Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Lẹ́yìn Ìkún Omi, Nóà rán ẹyẹ àdàbà kan jáde látinú ọkọ̀ áàkì, ẹyẹ náà sì mú “ewé ólífì” padà wá. Ibo ni ẹyẹ àdàbà náà ti rí ewé náà?
Bíbélì sọ fún wa pé “omi náà sì kún bo ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo òkè ńlá gíga lábẹ́ gbogbo ọ̀run fi wá di èyí tí a bò mọ́lẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:19) Nígbà tí ìkún omi náà fà, Nóà rán àdàbà kan jáde nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan síra wọn. Nígbà kejì, àdàbà náà padà wá, “ewé ólífì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ já wà ní àgógó rẹ̀, Nóà sì tipa bẹ́ẹ̀ wá mọ̀ pé omi náà ti fà kúrò ní ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 8:8-11.
Lóòótọ́, kò sí bá a ṣe lè mọ ibi tí omi náà gbòòrò dé lórí ilẹ́ ayé nísinsìnyí, nítorí pé Ìkún Omi náà ti yí ojú ilẹ̀ ayé padà. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé omi náà bo ibi tó pọ̀ jù lọ láyé fún àkókò pípẹ́ tí ọ̀pọ̀ igi fi kú. Síbẹ̀, ó jọ bíi pé àwọn igi kan wà lábẹ́ omi láìkú jálẹ̀ àkúnya omi náà, irú àwọn igi yìí ló padà rúwé nígbà tí ìkún omi náà fà.
Ìwé The New Bible Dictionary sọ nípa igi ólífì pé: “Bá a bá gé igi ólífì lulẹ̀, ẹ̀ka tuntun máa ń sọ jáde láti ara gbòǹgbò rẹ̀ débi pé ó máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ka márùn-ún tí ó máa ń sọ jáde. Igi ólífì tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú máa ń sọ lọ́nà yìí.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The New Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge sọ pé: “Ẹ̀mí igi ólífì yi gan-an ni.” Lónìí, kò sẹ́ni tó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ikún omi náà, kó sẹ́ni tó lè sọ bí iyọ̀ ṣe wà nínú ikún omi náà tó tàbí tó mọ ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù rẹ̀. Nítorí náà, a kò lè sọ ipa tí ìkún omi náà yóò ti ní lórí igi ólífì àtàwọn ewéko mìíràn.
Àmọ́ ṣá o, àwọn igi ólífì inú igbó kò lè wà láàyè níbi tó bá tutù gan-an, irú bí orí àwọn òkè ńlá. Ó sábà máa ń hù lórí ilẹ̀ tí kò ga ju ẹgbẹ̀rún kan mítà lọ níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ tutù jù. Ìwé náà The Flood Reconsidered sọ pé: “Látàrí ewé tí a ṣẹ̀sẹ̀ já náà, Nóà lè wá mọ̀ pé ìkún omi tó wà lórí ilẹ̀ tí bẹ̀rẹ̀ sí fà.” Nígbà tí Nóà tún rán àdàbà náà jáde ní ọ̀sẹ̀ kan sí ìgbà yẹn, àdàbà náà kò padà mọ́, èyí tó fi hàn pé àdàbà náà ti rí àwọn igi tó pọ̀ tó, níbi tó ti lè máa gbádùn.—Jẹ́nẹ́sísì 8:12.