Ìgbésí Ayé ní Àkókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Owó
“Ó sì jókòó ní ìdojúkọ àwọn àpótí ìṣúra, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkíyèsí bí ogunlọ́gọ̀ náà ṣe ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra; ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì ń sọ ẹyọ owó púpọ̀ sínú wọn. Wàyí o, òtòṣì opó kan wá, ó sì sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú rẹ̀, tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an.”—MÁÀKÙ 12:41, 42.
BÍBÉLÌ sábà máa ń mẹ́nu kan owó. Bí àpẹẹrẹ, a rí i nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere bí Jésù ṣe lo oríṣiríṣi ẹyọ owó láti fi kọ́ni ní àwọn ìlànà tó ṣe pàtàkì. Ó fa ẹ̀kọ́ yọ nínú ọrẹ tí obìnrin opó kan ṣe pẹ̀lú “ẹyọ owó kéékèèké méjì,” bó ṣe wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí. Nígbà kan, ó fi ẹyọ owó kan tó ń jẹ́ dínárì han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti jẹ́ kí wọ́n mọ ojú tó yẹ kí wọ́n máa fi wo àṣẹ ìjọba.a—Mátíù 22:17-21.
Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe owó? Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe owó ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì? Báwo ni wọ́n ṣe ń lò ó? Kí la sì rí kọ́ nínú Bíbélì nípa èrò tó yẹ ká ní nípa owó?
Látorí Ṣíṣe Pàṣípààrọ̀ Dórí Lílo Mẹ́táàlì Iyebíye
Kí wọ́n tó ṣe owó, ńṣe làwọn oníṣòwò máa ń ṣe pàṣípààrọ̀ nǹkan. Wọ́n máa ń fi iṣẹ́ àti àwọn nǹkan ìní ṣe pàṣípààrọ̀, ìníyelórí wọn sì gbọ́dọ̀ dọ́gba. Àmọ́ ìnira tó pọ̀ ló wà nínú ṣíṣe pàṣípààrọ̀ nǹkan. Kí ẹni méjì tó fẹ́ ṣe pàṣípààrọ̀ nǹkan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, nǹkan tí wọ́n fẹ́ lò gbọ́dọ̀ jẹ́ nǹkan tí ẹnì kejì wọn fẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn oníṣòwò ló tún máa wá bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn ẹrù tó wúwo, bí àwọn ẹran tàbí àpò ọkà tí wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀.
Nígbà tó yá, àwọn oníṣòwò wá rí i pé àwọn nílò ohun kan tó máa túbọ̀ rọrùn téèyàn lè lò láti fi ra ọjà àti èyí tí èèyàn lè gbà tó bá ta ọjà. Wọ́n wá rí i pé, ohun tó máa yanjú ọ̀ràn náà ni pé kí àwọn máa lo mẹ́táàlì iyebíye bíi góòlù, fàdákà àti bàbà. Nínú àwòrán tó wà níbi yìí, wàá rí oníṣòwò kan tó ń lo mẹ́táàlì iyebíye kan tó jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ àtàwọn ègé góòlù láti fi ra ọjà tàbí sanwó iṣẹ́. Wọ́n á fara balẹ̀ wọn àwọn mẹ́táàlì náà lórí òṣùwọ̀n kí wọ́n tó fi àwọn ẹrù náà ṣe pàṣípààrọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúráhámù ra ilẹ̀ ìsìnkú to fẹ́ fi sin Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n, ó wọn iye fàdákà tí ẹni tó ni ilẹ̀ náà sọ.—Jẹ́nẹ́sísì 23:14-16.
Ní àkókò tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin tí wọ́n kọ sílẹ̀, àwọn oníṣòwò tó ní ojúkòkòrò máa ń lo òṣùwọ̀n èké tàbí èyí tí kò péye kí wọ́n lè rẹ́ àwọn oníbàárà jẹ. Ohun ìríra ni ìwà àìṣòótọ́ jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ oníṣòwò pé: “Kí ẹ ní òṣùwọ̀n pípéye, ìwọ̀n pípéye.” (Léfítíkù 19:36; Òwe 11:1) Lónìí, á dára kí àwọn tó ń ta ọjà rántí pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ojúkòkòrò àti àìṣòótọ́ kò yí pa dà.—Málákì 3:6; 1 Kọ́ríńtì6:9, 10.
Bí Wọ́n Ṣe Kọ́kọ́ Ṣe Àwọn Ẹyọ Owó
Ó jọ pé ìlú Lydia (ìyẹn Tọ́kì òde òní) ni wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe àwọn ẹyọ owó, ìyẹn ṣáájú nǹkan bí ọdún 700 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Kò pẹ́ tí àwọn tó ń fi mẹ́táàlì rọ nǹkan ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹyọ owó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ, tí àwọn èèyàn tó wà ní àwọn ilẹ̀ tá a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì wá bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n.
Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ẹyọ owó? Oníṣẹ́ mẹ́táàlì á yọ́ mẹ́táàlì lórí iná (1) á sì dà á sínú ohun kan táá mú kí mẹ́táàlì náà rí pẹlẹbẹ (2). Lẹ́yìn náà, yóò ki àwọn mẹ́táàlì tó rí pẹlẹbẹ náà bọ àárín ohun tí wọ́n ti fín àmì tàbí àwòrán sí (3). Á wá fi òòlù gba ohun tí wọ́n fín àwòrán sí náà mọ́ ara mẹ́táàlì pẹlẹbẹ náà kó bàa lè hàn lára rẹ̀ (4). Bí wọ́n ṣe máa ń sáré ṣe é kì í jẹ́ kí àwòrán náà bọ́ sí àárín àwọn kan lára ẹyọ owó mẹ́táàlì náà. Àwọn oníṣẹ́ mẹ́táàlì yóò ṣa àwọn ẹyọ owó náà jọ, wọ́n á ṣe ìdíwọ̀n wọn láti rí i dájú pé wọ́n kò wúwo ju ara wọn lọ, wọ́n tún máa ń gé àwọn mẹ́táàlì tó bá wà ní eteetí ẹyọ owó náà kúrò, tó bá yẹ bẹ́ẹ̀ (5).
Àwọn Olùpààrọ̀ Owó, Àwọn Agbowó Orí Àtàwọn Oníṣẹ́ Báńkì
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, wọ́n ń kó ẹyọ owó láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá sí ilẹ̀ Palẹ́sínì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arìnrìn àjò tó wá sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù máa ń kó ẹyọ owó ilẹ̀ òkèèrè dání wá síbẹ̀. Àmọ́ àwọn tó ń bójú tó tẹ́ńpìlì kì í gba owó orí tẹ́ńpìlì lọ́wọ́ àwọn èèyàn àyàfi táwọn èèyàn náà bá lè fi oríṣi ẹyọ owó kan sanwó. Inú tẹ́ńpìlì làwọn tó ń pààrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè ti ń ṣòwò, wọ́n sì máa ń gba owó tó pọ̀ gan-an tí wọ́n bá fẹ́ pààrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè sí owó tí oníbàárà bá fẹ́. Jésù dá àwọn oníwọra èèyàn yìí lẹ́bi. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti sọ ilé Jèhófà di “ilé ọjà títà” àti “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”—Jòhánù 2:13-16; Mátíù 21:12, 13.
Àwọn olùgbé Palẹ́sìnì tún ní láti san oríṣiríṣi owó orí. Ọ̀kan ni “owó orí” táwọn alátakò Jésù bi í ní ìbéèrè nípa rẹ̀. (Mátíù 22:17) Àwọn owó orí míì ni owó ojú ọ̀nà àti owó lórí àwọn ẹrù tí wọ́n ń kó wọ̀lú àtèyí tí wọ́n ń kó lọ sílẹ̀ òkèèrè. Aláìṣòótọ́ àti ẹni yẹ̀yẹ́ làwọn èèyàn mọ àwọn tó ń gbowó orí ìjọba nílẹ̀ Palẹ́sìnì sí. (Máàkù 2:16) Àwọn agbowó orí máa ń kó ọrọ̀ jọ nípa bíbu owó lé àwọn tó ń sanwó orí, wọ́n á sì wá tọ́jú èyí tó lé lórí owó náà sí àpò ara wọn. Àmọ́, àwọn agbowó orí kan, bíi Sákéù, fetí sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, wọ́n sì fi ìwà àìṣòótọ́ wọn sílẹ̀. (Lúùkù19:1-10) Bákan náà, lóde òní àwọn tó bá fẹ́ máa tọ Kristi lẹ́yìn gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo títí kan iṣẹ́ ajé wọn.—Hébérù 13:18.
Àwọn míì tó ń bójú tó owó ni àwọn oníṣẹ́ báńkì. Yàtọ̀ sí pípààrọ̀ owó ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n máa ń báni tọ́jú owó pa mọ́, wọ́n ń yáni lówó, wọ́n sì máa ń san owó èlé fún àwọn tó fowó wọn ṣòwò lọ́dọ̀ báńkì. Jésù mẹ́nu kan àwọn oníṣẹ́ báńkì nínú àkàwé tó sọ nípa àwọn ẹrú tí ọ̀gá wọn fún ní iye tó yàtọ̀ síra láti fi ṣòwò.—Mátíù 25:26, 27.
Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí, àwọn èèyàn ní láti ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rí owó ra ohun tí wọ́n nílò. Gbólóhùn tí Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì Ọba ní ọ̀pọ̀ ọ̀gọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn pé kí ó kọ ṣì jóòótọ́, ó ní: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” Àmọ́ Sólómọ́nì tún sọ pé ọgbọ́n ṣe pàtàkì gan-an ju owó lọ nítorí pé ó “máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Inú Bíbélì la ti lè rí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀.
Jésù mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní èrò tó tọ́ nípa owó nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a ó fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n tí a bá ń ṣọ́wó ná, tí a bá jẹ́ olóòótọ́ nídìí rẹ̀, tí a kò sì nífẹ̀ẹ́ owó.—1 Tímótì 6:9, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí náà, “Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ẹyọ Owó” lójú ìwé 26.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ẹyọ Owó
● Owó lepton bàbà jẹ́ ọ̀kan lára ẹyọ owó tó kéré jù lọ tí wọ́n ń ná ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nílẹ̀ Palẹ́sìnì. Ẹyọ owó lepta méjì ni owó iṣẹ́ tí alágbàṣe kan bá ṣe ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹyọ owó lepta méjì ni opó tálákà yẹn sọ sínú àpótí ìṣúra tó wà ní tẹ́ńpìlì.—Máàkù 12:42.
● Ẹyọ owó dírákímà fàdákà jẹ́ ẹyọ owó ilẹ̀ Gíríìsì, òun sì ni alágbàṣe kan máa gbà fún iṣẹ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iṣẹ́ ọjọ́ kan. (Lúùkù 15:8, 9) Dírákímà méjì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin Júù máa ń san lọ́dún fún owó orí tẹ́ńpìlì.—Mátíù 17:24.
● Ẹyọ owó dínárì fàdákà jẹ́ ẹyọ owó ilẹ̀ Róòmù tó ní àwòrán Késárì nínú, nítorí náà òun ló máa dára jù fún ẹyọ owó tí wọ́n fi ń san “owó òde,” èyí tí ìjọba Róòmù ń gbà lọ́wọ́ gbogbo ọkùnrin Júù tó ti tó owó orí san. (Róòmù 13:7) Agbanisíṣẹ́ máa ń san dínárì kan fún òṣìṣẹ́ kan fún iṣẹ́ wákàtí méjìlá tó jẹ́ iṣẹ́ ọjọ́ kan.—Mátíù 20:2-14.
● Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n máa ń ná ògidì ṣékélì fàdákà nílẹ̀ Palẹ́sínì, ìlú Tírè ni wọ́n sì ti ṣe owó náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, ṣékélì ìlú Tírè ni ọgbọ̀n “ẹyọ fàdákà” tí àwọn olórí àlùfáà san fún Júdásì Ísíkáríótù nítorí pé ó da Jésù.—Mátíù 26:14-16.
Bí ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan ṣe tóbi tó