KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÌJỌBA ỌLỌ́RUN—ÀǸFÀÀNÍ WO LÓ MÁA ṢE Ẹ́?
Ìjọba Ọlọ́run Kí Nìdí Tó fi Ṣe Pàtàkì Gan-an sí Jésù?
Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sọ nínú ìwàásù rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà, bí wọ́n ṣe lè mú inú Ọlọ́run dùn àti bí wọ́n ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́. (Mátíù 6:5-13; Máàkù 12:17; Lúùkù 11:28) Àmọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù fẹ́ràn láti máa sọ jù nínú ìwàásù rẹ̀, torí pé ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ nìyẹn.—Lúùkù 6:45.
Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jésù fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ “wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run. (Lúùkù 8:1) Tẹ̀mítẹ̀mí ló fi ṣe é, kódà ó rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì kó lè kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ ìwàásù Jésù wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìgbà tí “Ìjọba Ọlọ́run” fara hàn nínú àwọn ìwé náà, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú èyí ló jẹ́ ọ̀rọ̀ Jésù, ìwọ̀nyí ò sì tó nǹkan nínú gbogbo ohun tí Jésù sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run!—Jòhánù 21:25.
Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an sí Jésù? Ohun kan ni pé Ọlọ́run ti yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Alákòóso Ìjọba náà. (Aísáyà 9:6; Lúùkù 22:28-30) Ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé Jésù fẹ́ di ọba tàbí torí kó lè dé ipò ọlá ni ọ̀rọ̀ Ìjọba náà fi jẹ ẹ́ lógún tó bẹ́ẹ̀. (Mátíù 11:29; Máàkù 10:17, 18) Ó ṣe tiẹ̀ fún Ọlọ́run ni, tọkàntọkàn ló sì fi gbé Ìjọba náà lárugẹ. Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí Jésù gan-an nítorí pé Ìjọbaa náà máa ṣe nǹkan pàtàkì fún Jèhófà baba rẹ̀ Ọ̀run àti gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́.
OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE FÚN JÈHÓFÀ
Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run dọ́kàn. (Òwe 8:30; Jòhánù 14:31) Kò sì sóhun méjì tó fà á ju pé Baba rẹ̀ ní àwọn ànímọ́ àtàtà tó fa Jésù mọ́ra gidigidi, àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, àánú àti ìdájọ́ òdodo. (Diutarónómì 32:4; Aísáyà 49:15; 1 Jòhánù 4:8) Ó dájú pé ó ń dun Jésù bí àwọn èèyàn ṣe ń purọ́ mọ́ Baba rẹ̀, àgàgà bí wọ́n ṣe ń sọ kiri pé Ọlọ́run ò rí tiwa rò àti pé ó tẹ́ ẹ lọ́rùn bá a ṣe ń jìyà. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi máa ń hára gàgà láti kéde “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run,” ó kúkú mọ̀ pé Ìjọba yẹn ló máa fi àwọn òpùrọ́ hàn ní elékèé, tá á sì sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́. (Mátíù 4:23; 6:9, 10) Àmọ́ ọ̀nà wo ni Ìjọba náà máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
Ìjọba tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Jèhófà máa lò láti ṣe àwọn ìyípadà gbankọgbì tí yóò mú ìdẹ̀ra bá aráyé. Bíbélì sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù” kúrò ní ojú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ olódodo. Àní Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ń fa omijé kúrò pátápátá, “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ìjọba yìí ni Ọlọ́run á fi yanjú gbogbo ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn.b
Abájọ tó fi máa ń yá Jésù lára láti sọ fún àwọn èèyàn nípa Ìjọba náà! Ó mọ̀ pé Ìjọba yẹn máa gbé Jèhófà ga bí Ọlọ́run alágbára àti Bàbá oníyọ̀ọ́nú. (Jákọ́bù 5:11) Jésù tún mọ̀ pé Ìjọba náà máa ṣe àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ olódodo láǹfààní.
OHUN TÍ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE FÚN ÀWỌN OLÓDODO
Jésù ti ń gbé lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó wá sáyé. Òun ni Ọlọ́run lò láti ṣẹ̀dá ohun gbogbo tá à ń rí, látorí ìsálú ọ̀run tó kún fọ́fọ́ fún àìmọye onírúurú ìràwọ̀ àtàwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ títí dórí arabaríbí pílánẹ́ẹ̀tì wa àtàwọn ohun alààyè inú rẹ̀. (Kólósè 1:15, 16) Àmọ́ nínú gbogbo ohun mèremère yìí, àwa èèyàn ni Jésù “ní ìfẹ́ni” àrà ọ̀tọ̀ sí.—Òwe 8:31.
Jésù fi hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé lóòótọ́ ni òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti sọ pé nítorí kí òun lè “polongo ìhìn rere” fún àwọn òtòṣì ni òun ṣe wá sáyé. (Lúùkù 4:18) Ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹnu lásán ni Jésù fi sọ ọ́. Lemọ́lemọ́ ló fi hàn nínú ìṣe rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nìgbà tí Jésù rí ogunlọ́gọ̀ ńlá tó wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, “àánú wọn ṣe é, ó sì wo àwọn aláìsàn wọn sàn.” (Mátíù 14:14) Èyí mú wa rántí ọkùnrin tó wà nínú ìrora àrùn burúkú kan, tó lo ìgbàgbọ́ pé bí Jésù bá sáà ti fẹ́, ó lè mú òun lára dá. Ìfẹ́ mú kí Jésù ṣàánú ọkùnrin náà, ó wí pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí ìwọ mọ́.” Ni àrùn náà bá pòórá. (Lúùkù 5:12, 13) Jésù tún rí Màríà ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń ṣọ̀fọ̀ ikú àbúrò rẹ̀ Lásárù, Jésù “kérora nínú ẹ̀mí,” “ó dààmú,” ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:32-36) Ọjọ́ kẹrin rèé tí Lásárù ti kú, síbẹ̀, Jésù ṣe ohun ìyanu lọ́jọ́ náà, ó jí Lásárù dìde wá sí ìyè!—Jòhánù 11:38-44.
Ṣùgbọ́n Jésù mò pé ìtura ráńpẹ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí lè mú wá. Bó pẹ́ bó yá, àwọn tí ó wò sàn á tún ṣàìsàn, àwọn tí ó sì jí dìde ṣì máa kú. Síbẹ̀, Jésù gbà pé Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìṣòro náà. Ìdí nìyẹn tí Jésù ò ṣe fọ̀rọ̀ náà mọ sórí iṣẹ́ ìyanu nìkan; ó tún fi ìtara wàásù “ìhìn rere Ìjọba náà.” (Mátíù 9:35) Ní ti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, kékeré la tíì rí, ó ṣì máa dárà kárí ayé nínú Ìjọba Ọlọ́run. Díẹ̀ rèé nínú àwọn ìlérí Bíbélì tó ń bọ̀ wá ṣẹ lọ́jọ́ ọ̀la.
Kò ní sí àìsàn mọ́.
“Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” Láfikún, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ńṣe mí.’”—Aísáyà 33:24; 35:5, 6.
Kò ní sí ikú mọ́.
“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
“Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.
Àwọn tó ti kú á pa dà wá sí ìyè.
“Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.
“Àjíǹde yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
Àìrílégbé àti àìríṣẹ́ kò ní sí mọ́.
“Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21, 22.
Ogun á kásẹ̀ nílẹ̀.
“Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.
“Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.
Oúnjẹ á tó, á tún ṣẹ́ kù.
“Ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”—Sáàmù 67:6.
“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
Àwọn èèyàn ò ní tòṣì mọ́.
“A kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì.”—Sáàmù 9:18.
“Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, Ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, Yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12, 13.
Ẹ ò rí i pé àwọn ìlérí tá a gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí ìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì gan-an sí Jésù. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó máa ń yá a lára láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo ẹni tó bá fetí sílẹ̀, nítorí ó mọ̀ pé Ìjọba náà ló máa yanjú àwọn ìṣòro tó ń bá aráyé fínra lónìí.
Ǹjẹ́ àwọn ìlérí nípa Ìjọba yìí fún ẹ láyọ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run? Kí lo lè ṣe tí wàá fi gbádùn àwọn ìbùkún tó máa mú wá lọ́jọ́ iwájú? Àkòrí tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
a Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí Jésù ń bẹ láàyè lọ́run, ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ò sì kúrò lọ́kàn rẹ̀ látìgbà tó ti pa dà sí ọ̀run.—Lúùkù 24:51.
b Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà fún àkókò kan, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.