Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan tó jẹ́ oníyàwó púpọ̀ tó sì máa ń ṣàtakò sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pinnu láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló mú kí pásítọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Pentecostal kan yí ohun tó gbà gbọ́ pa dà? Kí ló mú kí obìnrin kan tó ní ìṣòro nígbà èwe rẹ̀ borí ìkórìíra tó ní fún ara rẹ̀ tó sì sún mọ́ Ọlọ́run? Kí ló mú kí ọkùnrin kan tó fẹ́ràn orin onílù kíkankíkan di ẹni tó ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.
“Mo ti wá di ọkọ rere.”—RIGOBERT HOUETO
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1941
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BENIN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍYÀWÓ PÚPỌ̀, MO TÚN Ń ṢÀTAKÒ SÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọmọ ìlú Kútọnu ni mí, ìlú ńlá ni ìlú yìí ní orílẹ̀-èdè Benin. Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n fi kọ́ mi dàgbà, àmọ́ mi ò kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà ládùúgbò mi ni wọ́n jẹ́ oníyàwó púpọ̀, nítorí pé òfin ìjọba kò kà á léèwọ̀ nígbà yẹn. Ní èmi náà bá fẹ́ ìyàwó mẹ́rin.
Láwọn ọdún 1970 sí 1979, nígbà tí wọ́n ń ṣe àyípadà nínú ọ̀ràn ìṣèlú, mo ronú pé ìyẹn máa ṣe orílẹ̀-èdè mi láǹfààní. Mo fi taratara ṣàtìlẹ́yìn fún àyípadà náà, mo sì dara pọ̀ mọ́ ètò ìṣèlú. Àwọn tó ń ṣe àyípadà náà kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá, nítorí pé wọn kò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Mo wà lára àwọn tó ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí wọ́n lé àwọn míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nílùú lọ́dún 1976, mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti rí i pé wọn kò pa dà mọ́.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tó di ọdún 1990, àyípadà nínú ọ̀ràn ìṣèlú parí. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé, kò pẹ́ tí àwọn míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún fi pa dà dé. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn èèyàn yìí. Àmọ́ lákòókò yẹn, mo ti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbòmíì. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan lára àwọn ẹni tuntun tá a jọ ń ṣiṣẹ́, kò sì pẹ́ tó dé tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. Ó fi àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti onídàájọ́ òdodo hàn mí. (Diutarónómì 32:4; 1 Jòhánù 4:8) Àwọn ànímọ̀ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo fẹ́ láti mọ sí i nípa Jèhófà, nítorí náà, mo gbà kó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìfẹ́ tòótọ́ tí wọ́n ní fún ara wọn wú mi lórí gan-an, kò sí ẹ̀mí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tàbí ẹ̀yà kan ga ju ọ̀kan lọ láàárín wọn. Bí mo ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló túbọ̀ ń dá mi lójú pé, àwọn gan-an ni ọmọlẹ́yìn Jésù.—Jòhánù 13:35.
Mo pinnu pé, tí mo bá fẹ́ sin Jèhófà, mo ní láti fi Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sílẹ̀. Kò rọrùn rárá láti ṣe èyí, nítorí pé ẹ̀rù ń bà mí pé, kí làwọn èèyàn á máa sọ. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo lo ìgboyà, mo sì kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì.
Àmọ́, àyípadà pàtàkì kan tún wà tí mo ní láti ṣe. Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ pé, Ọlọ́run kò fọwọ́ sí níní ìyàwó tó ju ẹyọ kan lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24; Mátíù 19:4-6) Lójú Ọlọ́run, ìyàwó tí mo kọ́kọ́ fẹ́ ni ìyàwó mi. Nítorí náà, àwa méjèèjì lọ forúkọ ìgbéyàwó wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, mo sì ní kí àwọn ìyàwó yòókù máa lọ, àmọ́ mo fún wọn láwọn nǹkan tí wọ́n máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, méjì lára àwọn ìyàwó mi tẹ́lẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìyàwó mi kò fi ẹ̀sìn Kátólíìkì sílẹ̀, síbẹ̀ kò dí mi lọ́wọ́ sísin Jèhófà. Èmi àti ìyàwó mi gbà pé mo ti di ọkọ rere.
Èrò mi nígbà kan ni pé, mo lè tipasẹ̀ òṣèlú mú kí nǹkan dẹrùn fún àwọn èèyàn tó wà lágbègbè mi, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá náà já sí. Ó ti wá yé mi báyìí pé, Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro èèyàn. (Mátíù 6:9, 10) Mo dúpẹ́ pé Jèhófà fi hàn mí bí mo ṣe lè gbé ìgbésí ayé aláyọ̀.
“Kò rọrùn láti ṣe àwọn àyípadà pàtàkì.”—ALEX LEMOS SILVA
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1977
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BRAZIL
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: PÁSÍTỌ̀ ṢỌ́Ọ̀ṢÌ PENTECOSTAL
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àgbègbè kan tí kò jìn sí ìlú Itu, ní ìpínlẹ̀ São Paulo ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Wọ́n mọ àgbègbè yìí dáadáa nítorí ìwà ọ̀daràn tó wọ́pọ̀ níbẹ̀.
Mo máa ń hùwà ipá gan-an, mo sì máa ń ṣèṣekúṣe. Bákan náà, mo tún máa ń gbé oògùn olóró lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Nígbà tó yá, mo rí i pé, tí mo bá ń bá a nìṣó báyìí, ẹ̀wọ̀n tàbí ikú àìtọ́jọ́ ló máa yọrí sí fún mi, nítorí náà, mo jáwọ́. Lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Pentecostal, nígbà tó sì yá, mo di pásítọ̀.
Mo gbà pé mo lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì. Mo tiẹ̀ máa ń ṣe ètò kan lórí rédíò àdúgbò, ètò náà jẹ́ ti ẹ̀sìn, èyí sì mú káwọn èèyàn mọ̀ mí lágbègbè náà. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ṣọ́ọ̀ṣì náà kò ní ire àwọn èèyàn wọn lọ́kàn, wọn kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ ka Ọlọ́run pàápàá sí. Mo wá gbà pé, ìfẹ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì náà ni pé kí wọ́n kàn kówó jọ. Nítorí náà, mo pinnu láti kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lójú ẹsẹ̀ ni mo rí i pé ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn yòókù. Ohun méjì kan wà tó wú mi lórí gan-an nínú ọ̀rọ̀ wọn. Àkọ́kọ́ ni pé, yàtọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò rẹ̀, wọ́n tún ń ṣe ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀. Èkejì ni pé, wọn kì í lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú tàbí ogun. (Aísáyà 2:4) Nǹkan méjì yìí jẹ́ kí n gbà pé mo ti rí ẹ̀sìn tòótọ́, ìyẹn ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 7:13, 14.
Mo wá rí i pé, tí mo bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, mo ní láti ṣe àwọn àyípadà pàtàkì kan. Mo ní láti túbọ̀ wá àyè gbọ́ ti ìyàwó àtàwọn ọmọ mi. Mo tún ní láti túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Kò rọrùn láti ṣe àwọn àyípadà pàtàkì náà, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo ṣe àṣeyọrí. Inú ìyàwó mi dùn láti rí àyípadà tí mo ṣe yìí. Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣáájú mi, àmọ́ ó túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Kò pẹ́ tí àwa méjèèjì fi gbà pé a fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọjọ́ kan náà la ṣe ìrìbọmi.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Èmi àti ìyàwó mi ti láǹfààní láti ran àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ìdílé aláyọ̀ ni wá. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà pè mí láti wá mọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì ń yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà lóòtọ́! Ó ti yí ìgbésí ayé mi pa dà.
“Mo mọ́ tónítóní, mo sì ń gbádùn ìgbésí ayé mi.”—VICTORIA TONG
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1957
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO NÍ ÌṢÒRO NÍGBÀ ÈWE MI
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Newcastle tó wà ní ìpínlẹ̀ New South Wales ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Ọmọ méje làwọn òbí mi bí, bàbá mi jẹ́ oníwà ipá, ó sì máa ń mu ọtí púpọ̀, màmá mi náà máa ń hùwà ipá, èmi sì ni àkọ́bí wọn. Màmá mi máa ń lù mí nílùkulù, ó sì tún máa ń bú mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti sọ fún mi pé, mi ò dáa, inú iná ọ̀run àpáàdì ni mo sì máa lọ. Ohun tó fi ń halẹ̀ mọ́ mi yìí máa ń bà mí lẹ́rù gan-an.
Lọ́pọ̀ ìgbà, mi ò kì í lè lọ síléèwé nítorí àpá tí màmá mi dá sí mi lára nígbà tó bá lù mí. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá, ìjọba mú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí mi, wọ́n sì ń bójú tó mi, lẹ́yìn náà wọ́n mú mi lọ sí ilé àwọn onísìn. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo sá kúrò nílé àwọn onísìn náà. Mi ò fẹ́ pa dà sí ilé wa, nítorí náà, mò ń sùn ní ìta ní òpópónà Kings Cross, lágbègbè ìlú Sydney.
Bí mo ṣe ń sùn ní ìta yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mò ń mu ọtí àmujù, mò ń wo àwòrán oníhòòhò, mo sì tún ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ mú kí ẹ̀rù bà mí gan-an. Lákòókò náà, mò ń gbé nínú ọ̀kan lára yàrá ilé ọkùnrin kan tó ní ilé ìgbafẹ́ alaalẹ́. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin méjì wá sọ́dọ̀ ọkùnrin yìí. Ó ní kí n lọ sí inú yàrá, àmọ́ mò ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Ẹni tó ni ilé ìgbafẹ́ náà ń ṣètò láti tà mí fún àwọn ọkùnrin méjì náà. Wọ́n á wá tọ́jú mi pa mọ́ sínú ọkọ̀ òkun akẹ́rù tó ń lọ́ sí ìlú Japan kí n lè máa lọ báwọn ṣiṣẹ́ nílé ọtí. Ẹ̀rù bà mí gan-an, ni mo bá fò látorí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà kan sílẹ̀, mo sì sá lọ.
Mo rí ọkùnrin kan tó wá sí ìlú Sydney, mo sì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà fún un, kó bàa lè fún mi lówó díẹ̀ kan. Àmọ́ kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ní kí n ká lọ sí ibi tí òun dé sí, kí n lè wẹ̀ kí n sì jẹun. Ohun tó wá yọrí sí ni pé, mi ò kúrò níbẹ̀ mọ́. Ọdún kan lẹ́yìn náà, àwa méjèèjì ṣègbéyàwó.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, oríṣiríṣi èrò ló wá sí mi lọ́kàn. Inú bí mi gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé Sátánì ló ń fa ìwà ibi, nítorí pé ohun tí wọ́n kọ́ mi tẹ́lẹ̀ ni pé Ọlọ́run ló ń jẹ́ ká máa jìyà. Ara tù mí pẹ̀sẹ̀ nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í fi ìyà jẹ àwọn èèyàn nínú iná ọ̀run àpáàdì, ó ti pẹ́ gan-an tí ẹ̀kọ́ yìí ti máa ń dẹ́rù bà mí.
Inú mi dùn láti rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jẹ́ kí Bíbélì darí wọn nínú gbogbo ìpinnu tí wọ́n bá ń ṣe. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń wàásù, wọ́n tún ń ṣe ohun tí wọn ń kọ́ àwọn èèyàn. Mo jẹ́ èèyàn kan tó ṣòro láti bá da nǹkan pọ̀, àmọ́ láìka ohun tí mo bá sọ tàbí ṣe sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún mi wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ mi.
Ohun tó wá jẹ́ ìdààmú ọkàn mi báyìí ni, èrò tí mo ní pé mi ò jámọ́ nǹkan kan. Mo kórìíra ara mi gan-an, àní èrò yìí ṣì wà bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí mo ti ṣe ìrìbọmi tí mo sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ èrò mi ni pé kò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé.
Àmọ́ nǹkan yí pa dà lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí mo ti ṣe ìrìbọmi. Lọ́jọ́ kan tí ẹnì kan ń sọ àsọyé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹni yìí tọ́ka sí ìwé Jákọ́bù 1:23, 24. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé dígí tí èèyàn lè fi wo ara rẹ̀ lọ́nà tí Jèhófà ń gbà wò ó. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara mi pé, ṣé ohun tí mò ń rí pé mo jẹ́ yàtọ̀ sí nǹkan tí Jèhófà rí ni? Mi ò kọ́kọ́ fara mọ́ òye tuntun tí mo ní nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí. Èrò mi ṣì ni pé, Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ mi.
Lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, mo ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ìyẹn ìwé Aísáyà 1:18, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa. . . . Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀, pé: “Vicky, ó yá, jẹ́ ká yanjú ọ̀ràn yìí láàárín ara wa. Mo mọ̀ ẹ́, mo mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.”
Mi ò lè sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Mo sì ń ṣiyè méjì pé, Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ mi, àmọ́ mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ẹbọ ìràpadà Jésù. Ó wá yé mi pé, ó ti pẹ́ gan-an tí Jèhófà ti ń ṣe sùúrù fún mi, tó ń fi ìfẹ́ hàn sí mi ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Síbẹ̀, ohun tí mò ń sọ fún Ọlọ́run ni pé: “Ìfẹ́ tí o fi hàn kò tó láti ṣàǹfààní fún mi. Ikú ìrúbọ tí Ọmọ rẹ kú, kò tó láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀.” Ńṣe ló dà bíi pé, mo ń sọ fún Jèhófà pé ìràpadà náà kò wúlò fún mi. Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí ẹ̀bùn ìràpadà yìí, mo wá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, mo mọ́ tónítóní, mo sì ń gbádùn ìgbésí ayé mi. Àárín èmi àti ọkọ mi ti túbọ̀ dára, inú mi sì dùn pé mo lè lo ìrírí mi láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Mo sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà gan-an.
“Èyí ni ìdáhùn sí àdúrà mi.”—SERGEY BOTANKIN
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: RỌ́ṢÍÀ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO FẸ́RÀN ORIN ONÍLÙ KÍKANKÍKAN
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Votkinsk, ni wọ́n ti bí mi, ibẹ̀ náà sì ni wọ́n ti bí ọ̀gbẹ́ni Pyotr Ilich Tchaikovsky tó jẹ́ gbajúgbajà olórin. Tálákà làwọn òbí mi. Bàbá mi ní àwọn ìwà tó dáa, àmọ́ ó máa ń mu ọtí púpọ̀, nítorí náà, wàhálà sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé wa.
Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé dáadáa, bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé mi ò jámọ́ nǹkan kan, mi ò sì lè ṣe dáadáa bíi tàwọn ẹgbẹ́ mi. Èyí kò jẹ́ kí n lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, mi ò sì fọkàn tán àwọn èèyàn mọ́. Mi ò kì í gbádùn ilé ìwé tí mò ń lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n bá ní kí n sọ̀rọ̀, mi ò kì í sábà lè ṣàlàyé àwọn nǹkan pàtàkì tí mo lè ṣàlàyé tó bá jẹ́ pé ìgbà míì ni wọ́n ní kí n wá ṣàlàyé. Nígbà tí mo fẹ́ ti kíláàsì kan bọ́ sí òmíràn lákòókò tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ohun tí wọ́n kọ sínú èsì ìdánwò mi ni pé: “Kò mọ ọ̀rọ̀ tó yẹ kó lò, kò mọ bó ṣe lè ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn bà mí nínú jẹ́, ó tún mú kí n túbọ̀ wo ara mi pé mi ò jámọ́ nǹkan kan. Èyí mú kí n máa ronú pé ìgbésí ayé mi kò lójú.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí. Ọtí mímu kọ́kọ́ mú kí ara tù mí. Àmọ́ tí mo bá ti mu ọtí púpọ̀, ẹ̀rí ọkàn mi máa ń dà mí láàmú. Ìgbésí ayé mi wá dojú rú. Ẹ̀dùn ọkàn wá bá mi, àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni mi ò fi ní kúrò nílé títí ilẹ̀ fi máa ṣú. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú láti pa ara mi.
Nígbà tí mo pé ọmọ ogún ọdún, mo rí ohun kan tó máa mú ìtura bá mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ orin onílù kíkankíkan. Orin yìí máa ń múnú mi dùn, mo sì wá àwọn èèyàn míì tí wọ́n máa ń gbọ́ orin náà rí. Mo fi irun mi sílẹ̀ kí ó lè gùn, mo dá etí mi lu, mo sì ń múra bí àwọn olórin tí mo fẹ́ràn. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀mí mi wewu, mo sì di oníjàgídíjàgan, mo tún sábà máa ń bá àwọn ará ilé mi jiyàn.
Èrò mi ni pé, gbígbọ́ orin onílù kíkankíkan máa jẹ́ kí n láyọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Mo wá yàtọ̀ pátápátá! Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan tí kò dáa nípa àwọn gbajúgbajà olórin tí mò ń wo àwòkọ́ṣe wọn, inú mi bà jẹ́ gan-an.
Ni mo bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an láti pa ara mi. Ohun kan tó ń dá mi dúró ni, bí ọ̀ràn náà ṣe máa rí lára màmá mi. Ó fẹ́ràn mi gan-an, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún mi. Ipò náà wá túbọ̀ tojú sú mi. Kò wù mí láti máa wà láàyè, àmọ́ mi ò lè gbẹ̀mí ara mi.
Kí n bàa lè mú èrò yìí kúrò lọ́kàn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé olókìkí ti àwọn ará Rọ́ṣíà. Ìwé kan wà tí akọni inú rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì. Kò pẹ́ tí èmi náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ láti ṣe nǹkan fún Ọlọ́run àti láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Mo fi gbogbo ọkàn mi gbàdúrà sí Ọlọ́run, mi ò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Mo bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa. Nígbà tí mò ń gbàdúrà náà lọ́wọ́, ara tù mí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà ló túbọ̀ mú kí ẹnu yà mí. Ní wákàtí méjì lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá kanlẹ̀kùn yàrá mi, ó sì ní òun fẹ́ láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo gbà pé èyí ni ìdáhùn sí àdúrà mi. Ọjọ́ yẹn ni ìgbà ọ̀tun bẹ̀rẹ̀ ní ìgbésí ayé mi.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, mo kó gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ orin onílù kíkankíkan tí mo ní dà nù. Síbẹ̀, orin náà ṣì wà lágbárí mi fún àkókò pípẹ́. Nígbàkigbà tí mo bá rìn kọjá níbi tí wọ́n ti ń gbọ́ irú àwọn orin yìí, ojú ẹsẹ̀ ni mo máa ń rántí ìgbésí ayé tí mo gbé sẹ́yìn. Mi ò fẹ́ máa rántí ìgbésí ayé jákujàku tí mo gbé sẹ́yìn, mi ò sì fẹ́ kó dà pọ̀ mọ́ àwọn nǹkan rere tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi ní báyìí. Ìdí nìyẹn tí mi ò kì í fi í kọjá mọ́ láwọn ibi tí wọ́n ti ń gbọ́ irú àwọn orin bẹ́ẹ̀. Nígbàkigbà tí mo bá sì fẹ́ máa rántí àwọn ohun tí mo ti ṣe sẹ́yìn, ńṣe ni mo máa ń gbàdúrà gan-an. Èyí ti mú kí n ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:7.
Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, mo rí i pé, ó yẹ káwọn Kristẹni sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. (Mátíù 28:19, 20) Èrò mi ni pé mi ò lè ṣe ìyẹn láé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ohun tí mò ń kọ́ ń fún mi ní ayọ̀ àti àlàáfíà ọkàn tó pọ̀. Mo mọ̀ pé ó yẹ káwọn míì náà mọ̀ nípa òtítọ́ yìí. Láìka ẹ̀rù tó ń bà mí sí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí mò ń kọ́ fún àwọn èèyàn. Sí ìyàlẹ́nu mi, ńṣe ni mo túbọ̀ ń ní ìgboyà bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn. Ó tún jẹ́ kí àwọn ohun tuntun tí mò ń kọ́ yìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ lọ́kàn mi.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mo ti ṣe ìgbéyàwó báyìí, mo sì ti láǹfààní láti kọ́ àwọn èèyàn títí kan àbúrò mi obìnrin àti màmá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jíjọ́sìn Ọlọ́run àti ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run ti mú kí ìgbésí ayé mi dára gan-an.