Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
KÍ NÌDÍ tí obìnrin kan tó ti lé ní ẹni ọgọ́ta [60] ọdún fi jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà? Kí ló mú kí àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó kan fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ojúbọ, tó sì wá di òjíṣẹ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni? Báwo ni obìnrin kan tí wọ́n gbà ṣọmọ láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ṣe borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní pé wọ́n pa òun tì? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.
“Mi ò kì í ṣe ẹrú òrìṣà mọ́.”—ABA DANSOU
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1938
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: BENIN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ABỌ̀RÌṢÀ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Abúlé kan tó ń jẹ́ So-Tchahoué, ni mo ti dàgbà, ó wà nítòsí adágún, ẹrọ̀fọ̀ sì wà lágbègbè yìí. Àwọn ará abúlé yìí máa ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa, wọ́n máa ń sin màlúù, ewúrẹ́, àgùntàn, ẹlẹ́dẹ̀ àtàwọn nǹkan abìyẹ́. Kò sí ọ̀nà orí ilẹ̀ téèyàn lè gbà lágbègbè yìí, nítorí náà, ọkọ̀ ojú omi làwọn èèyàn máa ń wọ̀ káàkiri. Igi àti koríko ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé wọn, àmọ́ àwọn kan wà tí wọ́n fi bíríkì kọ́ tiwọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ibẹ̀ ló jẹ́ òtòṣì. Àmọ́, ìwà ọ̀daràn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀ bíi ti àwọn ìlú ńlá.
Nígbà tí mo wà ní kékeré, bàbá mi ní kí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ sí ilé òrìṣà kan tó wà ládùúgbò wa, níbi tí wọ́n ti mú wa wọnú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ náà. Nígbà tí mo dàgbà, mo sọ Dudua (ìyẹn Oduduwa) tó wá látinú àṣà ìbílẹ̀ àwọn Yorùbá di òrìṣà tí mò ń bọ. Mo kọ́lé fún òrìṣà yìí, mo sì ń fi iṣu, epo pupa, ìgbín, adìyẹ, àdàbà àti onírúurú ẹranko rúbọ sí i déédéé. Owó kékeré kọ́ ni mò ń ná sórí àwọn ìrúbọ yìí, mo sì máa ń fẹ́rẹ̀ ná gbogbo owó tó ń wọlé fún mi sórí rẹ̀.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé, kò fẹ́ ká máa lo ère nínú ìjọsìn wa. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Kọ́ríńtì 10:14) Mo wá mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Nítorí náà, mo kó gbogbo ère mi dà nù, mo sì kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà kúrò nílé mi. Mi ò lọ sọ́dọ̀ àwọn baba aláwo mọ́, mi ò sì bá wọn lọ́wọ́ sí ètùtù ìlú àti ètùtù ìgbà ìsìnkú mọ́.
Nítorí pé mo ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún, kò rọrùn fún mi láti ṣe àwọn àyípadà yìí. Àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí àtàwọn aládùúgbò ta kò mí, wọ́n sì fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 18:10, tù mí nínú gan-an, ó ní: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.”
Lílọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ohun míì tó ràn mí lọ́wọ́. Níbẹ̀, mo rí ìfẹ́ tó yẹ kó wà láàárín àwọn Kristẹni, inú mi sì dùn gan-an nítorí pé ìlànà Bíbélì làwọn èèyàn yìí ń tẹ̀ lé ní ìgbésí ayé wọn. Ohun tí mo rí jẹ́ kí n gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Bí mo ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. Yàtọ̀ sì ìyẹn, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù ńlá kan kúrò lọ́rùn mi. Nígbà kan, mo máa ń ná owó mi sórí àwọn ère tí kò lẹ́mìí tí wọ́n kò lè ṣe àǹfààní kankan fún mi. Àmọ́ ní báyìí, mò ń jọ́sìn Jèhófà ẹni tó máa mú àwọn ìṣòro wá kúrò títí láé. (Ìṣípayá 21:3, 4) Mo láyọ̀ pé, mi ò kì í ṣe ẹrú òrìṣà mọ́, àmọ́ dípò ìyẹn, mo jẹ́ ẹrú Jèhófà! Òun ni ààbò mi.
“Láti kékeré ni mo ti fẹ́ mọ Ọlọ́run.”—SHINJI SATO
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1951
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JAPAN
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÀLÙFÁÀ Ẹ̀SÌN ṢINTÓ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àgbègbè Fukuoka ni mo dàgbà sí. Àwọn òbí mi fẹ́ràn ẹ̀sìn gan-an, láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ mi pé kí n máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run Ṣintó. Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo sábà máa ń ronú nípa bí màá ṣe rí ìgbàlà, ó sì wù mí gan-an láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà nínú ìṣòro. Mo rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí mo ṣì wà ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, lọ́jọ́ kan olùkọ́ wa ní ká sọ ohun tá a fẹ́ ṣe tá a bá dàgbà. Àwọn ọmọ kíláàsì mi ń sọ oríṣiríṣi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, àwọn kan sọ pé àwọn fẹ́ di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Àmọ́ èmi sọ pé mo fẹ́ láti sin Ọlọ́run. Gbogbo wọ́n fi mí rẹ́rìn-ín.
Nígbà tí mo jáde ilé ìwé girama, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ láti di olùkọ́ ìsìn. Lákòókò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, mo pàdé àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó kan tó máa ń lo àkókò tọ́wọ́ rẹ̀ dilẹ̀ láti ka ìwé kan tí ẹ̀yìn rẹ̀ dúdú. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin yìí béèrè lọ́wọ́ mi, ó ní, “Sato, ǹjẹ́ o mọ ìwé yìí?” Mo ti kíyè sí èèpo ẹ̀yìn ìwé náà, nítorí náà, mo dá a lóhùn pé, “Bíbélì” ni. Ó wá sọ pé, “Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ di àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó ló yẹ kó ka ìwé yìí.”
Lójú ẹsẹ̀, mo lọ ra Bíbélì kan. Mo fi Bíbélì náà sí ibi téèyàn ti lè tètè rí i níbi tí mò ń kówèé sí, mo sì ń bójú tó o dáadáa. Àmọ́, mi ò wá àyè láti kà á rárá, nítorí pé iṣẹ́ ilé ìwé jẹ́ kọ́wọ́ mi dí gan-an. Nígbà tí mo parí ilé ìwé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ojúbọ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó. Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ ohun tó wù mí láti kékeré nìyẹn.
Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi wá rí i pé, ohun tí mo rò pé jíjẹ́ àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó máa jẹ́ kọ́ ló jẹ́. Ọ̀pọ̀ àlùfáà ẹ̀sìn yìí ni kò nífẹ̀ẹ́ tàbí bìkítà fún àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò tiẹ̀ ní ìgbàgbọ́. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá mi tiẹ̀ sọ fún mi pé: “Tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí níbí yìí, ọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n orí nìkan ní kó o máa sọ. Kò sáyè fún ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ níbí yìí ó.”
Ohun tó sọ yìí mú kí ẹ̀sìn Ṣintó tojú sú mi. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mò ń bá iṣẹ́ mi nìṣó ní ojúbọ náà, àmọ́ mò ń ṣèwádìí àwọn ẹ̀sìn yòókù. Síbẹ̀, kò sí èyí tó sàn lára wọn. Bí mo ṣe ń ṣèwádìí àwọn ẹ̀sìn lọ́kan kò jọ kan, bẹ́ẹ̀ náà ni nǹkan túbọ̀ ń tojú sú mi. Èyí mú kí n rò pé kò sí òtítọ́ nínú ẹ̀sìn kankan.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́dún 1988, mo pàdé ẹlẹ́sìn Búdà kan tó gbà mí níyànjú pé kí n ka Bíbélì. Èyí mú kí n rántí àlùfáà ẹ̀sìn Ṣintó tí mo pàdé lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, tí òun náà ní kí n ka Bíbélì. Mo gbà láti ṣe ohun tí wọ́n sọ yìí. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, kò pẹ́ rárá tí mo fi nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì kíkà gan-an. Ìgbà míì wà tí mo máa ń kà á láti alẹ́ títí di ìgbà tí ilẹ̀ fi máa mọ́.
Ohun tí mo kà mú kí n fẹ́ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run tó ni Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ tó wà nínú ìwé Mátíù 6:9-13. Mo máa ń gba àdúrà yìí ní àgbà-tún-gbà ní wákàtí méjìméjì, mo ń gba àdúrà yìí pàápàá nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ní ojúbọ Ṣintó.
Mo ní ìbéèrè tó pọ̀ lórí ohun tí mò ń kà. Lákòókò tí mò ń sọ yìí, mo ti fẹ́ ìyàwó, mó sì mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí pé wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ìyàwó mi rí. Mo wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà tí mo rí ọ̀kan lára wọn, ńṣe ni mo da ìbéèrè bò ó. Orí mi wú nígbà tí Obìnrin náà fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi. Ó ṣètò pé kí ọkùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tètè mọ̀ pé, àwọn tí mo ti hùwà àìlọ́wọ̀ sí nígbà kan rí wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìpàdé náà. Àmọ́, wọ́n kí mi tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n sì gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀.
Mo kẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé náà pé, Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì bọlá fún wọn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tèmi kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, iṣẹ́ àlùfáà tí mò ń ṣe ni mo gbájú mọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n pa ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa méjèèjì tì. Mo wá rí i pé, àwọn èèyàn tó wá jọ́sìn ní ojúbọ ni mó máa ń fetí sí dáadáa tí wọ́n bá ń bá mi sọ̀rọ̀, àmọ́ mi ò tíì fìgbà kan rí fetí sí ohun tí ìyàwó mi fẹ́ sọ.
Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nìṣó, mo kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, àwọn nǹkan náà sì mú kí n sún mọ́ ọn. Àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Róòmù 10:13, máa ń wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Láti kékeré ni mo ti fẹ́ mọ Ọlọ́run, àmọ́ ní báyìí, mo ti wá mọ̀ ọ́n!
Mo wá rí i pé, èrò mi ti yàtọ̀ sí táwọn tó wà ní ojúbọ náà. Lákọ̀ọ́kọ́, mo ní ìdààmú ọkàn lórí ohun táwọn èèyàn máa rò tí mo bá kúrò nínú ẹ̀sìn Ṣintó. Àmọ́, ó ti pẹ́ tí mo ti máa ń sọ fún ara mi pé, màá kúrò tó bá jẹ́ pé inú ẹ̀sìn míì ni wọ́n ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Nítorí náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1989, mo ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn mi sọ. Mo kúrò ní ojúbọ náà, mo sì fi ara mi fún Jèhófà.
Kò rọrùn rárá láti kúrò ní ojúbọ náà. Àwọn tó jẹ́ ọ̀gá mi fìbínú sọ̀rọ̀ sí mi, wọ́n sì fẹ́ fi ipá mú mi kí n lè dúró. Àmọ́ èyí tó wá le gan-an ni bí mo ṣe máa sọ èrò mi fún àwọn òbí mi. Lójú ọ̀nà, nígbà tí mò ń lọ sí ilé àwọn òbí mi, àníyàn gbà mí lọ́kàn débi pé ńṣe ni ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n nílẹ̀! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo dúró lójú ọ̀nà tí mò ń gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi lókun.
Nígbà tí mo délé àwọn òbí mi, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí láti sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn. Ọ̀pọ̀ wákàtí kọjá. Àmọ́, lẹ́yìn tí mo ti gbàdúrà-gbàdúrà, mo ṣàlàyé gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún bàbá mi. Mo sọ fún un pé, mo ti mọ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì máa fi ẹ̀sìn Ṣintó sílẹ̀ kí n bàa lè sin Ọlọ́run tòótọ́. Ọ̀rọ̀ yẹn bá bàbá mi lójijì, inú rẹ̀ sì bà jẹ́. Àwọn ẹbí wa yòókù wá sí ilé wa, wọ́n sì ń gbìyànjú láti yí mi lérò pa dà. Mi ò fẹ́ ṣe ohun tó máa dun àwọn èèyàn mi, àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, mo mọ̀ pé jíjọ́sìn Jèhófà ni ohun tó tọ́. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn mi wá bọ̀wọ̀ fún mi nítorí ìpinnu tí mo ṣe yẹn.
Òótọ́ ni pé mi ò lọ sí ojúbọ mọ́, àmọ́ mo ní láti mú ọkàn mi kúrò nínú ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà ti di ara fún mi. Mo sapá gan-an láti mú ọkàn kúrò níbẹ̀, àmọ́ ó jọ pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń rántí iṣẹ́ náà.
Ohun méjì ló ràn mí lọ́wọ́ láti mú èrò yìí kúrò lọ́kàn. Àkọ́kọ́ ni pé, mo wá inú ilé mi dáadáa, mo sì kó gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ jọ. Lẹ́yìn náà, mo dáná sun wọ́n, ìyẹn àwọn ìwé, àwòrán, títí kan àwọn ohun ìrántí olówó iyebíye tí mo ní lọ́wọ́. Ìkejì ni pé, mo lo gbogbo àǹfààní tí mo ní láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì tì mí lẹ́yìn, èyí ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Díẹ̀díẹ̀ ni mo mọ́kàn kúrò nínu àwọn nǹkan tí mò ń ṣe nínú ẹ̀sìn Ṣintó.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ mo pa ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi tì, èyí sì mú kí wọ́n dánìkan wà. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò pẹ̀lú wọn, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ pé káwọn ọkọ máa ṣe, àárín wa túbọ̀ gún régé. Nígbà tó yá, ìyàwó mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú mi. Èmi àti ìyàwó mi, ọmọkùnrin wa àti ọmọbìnrin wa pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ la jọ ń ṣe ìjọsìn tòótọ́.
Nígbà tí mo ronú nípa ohun tó wù mí ní kékeré pé, mó fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run, mo sì fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, mo rí i pé ọwọ́ mi ti tẹ ohun tó wù mí, àtèyí tó jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà fún oore tó ṣe fún mi.
“Lọ́kàn mi, mo mọ̀ pé ohun kan wà tí mo ṣaláìní.”—LYNETTE HOUGHTING
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1958
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: SOUTH AFRICA
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO NÍ Ẹ̀DÙN ỌKÀN PÉ WỌ́N PA MÍ TÌ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Germiston ni wọ́n ti bí mi, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ ló ń gbé ibẹ̀, wọ́n máa ń wa kùsà níbẹ̀, ìwà ọ̀daràn kò pọ̀ ní ìlú yìí. Èrò àwọn òbí mi ni pé, àwọn kò ní lè tọ́jú mi, nítorí náà wọ́n pinnu pé àwọn á gbé mi fún ẹni tó máa gbà mí ṣọmọ. Láti ọmọ ọjọ́ mẹ́rìnlá, ni tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ti gbà mí ṣọmọ, àwọn ni mo sì kà sí bàbá àti ìyá mi. Àmọ́, nígbà tí mo mọ bí mo ṣe jẹ́ gan-an, mo ní ẹ̀dùn ọkàn pé wọ́n pa mí tì. Mo wá rí i pé mi ò kì í ṣe ọmọ àwọn tó gbà mí ṣọmọ, mo sì ní èrò pé wọn kò lóye mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ilé ọtí, èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń jó nígbà tí àwọn olórin bá ń kọrin níbẹ̀. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá. Mo fẹ́ kí n rí tẹ́ẹ́rẹ́ bíi ti àwọn tí mo máa ń rí nínú ìpolówó sìgá. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ìlú Johannesburg, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹgbẹ́ búburú rìn. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo èdè rírùn, tí mò ń mu sìgá gan-an, tí mo sì máa ń mu ọtí púpọ̀ ní òpin ọ̀sẹ̀.
Síbẹ̀ náà, ara mi le. Mo máa ń gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ti àwọn obìnrin, mo sì máa ń ṣe àwọn eré ìdárayá míì. Mo tún ń ṣiṣẹ́ kára káwọn èèyàn lè mọ̀ mí dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ mi nílé iṣẹ́ kọ̀ǹpútà. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún mi láti ní owó lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn sì kà mí sí ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ ti mú òkè. Àmọ́, inú mi kò dùn rárá, ìgbésí ayé mi sì tojú sú mi. Lọ́kàn mi, mo mọ̀ pé ohun kan wà tí mo ṣaláìní.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé, ó fi ìfẹ́ yìí hàn sí wa nípa fífún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ńṣe ló dà bíi pé ó kọ lẹ́tà kan sí wa láti tọ́ wa sọ́nà ní ìgbésí ayé wa. (Aísáyà 48:17, 18) Mo rí i pé, tí mo bá fẹ́ jàǹfààní ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ń fúnni, mo ní láti ṣe àwọn àyípadà pàtàkì kan ní ìgbésí ayé mi.
Ohun kan tí mo ní láti ṣàtúnṣe sí ni àwọn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́. Mo ronú lórí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 13:20, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Ìlànà yìí mú kí n fi àwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń bá rìn nígbà kan sílẹ̀, mo sì yan àwọn ọ̀rẹ́ míì láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ìṣòro ńlá tí mo ní láti borí ni bí mo ṣe máa fi sìgá sílẹ̀, àṣà burúkú yìí ti mọ́ mi lára gan-an. Bí mo ṣe ń borí ìṣòro yìí díẹ̀díẹ̀ ni ìṣòro míì tún yọjú. Sìgá tí mo fi sílẹ̀ mú kí n sanra sí i, ìwọ̀n mi sì fi nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́rìnlá (13.6 kg) lé sí i! Èyí kò jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ sí ìrísí mi, ó sì gbà mí ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá kí n tó lè já ìwọ̀n tó lé sí i náà dà nù. Àmọ́, mo mọ̀ pé ó tọ́ bí mo ṣe fi sìgá sílẹ̀. Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, ó sì fún mi ní okun láti ṣàṣeyọrí.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, ara mi túbọ̀ le sí i. Mo tún ní ìtẹ́lọ́rùn, ìyẹn ni pé mi ò lépa ayọ̀ tí kì í tọ́jọ́, èyí tí iṣẹ́ ajé, ipò àti ọrọ̀ máa ń mú wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ń fún mi láyọ̀. Àbájáde èyí ni pé, mẹ́ta lára àwọn obìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ló ti dara pọ̀ mọ́ èmi àti ọkọ mi nínú ìjọsìn Jèhófà. Kí àwọn òbí mi tó gbà mí ṣọmọ tó kú, mo láǹfààní láti bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde sí Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Bíbélì sọ.
Sísún mọ́ Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn pé wọ́n pa mí tì. Jèhófà ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti jẹ́ ẹni iyì, bó ṣe mú kí n wà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ ìdílé kan tó wà kárí ayé. Mo ní bàbá, màmá àti ẹ̀gbọ́n àti àbúrò tó pọ̀ láàárín wọn.—Máàkù 10:29, 30.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Mo rí ìfẹ́ tó yẹ kó wà láàárín àwọn Kristẹni láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ojúbọ Ṣintó níbi tí mo ti ń jọ́sìn tẹ́lẹ̀