Bíbélì Ní Ìmísí Ọlọ́run Lóòótọ́
KÍ NI àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Bíbélì “ni imísi Ọlọrun”? (2 Tímótì 3:16 Bibeli Mimọ) Ní olówuuru, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí túmọ̀ sí “Ọlọ́run mí èémí sí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí àwọn tó kọ Bíbélì láti kọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n kọ.
Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn tó kọ Bíbélì ń “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fi pe àwọn ìwé Bíbélì ní “ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tímótì 3:15.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọ̀ jálẹ̀ pé Bíbélì kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Àwọn alárìíwísí ti gbógun ti Bíbélì pé kò jóòótọ́. Alàgbà Charles Marston tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wọn, ó ní “wọ́n rín Bíbélì fín gan-an débi tí wọn ò fi ka àwọn ìtàn inú rẹ̀ sí.” Àwọn kan sọ pé Bíbélì kò ju “ògbólógbòó àkójọ ìtàn àlọ́ àti àròsọ” lásán lọ.
Gbé Ẹ̀rí Rẹ̀ Yẹ̀ Wò
Torí náà, ṣé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn tó tọ̀nà nípa ọ̀ràn yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún aráyé wà. Ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ téèyàn bá pa ọ̀rọ̀ náà tì, téèyàn ò sì fiyè sí i, ó lè ṣekú pani pàápàá. Tó o bá ń wo Bíbélì bí ọ̀rọ̀ èèyàn dípò kó o máa wò ó bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò ní fi bẹ́ẹ̀ máa tọ́ ẹ sọ́nà nínú ohun tó o bá ń ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní lè gbé ìgbàgbọ́ rẹ ró bó ṣe yẹ.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Báwo lo ṣe lè fọkàn tán Bíbélì? Tóò, báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fọkàn tán ẹnì kan tó o bá pàdé? Ohun kan tó dájú ni pé, ó ṣòro láti fọkàn tán ẹni tí o kò mọ̀ dáadáa. Bó o bá ṣe ń mọ àwọn èèyàn kan dáadáa ni wàá mọ̀ bóyá wọ́n jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tó ṣeé fọkàn tán. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí tó o bá fẹ́ mọ Bíbélì kó o sì fọkàn tán an. Má kàn gba èrò àwọn ẹlẹ́tanú tàbí ìméfò tó ń ta ko Bíbélì. Torí náà, fara bálẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí tó ti Bíbélì lẹ́yìn pé ó ‘ní ìmísí Ọlọ́run.’
Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ Gbéjà Kò Ó
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ bà jẹ́ pé àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ Bíbélì sọ pé Bíbélì kò jóòótọ́, pé kò sì ṣeé fọkàn tán. Lónìí, bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì tiẹ̀ pe ara wọn ní Kristẹni, ohun tí wọ́n ń sọ nípa Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìyẹn New Dictionary of Theology ṣe sọ, ni pé “Ìwé Mímọ́ jẹ́ àkọsílẹ̀ tó tọwọ́ èèyàn wá.”
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ló sọ pé àwọn tí wọ́n kọ ìwé inú Bíbélì kọ́ ló kọ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé wòlíì Aísáyà kọ́ ló kọ ìwé Aísáyà. Wọ́n sọ pé lẹ́yìn ìgbà ayé Aísáyà ni wọ́n kọ ọ́. Ìwé alálàyé Bíbélì, ìyẹn Concise Bible Commentary, látọwọ́ Lowther Clarke sọ pé, “ọ̀pọ̀ èèyàn àti ọ̀pọ̀ ìran èèyàn” ló kọ ìwé Aísáyà. Àmọ́ ṣá o, irú ọ̀rọ̀ tó ń kóni ṣìnà bẹ́ẹ̀ ta ko ohun tí Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ léraléra pé Aísáyà ló kọ ìwé náà.—Mátíù 3:3; 15:7; Lúùkù 4:17; Jòhánù 12:38-41; Róòmù 9:27, 29.
Èyí tó burú jù ni ọ̀rọ̀ táwọn alárìíwísí Bíbélì sọ bí irú èyí tí alálàyé tó ń jẹ́ J. R. Dummelow sọ, ó ní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ “ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn àmọ́ tí ẹni tó kọ ìwé náà kọ ọ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí wọ́n sọ yìí tún ta ko àwọn ohun tí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi ṣe ẹ̀rí. Jésù kìlọ̀ nípa ohun tó pè ní “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì.” (Mátíù 24:15) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu fún Kristẹni kan láti gbà pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ yóò lọ́wọ́ sí ẹ̀tàn, pé yóò ti ìtàn kan lẹ́yìn, èyí tí wọ́n kọ bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ ni? Ó dájú pé Jésù kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.
Ǹjẹ́ Ẹni Tó Kọ Ọ́ Tiẹ̀ Ṣe Pàtàkì?
O lè béèrè pé “ǹjẹ́ ẹni tó kọ àwọn ìwé Bíbélì tiẹ̀ ṣe pàtàkì lóòótọ́?” Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe pàtàkì gan-an. Ǹjẹ́ o lè fọkàn tán ìwé kan tí wọ́n ní ó jẹ́ ìwé ìhágún tí ọ̀rẹ́ rẹ kọ kó tó kú, tó bá lọ jẹ́ pé òun kọ́ ló kọ ìwé náà? Ká sọ pé àwọn tó mọ̀ nípa ìwé ìhágún sọ pé ayédèrú ni ìwé náà, pé àwọn kan tí wọ́n ní ohun tó dáa lọ́kàn ló kọ ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn ọ̀rẹ́ rẹ. Ṣé wàá fojú pàtàkì wo ìwé náà? Ṣé wàá fọkàn tán ìwé náà pé ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ ló wà níbẹ̀?
Bí ọ̀ràn ṣe rí ní ti Bíbélì náà nìyẹn. Abájọ tí kò fi nira fún ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni pàápàá láti ṣàìgbọràn sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣòtítọ́, ìṣekúṣe àti àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń bẹnu àtẹ́ lu Bíbélì, tí wọ́n á sì sọ pé, “Ẹn, ṣebí Májẹ̀mú Láéláé ló sọ ìyẹn!” Èyí wá mú kó dà bíi pé ìwé yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò. Èrò wọn yìí sì fi hàn pé wọn ò ka ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pe “Májẹ̀mú Láéláé” ní “ìwé mímọ́” tó ‘ní ìmísí Ọlọ́run.’
O lè sọ pé “èèyàn ò kàn lè gbójú fo gbogbo ẹ̀rí táwọn ògbógi onímọ̀ àtàwọn ọ̀mọ̀wé mú wá.” Bẹ́ẹ̀ ni! Bí àpẹẹrẹ, a dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olóòótọ́ ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ inú Bíbélì. Ó ṣe kedere pé àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yọ́ wọnú àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bí wọ́n ti ń ṣàdàkọ Bíbélì léraléra láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá. Àmọ́ rántí pé kéèyàn mọ̀ pé àwọn àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yọ́ wọnú àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yàtọ̀ gan-an sí kéèyàn pa Bíbélì tì lódindi pé ìwé awúrúju kan látọwọ́ èèyàn ni.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú “Ìwé Mímọ́” Yẹ̀
Kí Pọ́ọ̀lù tó sọ pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì, ó sọ fún Tímótì ìdí tí irú àkọsílẹ̀ onímìísí bẹ́ẹ̀ fi ṣe pàtàkì. Ó ní, “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, . . . àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:1, 13) Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù làwọn tó dà bí “ọlọ́gbọ́n àtàwọn ọ̀mọ̀ràn” ti ń lo “àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà” láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà kí wọ́n sì sọ ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Kristi di ahẹrẹpẹ. (1 Kọ́ríńtì 1:18, 19; Kólósè 2:4, 8) Kí wọ́n má bàa kó èèràn ran Tímótì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì ‘láti máa bá a lọ nínú ohun tó ti kọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló nínú ìwé mímọ́’ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—2 Tímótì 3:14, 15.
Ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ náà máa ṣe ohun kan náà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí. Má ṣe fojú kéré ewu tó wà nínú “àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà” táwọn ọlọ́gbọ́nféfé máa ń ṣe láti kóni ṣìnà. Kàkà bẹ́ẹ̀, dáàbò bo ara rẹ bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kó o gbára lé ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi hàn ẹ́ bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe wúlò, tó sì ṣeé fọkàn tán jálẹ̀ ìtàn ìran èèyàn àti bó ṣe máa ń sọ ohun tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu nígbà tó bá sọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì. Wọ́n á tún fi hàn ẹ́ bí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe bára mu látòkèdélẹ̀, bí àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe ṣẹ láìkù síbì kan àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan míì tó wà nínú rẹ̀. Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí láti gba ìsọfúnni tó ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti rí i pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóòótọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o fọkàn tán ẹnì kan tó o bá pàdé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olóòótọ́ ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ inú Bíbélì