KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA LÓ MỌ ỌJỌ́ Ọ̀LA?
Àsọtẹ́lẹ̀ Tó ti Ṣẹ àti Àìmọye Tí Kò Ṣẹ
Ta ni kò wù kó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun lọ́jọ́ ọ̀la? Ó dájú pé kò sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tiẹ̀ máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ wọn kì í ṣẹ. Díẹ̀ nínú ohun tí wọ́n máa ń sọ rèé:
ÀWỌN ONÍMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ máa ń ṣe àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, wọ́n sì tún máa ń fi owó tabua ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú irú bí àkóbá tí àwọn tó ń ba àyíká jẹ́ máa ṣe sí ayé wa àti bóyá òjò máa rọ̀ láwọn àdúgbò kan ní ọjọ́ kejì.
ÀWỌN ÒGBÓǸKANGÍ ONÍMỌ̀ náà máa ń sọ ohun tí wọ́n rò pé á ṣẹlẹ̀ lágbo ìṣòwò àti ìṣèlú. Warren Buffett tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oníṣòwò tó lówó jù láyé ni àwọn èèyàn ti sọ di òòṣà nítorí ohun tó bá sọ nípa ọrọ̀ ajé máa ń ṣẹ. Onímọ̀ míì tó ń jẹ́ Nate Silver, máa ń ṣe ìwádìí oníṣirò kó lè sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèlú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà títí kan àwọn tó máa gba àmì ẹ̀yẹ fún ipa ribiribi tí wọ́n kó nínú àwọn fíìmù Hollywood lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
ÀWỌN ÌWÉ ÀTIJỌ́ làwọn kan kà sí ìwé àsọtẹ́lẹ̀. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Michel de Nostredame (Nostradamus) kọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò lóye àwọn ohun tó kọ nítorí àdììtú ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, síbẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé náà ti ń ṣẹ lónìí. Ìwé àtijọ́ míì ni Kàlẹ́ńdà àwọn Maya tó parí ní December 21, ọdún 2012. Àwọn kan sì máa ń wo ọdún yẹn gẹ́gẹ́ bí àmì pé àwọn àjálù burúkú máa tó ṣẹlẹ̀ láyé.
ÀWỌN AṢÁÁJÚ ÌSÌN máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa onírúurú àjálù tó máa kárí ayé kí wọ́n lè kìlọ̀ fáwọn èèyàn, kí wọ́n sì tún lè kó ọmọ ẹ̀yìn jọ fún ara wọn. Wòlíì kan tó ń jẹ́ Harold Camping tó máa ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ayé àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ polongo pé ayé máa pa run ní ọdún 2011. Àmọ́ ayé ọ̀hún náà la ṣì ń gbé títí dòní tí mìmì kàn ò sì mì.
ÀWỌN ABẸ́MÌÍLÒ máa ń fọ́nnu pé àwọn ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí. Edgar Cayce àti Jeane Dixon sọ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ṣẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n sọ ni kò ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Dixon sọ pé Ogun Àgbáyé kẹta máa wáyé ní ọdún 1958, Cayce sì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé, ìlú New York ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa rì ní nǹkan bí ọdún 1974 sí 1976 títí omi òkun á fi ya bò ó mọ́lẹ̀.
Tó bá di pé ká sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kó sì ṣẹ, ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó ṣe é gbára lé? Ìbéèrè yìí mọ́gbọ́n dání gan-an torí pé tá a bá mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, á mú ká ṣe àwọn ìpinnu tó dáa ní ìgbésí ayé wa.