ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌDÁRÒ 1-5
Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Jẹ́ Ká Ní Ìfaradà
Kí ló ran Jeremáyà lọ́wọ́ tó fi fara da ìṣòro tó lágbára gan-an, tí kò sì ṣìwà hù?
Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà máa “tẹ̀ ba mọ́lẹ̀” nítorí àwọn tó ti ronú pìwà dà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì máa mú ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn wọn
Ó ti kọ́ láti “ru àjàgà ní ìgbà èwe rẹ̀.” Tí ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fara da àdánwò ìgbàgbọ́ láti ìgbà ọ̀dọ́, ńṣe ni èyí á mú kó rọrùn fún un láti kojú àwọn ìṣòro tó ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú