Ta Ni Ábúráhámù?
TÍ A bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tí àwọn èèyàn kárí ayé kà sí àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ẹ̀sìn, ṣàṣà èèyàn ló dà bíi ti Ábúráhámù.a Bí àwọn Júù ṣe kà á sí ẹni ọ̀wọ̀ náà làwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni kà á sí ẹni ọ̀wọ̀. Àwọn èèyàn kan tiẹ̀ sọ pé “wọn kò kóyán rẹ̀ kéré nínú Ìwé Mímọ́ onírúurú ẹ̀sìn,” àti pé “ó jẹ́ àwòkọ́ṣe nínú kéèyàn ní ìgbàgbọ́.” Bíbélì pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 4:11.
Kí nìdí táwọn èèyàn fi ka Ábúráhámù sí ẹni ọ̀wọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí pàtàkì kan ni pé òun nìkan ṣoṣo lẹni tí Bíbélì dìídì pè ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23.
Àmọ́ ṣá o, èèyàn bíi tiwa ni Ábúráhámù. Ọ̀pọ̀ ìṣòro tí a máa ń ní lónìí lòun náà ní, tó sì borí wọn. Ṣé wàá fẹ́ mọ bó ṣe borí àwọn ìṣòro náà? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkùnrin pàtàkì yìí.
Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Rẹ̀
Ọdún 2018 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bí Ábúráhámù, ìlú Úrì ló sì gbé dàgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 11:27-31) Ìlú ńlá ni Úrì, ó sì jẹ́ ìlú ọlọ́rọ̀. Wọ́n máa ń bọ̀rìṣà gan-an níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Térà bàbá Ábúráhámù tiẹ̀ wà lára àwọn tó ń bọ onírúurú òrìṣà níbẹ̀. (Jóṣúà 24:2) Àmọ́, kàkà kí Ábúráhámù máa bá wọn bọ àwọn ère lásánlàsàn tí kò lẹ́mìí, Jèhófàb nìkan ṣoṣo ló ń sìn ní tirẹ̀.
Kí ló jẹ́ kí Ábúráhámù pinnu láti máa sin Jèhófà ní tirẹ̀? Ó ṣẹlẹ̀ pé ó bá Ṣémù ọmọ Nóà láyé, kódà Ṣémù lò tó àádọ́jọ [150] ọdún láyé lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúráhámù. Tó bá jẹ́ pé ó bá bàbá àgbàlagbà yẹn rìn, yóò ti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ lọ́dọ̀ bàbá yẹn. Ábúráhámù lè ti gbọ́ ìtàn látẹnu rẹ̀ ní tààràtà nípa bí wọ́n ṣe la Ìkún-omi tó kárí ayé nígbà yẹn já. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kó tún kọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa sin Jèhófà, Ọlọ́run tó pa Ṣémù àti ìdílé rẹ̀ mọ́ tí wọn kò fi bá Ìkún-omi náà lọ.
Ì báà jẹ́ ọ̀dọ̀ Ṣémù ní Ábúráhámù ti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ibòmíì, ó fi ohun tó kọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ sílò. Bí Jèhófà “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” ṣe wá rí i pé Ábúráhámù jẹ́ ẹni tó máa níwà tó dáa, ó ràn án lọ́wọ́ kó lè di èèyàn àtàtà.—Òwe 17:3; 2 Kíróníkà 16:9.
Bó Ṣe Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀
Ábúráhámù dàgbà, ó darúgbó, ìgbésí ayé rẹ̀ sì lárinrin. Lóòótọ́, ó ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, síbẹ̀ ìgbé ayé rere ló gbé. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i.
▪ Nígbà tí Ábúráhámù wà nílùú Úrì, Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó fi ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kó lọ máa gbé nílẹ̀ òkèèrè kan tóun máa fi hàn án. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù àti Sárà kò mọ ibi pàtó tí wọ́n ń lọ àti ìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé kí wọ́n kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n ṣe bí Ọlọ́run ṣe sọ. Nígbà tó yá, Ábúráhámù àti Sárà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì ń ṣí láti ibì kan lọ síbòmíì níbẹ̀.—Ìṣe 7:2, 3; Hébérù 11:8, 9, 13.
▪ Nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà kò tíì bímọ rárá, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, àti pé gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ ayé yóò rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 11:30; 12:1-3) Jèhófà sì fi dá a lójú lẹ́yìn náà pé òun yóò mú ìlérí yẹn ṣẹ. Ó sọ fún un pé irú-ọmọ rẹ̀ yóò pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.—Jẹ́nẹ́sísì 15:5, 6.
▪ Nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [99] tí Sárà sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé wọn yóò bí ọmọkùnrin kan. Lójú àwa èèyàn, èyí máa dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Ábúráhámù àti Sárà fi rí i pé kò sí ohunkóhun tó “ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà” láti ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 18:14) Ọdún kan lẹ́yìn náà, nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì. (Jẹ́nẹ́sísì 17:21; 21:1-5) Ọlọ́run sì sọ ní pàtó pé nípasẹ̀ Ísákì ni aráyé fi máa rí àwọn ìbùkún ńláǹlà gbà.
▪ Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ohun kan tó yani lẹ́nu. Ó sọ pé kí Ábúráhámù fi Ísákì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rúbọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ísákì kò tíì níyàwó, kò sì tíì bímọ nígbà yẹn.c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa dun Ábúráhámù gan-an pé òun máa pàdánù ọmọ òun nìyẹn, síbẹ̀ ó múra tán láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ. Ó dá Ábúráhámù lójú gan-an pé Ọlọ́run lágbára láti jí Ísákì dìde, tó bá gba pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, láti lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Hébérù 11:19) Bí Ábúráhámù ṣe ní kí òun fi ọmọ yẹn rúbọ, Ọlọ́run dá a dúró, kò jẹ́ kó pa á. Ó yin Ábúráhámù pé ó ṣègbọràn lọ́nà tó ta yọ. Jèhófà sì wá tún àwọn ìlérí rẹ̀ ìṣáájú sọ fún Ábúráhámù.—Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18.
▪ Ábúráhámù kú lẹ́yìn tó ti lo ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] láyé. Bíbélì sọ pé ó “kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an,” àti pé “ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:7, 8) Nípa bẹ́ẹ̀, ìlérí míì tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù pé yóò ní ẹ̀mí gígùn àti pé yóò kú ní àlàáfíà ṣẹ sí i lára.—Jẹ́nẹ́sísì 15:15.
Àpẹẹrẹ Tó Fi Lélẹ̀
Ábúráhámù kì í ṣe ẹni ìtàn lásán tàbí ẹni tó kàn gbé ẹ̀sìn lárugẹ láyé àtijọ́. Títí dòní là ń rántí rẹ̀, àwòkọ́ṣe sì ni ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo wa. (Hébérù 11:8-10, 17-19) Jẹ́ ká wo mẹ́rin lára àwọn ìwà tí Ábúráhámù ní. A ó bẹ̀rẹ̀ látorí ìwà rẹ̀ kan táwọn èèyàn mọ̀ jù, ìyẹn ìgbàgbọ́.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, orúkọ tí Ábúráhámù ń jẹ́ ni Ábúrámù, Sárà sì ń jẹ́ Sáráì. Nígbà tó yá, Ọlọ́run yí orúkọ Ábúrámù pa dà sí Ábúráhámù, tó túmọ̀ sí “baba ogunlọ́gọ̀,” ó sì yí orúkọ Sáráì pa dà sí Sárà, tó túmọ̀ sí “Ìyá Ọba.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:5, 15) Àmọ́ torí kó lè rọrùn, a máa pè wọ́n ní Ábúráhámù àti Sárà nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé yìí.
b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . . Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Sọ Pé Kí Ábúráhámù Fi Ọmọ Rẹ̀ Rúbọ?” lójú ìwé 23 nínú ìwé yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ábúráhámù Ṣe Pàtàkì Nínú Ìtàn Bíbélì
Nínú Bíbélì, ìwé Jẹ́nẹ́sísì fi orí mẹ́wàá àkọ́kọ́ sọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn púpọ̀ tí wọ́n nígbàgbọ́ gan-an, irú bí Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà. Àmọ́, ìtàn ìgbésí ọkùnrin kan ṣoṣo, ìyẹn Ábúráhámù, ló fẹ́rẹ̀ẹ́ gba gbogbo orí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó tẹ̀ lé e.
Yàtọ̀ síyẹn, inú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ti Ábúráhámù ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù nínú Bíbélì ti kọ́kọ́ jẹ yọ. Bí àpẹẹrẹ, inú ìtàn Ábúráhámù ni . . .
▪ Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Apata fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn Ẹni tó ń dáàbò bò wọ́n.—Jẹ́nẹ́sísì 15:1; wo Diutarónómì 33:29; Sáàmù 115:9; Òwe 30:5.
▪ Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa kéèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 15:6.
▪ gbólóhùn náà wòlíì ti kọ́kọ́ jẹ yọ.—Jẹ́nẹ́sísì 20:7.
▪ Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí òbí máa ń ní sí ọmọ.—Jẹ́nẹ́sísì 22:2.