OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?
Bíbélì fi hàn pé, gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀. Látọ̀dọ̀ Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́, ni a ti jogún èròkérò tó máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, nígbà míì a lè ṣe ohun tó burú, tí à á wá máa kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá. Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, kú nítorí tiwa, kó lè san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti jogún. Ẹbọ ìràpadà rẹ̀ ló mú ká lè máa rí ìdáríjì gbà. Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa ni.—Ka Róòmù 3:23, 24.
Àwọn kan tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń wò ó pé bóyá ni Ọlọ́run lè dárí jì wọ́n. Àmọ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Jòhánù 1:7) Kódà, tí ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá bá tiẹ̀ burú jáì, Jèhófà máa dárí jì wá pátápátá, tí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Ka Aísáyà 1:18.
Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá?
Tí a bá fẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run dárí jì wá, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ìyẹn ni pé ká lóye bó ṣe máa ń ṣe nǹkan, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ àti àwọn ohun tó ń fẹ́ ká ṣe. (Jòhánù 17:3) Tayọ̀tayọ̀ ni Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó ronú pìwà dà, tí wọ́n kọ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì sapá láti yí ìwà wọn pa dà.—Ka Ìṣe 3:19.
Kò ṣòro láti rí ojú rere Ọlọ́run, torí pé Jèhófà mọ ibi tí a kù sí. Aláàánú àti onínúure ni. Ǹjẹ́ bí Jèhófà ṣe ń ṣàánú wa tìfẹ́tìfẹ́ mú kó wù ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wàá ṣe máa ṣe ohun tó fẹ́?—Ka Sáàmù 103:13, 14.