Supreme Court Historical Society/Richard Strauss; Scalia: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Lavenburg
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Adájọ́ Kennedy
Adájọ́ O’Connor
Adájọ́ Souter
[Àwọn Credit Line]
Kennedy: Collection, The Supreme Court Historical Society/Robin Reid; O’Connor: Collection, The Supreme Court Historical Society/Richard Strauss; Souter: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Bailey
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Inú yàrá ilé ẹjọ́ tí wọ́n ti dájọ́ náà
[Credit Line]
Photograph by Franz Jantzen, Collection of the Supreme Court of the United States
-
-
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ SísọJí!—2003 | January 8
-
-
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Fọwọ́ Sí Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ
ỌJỌ́ ÌDÁJỌ́ NÁÀ pé ní June 17, 2002, ìyẹn ọjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbé ìpinnu rẹ̀ jáde. Ìdájọ́ wo ni wọ́n ṣe? Àkọlé àwọn ìwé ìròyìn sọ àbájáde rẹ̀. Ìwé ìròyìn The New York Times kéde pé: “Ilé Ẹjọ́ Mú Òfin Tí Wọ́n Fi De Ìbẹ̀wò Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Ṣe Kúrò.” Ìwé ìròyìn The Columbus Dispatch ti ìpínlẹ̀ Ohio sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Gíga Wọ́gi Lé Òfin Lílọ Gba Ìyọ̀ǹda.” Ìwé ìròyìn The Plain Dealer ti ìlú Cleveland, ìpínlẹ̀ Ohio, wulẹ̀ sọ ní tirẹ̀ pé: “Kò Pọn Dandan Káwọn Tó Ń Lọ Béèrè Nǹkan Nílé Àwọn Èèyàn Gba Ìyọ̀ǹda Ìjọba Ìbílẹ̀.” Àkọlé ìròyìn tó fara hàn lójú ewé tó dojú kọ ti ọ̀rọ̀ olóòtú nínú ìwé ìròyìn USA Today kéde pé: “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ Borí.”
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti wọ́gi lé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ kékeré dá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì wáyé látàrí bí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án ṣe fọwọ́ sí ìpinnu náà! Adájọ́ John Paul Stevens ló kọ àkọsílẹ̀ olójú ewé méjìdínlógún tí Ilé Ẹjọ́ náà gbé ìdájọ́ rẹ̀ kà. Ìdájọ́ náà túbọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nílé-lóko pé, Àtúnṣe Òfin Kìíní náà ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lẹ́yìn. Nínú àkọsílẹ̀ náà, Ilé Ẹjọ́ ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi lọ gba ìyọ̀ǹda náà ni pé, wọ́n ní “inú Ìwé Mímọ́ làwọ́n ti rí àṣẹ láti máa wàásù.” Lẹ́yìn èyí ni àwọn adájọ́ náà wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ àlàyé wọn sí, èyí tó kà báyìí pé: “Bí a bá ń lọ gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ ká tó wàásù, bí ìgbà tí à ń tàbùkù sí Ọlọ́run ló rí.”
Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà kà pé: “Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí tí Ilé Ẹjọ́ yìí ti ń wọ́gi lé òfin táwọn kan ń fi de wíwá ìtìlẹyìn àwọn èèyàn láti ojúlé dé ojúlé àti pípín ìwé kiri. Kì í ṣe ohun tó kàn ń ṣàdéédéé ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn pé, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹjọ́ yìí ló máa ń dá lórí ṣíṣàìka Àtúnṣe Òfin Kìíní sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì máa ń mú un wá síwájú ilé ẹjọ́ yìí, nítorí pé ìsìn wọn béèrè pé kí wọ́n máa lọ láti ojúlé dé ojúlé. Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Murdock àti Ìpínlẹ̀ Pennsylvania, . . . (1943), àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘sọ pé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù làwọ́n ń tẹ̀ lé, nípa kíkọ́ni “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Ìṣe 20:20. Wọn ò fọwọ́ kékeré mú àṣẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé, “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.” Máàkù 16:15. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé àṣẹ Ọlọ́run làwọ́n ń pa mọ́.’”
Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà tún fa ọ̀rọ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sí i látinú ẹjọ́ tó wáyé lọ́dún 1943 náà, ó sọ pé: “Lábẹ́ Àtúnṣe Òfin Kìíní, bí jíjọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti wíwàásù lórí àga ìwàásù ṣe ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìsìn yìí ṣe ṣe pàtàkì. Báwọn ìsìn tó ti wà tipẹ́ àtàwọn tó gbajúmọ̀ gan-an ṣe bófin mu lòun náà bófin mu.” Nígbà tí Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹjọ́ kan tó wáyé lọ́dún 1939, ó sọ pé: “Láti máa sọ pé káwọn èèyàn máa forúkọ sílẹ̀ nípa gbígba ìwé àṣẹ, èyí tí kò ní í jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti pín ìwé kiri ní fàlàlà láìsí ìdíwọ́, lòdì pátápátá sí ohun tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè yìí.”—Àwọn ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí ní lẹ́tà wínníwínní.
Ilé Ẹjọ́ náà wá sọ kókó kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ó sọ pé: “Àwọn ẹjọ́ wọ̀nyí fi hàn pé akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti má ṣe fara mọ́ òfin tó bá de ọ̀rọ̀ sísọ kì í ṣe ìjà tí wọ́n ń jà fún ẹ̀tọ́ tiwọn nìkan.” Àkọsílẹ̀ náà ṣàlàyé pé, àwọn Ẹlẹ́rìí “nìkan kọ́ làwọn ‘mẹ̀kúnnù’ tó ṣeé ṣe kí wọ́n di ẹni tí a fi òfin pa lẹ́nu mọ́ nípasẹ̀ irú àwọn òfin tí Abúlé náà ṣe.”
Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ ní sísọ pé “kì í ṣe pé” òfin náà “tàbùkù àwọn ìlànà tí Àtúnṣe Òfin Kìíní gbà láyè nìkan ni, àmọ́ ó tún tako òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó yẹ kó wà láwùjọ àwọn èèyàn tó wà lómìnira—ìyẹn nígbà tá a bá ń sọ pé aráàlú gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lọ sọ fún ìjọba pé òun fẹ́ bá aládùúgbò òun fọ̀rọ̀ wérọ̀, àti pé ó ní láti gba ìyọ̀ǹda kó tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Òfin kan tó ń sọ pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gba ìyọ̀ǹda kí wọ́n tó lè bá ẹlòmíràn fọ̀rọ̀ wérọ̀ ti yà kúrò pátápátá nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè wa tí òfin tì lẹ́yìn.” Àkọsílẹ̀ náà wá sọ nípa “aburú ńlá tí irú òfin bẹ́ẹ̀ máa ṣe.”
Ewu Ìwà Ọ̀daràn
Ojú wo ni Ilé Ẹjọ́ Gíga fi wo èrò àwọn aláṣẹ abúlé náà pé torí àtidáàbò bo àwọn aráàlú lọ́wọ́ àwọn fọ́léfọ́lé àtàwọn ọ̀daràn ni àwọn fi ṣe ṣòfin gbígba ìyọ̀ǹda náà? Ilé Ẹjọ́ náà ṣàlàyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbà pé àníyàn tí wọ́n ń ṣe nípa ọ̀ràn ààbò yẹn bọ́gbọ́n mu, àwọn ẹjọ́ tá a ti dá rí ti mú kó ṣe kedere pé, a ò gbọ́dọ̀ torí pé a fẹ́ dènà ìwà ọ̀daràn ká wá fojú kéré àkóbá tí irú òfin bẹ́ẹ̀ máa ṣe fún ohun tí Àtúnṣe Òfin Kìíní gbà láyè.”
Àkọsílẹ̀ Ilé Ẹjọ́ náà ń tẹ̀ síwájú pé: “Kò jọ pé ṣíṣàìgba ìyọ̀ǹda yìí á dí àwọn ọ̀daràn lọ́wọ́ láti má ṣe lọ kan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí òfin náà kò mẹ́nu kàn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kí àwọn èèyàn júwe ọ̀nà fún àwọn tàbí kí wọ́n ní kí wọ́n yá àwọn ní tẹlifóònù wọn lò, . . . tàbí kí wọ́n kọ orúkọ olórúkọ sílẹ̀, tí kò sì ní sí ìjìyà kankan fún wọn.”
Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ náà ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹjọ́ tí wọ́n dá ní ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní 1940, wọ́n kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tá a lò nínú àkọsílẹ̀ àwọn ẹjọ́ tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó dá àwọn ẹlẹ́sìn tó mú ẹjọ́ yìí wá [ìyẹn Watch Tower Society] sílẹ̀ léraléra lọ́wọ́ àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn wọ́n nítorí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí wọn, fi hàn pé Ilé Ẹjọ́ yìí ti gbé àwọn òmìnira tí Àtúnṣe Òfin Kìíní pèsè yẹ̀ wò dáadáa, èyí tí ẹjọ́ yìí dá lé.”
Báwo ni wọ́n wá ṣe dá ẹjọ́ yìí? Ìdájọ́ wọn ni pé: “Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti yí ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣe padà, a sì ti dá ẹjọ́ náà padà síbẹ̀ fún àgbéyẹ̀wò síwájú sí i níbàámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ wa. A pa á láṣẹ bẹ́ẹ̀.”
Ibi tí ẹjọ́ náà parí sí nìyẹn. Ìwé ìròyìn Chicago Sun-Times sọ pé: “Ilé Ẹjọ́ Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́yìn,” èyí sì wáyé látàrí bí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án ṣe fọwọ́ sí ìpinnu náà.
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?
Ojú wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ìjọ Wellsville nítòsí abúlé Stratton fi wo ìjagunmólú wọn yìí ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ? Kò sí ìdí kankan fún wọn láti máa fi yangàn kí ojú lè ti àwọn olùgbé Stratton. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò ní èrò òdì kankan lọ́kàn sí àwọn ọmọlúwàbí èèyàn tó ń gbé ní abúlé náà. Gregory Kuhar tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀ sọ pé: “Kì í ṣe pé ó wù wá láti ṣẹjọ́ rárá. Ó kàn jẹ́ pé òfin tí wọ́n gbé jáde náà kò bójú mu ni. Kì í ṣe àwa nìkan lohun tá a ṣe yìí wà fún, àmọ́ gbogbo èèyàn ni.”
Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé àwọn ò mú àwọn èèyàn ìlú náà bínú. Gene Koontz, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí níbẹ̀, ṣàlàyé pé: “March 7, 1998 la ti wàásù kẹ́yìn ní abúlé Stratton—ìyẹn ti lé lọ́dún mẹ́rin báyìí.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n dìídì sọ fún mi pé àwọn á fi ọlọ́pàá mú mi bi mo bá wàásù. Ọ̀pọ̀ ọdún la fi gbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìròyìn nípa bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń halẹ̀ pé ńṣe làwọ́n máa tì wá mọ́lé. Nígbà tá a sì béèrè pé kí wọ́n jẹ́ ká rí ibi tí wọ́n kọ òfin náà sí, wọn ò fún wa lésì kankan.”
Koontz fi kún un pé: “A fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn aládùúgbò wa. Bí àwọn kan bá sọ pé àwọn ò fẹ́ ká wá sílé àwọn, a óò bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wọn. Àmọ́ àwọn mìíràn wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí wa tí wọ́n sì ń gbà ká máa bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì.”
Gregory Kuhar ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe láti di ọ̀tá àwọn èèyàn Stratton ló mú wa tẹpẹlẹ mọ́ ẹjọ́ yìí. A wulẹ̀ fẹ́ fìdí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wa múlẹ̀ lábẹ́ Òfin ni.”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Bópẹ́bóyá, a retí láti padà lọ máa wàásù ní Stratton. Inú mi á dùn láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ilé kan nígbà tá a bá padà síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Kristi ti pa á láṣẹ, dandan ni pé ká padà lọ.”
Ipa kékeré kọ́ ni àbájáde ẹjọ́ tó wà láàárín “Watchtower pẹ̀lú Abúlé Stratton” yìí ti ní o. Lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbọ́ nípa ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà, wọ́n rí i pé àwọn kò lè lo òfin tí ìjọba ìbílẹ̀ bá ṣe mọ́ láti fi gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rùn-ún àgbègbè ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tí àwọn ìṣòro tó so mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ti di èyí tó yanjú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
“ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ TÚN TI JÀRE NÍ ILÉ ẸJỌ́ GÍGA JÙ LỌ”
Charles C. Haynes, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó sì tún jẹ́ alága ètò tó ń la àwọn èèyàn lọ́yẹ̀ nípa Àtúnṣe Òfin Kìíní, ló kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí lábẹ́ àkọlé náà, “Òmìnira Ìsìn,” èyí tí iléeṣẹ́ ìròyìn MSNBC tó máa ń ròyìn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì gbé jáde. Haynes ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lọ́sẹ̀ tó kọjá, [àwọn Ẹlẹ́rìí] tún ti jagun mólú ní ìgbà Kejìndínláàádọ́ta ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ—àwọn ẹjọ́ yìí sì ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ti pé, wọ́n ti mú kí ẹ̀tọ́ àwọn ará Amẹ́ríkà lábẹ́ Àtúnṣe Òfin Kìíní gbòòrò sí i.” Ó wá kìlọ̀ pé: “Ẹ máa rántí kókó yìí o: Bí ìjọba bá lè gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira ìsìn kan, ó lágbára láti gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira ìsìn èyíkéyìí— tàbí ti gbogbo ìsìn. . . . Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn kò fẹ́ gbọ́— kí wọ́n sì ti ilẹ̀kùn wọn. Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé ìjọba ni yóò wá máa pàṣẹ pé ẹni báyìí làwọ́n fún láṣẹ láti máa kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn. Fún ìdí yìí, a gbóṣùbà fún Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ.”
Haynes wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Gbogbo wa la jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbèsè ọpẹ́. Láìka iye ìgbà tí wọ́n lè tàbùkù wọn sí, tí wọ́n á lé wọn jáde nínú ìlú, tàbí tí wọ́n á tiẹ̀ lù wọ́n pàápàá, wọn ò jẹ́ jáwọ́ nínú jíjà fún òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn (wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jà fún òmìnira ìsìn tiwa náà). Nígbà tí wọ́n bá sì jàre, gbogbo wa là ń jàǹfààní rẹ̀.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Ohun Tí Àwọn Ìwé Ìròyìn Sọ Nípa—Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
◼ “Ilé Ẹjọ́ Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́yìn; Ìwàásù Ilé-dé-Ilé Kò Nílò Gbígba Ìyọ̀ǹda
Nínú iṣẹ́ kíkan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, ìgbà gbogbo ni [àwọn Ẹlẹ́rìí] gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń ti àwọn lẹ́yìn. Ní báyìí, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà tún ti tì wọ́n lẹ́yìn.”—Ìwé Ìròyìn Chicago Sun-Times, June 18, 2002.
◼ “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ Borí
Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbi tó o ti ń jẹun lọ́wọ́, á dára kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Nípa fífi tọkàntara tẹ̀ lé ìlànà ìsìn wọn, ìsìn tó yàtọ̀ sí gbogbo ìsìn tó kù yìí, tí àwọn tó ń ṣe é [ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] fi díẹ̀ dín ní mílíọ̀nù kan, ti ṣe ju gbogbo àwọn àjọ mìíràn lọ láti rí i pé tẹrútọmọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. . . .
“Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí, lílọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́. Nínú ẹjọ́ tó ju mẹ́rìnlélógún lọ láàárín ọdún márùnlélọ́gọ́ta, wọ́n ti borí lílò tí àwọn tó pọ̀ jù wọ́n lọ ń lo agbára òdì lórí wọn.”—Ìwé Ìròyìn USA TODAY, June 18, 2002.
◼ “Lílọ Láti Ilé Dé Ilé Bófin Mu. Ìjagunmólú Lèyí Jẹ́ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà pàṣẹ lọ́jọ́ Monday pé, àwọn olóṣèlú, àwọn onísìn, àwọn ẹgbẹ́ Girl Scouts àtàwọn mìíràn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti máa lọ láti ilé dé ilé láti sọ̀rọ̀ nípa ìlànà wọn láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ ń gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀.”—Ìwé Ìròyìn San Francisco Chronicle, June 18, 2002.
◼ “Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Sọ Pé: Kò Sẹ́ni Tó Lè Ní Kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Àtàwọn Ẹgbẹ́ Girl Scouts Má Ṣe Kan Ilẹ̀kùn Àwọn Èèyàn
WASHINGTON—Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti sọ lónìí pé, . . . lábẹ́ Òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òṣèlú, àtàwọn mìíràn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa kan ilẹ̀kùn àwọn èèyàn láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ ń gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀.
“Nínú ìdájọ́ tí àwọn adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án fọwọ́ sí, ilé ẹjọ́ náà sọ pé, lára àwọn ẹ̀tọ́ òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí Àtúnṣe Òfin Kìíní fàyè gbà ni pé, èèyàn lè lọ sí ẹnu ọ̀nà ẹnì kan ní tààràtà kó sì lọ sọ nǹkan kan fún onítọ̀hún.”—Ìwé Ìròyìn Star Tribune, Minneapolis, June 18, 2002.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Adájọ́ Stevens
[Credit Line]
Stevens: Collection, The Supreme Court Historical Society/Joseph Bailey
-