BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Mi Ò Kì Í Ṣe Ẹrú Ìwà Ipá Mọ́”
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1956
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: Canada
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ẹni táyé ti sú, oníṣekúṣe àti oníwà ipá
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ
Ìlú kan tó wà ní Calgary, Albarta lórílẹ̀-èdè Kánádà ni wọ́n ti bí mi. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọwọ́, àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀, lèmi àti ìyá mi bá kó lọ sílé àwọn òbí mi àgbà. Àwọn òbí mi àgbà nífẹ̀ẹ́ èmi àti ìyá mi gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kémìí náà máa láyọ̀. Inú mi ṣì máa ń dùn gan-an tí mo bá ń rántí àwọn àkókò mánigbàgbé yẹn.
Mi ò tíì ju ọmọ ọdún méje lọ tí ìgbésí ayé mi fi dìdàkudà. Màmá mi àti bàbá mi tún pa dà fẹ́ra wọn, a sì kó lọ sí St. Louis ní ìpínlẹ̀ Missouri lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Kò pẹ́ tí mo fi wá mọ̀ pé bàbá mi rorò gan-an. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí mo délé láti ilé ìwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi mí sí, bàbá mí mọ̀ pé àwọn ọmọ ilé ìwé mi halẹ̀ mọ́ mi nílé ìwé, àmọ́ mi ò gbẹ̀san. Inú bí bàbá mi gan-an lọ́jọ́ tí mò ń sọ yìí, mo sì jẹ dẹndẹ ìyà tó ju èyí tàwọn ẹlẹgbẹ́ mi nílé ìwé fi jẹ mí lọ! Mo fi ohun tí bàbá mí kọ́ mi lọ́jọ́ yẹn sọ́kàn pé ó yẹ kí n máa gbẹ̀san, mi ò sì tíì ju ọmọ ọdún méje náà lọ tí mo fi jà fúngbà àkọ́kọ́.
Inú màmá mi kì í dùn sí bí bàbá mi ṣe máa ń bínú sódì, èyí sì máa ń fa ìjà láàárín wọn, ọ̀pọ̀ ìgbà sì rèé, ńṣe ni wọ́n máa ń pariwo mọ́ ara wọn. Ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mí nígbà ti mo bẹ̀rẹ̀ sí í mutí yó, tí mo sì ń lo oògùn nílòkulò. Mo wá dẹni tó máa ń tètè bínú gan-an èyí lo sì máa ń sún mi sí ìjà ìgboro lọ́pọ̀ ìgbà. Nígbà tí màá fi jáde ilé ẹ̀kọ́ gíga, ìwà ipá ti sọ mí dìdàkudà.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18), mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ibẹ̀ ni mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ tó mú kí ń gbóná sí i nínú ìwà ipá. Lẹ́yìn ọdún márùn-ún, mo fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, mó sì lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrònú àti ìhùwà ẹ̀dá (psychology) nírètí pé Ọ́fíìsì Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ máa gbà mí síṣẹ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tí mó sì kó pa dà orílẹ̀-èdè Kánádà, mò ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi.
Nígbà tí mo wà ní yunifásítì, gbogbo nǹkan sú mi títí kan ìwà àwọn èèyàn lápapọ̀. Ó jọ pé onímọtara-ẹni-nìkan làwọn èèyàn, ìgbésí ayé kò ní ìtumọ̀ kankan, ó dà bí i pé ọ̀rọ̀ aráyé kò lójútùú rárá. Èrò mi tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn èèyàn máa sọ ayé yìí di ibi tó máa dùn ún gbé, àmọ́ lọ́kàn mi báyìí kó sóhun tó jọ ọ́ mọ́.
Ohun tí mo rí yìí túbọ̀ wá sọ ìgbésí ayé mi dìdàkudà, mo di ọ̀mùtí paraku, mò ń lo oògùn nílòkulò, mò ń wá owó lójú méjèèjì, mo sì ń fi ìbálòpọ̀ ṣayọ̀. Mò ń ti ilé ijó kan bọ́ sí òmíì, mo sì ń gbé obìnrin lóríṣiríṣi. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà lẹ́nu iṣẹ́ ológun máa ń kì mí láyà, èyí sì ń jẹ kí n jà lọ́pọ̀ ìgbà. Mo kórìíra ìrẹ́jẹ, torí èyí mo ṣe tán láti kojú ẹnikẹ́ni tí mo bá rò pé ó ń rẹ́ ẹlòmíì jẹ. Ká sòótọ́, mo ti dẹrú ìwà ipá.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PADÀ
Lọ́jọ́ kan, èmi àtọ̀rẹ́ mi kan ti mu oògùn olóró yó kẹ́ri nínú àjà ilẹ̀ tó wà nílé mi, a sì ń di igbó tá a fẹ́ lọ tà lọ́nà tí kò bófin mu sí òkè òkun, ni ọ̀rẹ́ mi bá béèrè pé ṣé mo gba Ọlọ́run gbọ́. Mo dá a lóhùn pé, “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé, mi ò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀!” Lọ́jọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun, ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bi mí pé, “Ṣé o rò pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ aráyé?” Ìbéèrè yẹn yà mí lẹ́nu gan-an torí ohun tí mo sọ lánàá, ó sì wú mi kí n mọ̀ sí i. Fún odindi oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ la jọ sọ, ó sì fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣòro fún mi jù lọ nípa ìgbésí ayé.
Àfẹ́sọ́nà mi tá a jọ ń gbé nígbà yẹn ò fẹ́ kí n sọ àwọn ohun tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ fún òun. Lọ́jọ́ Sunday kan, mo sọ fún un pé, mo ti pé àwọn Ẹlẹ́rìí sílé wa kí wọ́n lè wá máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí màá fi pa dà dé láti ibi iṣẹ́ lọ́jọ́ kejì, ó ti palẹ̀ gbogbo ohun tó wá nínú ilé mọ́, ó sì ti kó kúrò. Mo bọ́ síta, mo sì sunkún. Mo tún gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí màá lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà nínú àdúrà mi.—Sáàmù 83:18.
Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúngbà àkọ́kọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán, mo ṣì ń ká ìwé Ìwọ Lè Wàláàyè Títí Láé Lórí ilẹ̀ Aye tí wọ́n fi bá mí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, mo sì kà á tán lálẹ́ ọjọ́ yẹn.a Ohun tí mo kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo rí i pé aláàánú ni Jèhófà àti pé ó máa ń dùn ún tá a bá ń jìyà. (Àìsáyà 63:9) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí mi àti bí ọmọ rẹ̀ ṣe fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà nítorí mi gan-an ló wọ̀ mí lọ́kàn jù lọ. (1 Jòhánù 4:10) Mo wá rí i pé Jèhófà ti mú sùúrù fún mi gan-an “torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pétérù 3:9) Ó wá ṣe kedere sí mi pé ńṣe ni Jèhófà ń fà mí.—Jòhánù 6:44.
Láti ọ̀sẹ̀ yẹn lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Irun gígùn ló wà lórí mi, mo wọ yẹtí, ìrísí mi sì ń dẹ́rù bani, àmọ́ ńṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe mí bí mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n ti rí tipẹ́. Wọ́n hùwà bíi Kristẹni tòótọ́. Ńṣe lò dà bíi pé mo wà lọ́dọ̀ àwọn òbí mi àgbà, àmọ́ ní àyíká tó tún tuni lára jù yẹn lọ pàápàá.
Kò pẹ́ sígbà yẹn tí gbogbo nǹkan tí mò ń kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í tún ayé mi ṣe. Mo gé irun mi, mo jáwọ́ nínú gbogbo ìwà ìṣekúṣe, mo sì jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò àti mímu ọtí àmupara. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 11:14) Mo fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn, torí náà, nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé kò nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tí mò ń ṣe, mi ò wá àwíjàre fún irú àwọn ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn nǹkan yẹn máa ń dùn mí wọnú eegun lọ́pọ̀ ìgbà. Mo máa ń sọ fún ara mi pé: “Mi ò lè máa bá a lọ báyìí.” Láìrò ó lẹ́ẹ̀mejì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tún èrò àti ìwà mi ṣe. Àbájáde ẹ̀ ni pé, ìgbé ayé mi bẹ̀rẹ̀ sí í dá a sí i nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́. Ní July 29, 1989, ìyẹn oṣù kẹfà lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo ṣèrìbọmi, mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ
Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti yí ìwà mi pa dà. Nígbà kan, tí oníwà ipá kan bá gbéjà kò mí, mi ò kì í rò ó lẹ́ẹ̀mejì tí màá fi dá a pa dà fún un tí ìjà á sì di rannto. Àmọ́ ní báyìí, mò ń sapá láti “wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.” (Róòmù 12:18) Kì í ṣe mímọ̀ ọ́n ṣe mi, Jèhófà lọpẹ́ yẹ fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní agbára láti yí ìgbésí ayé pa dà.—Gálátíà 5:22, 23; Hébérù 4:12.
Dípò kí n di ẹrú fún oògùn ìlòkulò, ìwà ipá àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ṣe ni mo ń sa gbogbo ipá mi láti ṣe ohun tó wu Jèhófà Ọlọ́run, kí n sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Lára ẹ̀ ni bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, mo ṣí lọ si agbègbè ibòmíì láti wàásù ní agbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù. Fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí, mo ti ń gbádùn ayọ̀ tó wà nínú kíkọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ń rí bí Bíbélì ṣe ń tún ayé wọn ṣe bíi tèmi. Inú mi tún dùn pé màmá mi di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lára ohun tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ ni bí wọ́n ṣe rí i pé ìwà àti ìṣe mi ti yàtọ̀.
Lọ́dún 1999, ní El Salvador, mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ tí à ń pé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí. Ilé Ẹ̀kọ́ yẹn ti kọ́ mi, o sì ti mú kí n gbara dì láti máa múpò iwájú nínú iṣẹ́ ajíhìnrere, kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn. Ọdún yẹn náà ni mo ṣègbéyàwó pẹ̀lú Eugenia, olólùfẹ́ mi àtàtà. Àwa méjèèjì jọ ń sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ní Guatemala.
Ní báyìí, dípò tí ìgbésí ayé á fi tojú sú mi ńṣe ni mò ń láyọ̀. Bí mo sì ṣe ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò ti jẹ́ kí n dòmìnira kúrò nínú ìwà ìṣekúṣe àti ìwà ipá. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi kún fún ìfẹ́ tòótọ́ àti àlàáfíà.
a Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ báyìí