Kapadókíà Ibi Tí Wọ́n Ti Fi Àwọn Ihò Tí Ẹ̀fúùfù àti Ọ̀gbàrá Gbẹ́ Sínú Àpáta Ṣelé
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù sọ̀rọ̀ nípa Kapadókíà. Lára àwọn tó kọ lẹ́tà onímìísí rẹ̀ àkọ́kọ́ sí ni “àwọn olùgbé fún ìgbà díẹ̀ tí wọ́n tú ká káàkiri ní . . . Kapadókíà.” (1 Pétérù 1:1) Báwo ni ilẹ̀ Kapadókíà ṣe rí? Kí nìdí táwọn tó wà lágbègbè náà fi ń finú ihò abẹ́ àpáta ṣelé? Báwo ni ìsìn Kristẹni ṣe dé ọ̀dọ̀ wọn?
W. F. Ainsworth, arìnrìn àjò ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó lọ sí àgbègbè Kapadókíà láàárín ọdún 1840 sí 1849 sọ pé: “A ṣàdédé já sí àárín àgbájọ òkòtó àti ọwọ̀n àpáta tó pọ̀ gan-an, a ò sì mọbi tá a wà mọ́.” Títí dòní, ìrísí ilẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ṣì ń ya àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Turkey lẹ́nu. Àwọn òkúta tí wọ́n dà bí ère gbígbẹ́ tò lọ rẹrẹẹrẹ níbi tí wọ́n dúró gbagidi sí láàárín àwọn àfonífojì Kapadókíà. Àwọn kan rí bí ihò tí èéfín máa ń gbà jáde lórí ilé, wọ́n sì fi ohun tó tó ọgbọ̀n mítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ga. Àwọn mìíràn jọ bisikí tó dà bí òkòtó tí wọ́n fi ń mu áísìkirimù, tàbí òpó onígun mẹ́rin tàbí olú, tó rí gìrìwò.
Oríṣiríṣi aṣọ ẹwà ni oòrùn máa ń dà bo àwọn èrè wọ̀nyí lójoojúmọ́, bó ti ń tàn yòò sí wọn lára! Ní fẹ̀rẹ̀-kílẹ̀-mọ́ wọ́n máa ń láwọ̀ osùn. Ní ọjọ́kanrí àwọ̀ wọn á yí padà, á dà bíi ti eyín erin, tó bá sì dọwọ́ ìrọ̀lẹ́, à jọ àwọ̀ idẹ. Kí ló di “àgbájọ òkòtó àti ọwọ̀n àpáta tó pọ̀ gan-an” yìí? Kí sì nìdí táwọn èèyàn tó wà lẹ́kùn ibẹ̀ fi ń finú àwọn ihò àpáta náà ṣelé?
Ẹ̀fúùfù àti Ọ̀gbàrá Ló Bá Wọn Gbẹ́ Ẹ
Àárín gbùngbùn Anatolia tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po, níbi tí ilẹ̀ Éṣíà àti ilẹ̀ Yúróòpù ti pààlà ni àgbègbè Kapadókíà wà. Òkè títẹ́jú pẹrẹsẹ ni àgbègbè náà ì bá jẹ́ tí kì í bá ṣe tàwọn òkè ayọnáyèéfín tí wọ́n ti bú gbàù níbẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì. Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn òkè ayọnáyèéfín tó bú gbàù ló mú kí oríṣi àpáta méjì wà níbẹ̀, ìyẹn ni àpáta líle, dúdú kirikiri àti èyí tí kò le kongbári. Nígbà tí ohun tó dà bíi pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ tó rọ́ jáde látinú òkè ayọnáyèéfín bá tutù tán ló máa ń di àpáta funfun tí kò le yìí.
Bí odò ṣe ń ya lu àpáta tí ò le kongbári yìí, tí òjò ń rọ́ lé e lórí, tí ẹ̀fúùfù sì ń bì lù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ya, ó sì wá ń di àfonífojì tómi rọ́ dí. Nígbà tó yá, díẹ̀ lára àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tó wà nítòsí àwọn àfonífojì yìí bẹ̀rẹ̀ sí ya díẹ̀díẹ̀, wọ́n di ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọwọ̀n àpáta tó rí bí òkòtó, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbẹ́ àwọn ọwọ̀n tí ò sí níbòmíì mọ́ láyé sí àgbègbè yẹn. Àwọn kan lára àwọn ọwọ̀n àpáta tó rí bí òkòtó yìí jọ afárá oyin gan-an nítorí ihò tó wà nínú wọn. Àwọn tó ń gbé ní àgbègbè náà gbẹ́ yàrá sínú àwọn àpáta tí ò le kongbári náà, wọ́n sì ń yọ àwọn yàrá púpọ̀ sí i bí ìdílé wọn ṣe ń bí sí i. Àwọn ilé wọn yìí máa ń tutù nígbà ẹ̀ẹ̀rùn wọ́n sì máa ń móoru nígbà òtútù.
Bí Ibẹ̀ Ṣe Rí Nígbà Tí Ọ̀làjú Bẹ̀rẹ̀
Àwọn ará Kapadókíà tó ń gbénú àpáta yìí ì bá má mọ̀ nípa àwọn èèyàn míì tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé tí kì í ti ìtẹ̀síwájú tó dé bá ọ̀làjú nígbà ayé wọn. Àgbègbè Kapadókíà ni ọ̀nà tó gbajúmọ̀ náà, tó ń jẹ́ Silk Road gbà kọjá; ọ̀nà tó gùn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ààbọ̀ [6,500] kìlómítà yìí ló so Ilẹ̀ Ọba Róòmù mọ́ ilẹ̀ Ṣáínà, ibẹ̀ sì láwọn oníṣòwò sábà máa ń gbà. Yàtọ̀ sáwọn oníṣòwò tó ń gbabẹ̀, àwọn ọmọ ogun Páṣíà, Gíríìkì àti ti Róòmù tún máa ń gba ọ̀nà yìí. Àwọn arìnrìn àjò yìí mú àwọn èrò ẹ̀sìn tuntun wọlé.
Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa àwọn Júù ti tẹ̀ dó sí Kapadókíà. Àwọn Júù tó wá láti àgbègbè yìí sì wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Wọ́n lọ ṣayẹyẹ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì níbẹ̀. Ìdí nìyí tí àpọ́sítélì Pétérù fi lè wàásù fáwọn Júù tó jẹ́ ará Kapadókíà lẹ́yìn tí ẹ̀mí mímọ́ tú jáde. (Ìṣe 2:1-9) Ó dájú pé àwọn kan lára wọn gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́ wọ́n sì padà sílé tàwọn ti ẹ̀sìn tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìdí nìyí tí Pétérù fi kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kapadókíà nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́.
Àmọ́ ṣá o, bọ́dún ti ń gorí ọdún, àwọn Kristẹni tó wà ní Kapadókíà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí. Kódà àwọn aṣáájú mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ èèkàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì Kapadókíà, tí wọ́n gbáyé ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, fi gbogbo ara ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí ò sí nínú Ìwé Mímọ́ lẹ́yìn. Àwọn mẹ́ta ọ̀hún ni Gregory ti Nazianzus, Basil Ńlá àti àbúrò rẹ̀, Gregory ti Nyssa.
Basil Ńlá tún ní káwọn èèyàn máa gbé ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Àwọn ilé kẹ́jẹ́bú táwọn ara Kapadókíà ń gbé nínú ihò àpáta ṣe wẹ́kú pẹ̀lú irú ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tí Basil Ńlá ní kí wọ́n máa gbé. Báwọn tó ń gbé irú ìgbésí ayé ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ yìí ṣe ń pọ̀ sí i, wọ́n kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sínú àwọn ihò àpáta ńláńlá tó dà bí òkòtó náà. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹtàlá, ó ti tó bí ọ̀ọ́dúnrún ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti gbẹ́ sínú ihò àpáta náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yìí ló ṣì wà títí dòní olónìí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ilé àwọn aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ wọ̀nyí mọ́, báwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí bó ṣe wà látọdúnmọdún. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ihò àpáta náà làwọn èèyàn ṣì ń gbé inú rẹ̀ dòní. Ṣàṣà lẹni tó máa lọ sí Kapadókíà tí ò ní kan sáárá sí báwọn ará ibẹ̀ ṣe fọgbọ́n sọ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá di ilé tó ṣeé gbé.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KAPADÓKÍÀ
ṢÁÍNÀ (Cathay)