Apá 15
Wòlíì Kan Tó Wà Nígbèkùn Rí Ohun Tó Ń Bọ̀ Wá Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú Nínú Ìran
Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bíbọ̀ Mèsáyà. Bábílónì ṣubú
KÍ JERÚSÁLẸ́MÙ tó pa run ni wọ́n ti mú ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Dáníẹ́lì, tí ìwà títọ́ rẹ̀ pabanbarì, nígbèkùn lọ sí Bábílónì. Wọ́n fún òun àtàwọn Júù míì táwọn ará Bábílónì kó nígbèkùn nígbà tí wọ́n pa Júdà run lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan. Láàárín àkókò gígùn tí Dáníẹ́lì lò nílùú Bábílónì, Ọlọ́run rọ̀jò ìbùkún lé e lórí, ó pa á mọ́ nígbà tí wọ́n jù ú sínú ihò kìnnìún ó sì rí àwọn ìran tó jẹ́ kó mọ àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì dá lórí Mèsáyà àti àkóso Rẹ̀.
Dáníẹ́lì mọ ìgbà tí Mèsáyà máa dé. A sọ fún Dáníẹ́lì nípa ìgbà táwọn èèyàn Ọlọ́run lè máa retí dídé “Mèsáyà Aṣáájú,” èyí tó máa jẹ́ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] ti ọdún lẹ́yìn tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti mú Jerúsálẹ́mù pa dà bọ̀ sípò àti láti tún àwọn odi rẹ̀ kọ́. Ọjọ́ méje ló máa ń wà nínú ọ̀sẹ̀ kan; ọdún méje ló sì máa ń wà nínú ọ̀sẹ̀ ti ọdún. Ó pẹ́ gan-an tí Dáníẹ́lì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ká tó pa àṣẹ náà, ìyẹn lọ́dún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bá a bá kà á látìgbà yẹn, gígùn “ọ̀sẹ̀” mọ́kàndínláàádọ́rin [69] náà jẹ́ ọdún ọ̀rìnlénírínwó lé mẹ́ta [483], ó sì parí sí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Nínú apá tó kàn nínú ìtẹ̀jáde yìí, a máa rí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn. Dáníẹ́lì tún rí i nínú ìran pé wọ́n máa “ké” Mèsáyà náà “kúrò,” tàbí pa á run, gẹ́gẹ́ bí ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀.—Dáníẹ́lì 9:24-26.
Mèsáyà máa di Ọba ní ọ̀run. Nínú ìran pípabanbarì tí Dáníẹ́lì rí nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run, ó rí Mèsáyà náà tí wọ́n pè ní “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn,” tó ń lọ síwájú ìtẹ́ Jèhófà. Jèhófà fún un ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” Ìjọba yẹn máa wà títí láé. Dáníẹ́lì tún kẹ́kọ̀ọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn tí ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa Ìjọba Mèsáyà, àwọn míì máa bá Ọba ìjọba náà ṣàkóso, àwùjọ àwọn èèyàn yìí la pè ní “àwọn . . . ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ.”—Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27.
Ìjọba náà máa pa àwọn ìjọba ayé yìí run. Ọlọ́run fún Dáníẹ́lì ní agbára láti sọ ìtumọ̀ àlá kan tí kò yé Nebukadinésárì, ọba Bábílónì. Ọba rí ère gàgàrà kan tó ní orí wúrà, igẹ̀ àti apá rẹ̀ jẹ́ fàdákà, ikùn àti itan rẹ̀ sì jẹ́ bàbà, ojúgun rẹ̀ jẹ́ irin, ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin, apá kan amọ̀. Òkúta kan tí a gé látara òkè ńlá kọlu ẹsẹ̀ tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ náà, ó sì fọ́ ọ túútúú. Dáníẹ́lì ṣàlàyé pé àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ère náà ní dúró fún ọ̀wọ́ àwọn ọba tí agbára ayé máa wà lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n máa jẹ tẹ̀ léra, bẹ̀rẹ̀ látorí ọba Bábílónì tí orí wúrà dúró fún. Dáníẹ́lì rí i nínú ìran pé nígbà tí àwọn tó kẹ́yìn lára àwọn ọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé búburú yìí bá wà lórí àlééfà ni Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. Lẹ́yìn náà ni yóò máa ṣàkóso títí láé.—Dáníẹ́lì, orí 2.
Ìparun Bábílónì ṣojú Dáníẹ́lì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó gan-an nígbà náà. Kírúsì Ọba ṣẹ́gun ìlú náà gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ púpọ̀ sígbà yẹn tí wọ́n fi dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn, ìgbà yẹn gan-an sì ni àádọ́rin [70] ọdún pé tí ilẹ̀ wọn ti pa run. Bí àwọn gómìnà, àwọn àlùfáà àtàwọn wòlíì tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe ń fún àwọn Júù ní ìtọ́sọ́nà tó yẹ, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe àtúnkọ́ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì Jèhófà. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ọdún ọ̀rìnlénírínwó lé mẹ́ta [483] náà bá parí?
—A gbé e ka ìwé Dáníẹ́lì.