Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí A Ṣe Lè Tọ́jú Àwọn Òbí Wa Tó Ti Dàgbà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Àwọn ọmọ tó ti dàgbà ní láti rí i dájú pé àwọn tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà. Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ tó ti dàgbà gbọ́dọ̀ “kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ilé ara wọn, kí wọ́n san pa dà nínú ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọ́run.” (1 Tímótì 5:4, Ìròyìn Ayọ̀) Tí àwọn ọmọ tó ti tójú bọ́ bá ń rí i dájú pé àwọn tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà, àṣẹ Bíbélì tó sọ pé kí àwọn ọmọ bọlá fún àwọn òbí wọn ni wọ́n ń pa mọ́ yẹn.—Éfésù 6:2, 3.
Bíbélì ò ṣe òfin pàtó nípa béèyàn ṣe lè tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ tó ti dàgbà. Àmọ́, ó mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó tún jẹ́ ká rí àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà.
Lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo làwọn kan ṣe tọ́jú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà?
Onírúuru ọ̀nà ni wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ó sinmi lórí bí ipò nǹkan ṣe rí.
Jósẹ́fù gbé níbi tó jìnnà síbi tí Jékọ́bù bàbá rẹ̀ tó ti darúgbó ń gbé. Ó ṣètò fún Jékọ́bù láti wà nítòsí òun nígbà tó ṣeé ṣe fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, Jósẹ́fù pèsè ilé tí bàbá rẹ̀ á máa gbé, oúnjẹ táá máa jẹ, o sì tún dáàbò bò ó.—Jẹ́nẹ́sísì 45:9-11; 47:11, 12.
Rúùtù ṣí lọ sí ìlú ìyá ọkọ rẹ̀, ó sì ṣiṣẹ́ kára kó lè tọ́jú rẹ̀.—Rúùtù 1:16; 2:2, 17, 18, 23.
Jésù, nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó yan ẹni kan táá máa tọ́jú Màríà ìyá rẹ̀, torí ó ṣeé ṣe kí ọkọ Màríà ti kú nígbà yẹn.—Jòhánù 19:26, 27.a
Àwọn ìmọ̀ràn wo nínú Bíbélì ló lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń tọ́jú àgbàlagbà?
Àwọn ìlànà wà nínú Bíbélì tó lè ran àwọn tó ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Ká sòótọ́, àwọn tó ń tọ́jú àgbàlagbà sábà máa ń kojú àwọn ìṣòro tó ń tánni lókun tó sì ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, síbẹ̀ àwọn ìlànà Bíbélì á jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á.
Bọlá fún àwọn òbí rẹ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.”—Ẹ́kísódù 20:12.
Báwo la ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? O lè bọlá fún àwọn òbí rẹ tó o bá jẹ́ kí wọ́n lo òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ohun tó wù wọ́n níbàámu pẹ̀lú agbára àti ipò wọn. Dé ìwọ̀n àyè tó bá ṣeé ṣe tó, jẹ́ kí àwọn fúnra wọn pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́. Síbẹ̀, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kára lè tù wọ́n. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń bọ̀wọ̀ fún wọn nìyẹn.
Jẹ́ ẹni tó ń fòye báni lò, kó o sì máa dárí jini.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀, ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo àṣìṣe.”—Òwe 19:11.
Báwo la ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Tí òbí kan tó jẹ́ àgbàlagbà bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí tó ṣe ohun tó dà bíi pé kò mọyì bó o ṣe ń tọ́jú òun, bi ara rẹ pé, ‘Tó bá jẹ́ pé èmi ni mo wà nípò tí wọ́n wà, tó lójú nǹkan tí mo lè dá ṣe, tí nǹkan sì máa ń sú mi, báwo ló ṣe máa rí lára mi?’ Tó o bá ń fòye bá wọn lò, tó o sì lẹ́mìí ìdáríjì, o ò ní ṣe ohun táá túbọ̀ da ojú ọ̀rọ̀ rú.
Bá àwọn míì sọ̀rọ̀.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán, àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”—Òwe 15:22.
Báwo la ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Ṣe ìwádìí nípa bó o ṣe lè bójú tó àìlera tí àwọn òbí rẹ ní. Wádìí nípa ètò tí ìjọba ṣe tó lè mú kó rọrùn láti tọ́jú wọn. Sún mọ́ àwọn tó ti tọ́jú àwọn òbí tó jẹ́ àgbàlagbà kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn. Tó o bá láwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò, ó máa dáa kẹ́ ẹ ṣèpàdé, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun táwọn òbí yín nílò, bí ẹ̀ẹ́ ṣe máa tọ́jú wọn àti ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa kó.
Mọ̀wọ̀n ara rẹ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.”—Òwe 11:2.
Báwo la ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Mọ ibi tí agbára rẹ mọ. Bí àpẹẹrẹ, agbára kálukú wa ò dọ́gba, bẹ́ẹ̀ sì ni àkókò tá a ní láti ṣe nǹkan ò bára mu. Àwọn nǹkan yìí lè mú kó ṣòro fún wa láti tọ́jú àwọn òbí wa bá a ṣe fẹ́. Tó o bá rí i pé ọrùn ti ń wọ̀ ẹ́ bó o ṣe ń bójú tó àwọn òbí rẹ, o lè ní kí mọ̀lẹ́bí yín kan ràn ẹ́ lọ́wọ́, o sì lè ní káwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó ń tọ́jú àgbàlagbà bá ẹ tọ́jú wọn.
Tọ́jú ara rẹ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”—Éfésù 5:29.
Báwo la ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Òótọ́ ni pé ojúṣe rẹ ni láti tọ́jú àwọn òbí rẹ, síbẹ̀ ó tún yẹ kó o máa bójú tó ara rẹ. Tó o bá sì ti ṣègbéyàwó, kò yẹ kó o pa ìdílé rẹ tì. Bákan náà, máa jẹun dáadáa, máa wáyè sinmi kó o sì máa sùn dáadáa. (Oníwàásù 4:6) Tó bá ṣeé ṣe, á dáa kó o máa gbafẹ́ jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ara ẹ á jí pépé, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì lágbára láti tọ́jú àwọn òbí rẹ.
Ṣé Bíbélì fi dandan lé e pé àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ mú àwọn òbí wọn tó ti dàgbà sọ́dọ̀ kí wọ́n tó lè tọ́jú wọn?
Bíbélì ò sọ ní pàtó pé dandan ni káwọn ọmọ tó ti dàgbà mú àwọn òbí tó ti dàgbà sọ́dọ̀ kí wọ́n tó lè tọ́jú wọn. Àwọn ìdílé kan pinnu pé ó sàn káwọn òbí wọn tó ti darúgbó wà láyè ara wọn débi tó bá ṣeé ṣe tó. Àwọn míì sì pinnu pé àwọn á mú wọn sọ́dọ̀. Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n lè wá rí i pé ó máa dáa káwọn gbé wọn lọ sílé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó. Èyí ó wù kó jẹ́, á dáa kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà ṣe ìpàdé láti pinnu ohun tó bọ́gbọ́n mu jù.—Gálátíà 6:4, 5.
a Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jósẹ́fù [ọkọ Màríà] ti kú tipẹ́ àti pé Jésù ọmọ rẹ̀ ló ń bójú tó o látìgbà yẹn, àmọ́ kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí Màríà báyìí tí Jésù náà ń kú lọ? . . . Kristi tipa báyìí kọ́ àwọn ọmọ pé kí wọ́n máa pèsè ohun tí àwọn òbí wọn tó ti dàgbà nílò.”—The NIV Matthew Henry Commentary in One Volume, ojú ìwé 428 àti 429.