Fi Ìgboyà Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi.”—ÁMÓSÌ 7:15.
1, 2. Ta ni Ámósì, kí sì ni Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?
NÍGBÀ tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àlùfáà kan gbéjà kò ó. Àlùfáà náà jágbe mọ́ ọn pé: ‘Ìwàásù ẹ yìí tó gẹ́ẹ́! Ó yá, wábi gbà!’ Kí ni ẹlẹ́rìí náà wá ṣe? Ṣé ó tẹ̀ lé àṣẹ àlùfáà náà ni, àbí ó ń fi ìgboyà wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó? O lè mọ ohun tí ìránṣẹ́ náà ṣe nítorí pé ó kọ ìrírí ara rẹ̀ sínú ìwé kan tá a fi orúkọ rẹ̀ pè, ìyẹn ìwé Ámósì inú Bíbélì. Àmọ́, ká tó gbọ́ púpọ̀ sí i nípa bí àlùfáà náà ṣe gbéjà ko Ámósì, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tí Ámósì jẹ́.
2 Ta ni Ámósì? Ìgbà wo ló gbé ayé, ibo ló sì gbé? A rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn nínú Ámósì 1:1, ibẹ̀ kà pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì, ẹni tí ó wà lára àwọn olùsin àgùntàn láti Tékóà, . . . ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà ọba Júdà àti ní àwọn ọjọ́ Jèróbóámù ọmọkùnrin Jóáṣì, ọba Ísírẹ́lì.” Júdà ni Ámósì gbé. Tékóà ni ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ibẹ̀ sì jẹ́ kìlómítà mẹ́rìndínlógún síhà gúúsù Jerúsálẹ́mù. Ó gbé ayé níparí ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Tiwa nígbà tí Ùsáyà Ọba ń ṣàkóso ní Júdà, tí Ọba Jèróbóámù Kejì sì jẹ́ ọba ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì. Àgùntàn ni Ámósì ń sìn. Kódà, Ámósì 7:14 sọ pé kì í ṣe pé ó jẹ́ “olùṣọ́ agbo ẹran” nìkan ni, ó tún jẹ́ “olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè.” Èyí fi hàn pé, ó máa lọ ń ṣiṣẹ́ olùkórè láwọn ìgbà kan láàárín ọdún. Ó ń rẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìdí tí wọ́n sì fi ń rẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni kí èso rẹ̀ lè tètè pọ́n. Iṣẹ́ tó gba agbára gan-an ni.
“Lọ, Sọ Tẹ́lẹ̀”
3. Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ámósì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rò pé a ò tóótun láti wàásù?
3 Ámósì sọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an, ó ní: “Èmi kì í ṣe wòlíì tẹ́lẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì.” (Ámósì 7:14) Ní tòdodo, wọn ò bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ wòlíì, kò sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ wòlíì. Àmọ́, nínú gbogbo àwọn tí ń gbé ní Júdà pátá, Ámósì ni Jèhófà yàn láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Ọlọ́run ò yan ọba alágbára kan, kò yan àlùfáà kan tó dáńgájíá, kò sì yan ìjòyè kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Èyí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ tí ń fini lọ́kàn balẹ̀. A lè máà nípò tó ga nínú ayé, a sì lè má fi bẹ́ẹ̀ kàwé rẹpẹtẹ. Àmọ́, ṣé ó wá yẹ kíyẹn mú wa ronú pé a ò tóótun láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Jèhófà lè mú wa tóótun láti pòkìkí ọ̀rọ̀ rẹ̀, àní láwọn ìpínlẹ̀ tó ṣòro pàápàá. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí Jèhófà ṣe fún Ámósì gẹ́lẹ́ nìyẹn, gbogbo àwọn tó fẹ́ láti máa fi ìgboyà wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ bí wọ́n bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àpẹẹrẹ tí wòlíì onígboyà yẹn fi lélẹ̀.
4. Kí nìdí tó fi ṣòro fún Ámósì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Ísírẹ́lì?
4 Jèhófà sọ fún Ámósì pé: “Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.” (Ámósì 7:15) Iṣẹ́ ọ̀hún ò rọrùn rárá. Lákòókò yẹn, ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì wà lálàáfíà, kò séwu fún wọn, wọ́n sì láásìkí. Ọ̀pọ̀ ló ní “ilé ìgbà òtútù” àti “ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,” kì í sì í ṣe bíríkì alámọ̀ lásán ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé wọ̀nyí o, bí kò ṣe “òkúta gbígbẹ́” olówó iyebíye. Àwọn kan ní àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi eyín erin ṣe, wọ́n sì ń mu wáìnì tí wọ́n ṣe ní “àwọn ọgbà àjàrà fífani-lọ́kàn-mọ́ra.” (Ámósì 3:15; 5:11) Ìyẹn ló fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ka ọ̀rọ̀ ìwàásù sí. Ní tòótọ́, ìpínlẹ̀ tí Ámósì ti wàásù fara jọ èyí tí àwọn kan lára wa ti ń wàásù lónìí.
5. Àwọn ìwà tí ò dáa wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń hù?
5 Kì í ṣe pé ó burú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ní àwọn nǹkan ti ara o. Àmọ́, ọ̀nà èrú làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan gbà ń kó ọrọ̀ wọn jọ. Àwọn ọlọ́rọ̀ “ń lu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì” wọ́n tún “ń ni àwọn òtòṣì lára.” (Ámósì 4:1) Àwọn oníṣòwò aládàá ńlá, àwọn onídàájọ́, àtàwọn àlùfáà ń lẹ̀dí àpò pọ̀ láti ja àwọn òtòṣì lólè. Ẹ jẹ́ ká wa fi àkókò díẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan táwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún.
Wọ́n Tẹ Òfin Ọlọ́run Lójú
6. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ oníṣòwò ṣe ń rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ?
6 A óò kọ́kọ́ lọ sáàárín ọjà. Ibẹ̀ làwọn oníṣòwò tó jẹ́ alábòsí ti “sọ òṣùwọ̀n eéfà di kékeré” tí wọ́n sì “mú kí ṣékélì di ńlá,” kódà wọ́n ń “ta pàǹtírí . . . lásán-làsàn” bí ọkà. (Ámósì 8:5, 6) Ńṣe làwọn oníṣòwò ń rẹ́ àwọn oníbàárà jẹ nípa bí wọ́n ṣe ń díwọ̀n nǹkan tí wọ́n ń tà fún wọn, owó ọjà ti wọ́n jù, ayédèrú nǹkan ni wọ́n sì ń tà lọ́jà. Lẹ́yìn táwọn oníṣòwò yìí bá sì ti jẹ àwọn tálákà ní àjẹkeegun tí kò sówó lọ́wọ́ wọn mọ́, àwọn tálákà wọ̀nyí á wá sọra wọn dẹrú wọn. Àwọn oníṣòwò náà á wá rà wọ́n ní “iye owó sálúbàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.” (Ámósì 8:6) Àbẹ́ẹ̀rí nǹkan! Àwọn oníṣòwò tó jẹ́ oníwọra wọ̀nyí gbà pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn ò sàn ju sálúbàtà ẹsẹ̀ lásán-làsàn lọ! Ẹ ò rí i pé wọn ò ka àwọn tálákà sí rárá, wọ́n sì ń tẹ Òfin Ọlọ́run lójú pẹ̀lú! Síbẹ̀, àwọn oníṣòwò yìí kan náà ń pa òfin “sábáàtì” mọ́ lójú méjèèjì. (Ámósì 8:5) Ká sọ tòótọ́, wọ́n ní ìtara fún ìsìn àmọ́ ìtara ojú ayé lásán ni.
7. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn oníṣòwò Ísírẹ́lì láti rú Òfin Ọlọ́run?
7 Ọ̀nà wo làwọn oníṣòwò náà ń gbé e gbà tọ́wọ́ ìyà ò fi bà wọ́n fún rírú tí wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ”? (Léfítíkù 19:18) Ohun tí ò mú kọ́wọ́ ìyà bà wọ́n ni pé àwọn àtàwọn tó yẹ kó fìdí Òfin múlẹ̀, ìyẹn àwọn onídàájọ́, ló jọ ń pa àpabò ìwà burúkú yìí. Ní ẹnu ibodè ìlú, níbi tí wọ́n ti ń gbẹ́jọ́, làwọn onídàájọ́ ‘ti ń gba owó mẹ́numọ́, tí wọ́n sì ń yí ẹjọ́ àwọn òtòṣì po.’ Dípò táwọn onídàájọ́ ì bá fi máa gbọ́ tàwọn òtòṣì, ńṣe ni wọ́n ń yí ẹjọ́ wọn po tí wọ́n bá ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ámósì 5:10, 12) Ó túmọ̀ sí pé àwọn onídàájọ́ pàápàá ò ka Òfin Ọlọ́run sí.
8. Ìwà wo làwọn àlùfáà burúkú yẹn ṣe bíi pé àwọn ò rí?
8 Ipa wo làwọn àlùfáà Ísírẹ́lì wá ń kó ní tiwọn? Ká tó lè mọ èyí, a gbọ́dọ̀ yíjú síbòmíràn. Ẹ wò irú ẹ̀ṣẹ̀ táwọn àlùfáà náà fàyè gbà “nínú ilé àwọn ọlọ́run wọn”! Ọlọ́run tipasẹ̀ Ámósì sọ pé: “Ọkùnrin kan àti baba rẹ̀ sì ti lọ sọ́dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan náà, fún ète sísọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.” (Ámósì 2:7, 8) Ìyẹn mà ga o! Bàbá kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì àti ọmọ rẹ̀ ń bá aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì kan náà ṣèṣekúṣe. Àwọn àlùfáà burúkú wọ̀nyẹn sì ń ṣe bíi pé àwọn ò rí irú ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀!—Léfítíkù 19:29; Diutarónómì 5:18; 23:17.
9, 10. Èwo nínú Òfin Ọlọ́run làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò pa mọ́, báwo nìyẹn sì ṣe bá ohun tó ń lọ lákòókò tiwa yìí mu?
9 Nígbà tí Jèhófà ń sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn tí wọ́n dá, ó ní: “Àwọn ẹ̀wù tí wọ́n fi ipá gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò ni wọ́n sì nà gbalaja lé lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo pẹpẹ; wáìnì àwọn tí a bu ìtanràn lé ni wọ́n sì ń mu nínú ilé àwọn ọlọ́run wọn.” (Ámósì 2:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn náà lápapọ̀ ò tún tẹ̀ lé òfin inú Ẹ́kísódù 22:26, 27 tó sọ pé ẹ̀wù tẹ́nì kan bá gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò lẹni náà gbọ́dọ̀ dá padà kílẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń tẹ́ àwọn ẹ̀wù náà sílẹ̀ tí wọ́n á sì nà gbalaja lé wọn lórí nígbà tí wọ́n bá ń jẹ tí wọ́n sì ń mu níwájú àwọn ọlọ́run wọn. Wọ́n á tún fi owó ìtanràn tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn òtòṣì ra wáìnì tí wọ́n á mu níbi àjọyọ̀ ìsìn èké. Ẹ ò rí i bí wọ́n ṣe ṣìnà lọ ráúráú kúrò lójú ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́!
10 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìnítìjú wọ̀nyí ń tẹ méjì tó tóbi jù lọ nínú àwọn Òfin lójú, èyí tó ní kí wọn fẹ́ràn Jèhófà àti ọmọnìkejì wọn. Ọlọ́run wá rán Ámósì pé kó lọ dá wọn lẹ́bi fún ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n ń hù. Lónìí, ìwà búburú jáì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì hù yìí làwọn orílẹ̀-èdè ayé àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń hù. Níbi tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù fáwọn kan, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ti di ẹdun arinlẹ̀, tí ọkàn wọn sì gbọgbẹ́. Ìwàkiwà tó kún ọwọ́ àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn tí wọ́n jẹ́ aṣáájú nídìí òwò ńlá, nídìí ìṣèlú, àti nínú ìsìn èké ló sì fa sábàbí yìí. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn tíyà ń jẹ tí wọ́n sì ń sapá láti wá a kàn ṣeré rárá. Ìdí nìyẹn tó fi yan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní láti ṣe irú iṣẹ́ tí Ámósì ṣe, ìyẹn iṣẹ́ fífi ìgboyà wàásù ọ̀rọ̀ Rẹ̀.
11. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ámósì?
11 Nítorí pé iṣẹ́ tá à ń ṣe àtèyí tí Ámósì ṣe jọra gan-an, a ó jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ tá a bá gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò. Àní, Ámósì jẹ́ ká mọ̀ nípa (1) ohun tó yẹ ká wàásù rẹ̀, (2) bó ṣe yẹ ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, àti (3) ìdí táwọn alátakò kò fi lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. Ẹ jẹ́ ká wá gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.
Bá A Ṣe Lè Fara Wé Ámósì
12, 13. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé inú òun ò dùn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ni wọ́n sì ṣe nípa rẹ̀?
12 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe dá lórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20; Máàkù 13:10) Bẹ́ẹ̀ náà la tún ń wàásù nípa ìkìlọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, bíi ti Ámósì tó polongo pé ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Jèhófà yóò dé bá àwọn ẹni ibi. Bí àpẹẹrẹ, Ámósì 4:6-11 fi hàn pé léraléra ni Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé inú òun ò dùn sí wọn rárá. Ó sọ àwọn èèyàn náà di ‘aláìní oúnjẹ,’ “[ó] sì tún fawọ́ eji wọwọ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ [wọn],” ó fi “ìjógbẹ àti èbíbu” kọlù wọ́n, ó sì tún rán “àjàkálẹ̀ àrùn” sáàárín wọn. Ǹjẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà? Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kò padà sọ́dọ̀ mi.” Àní, léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jèhófà sílẹ̀.
13 Jèhófà fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò ronú pìwà dà. Àmọ́, wọ́n kọ́kọ́ gba ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ o. Nítorí èyí, Ọlọ́run polongo pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” (Ámósì 3:7) Ọlọ́run sọ fún Nóà pé Ìkún Omi ń bọ̀, ó sì sọ fún un pé kó kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Bákan náà ni Jèhófà sọ fún Ámósì pé kó kìlọ̀ ìkẹyìn fáwọn èèyàn. Ó ṣeni láàánú pé Ísírẹ́lì kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ tó tọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yìí, wọn ò sì ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe.
14. Kí ni ayé ìgbà Ámósì fi jọ èyí tá a wà yìí?
14 Láìsí àní-àní, ẹ óò gbà pé ọjọ́ Ámósì jọ ọjọ́ tiwa lónìí gan-an. Jésù Kristi sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríṣiríṣi àwọn àjálù tó máa wáyé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí yóò kárí ayé. (Mátíù 24:3-14) Àmọ́, bó ṣe rí lọ́jọ́ Ámósì, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn lónìí ni ò kọbi ara sí àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn, wọn ò sì tún kọbi ara sí ìhìn Ìjọba náà. Irú àgbákò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ò ronú pìwà dà kò ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa kò. Jèhófà kìlọ̀ fún wọn pé: “Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ.” (Ámósì 4:12) Wọ́n pàdé Ọlọ́run ní ti pé ìdájọ́ gbígbóná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run dé sórí wọn nígbà táwọn ọmọ ogun Ásíríà ṣẹ́gun wọn. Ayé òde òní tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ‘pàdé Ọlọ́run’ ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Àmọ́ nísinsìnyí tí sùúrù Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó, à ń gba gbogbo èèyàn níyànjú pé kí wọ́n, “Wá Jèhófà, kí [wọ́n] sì máa wà láàyè nìṣó.”—Ámósì 5:6.
À Ń Fojú Winá Àtakò Bíi Ti Ámósì
15-17. (a) Ta ni Amasááyà, kí ló sì ṣe nípa ìkéde Ámósì? (b) Àwọn ẹ̀sùn wo ni Amasááyà fi kan Ámósì?
15 Kì í ṣe nínú ohun tí a ó wàásù rẹ̀ nìkan la ti lè fara wé Ámósì, a tún lè fara wé e nínú bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Kókó yìí ni orí keje tẹnu mọ́, níbi tá a ti sọ fún wa nípa àlùfáà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wa. “Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì” ni àlùfáà náà. (Ámósì 7:10) Ìlú Bẹ́tẹ́lì ni ojúkò ìjọsìn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà, ère ọmọ màlúù sì wà lára ohun tí wọ́n ń jọ́sìn. Amasááyà ni àlùfáà ìsìn tí wọ́n ń ṣe ní Orílẹ̀-èdè náà. Kí ló ṣe nígbà tí Ámósì ń kéde láìfòyà?
16 Amasááyà sọ fún Ámósì pé: “Ìwọ olùríran, máa lọ, sá lọ sí ilẹ̀ Júdà, ibẹ̀ ni kí o sì ti máa jẹ oúnjẹ, ibẹ̀ sì ni o ti lè sọ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ tún sọ tẹ́lẹ̀ mọ́ ní Bẹ́tẹ́lì, nítorí ibùjọsìn ọba ni, ilé ìjọba sì ni.” (Ámósì 7:12, 13) Lẹ́nu kan, ohun tí Amasááyà ń sọ ni pé: ‘Gba ọ̀nà ilé rẹ lọ! A ti ní ìsìn tiwa.’ Ó tún gbìyànjú láti kó sí ìjọba lórí kí wọ́n lè fòfin de iṣẹ́ Ámósì, ó sọ fún Ọba Jèróbóámù Kejì pé: “Ámósì ti di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí ọ nínú ilé Ísírẹ́lì gan-an.” (Ámósì 7:10) Ẹ̀sùn ìṣọ̀tẹ̀ síjọba ni Amasááyà mà fi kan Ámósì yìí! Ó sọ fún Ọba pé: “Èyí ni ohun tí Ámósì wí, ‘Jèróbóámù yóò tipa idà kú; àti ní ti Ísírẹ́lì, láìsí àní-àní, yóò lọ sí ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.’”—Ámósì 7:11.
17 Nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Amasááyà parọ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó sọ pé: “Èyí ni ohun tí Ámósì wí.” Àmọ́, Ámósì ò tíì fìgbà kan rí sọ pé látọ̀dọ̀ òun ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó máa ń sọ nígbà gbogbo ni pé: “Èyí ní ohun tí Jèhófà wí.” (Ámósì 1:3) Ó tún fẹ̀sùn kan Ámósì pé ó sọ pé: “Jèróbóámù yóò tipa idà kú.” Àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ámósì 7:9, ohun tí Ámósì sọ tẹ́lẹ̀ ni pé: “Èmi [Jèhófà] yóò sì fi idà dìde sí ilé Jèróbóámù.” Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé àjálù yìí yóò wà sórí “ilé” Jèróbóámù, ìyẹn àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Síwájú sí i, Amasááyà tún fẹ̀sùn kan Ámósì pé ó sọ pé: ‘Láìsí àní-àní, Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn.’ Àmọ́ Ámósì ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé èyíkéyìí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bá padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run yóò rí ìbùkún gbà. Ó dájú nígbà náà pé ńṣe ni Amasááyà yí irọ́ pọ̀ mọ́ òótọ́ láti lè mú kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù tí Ámósì ń ṣe.
18. Àwọn ọ̀nà wò ni ọgbọ́n tí Amasááyà lò fi bá èyí táwọn àlùfáà máa ń lò lóde òní mu?
18 Ǹjẹ́ ẹ ṣàkíyèsí bí ọgbọ́n tí Amasááyà lò yìí ṣe jọ èyí táwọn alátakò àwọn èèyàn Jèhófà ń lò lóde òní? Gẹ́gẹ́ bí Amasááyà ṣe jà fitafita láti pa Ámósì lẹ́nu mọ́ nígbà náà lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ náà làwọn àlùfáà, àwọn bíṣọ́ọ̀bù, àtàwọn olórí ìsìn ọjọ́ wa ṣe ń gbìyànjú láti bẹ́gi dínà iṣẹ́ ìwàásù táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣe. Amasááyà fẹ̀sùn èké kan Ámósì pé ó ń ṣọ̀tẹ̀ síjọba. Bákan náà làwọn àlùfáà kan lónìí ṣe ń fẹ̀sùn èké kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ọ̀tà àlàáfíà ni wá. Bí Amasááyà sì ṣe yíjú sí ọba láti wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kó lè gbéjà ko Ámósì, bẹ́ẹ̀ làwọn àlùfáà wọ̀nyí ṣe ń yíjú sí ìjọba òṣèlú tí wọ́n ti bá lẹ̀dí àpò pọ̀ káwọn yẹn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwọn Alátakò Ò Lè Dá Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Dúró
19, 20. Kí ni Ámósì ṣe nígbà tí Amasááyà ń ta kò ó?
19 Kí ní Ámósì wá ṣe sí àtakò Amasááyà yìí? Lákọ̀ọ́kọ́, Ámósì béèrè lọ́wọ́ àlùfáà náà pé: “Ìwọ ha ń sọ pé: ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Ísírẹ́lì’?” Wòlíì onígboyà yìí ò lọ́ tìkọ̀ rárá, ńṣe ló wá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó dájú pe Amasááyà ò fẹ́ gbọ́. (Ámósì 7:16, 17) Ámósì ò jẹ́ kí wọ́n kó jìnnìjìnnì bá òun. Àpẹẹrẹ àtàtà gbáà mà lèyí jẹ́ fún wa o! Tó bá di pé ká sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, a ò ní ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wa, kódà bá a tiẹ̀ ń gbé láwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn tó ń ṣe bí Amasááyà lóde òní ti ń ṣenúnibíni rírorò pàápàá. Bíi ti Ámósì, à ń bá a nìṣó ní pípolongo pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí.” Àwọn alátakò ò sì lè dá ìṣẹ́ ìwàásù wa dúró láé, nítorí pé “ọwọ́ Jèhófà” wà pẹ̀lú wa.—Ìṣe 11:19-21.
20 Ó yẹ kí Amasááyà ti mọ̀ pé asán ni gbogbo làlà-koko-fẹ̀fẹ̀ òun máa já sí. Ámósì ti ṣàlàyé ìdí tí kò fi ní sẹ́nì kankan lókè eèpẹ̀ tó lè pa òun lẹ́nu mọ́, èyí sì ni kókó kẹta tí a óò gbé yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ámósì 3:3-8 wí, Ámósì kọ́kọ́ lo ọ̀wọ́ àwọn ìbéèrè àti àkàwé láti fi hàn pé, bí ò bá sídìí o, obìnrin kì í jẹ́ kúmólú. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá sọ ohun tó ni lọ́kàn, ó ní: “Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù! Ta ni kì yóò fòyà? Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kì yóò sọ tẹ́lẹ̀?” Ohun tí Ámósì fi ń yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni pé: ‘Gẹ́gẹ́ bí ẹ ò ti ní yéé fòyà nígbà tẹ́ ẹ bá rí kìnnìún tí ń ké ramúramù, bẹ́ẹ̀ lèmi náà ò ní yéé wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tí Jèhófà ti pa á láṣẹ pé kí n ṣe bẹ́ẹ̀.’ Ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí Ámósì ní fún Ọlọ́run ló mú kó máa fìgboyà sọ̀rọ̀.
21. Ọwọ́ wo la fi mú àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé ká máa wàásù ìhìn rere?
21 Àwa náà gbọ́ àṣẹ látọ̀dọ̀ Jèhófà pé ká wàásù. Kí là ń ṣe nípa àṣẹ náà? Bíi ti Ámósì àtàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwa náà ń fìgboyà sọ̀rọ̀ Rẹ̀. (Ìṣe 4:23-31) Inúnibíni táwọn alátakò ń ṣe sí wa tàbí ẹ̀mí àìbìkítà táwọn tá à ń wàásù fún ń fi hàn, kò ní mú wa dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró láé. Irú ẹ̀mí ìtara bíi ti Ámósì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ní ń sún wa láti máa bá a nìṣó láti fi ìgboyà polongo ìhìn rere náà. Iṣẹ́ wa ni pé ká kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìdájọ́ Jèhófà tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Báwo ni ìdájọ́ náà ṣe máa rí? A óò dáhùn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Inú ipò wo ni Ámósì ti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kò ṣe?
• Bíi ti Ámósì, kí ló yẹ ká máa wàásù rẹ̀?
• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká máa fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa?
• Kí nìdí táwọn alátakò kò fi lè dá iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa dúró?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ámósì, olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́, ni Ọlọ́run yàn láti ṣe iṣẹ́ Rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bíi ti Ámósì, ǹjẹ́ ò ń fìgboyà kéde ìhìn Jèhófà?