ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40
Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́” Yìí
“Ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀, kí ẹ máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo.”—1 KỌ́R. 15:58.
ORIN 58 À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló mú kó dá wa lójú pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí?
ṢÉ Ẹ̀YÌN ọdún 1914 ni wọ́n bí ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” lo ti ṣe kékeré, inú ẹ̀ náà lo sì dàgbà sí. (2 Tím. 3:1) Gbogbo wa pátá là ń gbọ́ ìròyìn àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Lára wọn ni ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ìwà tí kò bófin mu tó ń pọ̀ sí i àti inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwa èèyàn Jèhófà. (Mát. 24:3, 7-9, 12; Lúùkù 21:10-12) Bákan náà là ń rí ìwà abèṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn èèyàn á máa hù lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí. (Wo àpótí náà “Ohun Táwọn Èèyàn Jẹ́ Lónìí.”) Ó dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” là ń gbé báyìí.—Míkà 4:1.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?
2 Torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn 1914, ó dájú pé apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé báyìí. Níwọ̀n bí òpin ti sún mọ́lé gan-an, a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì kan: Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí bá dópin? Kí ni Jèhófà sì fẹ́ ká máa ṣe bá a ṣe ń retí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀?
KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀ TÍ “ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN” BÁ DÓPIN?
3. Bí 1 Tẹsalóníkà 5:1-3 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìkéde wo làwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe?
3 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:1-3. Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan “ọjọ́ Jèhófà.” Bó ṣe wà níbi tá a kà yìí, ọjọ́ Jèhófà ni àkókò kan tó máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun “Bábílónì Ńlá” tó sì máa dópin nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìfi. 16:14, 16; 17:5) Àmọ́ kí “ọjọ́” náà tó bẹ̀rẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “Àlàáfíà àti ààbò!” (Àwọn Bíbélì kan pè é ní: “Àlàáfíà àti àìléwu.”) Àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè sábà máa ń lo gbólóhùn yìí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí àjọṣe tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ṣe lè túbọ̀ gún régé.b Bó ti wù kó rí, ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” tí Bíbélì ń sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nígbà tí wọ́n bá ṣe ìkéde yìí, àwọn èèyàn ayé máa ronú pé àwọn aṣáájú yẹn ti mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé, pé ayé ti dùn ún gbé àti pé kò séwu mọ́. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, “ìparun òjijì” ló máa dé bá wọn torí pé ìgbà yẹn ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀.—Mát. 24:21.
4. (a) Kí làwọn nǹkan tá ò mọ̀ nípa ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” yìí? (b) Kí la mọ̀ nípa ẹ̀?
4 Àwọn nǹkan kan wà tá a mọ̀ nípa ìkéde “àlàáfíà àti ààbò.” Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tí a kò mọ̀. A ò mọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ táá mú kí wọ́n ṣe ìkéde náà, a ò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà ṣe é. A ò mọ̀ bóyá ìkéde kan ṣoṣo ló máa jẹ́ tàbí ó máa jẹ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, ohun kan dá wa lójú: Àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè ò lè mú kí àlàáfíà jọba láyé, torí náà a ò ní jẹ́ kí ìkéde yẹn tàn wá jẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ìkéde yẹn máa jẹ́ àmì tí Bíbélì ní ká máa retí. Òun ló sì máa jẹ́ àmì pé “ọjọ́ Jèhófà” ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀!
5. Báwo lohun tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:4-6 ṣe múra wa sílẹ̀ de “ọjọ́ Jèhófà”?
5 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:4-6. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe àtohun tó yẹ ká ṣọ́ra fún ká lè múra sílẹ̀ de “ọjọ́ Jèhófà.” Ó rọ̀ wá pé ká má ṣe “máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe.” Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ “wà lójúfò” ká sì máa ronú lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má bàa di pé à ń dá sọ́rọ̀ òṣèlú ká má sì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá lọ dá sọ́rọ̀ òṣèlú pẹ́nrẹ́n, á jẹ́ pé a ti ń di “apá kan ayé” nìyẹn. (Jòh. 15:19) A sì mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí àlàáfíà jọba níbi gbogbo láyé.
6. Ìrànwọ́ wo la fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn, kí sì nìdí?
6 Yàtọ̀ sí pé ká wà lójúfò, ó tún ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Ká fi sọ́kàn pé, tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, kò ní ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sin Jèhófà. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìwàásù kọjá ohun téèyàn ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú, ó sì jẹ́ kánjúkánjú!c
JẸ́ KÍ ỌWỌ́ RẸ DÍ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
7. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe báyìí?
7 Níwọ̀nba àkókò díẹ̀ tó kù kí “ọjọ́ Jèhófà” bẹ̀rẹ̀, Jèhófà fẹ́ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ká sì jẹ́ kọ́wọ́ wa dí. A gbọ́dọ̀ rí i pé à ń “ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Kódà, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan táá ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó tún jẹ́ ká mọ ohun tá a máa ṣe, ó ní: “Bákan náà, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:4, 8, 10; Mát. 24:14) Wò ó ná: Nígbàkigbà tó o bá ń wàásù, ṣe lò ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹn ṣẹ!
8. Kí ló fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ń tẹ̀ síwájú?
8 Kí la lè sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, ṣé ó ń tẹ̀ síwájú? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ọdọọdún ni ìbísí ń wá. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń pọ̀ sí i kárí ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Lọ́dún 1914, díẹ̀ làwọn akéde fi lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,155), ilẹ̀ mẹ́tàlélógójì (43) péré ni wọ́n sì wà. Àmọ́ lónìí, mílíọ̀nù mẹ́jọ àtààbọ̀ ni wá, a sì ń wàásù ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240) ilẹ̀! Síbẹ̀, iṣẹ́ ò tíì parí o. Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn púpọ̀ sí i mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé.—Sm. 145:11-13.
9. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run nìṣó?
9 Àá ṣì máa bá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run yìí nìṣó títí dìgbà tí Jèhófà fúnra ẹ̀ bá sọ pé ó ti tó. Báwo ni àsìkò táwọn èèyàn ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi ṣe máa pẹ́ tó? (Jòh. 17:3) A ò mọ̀. Ohun kan tó dá wa lójú ni pé “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” ṣì láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà, torí pé tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, ẹ̀pa ò ní bóró mọ́. (Ìṣe 13:48) Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù?
10. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń fún wa ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
10 Nípasẹ̀ ètò rẹ̀, Jèhófà ń fún wa ní gbogbo nǹkan tá a nílò ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Nínú ìpàdé yẹn, wọ́n ń kọ́ wa lóhun tá a máa bá àwọn èèyàn sọ nígbà àkọ́kọ́ àti nígbà ìpadàbẹ̀wò. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ètò Jèhófà tún fún wa ní Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ohun tó wà nínú àpótí yẹn máa ń jẹ́ ká lè . . .
bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò,
mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́,
mú káwọn èèyàn fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì,
kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń jẹ́ ká
rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ sórí ìkànnì wa, kí wọ́n sì wá sípàdé.
Àmọ́ o, kì í ṣe ká kàn ní àwọn irinṣẹ́ yìí, ó ṣe pàtàkì ká máa lò wọ́n.d Tí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn kan. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á lè rí ohun táá máa kà kó o tó tún pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Torí náà, ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti rí i pé à ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run déédéé.
11. Ki ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wà fún?
11 Ohun míì tí Jèhófà tún pèsè fún wa ká lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lohun tó wà lórí ìkànnì jw.org®, tá a pè ní Online Bible Study Lessons, ìyẹn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (Wo abala BIBLE TEACHINGS > ONLINE LESSONS.) Kí ló wà fún? Lóṣooṣù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló máa ń lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó wà lórí ìkànnì wa sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn kan tá a wàásù fún lè má fẹ́ ká máa wá sọ́dọ̀ àwọn láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá a bá bá irú wọn pàdé, ẹ jẹ́ ká fi abala yìí hàn wọ́n lórí ìkànnì wa tàbí ká fi ìlujá rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn.e
12. Àwọn nǹkan wo làwọn èèyàn máa kọ́ nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
12 Díẹ̀ lára ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni: “Bíbélì àti Ẹni Tó Ṣe É,” “Àwọn Èèyàn Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Wọn” àti “Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fúnni Nírètí Tó Wà Nínú Bíbélì.” Àwọn àkòrí yìí jẹ́ káwọn èèyàn mọ:
Bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́
Ẹni tí Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì jẹ́
Ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn
Ìdí táwọn èèyàn fi ń jìyà
Àwọn ẹ̀kọ́ yẹn tún sọ bí Jèhófà ṣe máa . . .
fòpin sí ìyà àti ikú,
jí àwọn tó ti kú dìde àti
bó ṣe máa fi Ìjọba rẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn tó ti kùnà.
13. Tẹ́nì kan bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa, ṣó tún nílò kí Ẹlẹ́rìí kan máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́? Ṣàlàyé.
13 Ti pé ẹnì kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa kò túmọ̀ sí pé kò nílò kí Ẹlẹ́rìí kan kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Àwa ni Jésù gbéṣẹ́ fún pé ká sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. A retí pé tẹ́nì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa bá mọyì ohun tó ń kọ́, á fẹ́ mọ̀ sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, á gbà kẹ́nì kan wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Kódà lọ́wọ́ ìparí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, ibì kan wà tí wọ́n ti máa béèrè pé ṣó fẹ́ kẹ́nì kan wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, á kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù tó wà níbẹ̀. Ẹ wo bó ṣe wúni lórí tó pé kárí ayé làwọn èèyàn ti ń béèrè pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́, ó kéré tán ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230) èèyàn ló ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́! Ká sòótọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀rọ àti kẹ́nì kan máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
MÁA SỌ ÀWỌN ÈÈYÀN DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN
14. Bí Jésù ṣe sọ nínú Mátíù 28:19, 20, kí la gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe, kí sì nìdí?
14 Ka Mátíù 28:19, 20. Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa ká lè ‘sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn, ká sì máa kọ́ wọn pé kí wọ́n pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́.’ A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n fara wọn sábẹ́ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Ìyẹn máa gba pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sọ òtítọ́ di tiwọn. Lédè míì, kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn nìkan ló máa jẹ́ kí wọ́n la ọjọ́ Jèhófà já.—1 Pét. 3:21.
15. Kí ni kò yẹ ká máa fi àkókò wa ṣe, kí sì nìdí?
15 Bá a ṣe sọ ṣáájú, a ò rọ́jọ́ mú so lókùn, ohun tó kù kí ayé búburú yìí dópin kò sì tó nǹkan mọ́. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ ká fi àkókò ṣòfò, ká wá máa pààrà ọ̀dọ̀ àwọn tí kò ṣe tán láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. (1 Kọ́r. 9:26) Iṣẹ́ wa ti di kánjúkánjú báyìí! Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà tó yẹ ká wàásù fún, torí náà ẹ jẹ́ ká wá irú wọn lọ kó tó pẹ́ jù.
MÁ ṢE NÍ OHUNKÓHUN ṢE PẸ̀LÚ Ẹ̀SÌN ÈKÉ
16. Bó ṣe wà nínú Ìfihàn 18:2, 4, 5, 8, kí ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣe? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
16 Ka Ìfihàn 18:2, 4, 5, 8. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan míì tí Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn rẹ̀ ṣe. Gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ rí i pé a ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú Bábílónì Ńlá, ká má sì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú rẹ̀ bó ti wù kó kéré mọ. Àwọn kan lè ti máa ṣe ẹ̀sìn èké kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà àti ìṣe ẹ̀sìn náà. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n máa ń fowó ṣètìlẹyìn fún irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀. Àmọ́, káwọn alàgbà tó lè fọwọ́ sí i pé kẹ́nì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ jáwọ́ pátápátá nínú ẹ̀sìn èké tó ń dara pọ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀. Ó máa ní láti kọ lẹ́tà sí wọn pé òun kì í ṣe ọ̀kan lára wọn mọ́, ó sì tún gbọ́dọ̀ yọwọ́ yọsẹ̀ pátápátá nínú ètò tàbí ẹgbẹ́ èyíkéyìí tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Bábílónì Ńlá.f
17. Irú iṣẹ́ wo làwa Kristẹni ò lè ṣe, kí sì nìdí?
17 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ rí i dájú pé iṣẹ́ wa kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Bábílónì Ńlá. (2 Kọ́r. 6:14-17) Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan kò gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí. Bákan náà, tí Kristẹni kan bá ń bá ẹnì kan ṣiṣẹ́, kò ní bá wọn ṣe iṣẹ́ tó máa gba àkókò gígùn níbi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn èké. Tó bá sì jẹ́ pé iṣẹ́ ara ẹ̀ ló ń ṣe, ó dájú pé kò ní gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ètò èyíkéyìí lára Bábílónì Ńlá, kò sì ní ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá jẹ mọ́ ẹ̀sìn èké. Kí nìdí tọ́rọ̀ yìí fi lágbára tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a ò fẹ́ lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tí wọ́n ń ṣe nínú ẹ̀sìn èké, yálà ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni, orin wọn, ìṣe wọn tàbí àṣà wọn torí pé ohun àìmọ́ ni wọ́n lójú Ọlọ́run.—Àìsá. 52:11.g
18. Báwo ni arákùnrin kan ṣe fi ìlànà Bíbélì sílò nígbà tí wọ́n fi iṣẹ́ kan lọ̀ ọ́?
18 Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ẹnì kan bẹ alàgbà kan tó ń ṣiṣẹ́ káfíńtà níṣẹ́, ó ní kó bá ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ṣe iṣẹ́ kékeré kan. Ẹni yẹn mọ̀ pé ó pẹ́ tí arákùnrin wa ti máa ń sọ pé òun kì í gbaṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Síbẹ̀, ọkùnrin yẹn ń wá ẹni tó máa bá wọn ṣe iṣẹ́ yẹn lójú méjèèjì torí pé kò rí ẹlòmíì tó lè ṣe é. Láìfi ìyẹn pè, arákùnrin wa ò gbà láti ṣe iṣẹ́ náà torí pé kò fẹ́ tẹ ìlànà Bíbélì lójú. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, gàdàgbà-gadagba ni ìwé ìròyìn ayé kan gbé àwòrán káfíńtà tó ń bá wọn kan àgbélébùú mọ́ iwájú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn jáde. Ká sọ pé arákùnrin wa gba iṣẹ́ yẹn ni, àwòrán ta ni ì bá wà nínú ìwé ìròyìn náà? Ẹ wo bí ìyẹn ì bá ṣe kó ẹ̀dùn ọkàn bá arákùnrin yẹn àtàwọn ará yòókù! Ẹ sì wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà.
ÀWỌN NǸKAN WO LA TI KỌ́?
19-20. (a) Àwọn nǹkan wo la ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? (b) Àwọn nǹkan míì wo la máa kọ́?
19 Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe fi hàn, ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó máa wáyé láìpẹ́ ni ìkéde “àlàáfíà àti ààbò” táwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe. Àmọ́ Jèhófà ti kọ́ wa, a mọ̀ pé ariwo lásán ló máa jẹ́ torí pé wọn ò lè mú ojúlówó àlàáfíà wá. Kí wá ni ṣíṣe báyìí kí wọ́n tó ṣe ìkéde yẹn, tí ìparun òjijì á sì dé bá wọn? Ṣe ló yẹ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké èyíkéyìí. Ìyẹn máa gba pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a kì í ṣe ara wọn mọ́, ká má sì gbaṣẹ́ èyíkéyìí tó ní ín ṣe pẹ̀lú Bábílónì Ńlá.
20 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì tún máa wáyé ní apá ìgbẹ̀yìn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. Àwọn nǹkan kan sì wà tí Jèhófà máa fẹ́ ká ṣe. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo là ń retí, kí sì làwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe? Yàtọ̀ síyẹn, kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 71 Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá!
a Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde pé “àlàáfíà àti ààbò” ti dé. Ìkéde yìí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ìpọ́njú ńlá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe títí dìgbà yẹn? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Bí àpẹẹrẹ, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ lórí ìkànnì wọn pé àwọn ń mú kí “àlàáfíà àti ààbò jọba káàkiri ayé.”
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìdájọ́ Ọlọ́run—Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn Kó Tó Ṣèdájọ́?” nínú ìwé ìròyìn yìí.
d Tó o bá fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bó o ṣe lè lo àwọn ohun tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2018.
e Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Potogí nìkan ló wà báyìí, a máa gbé àwọn èdè míì síbẹ̀ tó bá yá.
f Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ èyíkéyìí tó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sìn èké, bí ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àwọn míì bẹ́ẹ̀, a kì í sì í lọ síbi eré ìdárayá tàbí ìmárale táwọn onísìn ṣètò. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa bóyá Kristẹni kan lè dara pọ̀ mọ́ àjọ YMCA (Young Men’s Christian Association) lábẹ́ “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 1979. Ìlànà kan náà ló kan àjọ YWCA (Young Women’s Christian Association). Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè sọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sọ́rọ̀ tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn nínú àwọn ẹgbẹ́ yìí, síbẹ̀ ìwádìí fi hàn pé àwọn ẹlẹ́sìn ló dá wọn sílẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni wọ́n sì ń gbé lárugẹ.
g Tó o bá fẹ́ àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa bóyá Kristẹni kan lè ṣe iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn èké, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 1999.
h ÀWÒRÁN: Ó ya àwọn èèyàn tó wà nílé oúnjẹ kan lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n pé wọ́n ti kéde “àlàáfíà àti ààbò.” Àmọ́ ìròyìn yẹn kò ya tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tó wà níbẹ̀ lẹ́nu. Òde ẹ̀rí ni tọkọtaya yẹn wà, àmọ́ wọ́n yà síbẹ̀ fún ìsinmi ráńpẹ́.