Gbogbo Ìwé Inú Bíbélì Wà Níṣọ̀kan
“A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 PÉTÉRÙ 1:21.
KÍ NI BÍBÉLÌ FI YÀTỌ̀? Àwọn àkọsílẹ̀ ayé àtijọ́ sábà máa ń ta kora, kódà bí wọ́n tiẹ̀ kọ wọ́n láàárín ìgbà kan náà. Tí èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá kọ̀wé, ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ní àkókò tó yàtọ̀ síra, àwọn ìwé náà kò ní ṣàì ta kora ní àwọn ibì kan. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé ẹnì kan ṣoṣo ni Òǹṣèwé gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] inú Bíbélì, tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí láì ta kora.—2 Tímótì 3:16.
ÀPẸẸRẸ: Mósè tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ nínú ìwé àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì pé “irú-ọmọ” kan ń bọ̀ tó máa gba aráyé là. Nígbà tó yá, ìwé yìí tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé irú-ọmọ yẹn máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:17, 18; 26:24; 28:14) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì Nátánì jẹ́ ká mọ̀ pé irú-ọmọ náà yóò wá láti ìlà ìdílé Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 7:12) Ẹgbẹ̀rún ọdún kan lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù àti àwọn kan tí Ọlọ́run yàn lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló máa para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ náà. (Róòmù 1:1-4; Gálátíà 3:16, 29) Níkẹyìn, ìgbà tó máa fi di ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìwé Ìṣípayá tó kẹ́yìn Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn tó para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ yẹn máa jẹ́rìí nípa Jésù lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á jíǹde sókè ọ̀run, wọ́n yóò sì bá Jésù ṣàkóso lọ́run fún ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún. Àti pé àwọn tó para pọ̀ jẹ́ irú ọmọ yìí máa pa Èṣù run, wọn á sì gba aráyé là.—Ìṣípayá 12:17; 20:6-10.
OHUN TÍ ÀWỌN TÓ Ń ṢÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀ INÚ BÍBÉLÌ SỌ: Lẹ́yìn tí ọ̀gbẹ́ni Louis Gaussen ti fara balẹ̀ ṣe àyẹ̀wò ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó wà nínú Bíbélì dáadáa, ó kọ̀wé pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún òun láti rí “bí ìwé yìí, tó gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún kí onírúurú òǹkọ̀wé tó kọ ọ́ parí, ṣe wà níṣọ̀kan pátápátá, . . . tí àwọn òǹkọ̀wé yẹn sì kọ̀wé lórí kókó kan náà, ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, lọ́nà tó ṣọ̀kan, bíi pé àwọn fúnra wọn ti mọ kókó tí wọ́n ń kọ̀wé lé lórí dunjú, ìyẹn ìtàn bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe gba aráyé là.”—Theopneusty—The Plenary Inspiration of the Holy Scriptures.
KÍ LÈRÒ RẸ? Ǹjẹ́ o rò pé ìwé kan tí nǹkan bí ogójì [40] èèyàn kọ, tó sì gba ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún kí wọ́n tó kọ ọ́ parí, lè wà ní ìṣọ̀kan láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí láì ta kora níbì kankan? Ǹjẹ́ ti Bíbélì kò yàtọ̀ gédégbé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
“Tí a bá wo ìwé Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá pa pọ̀, a óò rí i pé ṣe ni gbogbo rẹ̀ para pọ̀ jẹ́ ìwé kan ṣoṣo . . . Nínú gbogbo ìwé ayé yìí, kò sì ìwé tó dà bí tirẹ̀, tàbí èyí tó tiẹ̀ sún mọ́ ọn.”—THE PROBLEM OF THE OLD TESTAMENT, LÁTI ỌWỌ́ JAMES ORR