“Àṣẹ Àgbékalẹ̀ Jèhófà” Kò Lè Kùnà
“Ẹ jẹ́ kí n tọ́ka sí àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà; Ó ti wí fún mi pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi . . . Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ.’”—SÁÀMÙ 2:7, 8.
1. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn àti ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè ní lọ́kàn?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ní ohun kan lọ́kàn fún ìran ènìyàn àti fún ilẹ̀ ayé. Àwọn orílẹ̀-èdè náà ní ohun kan lọ́kàn. Àmọ́ àwọn ohun tí wọ́n ní lọ́kàn yìí yàtọ̀ síra wọn pátápátá! Kò sì yẹ̀ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí Ọlọ́run ti sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.” Ó dájú pé àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn gbọ́dọ̀ ṣẹ, nítorí ó tún sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:9-11.
2, 3. Kí ló hàn kedere nínú sáàmù kejì, àwọn ìbéèrè wo ló sì gbé dìde?
2 Sáàmù kejì jẹ́ ká rí i kedere pé ète Ọlọ́run nípa Mèsáyà Ọba rẹ̀ yóò nímùúṣẹ. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì tó kọ sáàmù yìí ni Ọlọ́run mí sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àkókò pàtàkì kan ń bọ̀ nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò wà nínú ìrúkèrúdò. Àwọn alákòóso wọn yóò lòdì sí Jèhófà Ọlọ́run àti Ẹni Àmì Òróró rẹ̀. Àmọ́, onísáàmù náà tún kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ jẹ́ kí n tọ́ka sí àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà; ó ti wí fún mi pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi . . . Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.’”—Sáàmù 2:7, 8.
3 Kí ni “àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà” túmọ̀ sí fún àwọn orílẹ̀-èdè? Báwo ló ṣe kan aráyé lápapọ̀? Àní, kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí fún gbogbo àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n ń ka sáàmù kejì?
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Wà Nínú Ìrúkèrúdò
4. Báwo lo ṣe máa ṣàkópọ̀ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Sáàmù 2:1, 2?
4 Nígbà tí onísáàmù náà ń tọ́ka sí ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn alákòóso wọn ń ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa kíkọ ọ́ lórin pé: “Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi wà nínú ìrúkèrúdò, tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì ń sọ nǹkan òfìfo lábẹ́lẹ̀? Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ti wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀.”—Sáàmù 2:1, 2.a
5, 6. Kí ni “nǹkan òfìfo” tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè ‘ń sọ lábẹ́lẹ̀’?
5 Kí ni “nǹkan òfìfo” tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè òde òní “ń sọ . . . lábẹ́lẹ̀”? Dípò tí wọn ì bá fi tẹ́wọ́ gba Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run, ìyẹn Mèsáyà tàbí Kristi, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè ‘ń sọ̀rọ̀ lábẹ́lẹ̀,’ wọ́n ń ṣàṣàrò lórí bí ọlá àṣẹ wọn yóò ṣe máa bá a lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ inú sáàmù kejì yìí tún ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa nígbà táwọn aláṣẹ Júù àti ti Róòmù jọ pawọ́ pọ̀ láti pa Jésù Kristi, Ẹni tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́la. Àmọ́, olórí ìmúṣẹ náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, nígbà tá a gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́run. Látìgbà yẹn, kò tíì sí ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lórí ilẹ̀ ayé tó tẹ́wọ́ gba Ọba tí Ọlọ́run yàn yìí.
6 Kí ni onísáàmù náà ní lọ́kàn nígbà tó béèrè pé ‘èé ṣe tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè fi ń sọ nǹkan òfìfo’? Ète wọn ló jẹ́ òfìfo; asán ni, ó sì di dandan kó kùnà. Wọ́n ò lè mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wá sí ayé yìí. Síbẹ̀, wọ́n bá a débi pé wọ́n lòdì sí ìṣàkóso Ọlọ́run. Ní ti tòótọ́, wọ́n fi ìbínú gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ lòdì sí Ọ̀gá Ògo Jù Lọ àti Ẹni Àmì Òróró rẹ̀. Wọ́n mà kúkú gọ̀ o!
Ọba Aṣẹ́gun Tí Jèhófà Yàn
7. Báwo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe lo Sáàmù 2:1, 2 nínú àdúrà wọn?
7 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sọ pé òun ni Sáàmù 2:1, 2 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà táwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n gbàdúrà pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ [Jèhófà], ìwọ ni Ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, àti ẹni tí ó sọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ẹnu baba ńlá wa Dáfídì, ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi di onírúkèrúdò, tí àwọn ènìyàn sì ń ṣe àṣàrò lórí àwọn nǹkan òfìfo? Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn olùṣàkóso sì wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’ Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àti Hẹ́rọ́dù [Áńtípà] àti Pọ́ńtíù Pílátù pẹ̀lú àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ní ti gidi ti kóra jọpọ̀ ní ìlú ńlá yìí lòdì sí Jésù ìránṣẹ́ rẹ mímọ́, ẹni tí ìwọ fòróró yàn.” (Ìṣe 4:24-27; Lúùkù 23:1-12)b Bẹ́ẹ̀ ni o, ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn dìtẹ̀ mọ́ Jésù, ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run fi òróró yàn. Àmọ́ ṣá o, sáàmù yìí yóò ní ìmúṣẹ mìíràn ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà ìyẹn.
8. Báwo ni Sáàmù 2:3 ṣe kan àwọn orílẹ̀-èdè òde òní?
8 Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ọba tó jẹ́ ènìyàn, irú bíi Dáfídì, àwọn orílẹ̀-èdè kèfèrí àtàwọn alákòóso wọn kóra wọn jọ lòdì sí Ọlọ́run àti ẹni tó fi òróró yàn. Àmọ́ ní àkókò tiwa ńkọ́? Àwọn orílẹ̀-èdè òde òní kò fẹ́ fara mọ́ ohun tí Jèhófà àti Mèsáyà rẹ̀ fẹ́ káwọn èèyàn ṣe. Nítorí náà, ohun tí ìṣe wọn fi hàn pé wọ́n ń sọ ni pé: “Ẹ jẹ́ kí a fa ọ̀já wọn já kí a sì ju okùn wọn nù kúrò lọ́dọ̀ wa!” (Sáàmù 2:3) Òfin èyíkéyìí tí Ọlọ́run àti Ẹni Àmì Òróró rẹ̀ bá gbé kalẹ̀ ni àwọn alákòóso àtàwọn orílẹ̀-èdè máa ń lòdì sí. Ó sì dájú pé gbogbo ipa tí wọ́n bá sà láti fa irú àwọn ọ̀já bẹ́ẹ̀ já kí wọ́n sì ju irú okùn bẹ́ẹ̀ nù ni yóò já sí pàbó.
Jèhófà Fi Wọ́n Ṣẹ̀sín
9, 10. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín?
9 Kò sóhun tó kan Jèhófà bí àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè tiẹ̀ ń sapá lọ́nàkọnà láti máa dá ṣàkóso ara wọn. Sáàmù kejì tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹni náà tí ó jókòó ní ọ̀run yóò rẹ́rìn-ín; Jèhófà yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín.” (Sáàmù 2:4) Ńṣe ni Ọlọ́run ń mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ lọ bí ẹni pé àwọn alákòóso wọ̀nyí kò já mọ́ nǹkankan. Ó fi wọ́n rẹ́rìn-ín nítorí àfojúdi wọn, ó si fi wọ́n ṣẹ̀sín. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yangàn. Oníyẹ̀yẹ́ ni wọ́n lójú Jèhófà. Ńṣe ló ń fi àtakò wọn tó já sí pàbó rẹ́rìn-ín.
10 Níbòmíràn nínú sáàmù, Dáfídì tún tọ́ka sí àwọn èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá, ó sì kọrin pé: “Ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Jí láti yí àfiyèsí rẹ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Má fi ojú rere hàn sí ọ̀dàlẹ̀ èyíkéyìí tí ó jẹ́ aṣenilọ́ṣẹ́. Wọ́n ń padà wá ṣáá ní àṣálẹ́; wọ́n ń gbó ṣáá bí ajá, wọ́n sì ń lọ yí ká ìlú ńlá náà. Wò ó! Wọ́n ń fi ẹnu wọn ṣe ìtújáde; àwọn idà wà ní ètè wọn, nítorí pé ta ni ó ń fetí sílẹ̀? Ṣùgbọ́n ìwọ fúnra rẹ, Jèhófà, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín; ìwọ yóò fi gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín.” (Sáàmù 59:5-8) Jèhófà fi ìyangàn àti ìdàrúdàpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́rìn-ín níbi tí wọ́n ti ń hùwà òmùgọ̀ sí Ọlọ́run.
11. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá gbìyànjú láti ṣe ohun tó lòdì sí ète Ọlọ́run?
11 Ohun tí Sáàmù kejì sọ mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára pé Ọlọ́run lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí. A lè ní ìdánilójú pé kò sígbà tí kì í mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, kì yóò sì ṣá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tì láé. (Sáàmù 94:14) Nítorí náà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá sapá láti ṣe ohun tó lòdì sí ète Jèhófà? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí sáàmù yìí wí, Ọlọ́run “yóò sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀,” bí ìgbà tí ààrá ńlá bá sán. Ìyẹn nìkan kọ́ o, “yóò [tún] kó ìyọnu bá wọn nínú ìkannú gbígbóná rẹ̀,” bíi mànàmáná tó lágbára.—Sáàmù 2:5.
Ọba Tí Ọlọ́run Gbé Gorí Ìtẹ́
12. Gígorí ìtẹ́ wo ni Sáàmù 2:6 ń tọ́ka sí?
12 Ó dájú pé ohun tí Jèhófà tipasẹ̀ onísáàmù náà sọ lẹ́yìn ìyẹn bí àwọn orílẹ̀-èdè nínú gan-an. Ọlọ́run wí pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.” (Sáàmù 2:6) Òkè Síónì jẹ́ òkè kan ní Jerúsálẹ́mù níbi tí a ti fi Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Àmọ́ Mèsáyà Ọba kò ní jókòó sórí ìtẹ́ kan ní ìlú yẹn tàbí sí ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé. Kódà, Jèhófà ti fi Jésù Kristi jọba gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba rẹ̀ tí ó yàn lórí Òkè Síónì ti ọ̀run.—Ìṣípayá 14:1.
13. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ọmọ rẹ̀ dá?
13 Mèsáyà Ọba náà wá sọ̀rọ̀ wàyí. Ó ní: “Ẹ jẹ́ kí n tọ́ka sí àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà [ẹni tó bá Ọmọ rẹ̀ dá májẹ̀mú kan fún Ìjọba náà]; ó [Jèhófà Ọlọ́run] ti wí fún mi pé: ‘Ìwọ ni ọmọ mi; òní ni èmi, àní èmi, di baba rẹ.’” (Sáàmù 2:7) Kristi tọ́ka sí májẹ̀mú Ìjọba náà nígbà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.”—Lúùkù 22:28, 29.
14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù ló ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba?
14 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 2:7 ti wí, Jèhófà fi hàn pé Jésù jẹ́ Ọmọ Òun nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi àti nípa jíjí i dìde sí ìyè tẹ̀mí. (Máàkù 1:9-11; Róòmù 1:4; Hébérù 1:5; 5:5) Dájúdájú, Ọba Ìjọba ti ọ̀run náà ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run. (Jòhánù 3:16) Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ó túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó máa bá a du ipò ọba torí pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ sí i. (2 Sámúẹ́lì 7:4-17; Mátíù 1:6, 16) Gẹ́gẹ́ bí sáàmù yìí ti wí, Ọlọ́run sọ fún Ọmọ rẹ̀ pé: “Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.”—Sáàmù 2:8.
15. Kí nìdí tí Jésù fi béèrè àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀?
15 Ọba náà, ìyẹn Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló wà ní ipò tó tẹ̀ lé ti Jèhófà. Jèhófà ti ri pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ nígbà tá a dán an wò, ó jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì ṣeé gbára lé. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù tún ni Àkọ́bí Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, Jésù Kristi “ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Gbogbo ohun tó máa ṣe ni pé kó kàn béèrè, Ọlọ́run yóò sì ‘fún un ní àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.’ Jésù béèrè àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹni ‘tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọmọ ènìyàn’ àti nítorí pé ó ní ìfẹ́ ọkàn tó ga láti mú ohun tí Baba rẹ̀ ọ̀run fẹ́ ṣe sorí ilẹ̀ ayé àti fún ìran ènìyàn ṣẹ.—Òwe 8:30, 31.
Ohun Tí Jèhófà Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
16, 17. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Sáàmù 2:9 wí, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè?
16 Níwọ̀n bí sáàmù kejì ti ń nímùúṣẹ nísinsìnyí, láàárín àkókò wíwàníhìn-ín Jésù Kristi tí a kò lè fojú rí, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè? Láìpẹ́, Ọba náà yóò mú ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn [ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè], bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.”—Sáàmù 2:9.
17 Ọ̀pá aládé àwọn ọba ayé ìgbàanì jẹ́ àmì ọlá àṣẹ tá a fi ń mọ ọba. Irin ni wọ́n fi ṣe àwọn ọ̀pá aládé kan, bí irú èyí tí sáàmù yìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Èdè àpèjúwe tá a lò níhìn-ín fi hàn pé ó máa rọrùn gan-an fún Kristi Ọba láti pa àwọn orílẹ̀-èdè run. Tá a bá fi ọ̀pá aládé tá a fi irin ṣe lu ìkòkò tí amọ̀kòkò kan ṣe, ńṣe ló máa fọ́ yángá, yóò fọ túútúú débi pé kò ní látùnṣe mọ́.
18, 19. Kí làwọn ọba ilẹ̀ ayé ní láti ṣe tí wọ́n bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run?
18 Ǹjẹ́ ó pọn dandan káwọn alákòóso orílẹ̀-èdè fojú winá irú ìparun yán-ányán-án bẹ́ẹ̀? Rárá o, nítorí pé onísáàmù náà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pàrọwà fún wọn pé: “Wàyí o, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye; ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 2:10) A pe àwọn ọba láti fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì lo ìjìnlẹ̀ òye. Ó yẹ kí wọ́n ronú nípa ìmúlẹ̀mófo àwọn ìwéwèé wọn tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún àǹfààní ìran ènìyàn.
19 Tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, wọ́n ní láti yí ipa ọ̀nà wọn padà. A gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà kí [wọ́n] sì kún fún ìdùnnú ti [àwọn] ti ìwárìrì.” (Sáàmù 2:11) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀? Dípò tí wọ́n á fi wà nínú ìrúkèrúdò, tàbí kí ọkàn wọn dàrú, wọ́n á lè máa yọ̀ nítorí ìrètí tí Mèsáyà Ọba yóò gbé ka iwájú wọn. Ó ṣe pàtàkì káwọn alákòóso ayé pa ẹ̀mí ìgbéraga àti ẹ̀mí ìjọra ẹni lójú tí wọ́n ń fi hàn nínú ìṣàkóso wọn tì. Láfikún síyẹn, wọ́n ní láti yí padà kó tó pẹ́ jù kí wọ́n sì lo ìjìnlẹ̀ òye nípa ìṣàkóso Jèhófà tó ga jù lọ tí kò sì láfiwé àti nípa agbára Ọlọ́run àti ti Mèsáyà Ọba rẹ̀ tí kò ṣeé dí lọ́wọ́.
“Ẹ Fi Ẹnu Ko Ọmọ Náà Lẹ́nu”
20, 21. Kí ni ‘fífi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu’ túmọ̀ sí?
20 Sáàmù kejì wá nawọ́ ìkésíni aláàánú sí àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè. Dípò kí wọ́n máa kóra jọ láti ṣe àtakò, ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu, kí ìbínú Rẹ̀ [ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run] má bàa ru, kí ẹ má bàa sì ṣègbé ní ọ̀nà náà, nítorí pé ìbínú rẹ̀ tètè máa ń ru sókè.” (Sáàmù 2:12a) Nígbà tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ bá gbé àṣẹ kan kalẹ̀, ó di dandan kéèyàn ṣègbọràn sí i. Ìgbà tí Ọlọ́run ti gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ ni àwọn alákòóso ayé ì bá ti jáwọ́ nínú ‘sísọ àwọn nǹkan òfìfo lábẹ́lẹ̀.’ Wọn ì bá ti tẹ́wọ́ gba Ọba náà lójú ẹsẹ̀ kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i.
21 Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n “fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu”? Àmì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ ní fífi ẹnu koni lẹ́nu jẹ́ lákòókò tí wọ́n kọ sáàmù yìí, àwọn èèyàn sì máa ń lò ó láti kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí ilé wọn, níbi tí wọ́n á ti ṣe wọ́n lálejò. Fífi ẹnu koni lẹ́nu tún lè jẹ́ àmì fífi ìdúróṣinṣin hàn sí ẹnì kan. (1 Sámúẹ́lì 10:1) Ńṣe ni Ọlọ́run ń pàṣẹ fáwọn orílẹ̀-èdè nínú ẹsẹ ìwé sáàmù kejì yìí pé kí wọ́n fi ẹnu ko Ọmọ òun lẹ́nu, tàbí pé kí wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a ti fòróró yàn.
22. Ìkìlọ̀ wo ló yẹ káwọn alákòóso orílẹ̀-èdè kọbi ara sí?
22 Ńṣe làwọn tó kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Ọba tí Ọlọ́run yàn ń fi ìwọ̀sí lọ Jèhófà. Wọn ò gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ alákòóso lórí ọ̀run òun ayé, wọn ò sì tẹ́wọ́ gba ọlá àṣẹ rẹ̀ àti agbára tó ní láti yan Ọba tó jẹ́ alákòóso dídára jù lọ fún aráyé. Àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè yóò ri pé ìrunú Ọlọ́run dé bá àwọn lójijì, nígbà tí wọ́n ṣì ń gbìyànjú láti mú ète wọn ṣẹ. “Ìbínú Rẹ̀ tètè máa ń ru sókè,” kò sì ṣeé dá dúró. Ó yẹ káwọn alákòóso orílẹ̀-èdè fi ẹ̀mí ìmoore gba ìkìlọ̀ yìí kí wọ́n sì ṣe ohun tó ní kí wọ́n ṣe. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀ sí ìyè.
23. Àkókò ṣì wà fún olúkúlùkù èèyàn láti ṣe kí ni?
23 Ohun tí sáàmù tó kàmàmà yìí fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni: “Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń sá di [Jèhófà].” (Sáàmù 2:12b) Àkókò àtiwá ààbò ṣì wà fún olúkúlùkù èèyàn. Àkókò tiẹ̀ ṣì wà fún àwọn alákòóso tó ń ṣètìlẹ́yìn fún ète àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá. Wọ́n lè sá wá sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó ń pèsè ibi ìsádi fúnni lábẹ́ Ìjọba rẹ̀. Àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ tètè wá nǹkan ṣe kó tó di pé Ìjọba Mèsáyà pa àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣàtakò run yan-ányán-án.
24. Báwo la ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ láyọ̀, kódà nínú ayé onídààmú yìí?
24 Tá a bá ń fi tọkàntara kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, tá a sì fi àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé wa, a lè gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, kódà nísinsìnyí pàápàá nínú ayé onídààmú yìí. Fífi ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò ń mú kí àjọṣe aláyọ̀ wà láàárín ìdílé, ó sì mú ká bọ́ nínú ọ̀pọ̀ ìdààmú àti ìbẹ̀rù tó ń yọ ayé yìí lẹ́nu. Títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé à ń múnú Ẹlẹ́dàá dùn. Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run nìkan ṣoṣo ló lè fúnni ní ìdánilójú “ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀” lẹ́yìn tó bá ti run àwọn tó ń ṣàtakò kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tó ń takò ohun tó tọ́ nípa kíkọ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀.—1 Tímótì 4:8.
25. Níwọ̀n bí “àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà” kò ti lè kùnà, kí la lè máa retí pé yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa?
25 “Àṣẹ Àgbékalẹ̀ Jèhófà” kò lè kùnà. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, Ọlọ́run mọ ohun tó dára jù lọ fún aráyé, yóò sì mú ète rẹ̀ ṣẹ láti fi àlàáfíà, ìtẹ́lọ́rùn, àti ààbò pípẹ́ títí lábẹ́ Ìjọba Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jíǹkí àwọn èèyàn onígbọràn. Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò wa, ó kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Láìsí àní-àní, àkókò yìí gan-an ló jẹ́ kánjúkánjú jù lọ láti “fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu” ká sì sin Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lákọ̀ọ́kọ́, Dáfídì Ọba ni “ẹni àmì òróró” náà, àwọn alákòóso Filísínì sì ni “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tí wọ́n kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ lòdì sí i.
b Àwọn ẹsẹ mìíràn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tún fi hàn pé Jésù ni Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run tá a tọ́ka sí nínú sáàmù kejì. Èyí hàn kedere nígbà tá a fi Sáàmù 2:7 wéra pẹ̀lú Ìṣe 13:32, 33 àti Hébérù 1:5; 5:5. Tún wo Sáàmù 2:9; àti Ìṣípayá 2:27.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni “nǹkan òfìfo” tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè “ń sọ . . . lábẹ́lẹ̀”?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi ń fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣẹ̀sín?
• Kí ni ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè?
• Kí ni ‘fífi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu’ túmọ̀ sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Dáfídì kọrin nípa Mèsáyà Ọba tó jẹ́ aṣẹ́gun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn alákòóso àtàwọn èèyàn Ísírẹ́lì dìtẹ̀ mọ́ Jésù Kristi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A ti gbé Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní Òkè Síónì ti ọ̀run