BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ
“Ó wù mí kí n di àlùfáà”
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1957
ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: MẸ́SÍKÒ
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ÀLÙFÁÀ, MO SÌ JẸ́ ONÍNÚ FÙFÙ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:
Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Texcoco ni wọ́n bí mi sí. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn òpópónà tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ eléruku, tí wọ́n sì rí gbágungbàgun. A máà ń rí àwọn tó ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gbé ọjà wá sí ìlú wa láti àwọn abúlé tó wà nítòsí. Tálákà ni ìdílé wa, èmi sì ni ìkeje nínú àwa ọmọ mẹ́sàn-án. Bàtà ni bàbá mi ń tún ṣe kó lè gbọ́ bùkátà ìdílé wa. Àmọ́ bàbá mi kú nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje. Láti ìgbà yẹn, màmá mi ló ń forí ṣe fọrùn ṣe ká lè rí oúnjẹ jẹ.
Bàbá màmá mi máa ń fi gòjé kọrin, àwọn sì ni olórí ẹgbẹ́ akọrin kan tó mọ orin ìsìn kọ dáadáa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló mọ onírúurú ohun èlò ìkọrin lò. Màmá mi wà nínú ẹgbẹ́ akọrin ṣọ́ọ̀ṣì. Àbúrò màmá mi máa ń fi ìtàn kọ orin, wọ́n sì tún má ń tẹ dùùrù. A ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré nínú ìdílé wa, ọmọ ìdí pẹpẹ ni mí ní ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì wù mí kí n di míṣọ́nnárì nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Mo tún fẹ́ràn kí n máa wo àwọn fíìmù ìjà kàrátè. Bí mo ṣe ń wo àwọn fíìmù yìí, èmi náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ipá.
Mo wọ ilé ẹ̀kọ́ ìsìn kan tó dà bí ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà ní ìlú Puebla. Ohun tó sì wà lórí ẹ̀mí mi ni pé, mo fẹ́ di àlùfáà nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àmọ́ ní ọdún tí mo lò kẹ́yìn ní ilé ìwé yẹn, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ Kátólíìkì bẹ̀rẹ̀ sí í kó mi nírìíra. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé fi ìṣekúṣe lọ̀ mí, àmọ́ mi ò gbà fún un. Ṣe ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wá mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti fẹ́ ìyàwó. Yàtọ̀ síyẹn, mo kíyè sí i pé alágàbàgebè ni àwọn àlùfáà kan. Nígbà tó yá, mo gbọ́kàn mi kúrò lórí pé mo fẹ́ di àlùfáà.
Ọmọ ìdí pẹpẹ ni mí ní ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì wù mí kí n di míṣọ́nnárì nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì. Mo tún fẹ́ràn kí n máa wo àwọn fíìmù ìjà kàrátè, ìyẹn sì jẹ́ kí n di oníwà ipá
Mo wá pinnu pé màá lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ń pè ní National Conservatory of Music ní ìlú Mẹ́síkò. Nígbà tí mo gboyè jáde níbẹ̀, mo ṣègbéyàwó, a sì bí ọmọ mẹ́rin. Mo máa ń kọrin nínú ìjọ Kátólíìkì tí wọ́n bá ń ṣe Máàsì, owó tí mò ń rí níbẹ̀ ni mo fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé mi.
Láti ìgbà tí èmi àti ìyàwó mi ti fẹ́ra ni àárín wa ò ti tòrò. A máa ń bá ara wa jà, ohun tó sì fà á ni pé a máa ń jowú ara wa. Ọ̀rọ̀ burúkú ni a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ sí ara wa, àmọ́ nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í lu ara wa nílùkulù. Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá, àwa méjèèjì pinnu láti pínyà. Lẹ́yìn ìyẹn, a kọ ara wa sílẹ̀.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:
Kí èmi àti ìyàwó mi tó pínyà ni mo ti kọ́kọ́ pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ kan, méjì lára wọn kan ilẹ̀kùn ilé wa, wọ́n ní àwọn fẹ́ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lójú ara mi, mo rò pé kò sí nǹkan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa kọ́ mi nípa ẹ̀sìn, ni mo bá pinnu pé màá já wọn nírọ́. Mo máa ń da àwọn ìbéèrè tó le ti mò rò pé kò ní ìdáhùn bò wọ́n. Ṣùgbọ́n, ó yà mí lẹ́nu pé, kò sígbà tí wọn kì í dá mi lóhùn, ìdáhùn wọn sì máa ń bá Bíbélì mu. Ìgbà yẹn ni èmi fúnra mi wá rí i pé, mi ò tiẹ̀ mọ nǹkan kan. Àmọ́ ìyàwó mi máa ń yájú sí wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ọwọ́ tèmi náà máa ń dí gan-an, bó ṣe di pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ Bíbélì ò wá mọ́ nìyẹn.
Ọdún márùn-ún lẹ́yìn ìyẹn ni mo tó tún pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, mo ti ń gbé pẹ̀lú obìnrin míì. Elvira ni orúkọ rẹ̀. Kì í ṣàtakò sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tiẹ̀, ìyẹn mú kó rọrùn fún mi láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún ló ṣì gbà kí n tó lè yí ìwà mi pa dà.
Mo wá rí i pé tí mo bá fẹ́ sin Jèhófà tọkàntọkàn, mo gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ìyípadà kan nígbèésí ayé mi. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo ní láti fi iṣẹ́ orin tí mo ń kọ ní ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. Ìyẹn wá já sí pé, kí n lọ wá iṣẹ́ míì tí màá fi máa gbọ́ bùkátà ìdílé mi. (Ìṣípayá 18:4) Mo tún gbọ́dọ̀ lọ fìdí ìgbéyàwó èmi àti Elvira múlẹ̀ lábẹ́ òfin.
Ọ̀kan lára ohun tó nira jù fún mi láti ṣe ni bí màá ṣe máa káwọ́ ìbínú mi. Àwọn ẹsẹ méjì kan nínú Bíbélì ló ràn mí lọ́wọ́. Àkọ́kọ́ ni Sáàmù 11:5, tó sọ pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá. Èkejì ni 1 Pétérù 3:7, ìyẹn kọ́ mi pé tí mo bá fẹ́ kí Jèhófà máa gbọ́ àdúrà mi, mo gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìyàwó mi. Bí mo ṣe ń ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, tí mo tún ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kápá ìbínú mi díẹ̀díẹ̀.
Mo kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé, tí mo bá fẹ́ kí Jèhófà máa gbọ́ àdúrà mi, mo gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìyàwó mi
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:
Ní báyìí, èmi àti ìdílé mi ń láyọ̀. Mo ń gbìyànjú láti tún àjọṣe àárín èmi àti àwọn ọmọkùnrin tí ìyàwó mi àkọ́kọ́ bí fún mi ṣe. Mo sì tún ń sapá kí n lè ran Elvira àti àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ó wù mí kí n di àlùfáà, kí n sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Àmọ́, ìsinsìnyí gan-an ni mo lè sọ pé mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe nǹkan gidi. Ní báyìí, mo ń kọ́ àwọn èèyàn ní iṣẹ́ orin, iṣẹ́ yìí ni mo sì fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà mú sùúrù fún mi, kí n lè yí pa dà, kí ìwà mi sì dára sí i!