ǸJẸ́ O MỌ̀?
Kí nìdí tí Bíbélì fi pe ìlú Nínéfè ìgbàanì ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀”?
Ìlú ńlá ni Nínéfè. Ibẹ̀ ni olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà. Oríṣiríṣi ààfin àwòṣífìlà àti àwọn tẹ́ńpìlì òrìṣà ló wà níbẹ̀. Àwọn òpópónà tó fẹ̀ àti àwọn ògiri gìrìwò-gìrìwò tún wà níbẹ̀. Wòlíì Hébérù kan tó ń jẹ́ Náhúmù pe ìlú yìí ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Náhúmù 3:1.
Àpèjúwe yìí bá Nínéfè mu gẹ́lẹ́, torí àwọn àwòrán ara ògiri tí wọ́n rí ní ààfin ọba Senakéríbù ní Nínéfè jẹ́rìí sí i pé òǹrorò ni àwọn ará Ásíríà. Nínú ọ̀kan lára àwọn àwòrán yẹn, wọ́n ya ẹnì kan tó ń dá ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ lóró, ó lọ́ ahọ́n rẹ̀, ó sì fà á já. Àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri àtàwọn ọ̀rọ̀ ìyangàn tí wọ́n kọ fi hàn pé, wọ́n máa ń lu ihò sí imú tàbí ètè àwọn tí wọ́n bá kó nígbèkùn. Wọ́n á fi ìkọ́ sí ojú ihò yìí, wọ́n á wá so okùn mọ́ ìkọ́ náà, èyí ni wọ́n fi ń fa àwọn ẹrú tí wọ́n bá ń kó wọn lọ. Wọ́n máa ń mú kí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n bá kó nígbèkùn gbé orí àwọn ọba wọn tí wọ́n bẹ́ kọ́ ọrùn, bí ìlẹ̀kẹ̀ abàmì.
Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Archibald Henry Sayce, tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ìtàn Ásíríà ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe hùwà òǹrorò sí àwọn kan tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú wọn. Ó ní: “Wọ́n kó orí èèyàn jọ ní òkìtì òkìtì. Wọ́n sun àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin lóòyẹ̀. Ìwà ìkà míì tí wọ́n tún hù ni pé, wọ́n gún àwọn ọkùnrin pa, wọ́n bó wọn láwọ lóòyẹ̀, wọ́n fọ́ wọn lójú tàbí kí wọ́n gé apá, ẹsẹ̀, etí àti imú wọn.”
Kí nìdí tí àwọn Júù fi máa ń ṣe ìgbátí yí òrùlé ilé wọn ká?
Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn Júù pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ, kí ìwọ má bàa fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ilé rẹ nítorí pé ẹnì kan . . . lè já bọ́ láti orí rẹ̀.” (Diutarónómì 22:8) Ìgbátí tí wọ́n ń ṣe yìí jẹ́ ètò ààbò tó ṣe pàtàkì, torí pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìdílé àwọn Júù máa ń lò sí orí òrùlé ilé wọn dáadáa.
Èyí tó pọ̀ jù nínú ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló máa ń ní òrùlé pẹrẹsẹ. Orí ilé wọn ni wọ́n máa ń lọ tí wọ́n bá fẹ́ yá oòrùn tàbí tí wọ́n bá fẹ́ gbatẹ́gùn tí ooru bá mú lọ́sàn-án tàbí kí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ níbẹ̀. Ibẹ̀ sì tún tura láti sùn sí tó bá di ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. (1 Sámúẹ́lì 9:26) Ẹni tó bá jẹ́ àgbẹ̀ sì lè sá ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ tàbí èso àjàrà tàbí kí ó sá ọkà tó fẹ́ lọ̀ sí orí òrùlé rẹ̀.—Jóṣúà 2:6.
Wọ́n tún máa ń lo orí òrùlé fún ìjọsìn, yálà ìjọsìn Ọlọ́run tàbí ti òrìṣà. (Nehemáyà 8:16-18; Jeremáyà 19:13) Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀sán ọjọ́ kan, àpọ́sítélì Pétérù lọ gbàdúrà lórí òrùlé. (Ìṣe 10:9-16) Tí wọ́n bá fi ọwọ́ igi àjàrà tàbí imọ̀ ọ̀pẹ ṣe àtíbàbà sórí ilé kan, ó máa ń pèsè ibòji tí ó tura.
Ìwé kan tó ń jẹ́ The Land and the Book sọ pé ilé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ní àtẹ̀gùn tàbí àkàbà tí wọ́n lè fi sọ̀ kalẹ̀ láti òrùlé sí “ìta láàárín ọgbà ilé kan.” Torí náà, ẹnì kan lè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òrùlé láì wọ inú ilé rárá. Èyí lè jẹ́ ká lóye ìkìlọ̀ Jésù nípa bó ṣe yẹ kí àwọn èèyàn tètè sá jáde kúrò nínú ìlú kan tí kò ní pẹ́ pa run. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀.”—Mátíù 24:17.