Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
KÍ NI ọkùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Scotland rí i pé ó ṣàǹfààní fíìfíì ju okòwò tó búrẹ́kẹ lọ? Kí ló ran ọkùnrin kan tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil lọ́wọ́ tó fi jáwọ́ nínú ìgbésí ayé oníwà pálapàla tó ń gbé àti nínú mímu kokéènì? Báwo ni ọkùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Slovenia ṣe jáwọ́ nínú mímu ọtí ní àmuyíràá? Ka ohun táwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ní láti sọ.
“Mo ronú pé mò ń gbádùn ìgbé ayé mi.”—JOHN RICKETTS
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1958
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: SCOTLAND
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍṢÒWÒ TÓ RÍ TAJÉ ṢE
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ilé ọlá ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Ọ̀gá Ológun ni bàbá mi nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, torí náà, ṣe la máa ń kó kiri. Yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Scotland tá a gbé, a tún gbé ní orílẹ̀-èdè England, Jámánì, Kẹ́ńyà, Malaysia, Ireland àti Kípírọ́sì. Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ ni wọ́n ti fi mí síléèwé tó ní ibùgbé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀-èdè Scotland. Mo wá gboyè jáde ní Yunifásítì Cambridge.
Lọ́mọ ogún ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó máa gbà mí lọ́dún mẹ́jọ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ epo rọ̀bì. Mo kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ yìí láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù, nígbà tó yá mo lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà, lẹ́yìn náà, mo kó lọ sí Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Ọsirélíà. Nígbà tí mo dé ilẹ̀ Ọsirélíà, mo dá ilé iṣẹ́ kan sílẹ̀, àmọ́ mo tà á nígbà tó yá.
Owó tí mo rí nídìí ilé iṣẹ́ tí mo tà náà pọ̀ débi pé mo fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́ ajé lẹ́ni ogójì [40] ọdún. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tí mo ní yìí láti máa fi rìnrìn àjò kiri. Mo ti gun alùpùpù yí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ká ní ẹ̀ẹ̀mejì, mo sì ti rìnrìn àjò yíká gbogbo ayé lẹ́ẹ̀kan. Mo ronú pé mò ń gbádùn ìgbé ayé mi.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Kó tó di pé mo fẹ̀yìn tì, mo ń ronú nípa ọ̀nà tí mo lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún irú ìgbé ayé tí mò ń gbé. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà, táwọn òbí mi ti ń mú mi lọ láti kékeré. Àmọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yẹn ò kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí mo ṣe fẹ́. Ni mo bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbà káwọn ẹlẹ́sìn Mormon máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ṣe ni mo sá kúrò lọ́dọ̀ wọn torí pé wọn ò gbára lé Bíbélì.
Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn mi. Lójú ẹsẹ̀ ni mo ti kíyè sí i pé orí Bíbélì ni wọ́n gbé gbogbo ẹ̀kọ́ wọn kà. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n kà fún mi ni ìwé 1 Tímótì 2:3, 4. Ẹsẹ yẹn sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” Ó wú mi lórí gan-an bí àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ṣe tẹnu mọ́ ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe kéèyàn ṣáà ti ní ìmọ̀ nìkan.
Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n lè nírú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run àti Jésù kì í ṣe Mẹ́talọ́kan tí àwọn kan pè ní àdììtú; kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n. (Jòhánù 14:28; 1 Kọ́ríńtì 11:3) Inú mi dùn gan-an láti kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe kedere yẹn. Ó tún ká mi lára pé mo ti ń fàkókò mi ṣòfò látọdún yìí nídìí bí mo ṣe ń sapá láti lóye ẹ̀kọ́ èké tí kò ṣeé lóye!
Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Orí mi wú gan-an fún bí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe kó èèyàn mọ́ra, tí wọ́n níwà ọmọlúwàbí, tí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bí wọ́n ṣe ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn síra wọn jẹ́ kí n gbà pátápátá lọ́kàn mi pé mo ti rí ìsìn tòótọ́.—Jòhánù 13:35.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, mo rí obìnrin arẹwà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Diane. Inú ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó sì láwọn ìwà tó dáa tó fani mọ́ra gan-an. Nígbà tó yá, a ṣègbéyàwó. Bí èmi àti Diane ṣe mọwọ́ ara wa, tó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú mi jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà lóòótọ́.
O wu èmi àti Diane gan-an láti kó lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù ìhìn rere látinú Bíbélì. Lọ́dún 2010, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Belize, ní Amẹ́ríkà Àárín. Níbi tá a kó lọ yìí, a wàásù fáwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí òùngbẹ ìmọ̀ Bíbélì sì ń gbẹ wọ́n.
Ọkàn mi wá balẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé mo mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí pé mò ń lo àkókò tó pọ̀ láti máa fi wàásù, mo láǹfààní láti máa kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa wo bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń yí ìgbésí ayé ẹnì kan pa dà ò láfiwé, bó ṣe yí ìgbésí ayé tèmi náà pa dà nìyẹn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo wá mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tí mo lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé.
“Wọ́n ṣe dáadáa sí mi gan-an.”—MAURÍCIO ARAÚJO
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1967
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: BRAZIL
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO GBÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ONÍṢEKÚṢE
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Avaré ní ìpínlẹ̀ São Paulo ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbé nílùú náà ló jẹ́ òṣìṣẹ́.
Bàbá mi kú nígbà tí màmá mi ṣì lóyún mi. Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo máa ń wọ aṣọ màmá mi nígbà tí wọ́n bá jáde lọ. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí obìnrin, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fojú ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ wò mí. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọmọdé bíi tèmi àtàwọn tó jù mí lọ.
Nígbà tí màá fi sún mọ́ ọmọ ogún ọdún, mo ti ń wá ẹni tí màá máa bá ní ìbálópọ̀ (ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin) níbikíbi tí mo bá ti lè rí wọn, ì báà jẹ́ nílé ọtí, láwọn ilé fàájì alaalẹ́, kódà ní ṣọ́ọ̀ṣì pàápàá. Ní ìgbà ayẹyẹ ìlú, màá múra bí obìnrin, màá sì máa jó nígbà táwọn ọmọ ilé ijó sáńbà bá ń jó kọjá níwájú àwọn èèyàn. Mo gbajúmọ̀ gan-an.
Àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀, àwọn aṣẹ́wó àtàwọn tó ti sọ oògùn di bárakú làwọn tá a jọ ń ṣọ̀rẹ́. Àwọn kan lára wọn ní kí n mu kokéènì wò, kò sì pẹ́ témi náà fi mọwọ́ ẹ̀ dáadáa. Nígbà míì, a máa ń mu kokéènì mọ́jú. Láwọn ìgbà míì, èmi nìkan á dá wà níbì kan, màá sì lo odindi ọjọ́ kan nìdí kokéènì. Mo wá rù gan-an débi pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ kiri pé mo ti lárùn kògbóògùn, ìyẹn àrùn éèdì.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ṣe dáadáa sí mi gan-an. Ọ̀kan lára ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n kà fún mi ni ìwé Róòmù 10:13, tó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn gbìn ín sí mi lọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì láti máa lo orúkọ Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá ti mu kokéènì ní gbogbo òru, màá ṣí fèrèsé, màá sì wo ojú ọ̀run, màá wá máa gbàdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú omijé lójú, màá máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́.
Ọkàn mi ò balẹ̀ bí mo ṣe ń rí ìyá mi tó máa ń banú jẹ́ ṣáá, bó ṣe ń wò mí, tí mo ń fi àwọn ìmukúmu tí mò ń mu ba ayé ara mi jẹ́, mo wá pinnu pé màá jáwọ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n fi dá mi lójú pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà máa túbọ̀ jẹ́ kí n lè dúró lórí ìpinnu mi láti jáwọ́ nínú mímu kokéènì, ó sì ràn mí lọ́wọ́ lóòótọ́!
Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ, mo rí i pé mo gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé mi. Èyí tó ṣòro fún mi jù lọ ni bí màá ṣe jáwọ́ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin bíi tèmi, torí pé ó ti wọ̀ mí lára gan-an. Àmọ́ ohun kan tó ràn mí lọ́wọ́ ni bí mo ṣe yẹra fáwọn tí wọ́n lè máa nípa búburú lórí mi. Mi ò kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ mọ́, mi ò sì lọ sílé ọtí àti ilé fàájì alaalẹ́ mọ́.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn láti ṣe àwọn àyípadà wọ̀nyẹn, ó tù mí nínú láti mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa mi àti pé kò ṣàì rí i bí mo ṣe ń sapá láti yí pa dà. (1 Jòhánù 3:19, 20) Nígbà tó fi máa di ọdún 2002, mo ti jáwọ́ nínú àṣà bíbá ọkùnrin bíi tèmi lò pọ̀, lọ́dún yẹn náà ni mo sì ṣèrìbọmi, tí mo sì wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Inú màmá mi dùn gan-an fáwọn ìyípadà tí mo ṣe yẹn débi pé òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ó bà mí nínú jẹ́ pé, àìsàn rọpárọsẹ̀ ti ń dà á láàmú tipẹ́tipẹ́. Síbẹ̀ náà, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa mú kí ìfẹ́ tí ó ní fún Jèhófà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sí i.
Ó ti lé lọ́dún mẹ́jọ báyìí tí mo ti ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò mi láti máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òótọ́ kan ni pé láwọn ìgbà míì mo ní láti gbéjà ko àwọn èròkérò tó máa ń wá sọ́kàn mi. Àmọ́, ọkàn mi máa ń balẹ̀ tí mo bá ń rántí pé bí mo ṣe pinnu láti má ṣe tẹ̀ lé èròkerò tó ń wá sí mi lọ́kàn yẹn máa jẹ́ kí n lè múnú Jèhófà dùn.
Bí mo ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, tí mo sì ń gbé ìgbé ayé tó ń múnú rẹ̀ dùn ti jẹ́ kí n túbọ̀ níyì lọ́wọ́ ara mi. Ní báyìí, mo ti di ẹni tó máa ń láyọ̀.
“Òkú ọ̀mùtí ni mí.”—LUKA ŠUC
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1975
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: SLOVENIA
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀MÙTÍ PARAKU
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Ljubljana, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Slovenia ni wọ́n ti bí mi. Mò ń gbádùn ìgbà kékeré mi títí dìgbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rin. Ìgbà yẹn ni bàbá mi ṣekú pa ara rẹ̀. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yẹn, màmá mi ní láti máa ṣiṣẹ́ kára láti bọ́ àwa ọmọkùnrin làǹtì lanti méjì, ìyẹn èmi àti ẹ̀gbọ́n mi.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], mo kó lọ sọ́dọ̀ ìyá-ìyá mi. Inú mi dùn láti máa gbé lọ́dọ̀ rẹ̀, torí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ń gbé ládùúgbò náà. Àyè tún gbà mí dáadáa láti máa ṣe ohun tó bá wù mi ju ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ màmá mi. Lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń mutí kiri lópin ọ̀sẹ̀. Mo fi irun mi sílẹ̀ kó gùn dáadáa, mò ń múra bí ọmọọ̀ta, ìgbà tó sì yá mo bẹ̀rẹ̀ sí í mú sìgá, igbó àtàwọn nǹkan míì.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo dán lílo oògùn olóró wò díẹ̀, àmọ́ mo kúkú fọwọ́ mú ọtí mímu, torí pé òun ni mo gbádùn jù lọ. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kọ́ọ̀bù wáìnì díẹ̀ ni mo máa ń mu, àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dẹni tó ń mu ju ìgò ọtí kan lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Mo bá a débi pé mo lè ṣeé kí ẹnikẹ́ni má mọ̀ pé mo ti mutí yó. Lọ́pọ̀ ìgbà, òórùn ọtí táwọn èèyàn bá gbọ́ lẹ́nu mi ni wọ́n á fi mọ̀ pé mo ti mutí. Pẹ̀lú ìyẹn náà, kò sẹ́ni tó máa mọ̀ pé mo ti parí ìgò ọtí bíi mélòó kan, bí mo sì ṣe ń mu wáìnì ni mo màá ń mu bíà àti ògógóró!
Àìmọye ìgbà ló jẹ́ pé èmi ni màá fa àwọn ọ̀rẹ́ mi dìde lẹ́yìn tá a bá ti lọ ilé fàájì alaalẹ́, nígbà tó sì jẹ́ pé ọtí témi mu tó ìlọ́po méjì tiwọn. Lọ́jọ́ kan, mo gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ pé òkú ọ̀mùtí ni mí, èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tó ń buni kù tí wọ́n sábà máa ń lò lórílẹ̀-èdè Slovenia láti fi bú ẹni tó lè mutí ju ẹnikẹ́ni lọ. Ọ̀rọ̀ yẹn dùn mí wọra gan-an.
Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí irú ìgbé ayé tí mò ń gbé. Mo wá ń wo ara mi pé mi ò jámọ́ nǹkan kan. Ó dà bíi pé kò sí nǹkan kan tí mo dáwọ́ lé láyé tó yọrí sí rere.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà yẹn, mo kíyè sí í pé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kíláàsì mi ti yí pa dà, ara ẹ̀ ti balẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Torí pé mo fẹ́ mọ ohun tó mú kó yí pa dà, mo sọ fún pé kó jẹ́ ká lọ síbì kan tí wọ́n ti máa ń ta ìpápánu. Nígbà tá a jọ ń sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ díẹ̀ nínú àwọn ohun tó ti kọ́ fún mi, àmọ́ gbogbo nǹkan tó ń sọ ṣàjèjì sí mi, torí wọn ò fi ẹ̀sìn kankan tọ́ mi dàgbà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì la ojú mi sí ọ̀pọ̀ òtítọ́ tó jinlẹ̀ tó sì múnú mi dùn. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé à ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5) Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé láìpẹ́ Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn ẹni ibi run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò sì fún gbogbo ẹni rere láǹfààní láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè. (Sáàmù 37:29) Ó wù mi gan-an láti wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ìgbésí ayé mi kémi náà lè wà lára àwọn èèyàn rere yẹn.
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló fi mi ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n mọ nǹkan tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ìwà tí wọ́n hù sí mi yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ gidi rárá. Mo wá rí i pé irú àwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń kó ló sún mi dédìí ọtí mímu. Látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ ni wọ́n á ti máa retí pé kí òpin ọ̀sẹ̀ dé kí wọ́n tún lè lọ mutí yó.
Mo já àwọn ọ̀rẹ́ yẹn sílẹ̀, mo sì fi ìbákẹ́gbẹ́ tó ṣeni láǹfààní pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rọ́pò rẹ̀. Bí mo ṣe máa ń wà láàárín wọn jẹ́ ìṣírí ńlá fún mi, torí pé àwọn èèyàn yìí dìídì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Díẹ̀díẹ̀, mo jáwọ́ nínú mímu ọtí ní àmuyíràá.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé kò dìgbà tí mo bá mu ọtí kí n tó lè ni ayọ̀. Mi ò tiẹ̀ mọ ohun tí ì bá ti ṣẹlẹ̀ sí mi ká ní ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀ náà ni mo ṣì ń gbé. Àmọ́, ó dá mi lójú gbangba pé ìgbésí ayé mi ti dára báyìí.
Láti nǹkan bí ọdún méje sẹ́yìn báyìí ni mo ti láǹfààní láti máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Slovenia. Bí mo ṣe mọ Jèhófà, tí mo sì ń sìn ín ti jẹ́ kí ìgbé ayé mi nítumọ̀.