Ìgbòkègbodò Àwọn Àgbẹ̀ Jálẹ̀ Ọdún ní “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
LỌ́DÚN 1908, àwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ohun kan tó múnú ẹni dùn gan-an ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù, níbi tí ìlú Gésérì tá a kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì wà látijọ́. Wàláà òkúta ẹfun kan tí wọ́n gbà pé ó ti wà láti ọ̀rúndún kẹwàá ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n rí. Wọ́n fi èdè Hébérù ìgbàanì kọ nǹkan kan sára wàláà náà, àwọn awalẹ̀pìtàn sì gbà pé ó jẹ́ àkópọ̀ ọ̀kankòjọ̀kan iṣẹ́ táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe jálẹ̀ ọdún. Wọ́n wá ń pe wàláà yìí ní Kàlẹ́ńdà Gésérì.
Orúkọ ẹni tó wà lára wàláà náà pé ó kọ ọ́ ni, Ábíjà. Ọ̀pọ̀ awalẹ̀pìtàn gbà pé ọmọ iléèwé lẹni tó kọ ọ́ lọ́nà ewì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àṣetiléwá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn awalẹ̀pìtàn kan ò gbà bẹ́ẹ̀.a Ṣé wàá fẹ́ fojú inú wo bí Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí nígbàanì látinú ohun tí ọmọ kan tó gbé láyé ìgbà yẹn kọ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ìtàn Bíbélì kan.
Oṣù Méjì fún Kíkórè
Látorí ìkórè gbogbo gbòò ni Ábíjà tó kọ kàlẹ́ńdà ìgbàanì yìí ti bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkórè gbogbo gbòò yìí, tó bọ́ sí oṣù Étánímù, ni àkọ́kọ́ lórí kàlẹ́ńdà yìí, ìdí pàtàkì wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi kà á sí àkókò àṣekágbá iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ́dún. Oṣù Étánímù yìí (tí wọ́n wá ń pè ní Tíṣírì nígbà tó yá) bọ́ sáàárín oṣù September àti October lórí kàlẹ́ńdà tiwa lónìí. Àsìkò àjọyọ̀ ló máa ń jẹ́ torí pé iṣẹ́ ìkórè yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí nígbà náà, Ábíjà pẹ̀lú á sì bá wọn ṣàjọyọ̀ náà. Fojú inú wo bínú rẹ̀ á ṣe máa dùn bó ṣe ń ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ níbi tó ti ń ṣe àtíbàbà tí wọ́n máa gbé fún ọ̀sẹ̀ kan, tí wọ́n á máa fọpẹ́ fún Jèhófà tayọ̀tayọ̀ nítorí ìkórè oko wọn!—Diutarónómì 16:13-15.
Ní àkókò yìí, èso ólífì á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbó tó fáwọn ará ilé Ábíjà láti kórè rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń fi ọ̀pá lu àwọn ẹ̀ka igi ólífì kí àwọn èso rẹ̀ lè gbọ̀n sílẹ̀. Ábíjà tó ṣì jẹ́ ọmọdé ò ní lè ṣe ìyẹn àmọ́ inú rẹ̀ á máa dùn bó ṣe ń wò wọ́n. (Diutarónómì 24:20) Tí wọ́n bá ti ṣèyẹn tán, wọ́n á wá kó èso ólífì náà lọ síbi tí wọ́n ti máa fi ọlọ tẹ̀ ẹ́ kí òróró rẹ̀ lè jáde. Ìdílé míì tiẹ̀ lè má kó tiwọn lọ síbẹ̀. Wọ́n á kàn da àwọn èso ólífì tí wọ́n fọ́ sínú omi, wọ́n á wá máa fi nǹkan ré òróró rẹ̀ tó bá léfòó. Lọ́rọ̀ kan ṣá, òróró ólífì wúlò gan-an ni, torí oúnjẹ nìkan kọ́ ló wà fún. Wọ́n ń rọ ọ́ sínú àtùpà, wọ́n sì tún fi ń wo ọgbẹ́, irú bí ọgbẹ́ tí Ábíjà ọ̀dọ́mọdé lè ní níbi tó ti ń ṣeré.
Oṣù Méjì fún Fífúnrúgbìn
Nígbà àkọ́rọ̀ òjò, ó ṣeé ṣe kínú Ábíjà máa dùn bí omi òjò tó ń rọ̀ náà bá ṣe ń tutù mọ́ ọn lára. Ó ṣeé ṣe kí bàbá rẹ̀ ti jẹ́ kó mọ bí òjò ti ṣe pàtàkì tó fún ilẹ̀ wọn. (Diutarónómì 11:14) Oòrùn á ti mú kí ilẹ̀ náà le, àmọ́ òjò tó rọ̀ yìí á mú kó rọ̀ kí ebè lè ṣeé kọ. Láyé ìgbà yẹn, wọ́n máa ń fi ẹranko fa ohun ìtúlẹ̀ onígi tí ẹnu rẹ̀ lè jẹ́ irin. Olóko á wá máa darí ohun ìtúlẹ̀ náà tẹ̀ lé ẹranko tó ń fà á kí poro rẹ̀ má bàa wọ́. Ilẹ̀ dára gan-an ní Ilẹ̀ Ìlérí, nítorí náà, bó ti wù kí ilẹ̀ kan kéré tó níbẹ̀, kódà kó jẹ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, wọ́n á gbin nǹkan sí i. Àmọ́ ohun ìtúlẹ̀ kéékèèké bí ọkọ́ ni wọ́n fi ń roko gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ṣá o.
Tí wọ́n bá ti wá túlẹ̀ tán wọ́n lè gbin àlìkámà àti ọkà bálì sí i. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, ọ̀rọ̀ irú ìfúnrúgbìn bẹ́ẹ̀ fún oṣù méjì ni Kàlẹ́ńdà Gésérì mẹ́nu kàn tẹ̀ lé e. Afúnrúgbìn lè da irúgbìn rẹ̀ sínú ìṣẹ́po ẹ̀wù rẹ̀, kó máa fọwọ́ bù ú láti ibẹ̀ kó sì máa fún un káàkiri oko.
Oṣù Méjì fún Gbígbin Irúgbìn Àgbìnkẹ́yìn
Kò sígbà tí “ilẹ̀ dáradára” náà kì í méso jáde. (Diutarónómì 3:25) Oṣù December ni òjò máa ń rọ̀ jù, tí ewéko tútù yọ̀yọ̀ yóò bo gbogbo ilẹ̀. Ìgbà yìí ni wọ́n ń gbin onírúurú ẹ̀wà àti ewébẹ̀ àgbìnkẹ́yìn. (Ámósì 7:1, 2) Nínú wàláà yẹn, Ábíjà pè é ní “ewébẹ̀ ìgbà ìrúwé,” tàbí ní ìtumọ̀ míì, “irúgbìn àgbìnkẹ́yìn.” Ní àsìkò yẹn, oúnjẹ aládùn tí wọ́n fàwọn ewébẹ̀ àsìkò yẹn sè máa ń wọ́pọ̀ gan-an ni.
Bí àkókò ọ̀gìnnìtìn yẹn bá ti wá kọjá, igi álímọ́ńdì á yọ òdòdò funfun àti aláwọ̀ osùn, èyí tó máa fi hàn pé wọ́n ti ń wọ ìgbà ìrúwé. Ojú ọjọ́ móoru tàìmóoru ni òdòdó igi yìí ti máa ń yọ o, kódà bó jẹ́ oṣù January.—Jeremáyà 1:11, 12.
Oṣù Kan fún Ìkórè Ọ̀gbọ̀
Ábíjà tún wá mẹ́nu kan ọ̀gbọ̀. Ìyẹn lè mú ẹ rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ olókè ní Jùdíà, ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà tí wọ́n bí Ábíjà. Ní ìlú Jẹ́ríkò, Ráhábù fi amí méjì pa mọ́ “sáàárín pòròpórò ọ̀gbọ̀ tí a . . . tò ní ẹsẹẹsẹ” sórí òrùlé rẹ̀ kó lè gbẹ. (Jóṣúà 2:6) Ọ̀gbọ̀ wúlò gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí wọ́n tó lè rí àwọn fọ́nrán okùn ọ̀gbọ̀, ara rẹ̀ ní láti kọ́kọ́ jẹrà ná. Tí ìrì bá ń sẹ̀ sí ọ̀gbọ̀ lára ó lè máa jẹrà díẹ̀díẹ̀, àmọ́ tí wọ́n bá kó o sínú odò tàbí adágún omi ó máa ń tètè jẹrà. Tó bá jẹrà tán wọ́n á wá yọ àwọn fọ́nrán okùn rẹ̀, wọ́n á fi hun aṣọ ìgbòkun, aṣọ àgọ́ tàbí aṣọ téèyàn lè wọ̀. Wọ́n tún máa ń fi ọ̀gbọ̀ ṣe òwú àtùpà.
Àwọn kan ò gbà pé wọ́n ń gbin ọ̀gbọ̀ lágbègbè ìlú Gésérì, torí omi ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀. Àwọn míì sọ pé apá ìparí ọdún ni wọ́n máa ń gbìn ín. Ìdí nìyẹn táwọn kan fi gbà pé “koríko” tí ẹran ń jẹ ni “ọ̀gbọ̀” tó wà nínú Kàlẹ́ńdà Gésérì túmọ̀ sí.
Oṣù Kan fún Ìkórè Ọkà Bálì
Lọ́dọọdún, lẹ́yìn ìgbà gígé ọ̀gbọ̀, Ábíjà máa ń rí ṣírí ọkà bálì tútù yọ̀yọ̀, ìyẹn sì ni nǹkan ọ̀gbìn tó mẹ́nu kàn tẹ̀ lé e nínú kàlẹ́ńdà rẹ̀. Oṣù àwọn Hébérù tó bọ́ sí àkókò yìí ni oṣù Ábíbù, tó túmọ̀ sí “Ṣírí Ọkà Tútù Yọ̀yọ̀,” bóyá tó ń tọ́ka sí pé ṣírí ọkà bálì ti gbó bó tilẹ̀ pé ó ṣì rọ̀. Jèhófà pàṣẹ pé: “Máa pa oṣù Ábíbù mọ́, kí o sì máa ṣe ayẹyẹ ìrékọjá fún Jèhófà.” (Diutarónómì 16:1) Oṣù Ábíbù yìí (tí wọ́n ń pè ní Nísàn nígbà tó yá) bọ́ sí apá kan oṣù March mọ́ apá kan April lóde òní. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tí ọkà bálì bá ń gbó ni wọ́n máa ń mọ̀ pé oṣù yìí ti bẹ̀rẹ̀. Lóde òní pàápàá, ìyẹn náà làwọn Júù tí wọ́n wà nínú ẹ̀ya ìsìn Júù tí wọ́n ń pè ní Karaite fi máa ń pinnu ìgbà tí ọdún tuntun tiwọn bẹ̀rẹ̀. Láìfọ̀rọ̀ gùn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti rí i pé wọ́n fi ìtì àkọ́so ọkà bálì síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Ábíbù.—Léfítíkù 23:10, 11.
Kòṣeémánìí ni ọkà Bálì jẹ́ fún ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ Ísírẹ́lì. Òun làwọn èèyàn sábà máa ń fi ṣe búrẹ́dì, pàápàá àwọn tálákà, torí pé owó rẹ̀ ò wọ́n tó ti àlìkámà.—Ìsíkíẹ́lì 4:12.
Oṣù Kan fún Kíkórè àti Dídíwọ̀n
Tó o bá fojú inú wo ìgbà ayé Ábíjà lọ́hùn-ún, àárọ̀ ọjọ́ kan ni yóò kàn rí i pé ìkùukùu òjò bẹ̀rẹ̀ sí í tú ká díẹ̀díẹ̀, tí yóò sì di pé òjò ò rọ̀ mọ́. Ìrì nìkan lá wá máa sẹ̀ sórí àwọn ewéko Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ́nẹ́sísì 27:28; Sekaráyà 8:12) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àgbẹ̀ mọ̀ pé láàárín àsìkò yìí sígbà Pẹ́ńtíkọ́sì, ó nírú ẹ̀fúùfù tó yẹ kó máa fẹ́ sáwọn nǹkan ọ̀gbìn tí wọ́n máa kórè, torí inú àwọn oṣù yìí ní oòrùn máa ń mú jù lọ́dún. Ẹ̀fúùfù tó ní ọ̀rinrin tó máa ń fẹ́ wá láti àríwá dáa fún onírúurú ọkà, àmọ́ kò dáa fáwọn igi eléso tó bá ní ìtànná. Ẹ̀fúùfù gbígbóná, tí kò ní ọ̀rinrin, tó ń fẹ́ wá láti gúúsù ló máa jẹ́ kí ìtànná igi lè lanu sílẹ̀ kó sì gbakọ láti lè méso jáde.—Òwe 25:23; Orin Sólómọ́nì 4:16.
Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ojú ọjọ́ ti rí sí i pé òjò ń rọ̀, ẹ̀fúùfù sì ń fẹ́ bó ṣe yẹ gẹ́lẹ́ kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fáwọn ewéko àtàwọn ohun abẹ̀mí mìíràn láyé. Nítorí náà, nígbà ayé Ábíjà, ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ “ilẹ̀ àlìkámà àti ọkà bálì àti àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì, ilẹ̀ ólífì olóròóró àti oyin.” (Diutarónómì 8:8) Ó ṣeé ṣe kí baba ńlá Ábíjà sọ fún un nípa ìgbà kan tí oúnjẹ yamùrá nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba, èyí tó fi hàn kedere pé Jèhófà bù kún wọn.—1 Àwọn Ọba 4:20.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ nípa ìkórè, ọ̀rọ̀ kan tún wà nínú kàlẹ́ńdà tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, táwọn kan gbà pé ó túmọ̀ sí “dídíwọ̀n.” Èyí lè tọ́ka sí dídíwọ̀n ohun téèyàn kórè láti lè fún ẹni tó ni ilẹ̀ oko náà àtàwọn òṣìṣẹ́ ní ìpín tiwọn tàbí láti fi san owó orí pàápàá. Àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé míì sọ pé “jíjẹ àsè” ni àwọn lóye ọ̀rọ̀ Hébérù yẹn sí, wọ́n ní ó ní láti jẹ́ pé ó ń tọ́ka sí Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀, tó máa ń wáyé lóṣù Sífánì (ìyẹn apá kan oṣù May mọ́ apá kan June).—Ẹ́kísódù 34:22.
Oṣù Méjì fún Kíkán Ewé Dà Nù
Ábíjà tún wá kọ nípa fífi oṣù méjì tọ́jú àjàrà. Bóyá òun pàápàá tiẹ̀ ti bá wọn kán dà nù lára ewé àjàrà tó ti pọ̀ jù kí oòrùn lè ráyè ta sí èso àjàrà. (Aísáyà 18:5) Lẹ́yìn èyí ni yóò wá kan ìgbà kíkó èso àjàrà jọ, èyí tó jẹ́ ìgbà táwọn ọmọdé ayé ìgbà yẹn fẹ́ràn gan-an. Àkọ́pọ́n èso àjàrà a sì máa dùn gan-an ni! Ábíjà lè ti gbọ́ nípa àwọn amí méjìlá tí Mósè rán lọ ṣamí Ilẹ̀ Ìlérí. Àsìkò àkọ́pọ́n èso àjàrà ni wọ́n lọ láti lọ wo bí ilẹ̀ náà ṣe dára tó. Nígbà yẹn, òṣùṣù èso àjàrà kan tóbi débi pé géńdé méjì ló ní láti gbé e!—Númérì 13:20, 23.
Oṣù Kan fún Èso Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn
Ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn lórí kàlẹ́ńdà Ábíjà dá lórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Láyé ìgbàanì, ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, àkókò èso ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn máa ń jẹ́ fáwọn àgbẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà ayé Ábíjà, Jèhófà lo ọ̀rọ̀ náà “apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn” láti fi ṣàpèjúwe pé ‘òpin ti dé bá àwọn ènìyàn òun Ísírẹ́lì.’ Ẹwà èdè ni Jèhófà lò yìí nínú èdè Hébérù bó ṣe fi “èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn” ṣàpèjúwe “òpin” tó máa dé bá Ísírẹ́lì. (Ámósì 8:2) Ó yẹ kí èyí rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ yẹn létí pé òpin ti dé bá àwọn àti pé ìdájọ́ Jèhófà ti dé sórí àwọn. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀tọ́ wà lára èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí Ábíjà ń sọ. Wọ́n lè fi ọ̀pọ̀tọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ṣe ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́ fún jíjẹ tàbí kí wọ́n pò ó pọ̀ kí wọ́n fi lé ojú eéwo kó lè sàn.—2 Àwọn Ọba 20:7.
Kàlẹ́ńdà Gésérì Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní
Ó jọ pé ọmọ náà, Ábíjà, mọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè rẹ̀ gan-an ni. Iṣẹ́ àgbẹ̀ sì kúkú wọ́pọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ká ní o ò tiẹ̀ wá mọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ rárá, àwọn ohun tí wàláà Gésérì sọ nípa rẹ̀ á jẹ́ kó o lè máa fojú inú rí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà tó o bá ń ka Bíbélì, ìyẹn á jẹ́ kóhun tó ò ń kà túbọ̀ yé ọ, kó sì túbọ̀ nítumọ̀ sí ọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn kan ò fi gbogbo ara gbà pé bí wọ́n ṣe to ohun tó wà nínú Kàlẹ́ńdà Gésérì bá bí Bíbélì ṣe sábà máa ń to oṣù mu. Nǹkan míì tún ni pé, ìgbà táwọn àgbẹ̀ apá ibì kan ní Ilẹ̀ Ìlérí ń ṣe àwọn iṣẹ́ oko kan lè yàtọ̀ díẹ̀ sígbà táwọn àgbẹ̀ apá ibòmíì níbẹ̀ ń ṣe é.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
OHUN TÓ ṢEÉ ṢE KÓ JẸ́ ÌTUMỌ̀ Ọ̀RỌ̀ INÚ KÀLẸ́ŃDÀ GÉSÉRÌ:
“Àwọn oṣù ìkórè èso àjàrà àti ti ólífì;
àwọn oṣù ìfúnrúgbìn;
àwọn oṣù ewéko ìgbà ìrúwé;
oṣù gígé ọ̀gbọ̀;
oṣù ìkórè ọkà báálì;
oṣù ìkórè àlìkámà àti dídíwọ̀n;
àwọn oṣù ìrẹ́wọ́ àjàrà;
oṣù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.”
[ìbuwọ́lùwé:] Ábíjàb
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b A rí i látinú ìwé Textbook of Syrian Semitic Inscriptions, Apá Kìíní, látọwọ́ John C. L. Gibson, 1971.
[Credit Line]
Archaeological Museum of Istanbul
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
NÍSÀN (ÁBÍBÙ)
March—April
ÍÍYÀ (SÍFÌ)
April—May
SÍFÁNÌ
May—June
TÁMÚSÌ
June—July
ÁBÌ
July—August
ÉLÚLÌ
August—September
TÍṢÍRÌ (ÉTÁNÍMÙ)
September—October
HÉṢÍFÁNÙ (BÚLÌ)
October—November
KÍSÍLÉFÌ
November—December
TÉBÉTÌ
December—January
ṢÉBÁTÌ
January—February
ÁDÁRÌ
February—March
FÍÁDÀ
March
[Credit Line]
Àgbẹ̀: Garo Nalbandian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ibi táwọn awalẹ̀pìtàn ti walẹ̀ nílùú Gésérì
[Credit Line]
© 2003 BiblePlaces.com
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Igi álímọ́ńdì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọ̀gbọ̀
[Credit Line]
Dr. David Darom
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọkà Bálì
[Credit Line]
U.S. Department of Agriculture