Kí Ni Jèhófà Ń Retí Pé Ká Máa Ṣe?
“Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.
1, 2. Kí ló lè mú kí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ kí ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
KRISTẸNI tòótọ́ ni Vera. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin, aláìlera sì ni. Ó sọ pé: “Mo máa ń yọjú lójú fèrèsé nígbà mìíràn, máa sì rí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi bí wọ́n ti ń wàásù láti ilé dé ilé. Ìyẹn sì máa ń pa mí lẹ́kún nítorí pé ó wù mí kí ń dara pọ̀ mọ́ wọn, àmọ́ àìsàn ò jẹ́ kí n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tó bí mo ṣe fẹ́.”
2 Ǹjẹ́ ó ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ rí? Lóòótọ́, gbogbo ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló fẹ́ máa rìn ní orúkọ rẹ̀ kí wọ́n sì máa ṣe àwọn ohun tó béèrè lọ́wọ́ wa. Àmọ́ tá a bá ń ṣàìsàn ńkọ́, tàbí kí ọjọ́ ogbó dé, tàbí a ní bùkátà tá à ń gbé? A lè máa dààmú pé èyí ò jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tó bí ọkàn wa ṣe ń fẹ́. Bí a bá wà nínú irú ipò yìí, ó dájú pé àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú Míkà orí kẹfà àti keje yóò fún wa níṣìírí. Orí méjèèjì yìí fi hàn kedere pé àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa bọ́gbọ́n mu, kò sì kọjá agbára wa.
Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Gbà Bá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lò
3. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ lò?
3 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo Míkà 6:3-5 ká sì kíyè sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò. Ẹ rántí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Míkà ti ya ọlọ̀tẹ̀. Síbẹ̀ náà, gbólóhùn oníyọ̀ọ́nú tí Jèhófà lò fún wọn ni, “Ìwọ ènìyàn mi.” Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ìwọ ènìyàn mi, jọ̀wọ́, rántí.” Dípò kó fi ìkanra ka ẹ̀sùn sí wọn lọ́rùn, ńṣe ló gbìyànjú láti mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa bíbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́?” Ó tiẹ̀ rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “jẹ́rìí lòdì sí” òun.
4. Ipa wo ló yẹ kí àpẹẹrẹ ìyọ́nú Ọlọ́run ní lórí wa?
4 Ní ti ọ̀ràn ìyọ́nú, àpẹẹrẹ ńláǹlà ni Ọlọ́run mà fi lélẹ̀ fún gbogbo wa yìí o! Kódà ó fi ìyọ́nú pe àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ nígbà ayé Míkà ní “ènìyàn mi” ó sì lo gbólóhùn náà “jọ̀wọ́” nígbà tó bá wọn sọ̀rọ̀. Láìsí àní-àní, ó ṣe pàtàkì kí àwa náà máa lo ìyọ́nú àti inúure nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ. Lóòótọ́, àwọn kan lè jẹ́ ẹni tí kò rọrùn láti bá da nǹkan pọ̀, tàbí kí wọ́n jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí. Síbẹ̀, bí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ ká sì yọ́nú sí wọn.
5. Kí ni kókó pàtàkì tó wà ní Míkà 6:6, 7?
5 Ẹ jẹ́ ká ṣí Bíbélì wa sí Míkà 6:6, 7 wàyí. Míkà béèrè àwọn ìbéèrè bíi mélòó kan, ó ní: “Kí ni èmi yóò gbé wá pàdé Jèhófà? Kí ni èmi yóò fi tẹrí ba fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè? Èmi yóò ha gbé odindi ọrẹ ẹbọ sísun wá pàdé rẹ̀, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan? Inú Jèhófà yóò ha dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò, sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ọ̀gbàrá òróró? Èmi yóò ha fi ọmọkùnrin mi àkọ́bí lélẹ̀ fún ìdìtẹ̀ mi, èso ikùn mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?” Rárá o, a ò lè fi “ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,” àti “ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ọ̀gbàrá òróró” mú inú Jèhófà dùn. Ṣùgbọ́n nǹkan kan wà tó lè mú inú rẹ̀ dùn. Kí ni nǹkan náà?
A Gbọ́dọ̀ Ṣe Ìdájọ́ Òdodo
6. Àwọn ohun mẹ́ta wo ni Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wa bó ṣe wà nínú Míkà 6:8?
6 Nínú Míkà 6:8, a ka ohun tí Jèhófà ń retí pé ká máa ṣe. Míkà béèrè pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” Ohun mẹ́ta tó ń béèrè yìí kan ìwà wa, èrò wa àti ìṣe wa. Ó yẹ kó wù wá láti fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn, ká máa ronú nípa wọn ká sì máa fi wọ́n ṣèwà hù. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó béèrè yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
7, 8. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti “ṣe ìdájọ́ òdodo”? (b) Ìwà ìrẹ́jẹ wo ló gbòde kan nígbà ayé Míkà?
7 Láti “ṣe ìdájọ́ òdodo” túmọ̀ sí pé ká ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe nǹkan tirẹ̀ sì ni ọ̀pá tá a ó fi díwọ̀n ìdájọ́ òdodo. Àmọ́ dípò káwọn èèyàn ìgbà ayé Míkà ṣe ìdájọ́ òdodo ní tiwọn, ègbè ni wọ́n ń ṣe. Láwọn ọ̀nà wo? Gbé Míkà 6:10 yẹ̀ wò. Níparí ẹsẹ yẹn, ó ṣàpèjúwe àwọn oníṣòwò pé wọ́n ń lo “òṣùwọ̀n eéfà tí kò kún,” ìyẹn òṣùwọ̀n tó kéré gan-an. Ẹsẹ kọkànlá sọ pé wọ́n ń lo “òkúta àfiwọn-ìwúwo tí a fi ń tanni jẹ.” Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ kejìlá ṣe wí, “ahọ́n wọ́n sì jẹ́ alágàálámàṣà ní ẹnu wọn.” Ìyẹn ni pé, òṣùwọ̀n èké, òkúta òṣùwọ̀n èké àti irọ́ pípa wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn oníṣòwò nígbà ayé Míkà.
8 Kì í ṣe ibi ọjà títà nìkan ni ìwà ìrẹ́jẹ wọn yìí mọ sí. Ó gbilẹ̀ nílé ẹjọ́ pẹ̀lú. Míkà 7:3 fi hàn pé “ọmọ aládé ń béèrè fún nǹkan, ẹni tí ń ṣèdájọ́ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún èrè.” Àwọn onídàájọ́ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè fìyà àìtọ́ jẹ àwọn aláìṣẹ̀. “Ẹni ńlá,” tàbí ọ̀tọ̀kùlú èèyàn pẹ̀lú ń bá wọn hùwà ọ̀daràn. Kódà Míkà sọ pé ọmọ aládé, ẹni tí ń ṣèdájọ́, àti ẹni ńlá “hun ún pọ̀ mọ́ra,” ìyẹn ni pé wọ́n jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ìwà ibi.
9. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ táwọn ìkà ń hù ṣe nípa lórí Júdà àti Ísírẹ́lì?
9 Ìwà ìrẹ́jẹ táwọn ìkà olórí ń hù nípa lórí gbogbo Júdà àti Ísírẹ́lì. Míkà 7:5 sọ pé àìsí ìdájọ́ òdodo ti fa àìsí ìgbẹ́kẹ̀lé láàárín àwọn alábàákẹ́gbẹ́, láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán àti láàárín tọkọtaya pàápàá. Ẹsẹ kẹfà sọ pé ìyẹn ti dá rúgúdù sílẹ̀ débi pé ìbátan tímọ́tímọ́ bí ọmọkùnrin àti baba, ọmọbìnrin àti ìyá ń tẹ́ńbẹ́lú ara wọn.
10. Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń hùwà nínú ayé tí ìwà ìrẹ́jẹ gbòde kan yìí?
10 Òde òní wá ńkọ́? Ǹjẹ́ a rí i pé irú ohun kan náà ń ṣẹlẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí àìsí ìdájọ́ òdodo, àìlèfọkàntánni, àti ìdàrúdàpọ̀ láàárín àwùjọ àti nínú ìdílé gbòde kan lónìí bíi ti ọjọ́ Míkà. Síbẹ̀, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ń gbé láàárín ayé aláìṣòdodo yìí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí ìrẹ́jẹ inú ayé wọnú ìjọ Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà ìṣòtítọ́ àti ìwà títọ́ la ó rọ̀ mọ́, a ó sì máa fi èyí hàn nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Lóòótọ́, a ń “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ǹjẹ́ ẹ ò gbà pé bá a bá ń ṣèdájọ́ òdodo, a ó máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún to ń wá látinú jíjẹ́ ẹgbẹ́ ará tó fọkàn tán ara wọn?
Báwo Làwọn Èèyàn Ṣe Ń Gbọ́ “Ohùn Jèhófà”?
11. Báwo ni Míkà 7:12 ṣe ń nímùúṣẹ?
11 Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé bó ti wù kí àìṣèdájọ́ òdodo gbilẹ̀ tó, onírúurú èèyàn yóò máa rí ìdájọ́ òdodo gbà. Wòlíì yìí sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò kó àwọn èèyàn jọ “láti òkun dé òkun, àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá” kí wọ́n lè di olùjọsìn Jèhófà. (Míkà 7:12) Lóde òní tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ní ìmúṣẹ ìkẹyìn, kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan pàtó ló ń jàǹfààní ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú, àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ló ń jàǹfààní náà. (Aísáyà 42:1) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
12. Báwo la ṣe ń gbọ́ “ohùn Jèhófà” lóde òní?
12 Láti dáhùn ìbéèrè yìí, gbé àwọn ọ̀rọ̀ tí Míkà kọ́kọ́ sọ yẹ̀ wò. Míkà 6:9 sọ pé: “Àní ohùn Jèhófà ké sí ìlú ńlá náà, ẹni tí ó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ yóò sì bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Báwo ni àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀ èdè ṣe lè gbọ́ “ohùn Jèhófà,” báwo sì ni èyí ṣe wé mọ́ ṣíṣe tí àwa náà ń ṣe ìdájọ́ òdodo? Ká sọ tòótọ́, àwọn èèyàn kì í gbọ́ ohùn Ọlọ́run ní tààràtà lóde òní. Àmọ́, àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà àti onírúurú ipò ìgbésí ayé ń gbọ́ ohùn Jèhófà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Ìdí rèé táwọn tó bá fetí sílẹ̀ ṣe ń “bẹ̀rù orúkọ” Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fún un ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀. Ó dájú pé ńṣe là ń fi ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ hàn bá a ṣe ń fi ìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ fún gbogbo èèyàn láìsí ojúsàájú yẹn, “ìdájọ́ òdodo” là ń ṣe.
A Gbọ́dọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Inú Rere
13. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín inú rere onífẹ̀ẹ́ àti ìfẹ́?
13 Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ohun kejì tí a béèrè lọ́wọ́ wa nínú Míkà 6:8 wàyí. Jèhófà fẹ́ ká “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú rere” ni a tún túmọ̀ sí “inú rere onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ adúróṣinṣin.” Gbólóhùn náà inú rere onífẹ̀ẹ́ túmọ̀ sí kéèyàn máa fi ìyọ́nú ṣaájò, ìyẹn ni gbígba ti ẹlòmíràn rò. Inú rere onífẹ̀ẹ́ yàtọ̀ sí ìfẹ́. Lọ́nà wo? Ní ti pé ìfẹ́ kó nǹkan púpọ̀ mọ́ra ju inú rere onífẹ̀ẹ́ lọ. A tiẹ̀ lè nífẹ̀ẹ́ ohun aláìlẹ́mìí àní títí kan èrò orí pàápàá. Bí àpẹẹrẹ Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó “nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró,” ó tún sọ nípa ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n” pẹ̀lú. (Òwe 21:17; 29:3) Àmọ́ ní ti inú rere onífẹ̀ẹ́, àwọn èèyàn nìkan ni a máa ń fi hàn sí, pàápàá àwọn tó ń sin Ọlọ́run. Ìyẹn ni Míkà 7:20 fi mẹ́nu kan “inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí a fún Ábúráhámù,” ẹni tó sin Jèhófà Ọlọ́run.
14, 15. Báwo la ṣe ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn, àpẹẹrẹ irú rẹ̀ wo la sì mẹ́nu kàn?
14 Ní Míkà 7:18, wòlíì náà sọ pé Ọlọ́run “ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” Míkà 6:8 kò kàn sọ pé ká ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ńṣe ló sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ ànímọ́ yìí. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń kọ́ wa? Òun ni pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun tá a máa ń fínnúfíndọ̀ ṣe nítorí pé ó wù wá láti ṣe é. Bíi ti Jèhófà, ìdùnnú ló máa ń jẹ́ fún wa láti fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sáwọn aláìní.
15 Lóde òní, irú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tá a mọ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ló máa ń fi hàn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan péré. Ní oṣù June, 2001, ìjì kan jà ó sì fa alagbalúgbú omíyalé ní ìlú Texas ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé jẹ́, títí kan ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] àwọn Ẹlẹ́rìí wá fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n lo àkókò wọn, wọ́n sì náwó nára láti lè ran àwọn Kristẹni arákùnrin wọn tó níṣòro yìí lọ́wọ́. Ó ju oṣù mẹ́fà lọ táwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí fi ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru láìdáwọ́dúró, títí kan òpin ọ̀sẹ̀, kí wọ́n lè tún Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́jọ àti ilé tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] kọ́ fáwọn Kristẹni arákùnrin wọn. Àwọn tí kò lè ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, fi oúnjẹ, ohun èlò àti owó ránṣẹ́. Kí nìdí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí fi dìde ìrànlọ́wọ́ sí àwọn ará wọn? Ìdí ni pé wọ́n “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Ó mà dùn mọ́ni o láti mọ̀ pé jákèjádò ayé làwọn ará wa ń ṣe irú àwọn ohun tó jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀! Láìsí àní-àní, dídi ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ inú rere,” bá a ṣe sọ pé ká ṣe kì í ṣe ìnira fún wa o, ohun ayọ̀ ni!
Jẹ́ Ẹni Tó Mẹ̀tọ́mọ̀wà Ní Bíbá Ọlọ́run Rìn
16. Àpèjúwe wo ló jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn?
16 Ohun kẹta tá a ní ká ṣe nínú Míkà 6:8 ni pé “kí o . . . jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.” Èyí túmọ̀ sí pé ká mọ̀ pé ó níbi tí agbára wa mọ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ohun tá à ń wí rèé: Fojú inú wo ọmọdébìnrin kan tó di ọwọ́ bàbá rẹ̀ mú pinpin bí wọ́n ṣe ń lọ nígbà tí ìjì ń jà lọ́wọ́. Ọmọbìnrin yìí mọ̀ pé ó níbi tágbára òun mọ, ṣùgbọ́n ó gbẹ́kẹ̀ lé bàbá rẹ̀. Ó yẹ kí àwa náà mọ̀ pé ó níbi tágbára wa mọ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá wa ọ̀run. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìgbẹ́kẹ̀lé yìí já? Ọ̀nà kan ni pé ká máa fi ìdí tó fi bọ́gbọ́n gan-an láti sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ sọ́kàn. Míkà rán wa létí ìdí mẹ́ta, àwọn nìyí: Jèhófà ni Olùdáǹdè wa, Olùṣamọ̀nà wa, àti Olùdáàbòbò wa.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè, tó ṣamọ̀nà wọn, tó sì dáàbò bò wọ́n láyé ọjọ́un?
17 Ní Míkà 6:4, 5, Ọlọ́run sọ pé: “Mo mú ọ gòkè wá kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Ní tòótọ́, Jèhófà ni Olùdáǹdè Ísírẹ́lì. Jèhófà sọ síwájú sí i pé: “Mo sì tẹ̀ síwájú láti rán Mósè, Áárónì àti Míríámù ṣíwájú rẹ.” Mósè àti Áárónì ni a lò láti ṣamọ̀nà orílẹ̀-èdè náà, tí Míríámù sì ṣamọ̀nà àwọn obìnrin Ísírẹ́lì nígbà kan tí wọ́n ń kọ orin ìṣẹ́gun. (Ẹ́kísódù 7:1, 2; 15:1, 19-21; Diutarónómì 34:10) Bí Jèhófà ṣe tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣamọ̀nà wọn nìyẹn. Ní ẹsẹ karùn-ún, Jèhófà rán orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì létí pé òun dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ Bálákì àti Báláámù, òun sì dáàbò bò wọ́n nínú apá tó kẹ́yìn ìrìn àjò wọn láti Ṣítímù ní ilẹ̀ Móábù dé Gílígálì ní Ilẹ̀ Ìlérí.
18. Báwo ni Ọlọ́run ṣe jẹ́ Olùdáǹdè, Olùṣamọ̀nà àti Olùdáàbòbò wa lọ́jọ́ òní?
18 Bí àwa pẹ̀lú ṣe ń bá Ọlọ́run rìn, ó ń dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ayé Sátánì, ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ ṣamọ̀nà wa, ó sì ń dáàbò bo wá lápapọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn alátakò. Ìdí yìí ló fi ṣe pàtàkì fún wa láti di ọwọ́ Bàbá wa ọ̀run mú pinpin bá a ṣe ń rìn la ìjì apá ìkẹyìn ìrìn àjò wa kọjá sí ibi tó sàn ju Ilẹ̀ Ìlérí ìgbàanì lọ, ìyẹn ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.
19. Báwo ni ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ṣe wé mọ́ mímọ ibi tí agbára wa mọ?
19 Jíjẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn ń ràn wá lọ́wọ́ láti fojú tó tọ́ wo ipò tá a wà. Èyí jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ara ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ni mímọ ibi tí agbára wa mọ. Ara tó ń dara àgbà tàbí àìsàn lè dín ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kù. Àmọ́ dípò ká jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, á dára ká rántí pé Ọlọ́run ń tẹ́wọ́ gba àwọn ìsapá wa àti àwọn ẹbọ tí à ń rú ‘ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kò ní.’ (2 Kọ́ríńtì. 8:12) Ní ti tòótọ́, Jèhófà ń retí pé ká sin òun tọkàntọkàn, ká máa sa gbogbo ipá wa bí ipò wa ṣe yọ̀ǹda fún wa tó. (Kólósè 3:23) Nígbà tá a bá fi gbogbo ọkàn wa àti ìtara wa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, yóò bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu.—Òwe 10:22.
Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Mú Ìbùkún Wá
20. Àwọn ohun wo là ń rí tó yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìdúródeni bíi ti Míkà?
20 Ìbùkún Jèhófà tá à ń rí gbà ń mú ká fara wé irú ẹ̀mí tí Míkà ní. Ó sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Míkà 7:7) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe kan ọ̀ràn pé ká máa fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà bá Ọlọ́run rìn? Níní ẹ̀mí ìdúródeni tàbí ẹ̀mí sùúrù yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún níní ìrẹ̀wẹ̀sì pé ọjọ́ Jèhófà kò tíì dé títí di báyìí. (Òwe 13:12) Ká sòótọ́ gbogbo wa là ń fẹ́ kí òpin ayé burúkú yìí ti dé. Àmọ́, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ là ń rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá Ọlọ́run rìn. Èyí ló wá jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká lẹ́mìí ìdúródeni. Ẹlẹ́rìí kan tó pẹ́ tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí sọ nípa èyí pé: “Bí mo ṣe ń fojú inú wo ohun tó lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́ta tí mo ti fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù, ó dá mi lójú pé mi ò pàdánù ohunkóhun nítorí dídúró tí mò ń dúró de Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ kí n bọ́ lọ́wọ́ onírúurú ìdààmú ọkàn.” Ṣé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn?
21, 22. Báwo ni Míkà 7:14 ṣe ń nímùúṣẹ lóde òní?
21 Ó dájú gbangba pé bíbá Jèhófà rìn ń ṣe wá láǹfààní. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kà nínú Míkà 7:14, Míkà fi àwọn èèyàn Ọlọ́run wé àwọn àgùntàn tí ọkàn wọ́n balẹ̀ bí wọ́n ṣe wà lọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn wọn. Lóde òní, tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ní ìmúṣẹ tó túbọ̀ gbòòrò sí i, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ń rí ìbàlẹ̀ ọkàn lọ́dọ̀ Jèhófà, Olùṣọ́ Àgùntàn wọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé. Wọ́n “ń dá gbé nínú igbó—ní àárín ọgbà igi eléso,” bá a ṣe yà wọ́n sọ́tọ̀ nípa tẹ̀mí kúrò nínú ayé tó túbọ̀ ń dani lọ́kàn rú tó sì kún fún ewu yìí.— Jòhánù 10:16; Diutarónómì 33:28; Jeremáyà 49:31; Gálátíà 6:16.
22 Àwọn èèyàn Jèhófà ń láásìkí, gẹ́gẹ́ bí Míkà 7:14 ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Míkà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àgùntàn, tàbí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó ní: “Jẹ́ kí wọ́n fi Báṣánì àti Gílíádì ṣe oúnjẹ.” Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tó wà ní Báṣánì àti Gílíádì ṣe máa ń jẹko nínú pápá tó tutù yọ̀yọ̀, bẹ́ẹ̀ láwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń láásìkí nípa tẹ̀mí lóde òní, ìyẹn sì jẹ́ ìbùkún mìíràn fáwọn tó ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà bá Ọlọ́run rìn.— Númérì 32:1; Diutarónómì 32:14.
23. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ṣíṣàyẹ̀wò ìwé Míkà 7:18, 19?
23 Nínú Míkà 7:18, 19, wòlíì náà ṣàlàyé nípa bí Jèhófà ṣe ń fẹ́ láti dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà. Ẹsẹ kejìdínlógún sọ pé Jèhófà “ń dárí ìrélànàkọjá jì,” ó sì “ń ré ìṣìnà . . . kọjá.” Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ kọkàndínlógún ṣe wí, ńṣe ni yóò “sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sínú ibú òkun.” Ẹ̀kọ́ wo ni ibí yìí ń kọ́ wa? Ó yẹ ká bi ara wa bóyá à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí. Ǹjẹ́ a máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá jì wọ́n? Bí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì wọ́nà láti ṣàtúnṣe, yóò dára ká ṣe gẹ́gẹ́ bíi Jèhófà tó ṣe tán láti dárí jini pátápátá.
24. Àǹfààní wo ni o ti rí nínú àkọsílẹ̀ Míkà?
24 Àǹfààní wo ni a ti rí nínú ṣíṣàgbéyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Míkà yìí? Ó ti rán wa létí pé Jèhófà ń jẹ́ kí àwọn tó sún mọ́ ọn ní ìrètí tòótọ́. (Míkà 2:1-13) Ó ti gbà wá níyànjú pé ká sa gbogbo ipá wa láti gbé ìsìn mímọ́ lárugẹ ká bàa lè máa rìn lórúkọ Ọlọ́run títí láé. (Míkà 4:1-4) Ó sì ti jẹ́ kó dá gbogbo wa lójú pé ipòkípò yòówù kí a wà, àwọn ohun tí Jèhófà béèrè kò kọjá agbára wa. Dájúdájú, àsọtẹ́lẹ̀ Míkà fún wa lókun ní tòótọ́ láti máa rìn lórúkọ Jèhófà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ní Míkà 6:8, kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe?
• Kí ló pọn dandan tá a bá fẹ́ ṣe “ìdájọ́ òdodo”?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a “nífẹ̀ẹ́ inú rere”?
• Kí ni ‘ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rìn’ wé mọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Pẹ̀lú bí ipò nǹkan ṣe burú tó nígbà ayé Míkà, ó ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣe ìdájọ́ òdodo nípa wíwàásù fún onírúurú èèyàn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ inú rere nípa pípèsè ohun táwọn ẹlòmíràn nílò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe, má sì ṣe ohun tó ju agbára rẹ lọ