Ǹjẹ́ O ti Jẹ Búrẹ́dì Tí Ń Fúnni Ní Ìyè?
ÀWỌN arìnrìn àjò afẹ́ kan wá sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àtijọ́, wọ́n wá wo àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó wà nílùú náà. Gbogbo bí wọ́n ṣe ń rìn káàkiri ti mú kí ebi máa pa wọ́n, ó sì wù wọ́n pé kí wọ́n jẹ oúnjẹ ìlú náà. Ni ọ̀kan nínú wọn bá tajú kán rí ilé oúnjẹ kan lọ́ọ̀ọ́kán. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, oúnjẹ aládùn kan tí wọ́n ń pè ní falafel ni wọ́n ń tà níbẹ̀, ìyẹn ẹ̀wà tí wọ́n fi tòmátì, àlùbọ́sà àtàwọn ewébẹ̀ míì sè. Búrẹ́dì ribiti kan tí wọ́n ń pè ní pita bread ni àwọn èèyàn sì fi ń kó ẹ̀wà náà jẹ. Oúnjẹ tí wọ́n jẹ yìí ló fún wọn lókun lákọ̀tun láti máa bá ìrìn àjò wọn lọ.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arìnrìn àjò yìí kò mọ̀ pé búrẹ́dì tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọ wọ́n lójú tí wọ́n jẹ yẹn ṣeé ṣe kó jẹ́ ìrírí mánigbàgbé tí wọ́n ní lọ́jọ́ náà. Orúkọ náà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù túmọ̀ sí “Ilé Búrẹ́dì,” ó sì ti lé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì níbẹ̀. (Rúùtù 1:22; 2:14) Búrẹ́dì ribiti tí wọ́n ń pè ní pita bread yẹn jẹ́ ọ̀kan lára búrẹ́dì tí wọ́n ń jẹ jù lọ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lónìí.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn, ní ìlú kan tí kò jìnnà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Sárà tó jẹ́ ìyàwó Ábúráhámù yan ‘àwọn búrẹ́dì ribiti’ fún àwọn àlejò pàtàkì mẹ́ta. (Jẹ́nẹ́sísì 18:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọkà báálì tàbí àlìkámà kan tí wọ́n máa ń fún àwọn ẹran ọ̀sìn jẹ ni Sárà fi ṣe “ìyẹ̀fun kíkúnná” tí ó lò. Sárà gbọ́dọ̀ tètè ṣe búrẹ́dì náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí àwọn òkúta gbígbóná ló ti yan án.—1 Àwọn Ọba 19:6.
Àlàyé yìí fi hàn pé ìdílé Ábúráhámù ló máa ń ṣe búrẹ́dì tí wọ́n ń jẹ nílé fúnra wọn. Nítorí tí wọn máa ń ṣí kiri láti ibì kan sí ibòmíràn, ó lè jẹ́ pé Sárà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kò ní irú ààrò tí wọ́n fi máa ń yan búrẹ́dì nígbà tí wọ́n ń gbé nílẹ̀ Úrì. Irú ọkà tó wà lágbègbè ibi tí wọ́n wà ló máa lò, á sì lọ̀ ọ́ di ìyẹ̀fun kíkúnná. Iṣẹ́ àṣelàágùn gbáà ni kéèyàn fi ọlọ ọlọ́wọ́ lọ ọkà di ìyẹ̀fun, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ odó àti ọmọ odó ni wọ́n máa ń lò nígbà yẹn.
Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún lẹ́yìn náà, Òfin Mósè pa á láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ọlọ ọlọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdógò fún gbèsè tí ẹni kan jẹ torí pé bí ìgbà ‘tí ó fi ipá gba ọkàn rẹ̀’ nìyẹn torí ó ti gba oúnjẹ lẹ́nu rẹ̀. (Diutarónómì 24:6) Ọlọ́run ka ọlọ ọlọ́wọ́ sí pàtàkì torí pé láì sí i, ìdílé kan ò ní lè ṣe búrẹ́dì tí wọ́n nílò lóòjọ́.—Wo àpótí náà “Lílọ Ìyẹ̀fun àti Yíyan Búrẹ́dì Láyé Ìgbà tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì.”
BÚRẸ́DÌ TÍ Ń GBÉ Ẹ̀MÍ RÓ
Ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìgbà tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kan búrẹ́dì, lọ́pọ̀ ìgbà sì ni àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì máa ń lo búrẹ́dì nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ka sí oúnjẹ. Jésù fi hàn pé gbogbo àwọn tó ń fi òótọ́ inú sin Ọlọ́run lè gbàdúrà pé: “Fún wa lónìí oúnjẹ [búrẹ́dì] wa fún ọjọ́ òní.” (Mátíù 6:11) Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, búrẹ́dì ń ṣàpẹẹrẹ oúnjẹ lápapọ̀, ohun tí Jésù ń jẹ́ ká mọ̀ ni pé á lè gbara lé Ọlọ́run pé kó pèsè oúnjẹ láti gbé ẹ̀mí wa ró lójoojúmọ́.—Sáàmù 37:25.
Ṣùgbọ́n, ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju búrẹ́dì tàbí oúnjẹ lọ. Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ [búrẹ́dì] nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run ló ń pèsè gbogbo ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílò pátápátá. Àkókò yìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní Íjíbítì. Wọ́n ti rìn fún nǹkan bí oṣù kan nínú aginjù Sínáì, gbogbo oúnjẹ wọ́n sì ti ń tán lọ. Nígbà tí wọ́n rí i pé ebi ń pa àwọn kú lọ ní aginjù tó gbẹ táútáú yẹn, wọ́n ṣàròyé pé: “A ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn” ní Íjíbítì.—Ẹ́kísódù 16:1-3.
Ká sòótọ́, àjẹpọ́nnulá ni búrẹ́dì ilẹ̀ Íjíbítì. Torí pé nígbà ayé Mósè, àwọn ará Íjíbítì ní àwọn tó mọ búrẹ́dì ṣe dáadáa, wọ́n sì máa ń ṣe oríṣiríṣi búrẹ́dì àti àkàrà. Síbẹ̀, oríṣi búrẹ́dì míì ni Jèhófà ní lọ́kàn tó fẹ́ pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀. Ó ṣèlérí pé: “Kíyè sí i, èmi yóò rọ̀jò oúnjẹ [búrẹ́dì] fún yín láti ọ̀run.” Bí Jèhófà ṣe sọ gẹ́lẹ́ ló rí, nítorí àárọ̀ kùtùkùtù ni wọ́n máa ń rí búrẹ́dì yìí. Ó máa ń rí bí “ohun fúlẹ́fúlẹ́ kíkúnná kan” tó dàbí ìrì dídì. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́kọ́ rí i, wọ́n béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: “Kí ni èyí?” Mósè wá ṣàlàyé fún wọn pé: “Oúnjẹ tí Jèhófà fi fún yín láti jẹ ni.” Wọ́n pe oúnjẹ yìí ní mánà,a òun sì ni wọ́n jẹ fún ogójì ọdún [40] gbáko.—Ẹ́kísódù 16:4, 13-15, 31.
Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dùn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí mánà tí Ọlọ́run pèsè fún wọn lọ́nà ìyanu. Nígbà tí wọ́n tọ́ ọ wò, ó dùn bí ‘àkàrà pẹlẹbẹ tó lóyin,’ ìpèsè náà sì kárí gbogbo wọn. (Ẹ́kísódù 16:18) Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọkàn wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí oríṣiríṣi oúnjẹ tó ti mọ́ wọ́n lára nílẹ̀ Íjíbítì. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, wọ́n ní: “Ojú wa kò rí nǹkan kan rárá bí kò ṣe mánà yìí.” (Númérì 11:6) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n fi ìbínú sọ pé: “Ọkàn wa sì ti fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra oúnjẹ játijàti yìí.” (Númérì 21:5) Àbí ẹ ò rí nǹkan, “oúnjẹ [búrẹ́dì] láti ọ̀run” tí Ọlọ́run pèsè fún wọn ni wọ́n wá ń pè ní nǹkan játijàti!—Sáàmù 105:40.
BÚRẸ́DÌ TÍ Ń FÚNNI NÍ ÌYÈ
Òótọ́ ni pé, a lè máà fi bẹ́ẹ̀ ka búrẹ́dì sí oúnjẹ pàtàkì. Síbẹ̀, Bíbélì sọ nípa búrẹ́dì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tí kò yẹ ká tẹ́ńbẹ́lú. Búrẹ́dì yìí lè fún wa ní ìbùkún ayérayé, Jésù sì fi wé mánà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kà kún.
Jésù sọ pé: “Èmi ni oúnjẹ [búrẹ́dì] ìyè.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ẹnikẹ́ni lè jẹ nínú rẹ̀, kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò wà láàyè títí láé; àti pé, ní ti tòótọ́, oúnjẹ tí èmi yóò fi fúnni ni ẹran ara mi nítorí ìyè ayé.”—Jòhánù 6:48-51.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn kò lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “búrẹ́dì” àti “ẹran ara.” Àmọ́, àpèjúwe yìí bá a mu gan-an torí pé búrẹ́dì ni oúnjẹ táwọn Júù sábà máa ń jẹ lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ sì rí nígbà tí wọ́n jẹ mánà fún ogójì ọdún gbáko nínú aginjù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mánà ti wá, síbẹ̀ kò lè fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n, ẹbọ tí Jésù rú yìí lè fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun. Lóòótọ́ Jésù gan-an ni “oúnjẹ [búrẹ́dì] ìyè.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ búrẹ́dì lèèyàn máa jẹ tí ebi bá ń pa á, á sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó pèsè rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí “oúnjẹ òòjọ́.” (Mátíù 6:11, Bíbélì Mímọ́) Tá a bá ń gbádùn oúnjẹ aládùn kan, a máa ń mọrírì rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká mọyì Jésù Kristi tó jẹ́ “oúnjẹ [búrẹ́dì] ìyè.”
Kí la lè ṣe tí a kò fi ní fìwà jọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò moore ìpèsè Jèhófà nígbà ayé Mósè, ká sì fi ìmọrírì hàn fún búrẹ́dì iyebíye tí Jèhófà pèsè fún wa? Jésù sọ ohun tá a lè ṣe, ó ní: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ mi, ẹ ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́.” (Jòhánù 14:15) Tá a bá ń pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́, a máa láǹfààní láti jẹ búrẹ́dì aládùn ní àjẹtẹ́rùn títí láé.—Diutarónómì 12:7.
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “mánà” wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà “man hu’?” tó túmọ̀ sí “kí ni èyí?”