ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍRÀ 6-10
Àwọn Tó Ń Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn Ni Jèhófà Fẹ́
Ẹ́sírà ṣètò láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù
Ẹ́sírà gba ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ Atasásítà Ọba kó lè pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú
Ọba “yọ̀ǹda gbogbo” ohun tí Ẹ́sírà “béèrè” láti fi kọ́ ilé Jèhófà, àwọn nǹkan bíi wúrà, fàdákà, àlìkámà, wáìnì, òróró, àti iyọ̀, ìṣirò gbogbo wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] bílíọ̀nù náírà
Ẹ́sírà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀
Ìrìn àjò wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù máa nira
Ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà, ojú ọ̀nà yẹn sì tún léwu
Ìrìn àjò náà gbà tó oṣù mẹ́rin
Ó gba pé kí àwọn tó pa dà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ àti ìgboyà
ÀWỌN NǸKAN TÍ Ẹ́SÍRÀ KÓ DÁNÍ NI . . .
Wúrà àti fàdákà tó wúwo tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlá [513] àpò sìmẹ́ǹtì Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó akọ erin ńlá mẹ́ta!
ÌṢÒRO TÍ ÀWỌN TÓ PA DÀ KOJÚ . . .
Àwọn ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí, ojú ọjọ́ nínú aṣálẹ̀, àwọn ẹranko eléwu