Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo ni wọ́n ṣe ń fi ìwé ránṣẹ́ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
Àwọn asáréjíṣẹ́ ọba ni wọ́n máa ń lọ fi ìwé tó bá jẹ mọ́ ti ìjọba ilẹ̀ Páṣíà jíṣẹ́. Ìwé Ẹ́sítérì ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń lo àwọn asáréjíṣẹ́ ní ilẹ̀ Páṣíà, ó ní: “[Módékáì] tẹ̀ síwájú láti kọ ọ́ ní orúkọ Ahasuwérúsì Ọba, ó sì fi òrùka àmì àṣẹ ọba dì í ní èdìdì, ó sì fi àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ránṣẹ́ nípa ọwọ́ àwọn asáréjíṣẹ́ lórí ẹṣin, tí wọ́n ń gun ẹṣin-agangan tí a ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn ọba, àwọn ọmọ abo ẹṣin asárétete.” (Ẹ́sítérì 8:10) Ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, àwọn aláṣẹ àti àwọn ológun máa ń lo irú ètò ìfìwéránṣẹ́ yìí.
Wọn kò fàyè gba àwọn èèyàn láti fi ìwé àdáni, irú èyí tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn míì kọ, ránṣẹ́ nípasẹ̀ ètò ìfìwéránṣẹ́ yìí. Ẹni tó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀ lè rán ẹrú rẹ̀ kó lọ bá òun fi ìwé jíṣẹ́. Àmọ́, ṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi ìwé rán àwọn ojúlùmọ̀ tàbí àwọn àjèjì pàápàá, tó bá ń lọ sí ọ̀nà ibi tí wọ́n fẹ́ fi ìwé náà ránṣẹ́ sí. Àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́, sójà tàbí àwọn oníṣòwò jẹ́ ẹni tí wọ́n lè fi ìwé rán. Ohun pàtàkì kan tí wọ́n sábà máa ń wò ni bí ẹni yẹn ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí, àti bóyá á lè fi ìwé náà jíṣẹ́ bí wọ́n ṣe fún un gẹ́lẹ́. Bíbélì fi hàn pé Pọ́ọ̀lù fi àwọn kan lára ìwé tó kọ rán àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń rin ìrìn àjò.—Éfésù 6:21, 22; Kólósè 4:7.
áwo ni ètò káràkátà ṣe rí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì?
Ohun tó wọ́pọ̀ jù nínú ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Ísírẹ́lì láyé àtijọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ darandaran àti ṣíṣe pàṣípààrọ̀ nǹkan. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọjà ní àwọn ẹnubodè ìlú, irú bíi “Ẹnubodè Àgùntàn,” “Ẹnubodè Ẹja” àti “Ẹnubodè Èéfọ́ Ìkòkò.” (Nehemáyà 3:1, 3; Jeremáyà 19:2) Ó jọ pé irú ọjà tí wọ́n ń tà ní ẹnubodè kọ̀ọ̀kan ni orúkọ wọ̀nyí ń tọ́ka sí. Bíbélì tún mẹ́nu ba “ojú pópó àwọn olùṣe búrẹ́dì” èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti àwọn ọjà míì tí wọ́n máa ń tà nígbà yẹn.—Jeremáyà 37:21.
Báwo ni owó ọjà ṣe rí nígbà yẹn? Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì sọ pé: “Láti ayé àtijọ́ ni iye owó ọjà kì í ti í dúró sójú kan, ó sì máa ń ṣòro láti fi ìdánilójú sọ iye tí owó ọjà kan lè jẹ́ níbì kan lásìkò kan pàtó.” Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìsọfúnni tí a rí nínú àwọn ìwé àtijọ́, títí kan Bíbélì pàápàá, fi hàn pé láyé ìgbà yẹn, iye ọjà máa ń wọ́n gógó nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, láyé àtijọ́ wọ́n máa ń ṣe òwò ẹrú. Nígbà tí wọ́n ta Jósẹ́fù sí oko ẹrú, ogún ẹyọ owó fàdákà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní ìṣírò ti ṣékélì, ni wọ́n tà á, ó sì ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ iye tí wọ́n sábà máa ń ta ẹrú ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jẹ́nẹ́sísì 37:28) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, iye tí wọ́n ń ta ẹrú ti di ọgbọ̀n ṣékélì. (Ẹ́kísódù 21:32) Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, iye náà ti di àádọ́ta [50] ṣékélì. (2 Ọba 15:20) Ní igba ọdún lẹ́yìn èyí, ìyẹn lásìkò tí àwọn ará Páṣíà ń ṣàkóso, iye tí wọ́n ń ta ẹrú ti lọ sókè sí àádọ́rùn-ún [90] ṣékélì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí fi hàn pé ayé òde òní kọ́ ni ìṣòro ọ̀wọ́n gógó ọjà bẹ̀rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Asáréjíṣẹ́ kan ní ilẹ̀ Páṣíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwòrán ara ògiri tó ń ṣàfihàn ọjà tí wọ́n ti ń ta èso
[Credit Line]
© DeA Picture Library/Art Resource, NY