KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ BÍBÉLÌ WÚLÒ FÚN WA LÓNÌÍ
Àwọn Ìlànà Tó Bá Ìgbà Mu, Tó Sì Wúlò Fún Gbogbo Èèyàn—Ìfẹ́
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:14.
ÈRÈ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Ìfẹ́ tí Bíbélì sábà máa ń mẹ́nu kàn kì í ṣe ìfẹ́ lọ́kọláya. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà Ọlọ́run. Irú ìfẹ́ yìí ló máa ń mú kéèyàn ní àwọn ìwà bí ìyọ́nú, ìdáríjì, ìrẹ̀lẹ̀, ìdúróṣinṣin, inúure, ìwà tútù àti sùúrù. (Míkà 6:8; Kólósè 3:12, 13) Ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àtobìnrin nígbà míì lè jẹ́ ìfẹ́ oréfèé tí kì í tọ́jọ́. Àmọ́, ìfẹ́ tá à ń sọ yìí ò rí bẹ́ẹ̀, ó jinlẹ̀ gan-an, kì í sì í ṣá.
Brenda tó ti pé ọgbọ̀n [30] ọdún tó ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó kì í tó ìfẹ́ tó máa wà láàárín wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jọ gbé pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.”
Sam, tó ti lé ní ọdún méjìlá [12] to ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Ó máa ń ya èmi àti ìyàwó mi lẹ́nu láti rí bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe gbéṣẹ́ tó àti bó ṣe rọrùn tó! Bó o bá ń fi sílò, nǹkan á lọ geerege. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ni mo máa ń fi sílò. Èyí sábà máa ń wáyé nígbà tára bá ń kan mí tàbí tó jẹ́ pé tara mi nìkan ni mò ń rò tàbí tó rẹ̀ mí. Láwọn àkókò bẹ́ẹ, ńṣe ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ yìí. Lẹ́yìn tí mo ba gbàdúrà, màá dì mọ́ ìyàwó mi, ńṣe lá wá dà bíi pé nǹkan ò ṣẹlẹ̀ rárá!”
“A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀”
Jésù sọ pé, “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn torí pé gbogbo ọgbọ́n gidi tá a nílò ló wà nínú Bíbélì. Àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà inú rẹ̀ gbéṣẹ́, ó sì bágbà mu. Kò sí ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè tí kò wúlò fún. Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwa èèyàn tó fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, ìyẹn ọba tó ju ẹ̀dá lọ, ló ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Àmọ́, ó dìgbà tẹ́nì kan bá fi ohun tó wà níbẹ̀ sílò kó tó lè wúlò fún un. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” (Sáàmù 34:8) Ǹjẹ́ o ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀?