Orí Kẹrìnlá
Wàá Jàǹfààní Májẹ̀mú Tuntun
1. Iṣẹ́ tó pín sí apá méjì wo ni Jeremáyà ṣe?
IṢẸ́ tó pín sí apá méjì ni Jèhófà gbé lé Jeremáyà lọ́wọ́. Apá kan rẹ̀ ni pé yóò ní “láti fà tu àti láti bì wó àti láti pa run àti láti ya lulẹ̀.” Apá kejì ni pé yóò ní “láti kọ́ àti láti gbìn.” Ọ̀nà tí Jeremáyà gbà ṣe apá àkọ́kọ́ ni pé ó táṣìírí ìwà ibi àwọn Júù agbéraga, ó sì kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lé àwọn àti Bábílónì lórí. Ọ̀nà tó sì gbà ṣe apá kejì ni pé ó sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó ní Ọlọ́run máa kọ́ ohun tó ní lọ́kàn láti kọ́, yóò sì gbin ohun tó ti pinnu láti gbìn. Apá kejì iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ yìí ló ń ṣe nígbà tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú àwọn Júù pa dà bọ̀ wá sí ilẹ̀ wọn.—Jer. 1:10; 30:17, 18.
2. Kí nìdí tí Jèhófà fi lóun yóò dá àwọn èèyàn òun lẹ́jọ́, báwo sì ni ìdájọ́ wọn ṣe máa le tó?
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà kéde pé Ọlọ́run máa mú àwọn èèyàn Rẹ̀ bọ̀ sípò, ìyẹn ò fi hàn pé Ọlọ́run máa wá gbọ̀jẹ̀gẹ́ fáwọn èèyàn rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn tàbí pé Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo máa dijú sí ìwà àìtọ́. Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ṣe ni yóò dá àwọn Júù tó yàyàkuyà yìí lẹ́jọ́. (Ka Jeremáyà 16:17, 18.) Nígbà ayé Jeremáyà, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ló “ń ṣe ìdájọ́ òdodo,” ìwọ̀nba díẹ̀ ló sì “ń wá ìṣòtítọ́,” débi pé Jèhófà ò lè gbójú fo ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó ní: “Kíkẹ́dùn ti sú mi.” (Jer. 5:1; 15:6, 7) Àwọn Júù yìí “padà sínú àwọn ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn, àwọn ti àkọ́kọ́, tí ó kọ̀ láti ṣègbọràn” sí ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, bí wọ́n ṣe lọ ń bọ̀rìṣà tún ń bí Ọlọ́run nínú. (Jer. 11:10; 34:18) Nítorí náà, Jèhófà yóò bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí, àní yóò tiẹ̀ nà wọ́n “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Èyí lè pe orí àwọn kọ̀ọ̀kan lára wọn wálé, kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.—Jer. 30:11; 46:28.
3. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbé àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun yẹ̀ wò?
3 Ọlọ́run wá gbẹnu Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun kan tí àǹfààní rẹ̀ máa pọ̀ gan-an tí yóò sì wà pẹ́ títí. Ohun náà ni májẹ̀mú tuntun. Bá a ṣe ń gbé àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ, èyí tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ wò, ó ṣe pàtàkì pé ká pàfiyèsí sí kókó tó ń múni láyọ̀ yìí, ìyẹn májẹ̀mú tuntun. Ṣe ni Jèhófà lóun máa fi rọ́pò májẹ̀mú tóun bá Ísírẹ́lì dá nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, èyí tó jẹ́ pé Mósè ṣe alárinà rẹ̀. (Ka Jeremáyà 31:31, 32.) Nígbà tí Jésù Kristi sì dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó mẹ́nu kan májẹ̀mú tuntun. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tuntun yìí kàn wá. (Lúùkù 22:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí májẹ̀mú yìí nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn ará Hébérù. Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà, ó wá fi ṣàlàyé bí májẹ̀mú tuntun ti ṣe pàtàkì tó. (Héb. 8:7-9) Àmọ́, kí ni májẹ̀mú tuntun náà? Kí nìdí tó fi ní láti wáyé? Àwọn wo ló kópa nínú májẹ̀mú yẹn, báwo sì ni ìwọ gan-an ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò.
KÍ NÌDÍ TÍ MÁJẸ̀MÚ TUNTUN FI WÁYÉ?
4. Kí ni májẹ̀mú Òfin jẹ́ kó ṣeé ṣe?
4 Ká tó lè lóye májẹ̀mú tuntun, a ní láti kọ́kọ́ mọ ète májẹ̀mú Òfin tó ti wà tẹ́lẹ̀. Ṣe ni májẹ̀mú Òfin jẹ́ kí àwọn ohun pàtàkì kan lè ṣeé ṣe ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì táwọn èèyàn rẹ̀ ń retí Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́n. 22:17, 18) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́wọ́ gba májẹ̀mú Òfin, wọ́n di “àkànṣe dúkìá” fún Ọlọ́run. Májẹ̀mú yẹn sì fi hàn pé inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Léfì ni àwọn àlùfáà orílẹ̀-èdè náà yóò ti máa wá. Nígbà tí Jèhófà ń bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú yẹn ní Òkè Sínáì, ó sọ̀rọ̀ nípa “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́,” ṣùgbọ́n kò sọ ìgbà tó máa wáyé àti ọ̀nà tó máa gbà wáyé. (Ẹ́kís. 19:5-8) Àmọ́ kó tó di pé ó wáyé, májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì dá yìí ti jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò lè pa Òfin Mósè mọ́ délẹ̀délẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Òfin náà ń jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn fara hàn kedere. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lábẹ́ Òfin yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa rúbọ lemọ́lemọ́ láti máa fi ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó wá hàn gbangba pé wọ́n nílò nǹkan tó dára jùyẹn lọ, ìyẹn ẹbọ pípé kan tí wọ́n máa rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré táá sì parí síbẹ̀. Àní sẹ́, wọ́n nílò ọ̀nà kan tí wọ́n máa fi rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́ẹ̀kan táá sì jẹ́ títí láé.—Gál. 3:19-22.
5. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun kan?
5 A lè wá rídìí tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣì wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú míì, ìyẹn májẹ̀mú tuntun. Nítorí inú rere àti ìfẹ́ tí Jèhófà ní, ó fẹ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ kan tó máa wà títí gbére tí àǹfààní rẹ̀ ò sì ní mọ sí orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Ọlọ́run gbẹnu Jeremáyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa wà nínú májẹ̀mú tuntun ọjọ́ iwájú yìí pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jer. 31:34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ayé Jeremáyà ni Ọlọ́run ṣe ìlérí yìí, gbogbo aráyé ló máa ṣe láǹfààní ńláǹlà lọ́jọ́ ọ̀la. Lọ́nà wo?
6, 7. (a) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn kan pé wọ́n jẹ́ni tó ń dẹ́ṣẹ̀? (b) Kí nìdí tí ṣíṣàyẹ̀wò májẹ̀mú tuntun fi lè múnú rẹ dùn?
6 Aláìpé ṣì ni wá, àìpé yìí sì máa ń jẹ yọ lára wa lọ́pọ̀ ìgbà. A rí àpẹẹrẹ èyí lára arákùnrin kan tó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti borí ìṣòro kan tí kò lọ bọ̀rọ̀. Ó ní: “Ìbànújẹ́ máa ń bá mi nígbà tí mo bá tún jìn sọ́fìn ìwà tí mò ń sapá láti borí. Mo máa ń rò pé kò sí ohun tí mo lè ṣe tí Ọlọ́run á fi dárí jì mí. Àtigbàdúrà gan-an máa ń dogun fún mi. Tí mo bá jàjà fẹ́ gbàdúrà mo máa ń bẹ̀rẹ̀ báyìí pé, ‘Jèhófà, mi ò mọ̀ bóyá wàá gbọ́ àdúrà mi yìí, àmọ́ . . . ’” Bákan náà, ó máa ń ṣe àwọn míì tó tún pa dà jìn sọ́fìn ìwà àìtọ́, tàbí àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ kan, bí ẹni pé “ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà” dínà mọ́ àdúrà wọn kó má lè dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Ìdárò 3:44) Ìdààmú ṣì máa ń bá àwọn míì lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ̀ sẹ́yìn, àní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. Kódà, Kristẹni kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere pàápàá lè sọ ohun kan táá tún wá kábàámọ̀ rẹ̀ pé òun ì bá má ti sọ ọ́.—Ják. 3:5-10.
7 Kí ẹnikẹ́ni nínú wa má rò pé òun ò lè ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó láéláé, torí a kì í rìn kí orí má mì. (1 Kọ́r. 10:12) Kódà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù alára rí i pé òun pàápàá ò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Ka Róòmù 7:21-25.) Ibi tí ọ̀rọ̀ ti kan májẹ̀mú tuntun gan-an nìyí. Ọlọ́run ṣèlérí pé ohun pàtàkì kan tó máa wáyé nínú májẹ̀mú tuntun yìí ni pé òun ò ní máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn mọ́. Àǹfààní tí kò láfiwé gbáà lèyí máa ṣe fún wa! Yóò dùn mọ́ Jeremáyà nínú gan-an bó ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, àní bó ṣe máa dùn mọ́ àwa náà bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tá a sì ń rí ọ̀nà tó lè gbà ṣe wá láǹfààní.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá májẹ̀mú tuntun?
KÍ NI MÁJẸ̀MÚ TUNTUN NÁÀ?
8, 9. Kí ló ná Jèhófà kí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tó lè ṣeé ṣe?
8 Bó o ṣe ń mọ Jèhófà sí i ni wàá túbọ̀ máa rí bó ṣe jẹ́ onínúure àti aláàánú tó sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé. (Sm. 103:13, 14) Nígbà tí Jeremáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun, ó sọ ọ́ kedere pé Jèhófà máa “dárí ìṣìnà wọn jì” kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. (Jer. 31:34) Àmọ́ Jeremáyà tiẹ̀ lè máa rò ó pé ọ̀nà wo ni Ọlọ́run máa gbé ọ̀rọ̀ ìdáríjì yìí gbà ná? Yóò ṣáà mọ̀ pé bí Ọlọ́run ṣe sọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú tuntun yìí, ṣe ló máa bá aráyé wọ àdéhùn kan. Àti pé, lọ́nà kan ṣáá, Jèhófà máa tipa májẹ̀mú yẹn mú ohun tó mí sí òun láti kọ sílẹ̀ ṣẹ, títí kan ọ̀rọ̀ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Tó bá sì wá tásìkò lójú Ọlọ́run yóò máa ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó kù nínú ète rẹ̀ payá, títí kan ohun tí Mèsáyà máa ṣe.
9 Ó ṣeé ṣe kó o ti máa rí àwọn òbí tó kẹ́ ọmọ wọn lákẹ̀ẹ́bàjẹ́, tí wọn kì í bá a wí. Ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà máa ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ó tì o! A rí èyí kedere nínú ọ̀nà tí májẹ̀mú tuntun yẹn gbà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ọlọ́run ò kàn dédé wọ́gi lé ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fẹ̀sọ̀ tẹ̀ lé gbogbo ìlànà ìdájọ́ òdodo rẹ̀, tó ṣètò ọ̀nà tó bófin mu tá a ó fi lè máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ńláǹlà ló ná an. O lè túbọ̀ lóye èyí tó o bá kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó ń ṣàlàyé májẹ̀mú tuntun. (Ka Hébérù 9:15, 22, 28.) Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ‘ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà,’ ó wá sọ pé “bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé.” Ẹ̀jẹ̀ inú májẹ̀mú tuntun tíbí yìí ń sọ kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ màlúù tàbí ti ewúrẹ́ tí wọ́n sábà máa fi ń rúbọ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin o. Ẹ̀jẹ̀ Jésù ló mú kí májẹ̀mú tuntun yìí ṣeé ṣe. Lọ́lá ẹbọ Jésù yìí, tó jẹ́ ẹbọ pípé, Jèhófà lè máa ‘dárí ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jì’ títí láé. (Ìṣe 2:38; 3:19) Àmọ́ àwọn wo ló máa kópa nínú májẹ̀mú tuntun yẹn tí wọ́n á sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí gbà? Orílẹ̀-èdè àwọn Júù kọ́ o. Torí Jésù sọ pé Ọlọ́run yóò kọ àwọn Júù, tó jẹ́ pé wọ́n ń fi ẹran rúbọ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, yóò sì yíjú sí orílẹ̀-èdè mìíràn. (Mát. 21:43; Ìṣe 3:13-15) “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, ló para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè yìí. Ní kúkúrú, májẹ̀mú Òfin ló wà láàárín Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè àwọn Júù, tí májẹ̀mú tuntun sì wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti Ísírẹ́lì tẹ̀mí, Jésù sì ni Alárinà rẹ̀.—Gál. 6:16; Róòmù 9:6.
10. (a) Ta ni “èéhù” Dáfídì? (b) Báwo ni aráyé ṣe lè jàǹfààní lára “èéhù” yìí?
10 Jeremáyà sọ pé Ẹni tó ń bọ̀, ìyẹn Mèsáyà, jẹ́ “èéhù” Dáfídì. Ó sì bá a mu bẹ́ẹ̀. Nítorí pé Jeremáyà ò tiẹ̀ tíì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wòlíì nígbà tí wọ́n ti yẹ àga mọ́ àwọn ọba tó ń jẹ láti ìlà ìdílé Dáfídì nídìí, tí wọ́n gé ìlà àwọn ọba náà lulẹ̀ bí ẹni gé igi. Àmọ́ kùkùté rẹ̀ kò kú. Nígbà tó yá, wọ́n bí Jésù ní ìlà ìdílé Dáfídì Ọba. Òun lẹni tá a lè pè ní “Jèhófà Ni Òdodo Wa,” èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ràn òdodo gan-an ni. (Ka Jeremáyà 23:5, 6.) Jèhófà gbà kí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo yìí jìyà lórí ilẹ̀ ayé kó sì kú. Ó wá ṣeé ṣe fún Jèhófà láti ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu, kó lo ìtóye ẹbọ ìràpadà tí Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “èéhù” Dáfídì yìí fara rẹ̀ rú, láti fi ṣe ìpìlẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. (Jer. 33:15) Èyí jẹ́ kí àwọn èèyàn kan dẹni tí Ọlọ́run lè polongo ní “olódodo fún ìyè,” kó fẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, kí wọ́n sì kópa nínú májẹ̀mú tuntun náà. Ẹ̀rí pé Ọlọ́run fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo sì tún hàn síwájú sí i ní ti pé àwọn míì tí kò kópa ní tààràtà nínú májẹ̀mú yẹn náà lè jàǹfààní nínú rẹ̀, wọ́n sì ti ń jàǹfààní rẹ̀ báyìí, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i níwájú.—Róòmù 5:18.
11. (a) Inú kí ni wọ́n kọ òfin májẹ̀mú tuntun sí? (b) Kí nìdí táwọn “àgùntàn mìíràn” fi nífẹ̀ẹ́ sí òfin májẹ̀mú tuntun?
11 Ṣé wàá tún fẹ́ mọ àwọn nǹkan míì tí májẹ̀mú tuntun fi yàtọ̀ sí májẹ̀mú ti Òfin Mósè? Ohun kan pàtàkì tó fi yàtọ̀ ni ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí. (Ka Jeremáyà 31:33.) Orí wàláà òkúta ni wọ́n kọ Òfin Mẹ́wàá ti májẹ̀mú Òfin sí, ó sì dàwátì nígbà tó yá. Ṣùgbọ́n ní ti májẹ̀mú tuntun, inú ọkàn àwọn èèyàn ni Jeremáyà sọ pé wọ́n máa kọ òfin rẹ̀ sí, yóò sì wà títí gbére. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n kópa nínú májẹ̀mú tuntun mọyì òfin yìí gan-an ni. Àwọn “àgùntàn mìíràn” tó ń retí pé wọ́n máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé, tí wọn kò kópa nínú májẹ̀mú tuntun náà ní tààràtà ńkọ́? (Jòh. 10:16) Inú àwọn náà dùn sí òfin Ọlọ́run. Ńṣe ni tiwọn dà bíi tàwọn àtìpó tó ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, tó jẹ́ pé wọ́n fara mọ́ Òfin Mósè, tí wọ́n sì ń jàǹfààní rẹ̀.—Léf. 24:22; Núm. 15:15.
12, 13. (a) Kí ni òfin májẹ̀mú tuntun? (b) Tó o bá wà lábẹ́ “òfin Kristi,” kí nìdí tí kò fi yẹ kó ṣe ọ́ bíi pé wọ́n ń fipá mú ọ sin Ọlọ́run?
12 Kí lo máa sọ tí wọ́n bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni òfin yìí tí wọ́n kọ sínú ọkàn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?’ Òfin yìí kan náà ni Bíbélì pè ní “òfin Kristi.” Àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó kópa nínú májẹ̀mú tuntun ni Ọlọ́run kọ́kọ́ fún ní òfin yẹn. (Gál. 6:2; Róòmù 2:28, 29) A lè fi ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ṣàkópọ̀ “òfin Kristi,” òun sì ni, ìfẹ́. (Mát. 22:36-39) Báwo ló ṣe ń di pé wọ́n kọ òfin yìí sínú ọkàn àwọn ẹni àmì òróró? Àwọn nǹkan pàtàkì táwọn ẹni àmì òróró máa ń ṣe tí òfin yìí á fi dèyí tí wọ́n kọ sínú ọkàn wọn ni pé, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbàdúrà sí Jèhófà. Nítorí náà, nǹkan méjèèjì yìí, tó jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́, ṣe pàtàkì gan-an nígbèésí ayé gbogbo Kristẹni tòótọ́, títí kan àwọn tí kò kópa nínú májẹ̀mú tuntun, àmọ́ tí wọ́n fẹ́ jàǹfààní nínú rẹ̀.
13 Ìwé Jákọ́bù pe “òfin Kristi” ní “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” àti “òfin àwọn ẹni òmìnira.” (Ják. 1:25; 2:12) Gbàrà tí wọ́n bá ti bí àwọn Júù ni wọ́n ti ń dẹni tó wà lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ ní ti májẹ̀mú tuntun tàbí òfin Kristi, kò sẹ́ni tí wọ́n ń bí sínú rẹ̀. Wọn kì í fipá mú èyíkéyìí lára àwọn tó ń tẹ̀ lé òfin Kristi láti máa sin Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń dùn mọ́ wọn láti mọ̀ pé Ọlọ́run lè kọ òfin rẹ̀ sínú ọkàn èèyàn, àti pé, lónìí aráyé lè jẹ àǹfààní ayérayé tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé májẹ̀mú yẹn máa mú wá.
Kí ni Ọlọ́run ṣe tá a fi lè máa rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lọ́lá májẹ̀mú tuntun? Báwo lo ṣe lè dẹni tó mọ òfin tí wọ́n ń kọ sínú ọkàn èèyàn?
ÀWỌN TÓ Ń JÀǸFÀÀNÍ MÁJẸ̀MÚ TUNTUN
14. Àwọn wo la wá rí pé ó ń jàǹfààní májẹ̀mú tuntun?
14 Báwọn kan ṣe mọ̀ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló ń kópa nínú májẹ̀mú tuntun, wọ́n lè rò pé àwọn yẹn nìkan ló ń jàǹfààní nínú rẹ̀. Bóyá wọ́n rò bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ló ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, ìyẹn búrẹ́dì àti wáìnì, èyí tí wáìnì ibẹ̀ ń dúró fún “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” náà. (Máàkù 14:24) Àmọ́ rántí pé ṣe ni àwọn tí wọ́n kópa nínú májẹ̀mú tuntun máa jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n á jọ di “irú-ọmọ” Ábúráhámù, èyí tí gbogbo orílẹ̀-èdè máa tipasẹ̀ rẹ̀ gba ìbùkún. (Gál. 3:8, 9, 29; Jẹ́n. 12:3) Nítorí náà, ṣe ni Jèhófà yóò lo májẹ̀mú tuntun láti fi mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé òun yóò bù kún gbogbo aráyé nípasẹ̀ “irú-ọmọ” Ábúráhámù.
15. Ipa wo ni Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró máa kó?
15 Jésù Kristi tó jẹ́ olórí nínú irú-ọmọ Ábúráhámù ni Àlùfáà Àgbà, òun ló sì ṣèrúbọ pípé tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ka Hébérù 2:17, 18.) Síbẹ̀, tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti jẹ́ kó hàn pé lọ́jọ́ iwájú, àwọn kan máa di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kís. 19:6) Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, inú ẹ̀yà kan ṣoṣo ni àlùfáà ti máa ń wá, tí ọba sì ń wá látinú ẹ̀yà míì. Torí náà, báwo ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn èèyàn rẹ̀ máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pa pọ̀ yìí ṣe máa wáyé? Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù kọ ìwé Pétérù Kìíní, àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí sọ di mímọ́ ló darí rẹ̀ sí. (1 Pét. 1:1, 2) Ó pè wọ́n ní “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní.” (1 Pét. 2:9) Èyí fi hàn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó kópa nínú májẹ̀mú tuntun máa jẹ́ àlùfáà lábẹ́ Kristi. Ìwọ wo irú àǹfààní ńlá tí ìyẹn sì máa jẹ́! Ojoojúmọ́ ni ẹ̀ṣẹ̀ ń fojú wa gbolẹ̀, bó ṣe ń “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” lé wa lórí. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ á ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó jẹ́ àlùfáà lábẹ́ Kristi yìí. (Róòmù 5:21) Wọ́n á ti mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn bá ṣàṣìṣe àti ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń bá wa nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, àwọn àti Kristi á lè máa gba tiwa rò bá a ṣe ń gbìyànjú láti borí ẹ̀ṣẹ̀ dídá.
16. Ìṣírí wo ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lè rí gbà nínú ìwé Ìṣípayá 7:9, 14?
16 Ìwé Ìṣípayá 7:9, 14 ṣàpèjúwe àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” pé wọ́n “wọ aṣọ funfun,” èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kà wọ́n sí ẹni mímọ́. Ọlọ́run ti ń kó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ báyìí, ìyẹn àwọn tó ń retí àtila “ìpọ́njú ńlá” náà já. Èyí tó fi hàn pé nísinsìnyí pàápàá, Ọlọ́run kà wọ́n sí olódodo láwọn ọ̀nà kan. A pè wọ́n ní olódodo, ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Róòmù 4:2, 3; Ják. 2:23) Àǹfààní tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ní yìí mà kàmàmà o! Tó o bá jẹ́ ara àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run yóò máa ràn ọ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń sapá láti wà ní mímọ́ lójú rẹ̀.
17. Báwo ló ṣe jẹ́ pé Jèhófà kì í “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ mọ́?
17 Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí Ọlọ́run ṣojú rere sí? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ohun tí Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ ni pé: “Èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jer. 31:34) Ọlá ẹbọ ìràpadà Jésù ni Ọlọ́run fi ń ṣe èyí fáwọn ẹni àmì òróró. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lọ́lá “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” yìí kan náà. Nígbà tí Jeremáyà sọ pé Ọlọ́run ò ní “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa dẹni tó ń gbàgbé nǹkan débi pé kò ní lè rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fi hàn pé tí Jèhófà bá ti lè fún ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìbáwí tó tọ́, tó sì dárí jì í nítorí pé ó ronú pìwà dà, ṣe ló máa ń gbé ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ náà jù sí ẹ̀yìn. Rántí ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì Ọba ṣẹ̀ nínú ọ̀ràn Bátí-ṣébà àti Ùráyà. Ọlọ́run bá Dáfídì wí, ó sì tún jìyà àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (2 Sám. 11:4, 15, 27; 12:9-14; Aísá. 38:17) Àmọ́, Ọlọ́run ò máa fojú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn wo Dáfídì títí ayé. (Ka 2 Kíróníkà 7:17, 18.) Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun, tó bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, kì í tún rántí rẹ̀ mọ́.—Ìsík. 18:21, 22.
18, 19. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú májẹ̀mú tuntun lórí ọ̀rọ̀ dídáríjini?
18 Nítorí náà, májẹ̀mú tuntun jẹ́ ká mọ apá kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò, yálà àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú yẹn ni o tàbí àwọn tí wọ́n nírètí pé àwọn máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé tí Jèhófà bá ti lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, ibi tọ́rọ̀ náà parí sí pátápátá nìyẹn. Nítorí náà, gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe nínú májẹ̀mú tuntun. Wá bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, kí n má sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti sọ pé mo dárí rẹ̀ ji àwọn èèyàn?’ (Mát. 6:14, 15) Bí èyí ṣe kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké ló kan ẹ̀ṣẹ̀ ńlá bíi kí ọkọ tàbí aya Kristẹni kan ṣe panṣágà. Tí ẹni tí aya rẹ̀ tàbí ọkọ rẹ̀ ṣe panṣágà bá pinnu láti dárí jì í torí pé ó ronú pìwà dà, ǹjẹ́ ohun tó tọ́ kọ́ ni pé kó má ṣe ‘rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́’? Lóòótọ́ kì í ṣe nǹkan tó rọrùn láti ju ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn ṣẹ̀ wá sẹ́yìn, ká sì gbàgbé rẹ̀, àmọ́ ìyẹn jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà.a
19 Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ lórí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tuntun yìí tiẹ̀ tún kan ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, àmọ́ tó ronú pìwà dà tí wọ́n sì gbà á pa dà. Ká ní onítọ̀hún ti mú wa pàdánù nǹkan kan tàbí ó ti bà wá lórúkọ jẹ́ lọ́nà kan ṣáá ńkọ́? Ní báyìí tí wọ́n ti wá gbà á pa dà sínú ìjọ, ipa wo ló yẹ kí ohun tá a kà nínú Jeremáyà 31:34 ní lórí èrò wa sí onítọ̀hún àti bí a ó ṣe máa ṣe sí i? Ǹjẹ́ a máa dárí jì í, ká má sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ wá náà mọ́? (2 Kọ́r. 2:6-8) Ká sòótọ́, ohun tó yẹ kí gbogbo ẹni tó bá mọyì májẹ̀mú tuntun gbìyànjú gan-an láti máa ṣe nígbèésí ayé wọn nìyẹn o.
Báwo la ṣe lè fi ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú májẹ̀mú tuntun nípa dídáríjini sílò?
ÀWỌN ÌBÙKÚN MÁJẸ̀MÚ TUNTUN NÍSINSÌNYÍ ÀTI NÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ
20. Ọ̀nà wo ni ìwà tìrẹ gbà yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà?
20 Nígbà ayé Jeremáyà, ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù dọ́gbọ́n ń sọ pé: “Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.” (Sef. 1:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ Jèhófà, wọ́n sì mọ irú ẹni tó jẹ́ déwọ̀n àyè kan, síbẹ̀ wọ́n lérò pé ṣe lá kàn fọwọ́ lẹ́rán máa wò wọ́n láìní ṣe ohunkóhun; pé kò kúkú bìkítà nípa ohun yòówù táwọn bá ń ṣe. Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, o mọ̀ pé kò sóhun téèyàn lè ṣe láṣegbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà, o bẹ̀rù Ọlọ́run, o ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó burú. (Jer. 16:17) O sì tún mọ̀ pé Baba onínúure ni Jèhófà. Gbogbo rere tá a ń ṣe ló ń kíyè sí, yálà àwọn èèyàn rí i tàbí wọn ò rí i.—2 Kíró. 16:9.
21, 22. Báwo ló ṣe jẹ́ pé kò tún sídìí láti máa sọ fún ọ pé: “Mọ Jèhófà”?
21 Apá pàtàkì kan nínú májẹ̀mú tuntun ni ohun tí Ọlọ́run sọ, pé: “Èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, . . . Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí.” (Jer. 31:33, 34) Lóde òní, àwọn ẹni àmì òróró ti fi hàn pé òfin Ọlọ́run wà lọ́kàn àwọn. Dípò tí wọ́n á fi máa tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ àtọwọ́dá ọmọ èèyàn, ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú òfin Ọlọ́run ni wọ́n fẹ́ràn. Wọ́n sì ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n mọ̀ kọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tayọ̀tayọ̀. Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí, tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, sì wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ Jèhófà wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Wọ́n ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé o wà lára àwọn tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. O mọ Jèhófà dáadáa, o sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Àǹfààní ńlá gbáà lo ní yìí o!
22 Àwọn nǹkan wo lo ti ṣe láti mú kí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i? Ó dájú pé wàá rántí ọ̀pọ̀ ìgbà tíwọ alára gbà pé Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ. Ìrírí wọ̀nyẹn jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì irú Ọlọ́run tó jẹ́. O lè ti rí i kedere pé òun ló jẹ́ kó o rántí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó mú kó o lè fara da ìṣòro kan tó o ní. Jẹ́ kí irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ máa wà lọ́kàn rẹ. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i ni wàá túbọ̀ máa mọ̀ ọ́n sí i, èyí sì jẹ́ àǹfààní kan tá a ń jẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a ó sì máa jẹ ẹ́ nìṣó.
23. Tó o bá mọ Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dárí rẹ̀ jì ọ́?
23 Ṣùgbọ́n, ìbùkún kan tún wà nínú májẹ̀mú tuntun tá a lè rí gbà nísinsìnyí. Mímọ̀ pé Jèhófà máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá lọ́lá májẹ̀mú tuntun máa jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn tó lè máa bá wa ṣáá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n ti ṣẹ́yún rí kó tó di pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run lè máa kẹ́dùn ṣáá tàbí kí ìdààmú ọkàn máa bá wọn nítorí pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀mí ọmọ tuntun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà bọ̀ légbodò. Àwọn míì náà sì máa ń kẹ́dùn bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n ti pààyàn rí nígbà tí wọ́n ń jagun. Àmọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, èyí tó jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì fún májẹ̀mú tuntun, gbogbo àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn máa ń rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ǹjẹ́ kò wá yẹ kó dá wa lójú pé tí Jèhófà bá fi lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ó ti gbà pé ọ̀ràn náà ti tán pátápátá nìyẹn? Nítorí náà, kò sídìí láti máa dààmú ara wa lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí rẹ̀ jì wá pátápátá.
24. Ìtùnú wo lo lè rí gbà látinú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jeremáyà 31:20?
24 A rí ẹ̀rí tó hàn gbangba pé Ọlọ́run máa ń dárí jini gan-an nínú Jeremáyà 31:20. (Kà á.) Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà ayé Jeremáyà, Jèhófà fìyà jẹ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì, tó wà ní àríwá (èyí tí Éfúráímù tí í ṣe ẹ̀yà tó gbajúmọ̀ níbẹ̀ dúró fún) nítorí pé wọ́n ń bọ̀rìṣà. Wọ́n sì wá dèrò ìgbèkùn. Síbẹ̀ Ọlọ́run kò ta àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yẹn nù, ńṣe ló yọ́nú sí wọn. Ojú “ọmọ tí a hùwà sí lọ́nà ìfẹ́ni” ló ṣì fi ń wò wọ́n. Tó bá ti ronú kàn wọ́n ṣe ni ìfun rẹ̀ máa ń “ru gùdù,” tó túmọ̀ sí pé góńgó ẹ̀mí rẹ̀ lọ̀rọ̀ wọn wà. Bí ọ̀rọ̀ wọn yìí ṣe jẹ yọ láàárín ọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú tuntun, jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe máa ń fi ìyọ́nú dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá.
25. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ṣètò májẹ̀mú tuntun?
25 Òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa lo májẹ̀mú tuntun láti fi dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yóò tó ṣẹ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Nígbà yẹn, Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó le ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ àlùfáà lábẹ́ rẹ̀ yóò ti mú kí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin dẹni pípé. Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn, aráyé yóò di ara ìdílé Jèhófà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo àwọn tó ń sìn ín láyé àtọ̀run. (Ka Róòmù 8:19-22.) Àtayébáyé ni gbogbo ìran èèyàn ti ń kérora lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ṣùgbọ́n nígbà yẹn, ẹ̀dá èèyàn yóò ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run,” tí wọ́n á bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nítorí náà, mọ̀ dájú pé wàá jàǹfààní rẹpẹtẹ nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun tí Ọlọ́run fìfẹ́ gbé kalẹ̀ yìí. Wàá sì jàǹfààní nísinsìnyí àti títí láé nípasẹ̀ “èéhù” Dáfídì, wàá sì tún gbádùn ‘òdodo ní ilẹ̀ náà.’—Jer. 33:15.
Báwo lo ṣe lè jàǹfààní májẹ̀mú tuntun nísinsìnyí àti lọ́jọ́ ọ̀la?
a A rí àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe ṣe tán láti dárí jini látinú bí Hóséà ṣe dárí ji Gómérì. Wo àlàyé tá a ṣe lórí ìwé Hóséà 2:14-16 nínú ìwé Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn, ojú ìwé 128 sí 130.