Máa Sin Ọlọ́run Tí Ń sọni Di Òmìnira
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” —1 JÒH. 5:3.
ǸJẸ́ O LÈ DÁHÙN?
Báwo ni Sátánì ṣe ń mú kó dà bíi pé àwọn òfin Ọlọ́run jẹ́ ẹrù ìnira?
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an nípa àwọn tá a bá yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
Kí ló máa mú ká lè máa jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run tó ń fúnni ní òmìnira?
1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo òmìnira, báwo ni ìyẹn sì ṣe fara hàn nínú ọ̀nà tó gbà bá Ádámù àti Éfà lò?
JÈHÓFÀ ni Ẹnì kan ṣoṣo tó ní òmìnira tí kò láàlà. Síbẹ̀, kì í ṣi òmìnira rẹ̀ lò; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fi mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípa pípinnu gbogbo ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ á máa ṣe fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti fún wọn ní òmìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n lo ìdánúṣe kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun rere tí wọ́n bá ní lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ kan ṣoṣo tí ń káni lọ́wọ́ kò ni Ọlọ́run pa fún Ádámù àti Éfà, ìyẹn sì ni èyí tó fi kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́n. 2:17) Èyí tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti máa ṣe ìfẹ́ Ẹlẹ́dàá wọn kí wọ́n sì tún ní òmìnira tó pọ̀ yanturu.
2. Kí nìdí tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ fi pàdánù òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn?
2 Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní òmìnira tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀, ó fún wọn ní ẹ̀rí ọkàn, ó sì nírètí pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wọn á mú kí wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́. (Jẹ́n. 1:27; Róòmù 2:15) Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà kò mọrírì Olùfúnni-ní-Ìyè tó jẹ́ ẹni àgbàyanu yìí àti òmìnira tó fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti fara mọ́ òmìnira tí kò bófin mu tí Sátánì sọ pé wọ́n máa ní, ìyẹn ni pé wọ́n á lè máa hu ìwà tó bá wù wọ́n. Àmọ́, dípò kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní òmìnira tó pọ̀ sí i, ńṣe ni wọ́n ta ara wọn àti àwọn ọmọ tí wọ́n máa bí lọ́jọ́ iwájú sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú àbájáde búburú.—Róòmù 5:12.
3, 4. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń gbìyànjú láti tàn wá jẹ ká má bàa pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́?
3 Bí Sátánì bá lè tan ẹ̀dá èèyàn pípé méjì jẹ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tí ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì, débi tí gbogbo wọn fi kọ Ọlọ́run sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó lè tan àwa pẹ̀lú jẹ. Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tó ń lò kò tíì yí pa dà. Ó ń gbìyànjú láti tàn wá jẹ ká lè máa ronú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run jẹ́ ẹrù ìnira, wọn kì í sì í jẹ́ ká gbádùn ara wa tàbí ká dára yá. (1 Jòh. 5:3) Irú èrò yìí lè ní ipa tó lágbára gan-an lórí ẹni pàápàá tó bá jẹ́ pé lemọ́lemọ́ lèèyàn ń gbà á láyè. Arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24], tó sì ti ṣèṣekúṣe rí sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ní ipa tó pọ̀ lórí mi, pàápàá jù lọ nítorí pé mò ń bẹ̀rù pé kí èrò mi má yàtọ̀ sí ti àwọn ojúgbà mi.” Ó lè ti ṣe ìwọ náà rí pé kó o dà bíi tàwọn ojúgbà rẹ.
4 Ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà míì, àwọn ojúgbà tó ń ní ipa búburú lórí ẹni lè wà nínú ìjọ. Ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Mo ti mọ àwọn ọ̀dọ́ kan táwọn àtàwọn aláìgbàgbọ́ jọ ń fẹ́ra. Àmọ́, mo wá rí i lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé bá a ṣe jọ ń kóra wa kiri, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń dà bí wọ́n ṣe dà. Àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí í yingin. Mi ò gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí mọ́ láwọn ìpàdé ìjọ, agbára káká ni mo sì fi ń lọ sóde ẹ̀rí. Èyí ló jẹ́ kí n rí i pé mo gbọ́dọ̀ já ara mi gbà lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi wọ̀nyí, ohun tí mo sì ṣe nìyẹn!” Ṣó o mọ bó ṣe rọrùn fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó láti mú kó o dà bí wọ́n ṣe dà? Jẹ́ ká jíròrò àpẹẹrẹ inú Bíbélì kan tó bọ́ sákòókò.—Róòmù 15:4.
Ó JÍ ỌKÀN-ÀYÀ WỌN LỌ
5, 6. Báwo ni Ábúsálómù ṣe tan àwọn míì jẹ, ṣé ìwà ẹ̀tàn rẹ̀ sì kẹ́sẹ járí?
5 A lè rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ní ipa búburú lórí àwọn míì nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni Ábúsálómù, tó jẹ́ ọmọ Dáfídì Ọba. Ábúsálómù dára bí egbin. Àmọ́, nígbà tó yá, ó ṣe bíi ti Sátánì nípa jíjẹ́ kí ìwọra mú kó fàyè gba èrò tí kò tọ́ nínú ọkàn rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa gba ipò ọba tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí mọ́ bàbá rẹ̀ lọ́wọ́.a Ábúsálómù bẹ̀rẹ̀ sí í dá ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí kí ipò ọba lè bọ́ sí i lọ́wọ́. Ó ń ṣe bíi pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù jẹ òun lógún, ó sì ń ṣe ohun tó mú kí wọ́n lérò pé ẹnikẹ́ni ò rí tiwọn rò láàfin ọba. Ńṣe lọ̀rọ̀ Ábúsálómù rí gẹ́lẹ́ bíi ti Èṣù nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó ń mú káwọn èèyàn rí òun bí olóore, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ń mú káwọn èèyàn rí bàbá rẹ̀ bí ẹni burúkú.—2 Sám. 15:1-5.
6 Ṣé ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Ábúsálómù kẹ́sẹ járí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kẹ́sẹ járí dé ìwọ̀n àyè kan torí Bíbélì sọ pé: “Ábúsálómù sì ń jí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ.” (2 Sám. 15:6) Àmọ́, ní òpin gbogbo rẹ̀, ìgbéraga Ábúsálómù yọrí sí ìparun rẹ̀. Èyí sì mú kí òun àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó fi ẹ̀tàn mú kàgbákò ikú ẹ̀sín.—2 Sám. 18:7, 14-17.
7. Kí làwọn ohun tá a lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúsálómù? (Wo àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14.)
7 Kí nìdí tó fi rọrùn fún Ábúsálómù láti rí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn tàn jẹ? Ó lè jẹ́ pé àwọn nǹkan tí Ábúsálómù sọ pé òun máa fún wọn ló wọ̀ wọ́n lójú. Tàbí kó jẹ́ pé bó ṣe dáa lọ́mọkùnrin ló mú kí wọ́n gba tiẹ̀. Èyí tó wù kó jẹ́, ohun kan tó dá wa lójú ni pé: Wọn kì í ṣe adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ọba tó yàn sípò. Lónìí, bí Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti jí ọkàn-àyà àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa lo àwọn èèyàn tí wọ́n fìwà jọ Ábúsálómù. Wọ́n lè máa sọ pé ‘àwọn ìlànà Jèhófà ti máa ń káni lọ́wọ́ kò jù.’ Wọ́n tún lè sọ pé, ‘ìwọ náà wo gbogbo àwọn èèyàn tí kò sin Jèhófà. Ńṣe ni wọ́n ń gbádùn ara wọn bí wọ́n ṣe fẹ́!’ Ṣé wàá gbìyànjú láti rí bí irú irọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe jìnnà sóòótọ́ tó kó o sì máa bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Ṣé wàá gbà pé “òfin pípé,” ìyẹn òfin Kristi, tí Jèhófà fi fúnni nìkan ló lè mú kó o ní ojúlówó òmìnira? (Ják. 1:25) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọwọ́ pàtàkì mú òfin yẹn kó o má sì ṣe jẹ́ kí Èṣù tàn ẹ́ láti ṣi òmìnira tí Jèhófà fún ẹ lò.—Ka 1 Pétérù 2:16.
8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ rí tó jẹ́ ká mọ̀ pé ríré àwọn ìlànà Jèhófà kọjá kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀?
8 Àwọn ọ̀dọ́ ni Sátánì sábà máa ń dójú sọ. Arákùnrin kan tó ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún. Ó ní: “Mi ò kí ń wo àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà híhù bí ohun tó ń dáàbò boni, ńṣe ni mo máa ń wò wọ́n bí ohun tó ń káni lọ́wọ́ kò.” Látàrí èyí, ó ṣèṣekúṣe. Síbẹ̀, ìyẹn ò mú kó láyọ̀. Ó sọ pé: “Ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í dá mi lẹ́bi, mo sì kábàámọ̀ ìwà tí mo hù yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Arábìnrin kan tó ṣèṣekúṣe nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Béèyàn bá ṣèṣekúṣe tán, ńṣe lọkàn èèyàn máa ń bà jẹ́, táá sì dà bíi pé èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan. Kódà, lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún [19] mo ṣì máa ń rántí bí ìṣekúṣe náà ṣe wáyé.” Arábìnrin mìíràn sọ pé: “Bí mo bá rántí bí ìwà mi ṣe ba àwọn tí mo kà sí ẹni ààyò lọ́kàn jẹ́ tó, ńṣe ni ìdààmú máa ń bá mi, tí mo máa ń rò pé àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà ti bà jẹ́, tí ọkàn mi sì máa ń dà rú. Ohun burúkú ni pé kéèyàn máa gbé láyé kó má sì gbádùn ojú rere Jèhófà.” Sátánì kò ní fẹ́ kó o ronú pé ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ tó ò ń dá máa já sí nìyẹn.
9. (a) Àwọn ìbéèrè wo ló máa jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò ojú tá a fi ń wo Jèhófà, àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ Ọlọ́run dáadáa?
9 Ẹ wo bó ṣe bani nínú jẹ́ tó pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà nínú ètò Ọlọ́run, tó fi mọ́ àwọn kan tó jẹ́ àgbàlagbà pàápàá, ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó nira pé béèyàn bá jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tán, dandan ni kó jẹ ìyà tó máa ń bá a rìn! (Gál. 6:7, 8) Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ni mo mọ ọgbọ́n ẹ̀tàn tí Sátánì ń lò àti pé ńṣe ni wọ́n máa ń ṣèpalára fúnni? Ṣé mo máa ń wo Jèhófà bí Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tó máa ń sọ òtítọ́ fún mi nígbà gbogbo tó sì fẹ́ ohun tó dára jù lọ fún mi? Ṣó dá mi lójú hán-únhán-ún pé bí ohun kan bá dára ní tòótọ́ tó sì máa mú kí n láyọ̀ gan-an, kò ní fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dù mí láé?’ (Ka Aísáyà 48:17, 18.) Kó o lè fi tọkàntọkàn dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí àwọn ìbéèrè yìí, o gbọ́dọ̀ ní òye tó jinlẹ̀ nípa Jèhófà. O gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dunjú, ó sì gbọ́dọ̀ yé ẹ pé torí pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ ló ṣe fún ẹ ní àwọn òfin àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì, kì í ṣe pé ó fẹ́ láti ká ẹ lọ́wọ́ kò.—Sm. 25:14.
GBÀDÚRÀ PÉ KÍ JÈHÓFÀ FÚN Ẹ NÍ ỌKÀN-ÀYÀ ỌGBỌ́N ÀTI TI ÌGBỌRÀN
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti fìwà jọ Sólómọ́nì Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin?
10 Nígbà tí Sólómọ́nì ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé: “Ọmọdékùnrin kékeré sì ni èmi. Èmi kò mọ bí a ti ń jáde lọ àti bí a ti ń wọlé.” Lẹ́yìn náà ló wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní ọkàn-àyà ọgbọ́n àti ti ìgbọràn. (1 Ọba 3:7-9, 12) Jèhófà ṣe ohun tí Sólómọ́nì béèrè tọkàntọkàn yẹn, ohun tó sì máa ṣe fún ìwọ náà nìyẹn, yálà o jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò ní fún ẹ ní òye àti ọgbọ́n lọ́nà ìyanu, ó máa sọ ẹ́ di ọlọgbọ́n bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ taápọntaápọn, tó ò ń gbàdúrà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tó o sì ń jàǹfààní látinú àwọn ìpèsè tẹ̀mí tá à ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ. (Ják. 1:5) Ó dájú pé àwọn ìpèsè yìí ni Jèhófà ń lò láti mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́mọdé gbọ́n ju gbogbo àwọn tí kò fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ràn rẹ̀ lọ, tó fi mọ́ àwọn táwọn èèyàn kà sí “ọlọ́gbọ́n àti amòye” nínú ayé.—Lúùkù 10:21; ka Sáàmù 119:98-100.
11-13. (a) Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú Sáàmù 26:4, Òwe 13:20 àti 1 Kọ́ríńtì 15:33? (b) Báwo lo ṣe máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí sílò?
11 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n máa jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa ṣe àṣàrò lórí ohun tá a bá ń kà, ká lè mọ Jèhófà dáadáa. Nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan, a máa rí ìlànà pàtàkì nípa bá a ṣe lè yan àwọn tí a ó máa bá ṣọ̀rẹ́. Wọ́n sọ pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.” (Sm. 26:4) “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́r. 15:33.
12 Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn? (1) Jèhófà fẹ́ ká fara balẹ̀ yan àwọn tí a ó máa bá ṣọ̀rẹ́. Ó fẹ́ dáàbò bò wá lọ́wọ́ ohun tó bá máa mú ká hùwà tí kò tọ́ tó sì máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. (2) Àwọn tí à ń bá ṣọ̀rẹ́ lè ní ipa rere tàbí ipa búburú lórí wa, bí ọ̀rọ̀ sì ṣe sábà máa ń rí nìyẹn. Àwọn gbólóhùn inú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká rí i pé ńṣe ni Jèhófà ń rọ̀ wá láti ṣe ohun tó tọ́. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Kíyè sí i pé Jèhófà kò sọ nínú èyíkéyìí lára àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn pé, “ìwọ kò gbọ́dọ̀ . . . ,” bíi pé ó ń gbé òfin kalẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló sọ wọ́n gẹ́gẹ́ bí òkodoro ọ̀rọ̀. Ó wá dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún wa pé: ‘Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni mò ń báa yín sọ yìí o. Kí lẹ máa ṣe nípa rẹ̀? Kí ló wà lọ́kàn yín?’
13 Lákòótán, torí pé Ọlọ́run sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gẹ́gẹ́ bí òkodoro ọ̀rọ̀, gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wúlò, onírúurú ipò la sì ti lè fi wọ́n sílò. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: Báwo ni mo ṣe lè yẹra fún kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn “tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́”? Ibo ni mo ti lè bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé? (Òwe 3:32; 6:12) Àwọn wo ni “àwọn ọlọgbọ́n” tí Jèhófà fẹ́ kí ń máa bá kẹ́gbẹ́? Àwọn wo ni “àwọn arìndìn” tó fẹ́ kí n yẹra fún? (Sm. 111:10; 112:1; Òwe 1:7) “Ìwà rere” wo ni mo máa bà jẹ́ bí mo bá ń kẹ́gbẹ́ búburú? Ṣé inú ayé nìkan ni mo ti máa bá ẹgbẹ́ búburú pàdé? (2 Pét. 2:1-3) Kí ni ìdáhùn rẹ sí àwọn ìbéèrè yìí?
14. Báwo lo ṣe lè mú kí Ìjọsìn Ìdílé rẹ sunwọ̀n sí i?
14 Ní báyìí tó o ti ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, o ò ṣe ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó máa jẹ́ kó o mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ọ̀rọ̀ tó bá kan ìwọ àti ìdílé rẹ?b Ẹ̀yin òbí sì tún lè fẹ́ láti jíròrò irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ máa ní in lọ́kàn pé ńṣe lẹ fẹ́ ran ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọrírì bí àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ tó ní sí wa ṣe jinlẹ̀ tó. (Sm. 119:72) Kódà, ńṣe ló yẹ kí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì tún sún mọ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì.
15. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bó o bá ń ní ọkàn-àyà ọgbọ́n àti ti ìgbọràn?
15 Báwo lo ṣe lè mọ̀ bó o bá ń ní ọkàn-àyà ọgbọ́n àti ti ìgbọràn? Ọ̀nà kan ni pé kó o fi èrò rẹ wé ti àwọn olóòótọ́ ìgbàanì, bíi Dáfídì Ọba, tó kọ̀wé pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:8) Bákan náà, ẹni tó kọ Sáàmù 119 sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 119:97) Irú ìfẹ́ yìí kì í ṣàdédé fò mọ́ni. Kéèyàn tó lè ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, àfi kó máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀, kó máa gbàdúrà, kó sì máa ṣe àṣàrò. Bákan náà, ìfẹ́ yìí á pọ̀ sí i béèyàn ṣe ń rí ìbùkún yanturu tó ń wá látinú títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Sm. 34:8.
MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÒMÌNIRA TÓ O NÍ GẸ́GẸ́ BÍI KRISTẸNI BỌ́ MỌ́ Ẹ LỌ́WỌ́!
16. Kí ni a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé bí a kò bá fẹ́ kí ojúlówó òmìnira wa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?
16 Jálẹ̀ ìtàn, onírúurú orílẹ̀-èdè ti ja ọ̀pọ̀ ogun rírorò torí kí wọ́n lè gbòmìnira. Ṣé kò wá yẹ kí ìwọ náà múra tán láti jà fitafita nípa tẹ̀mí kí òmìnira tó o ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni má bàa bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Má ṣe gbàgbé pé kì í ṣe Sátánì àti ẹ̀mí ayé tó ń lò láti ṣèpalára fúnni nìkan ni ọ̀tá rẹ o. O tún ní láti wọ̀yá-ìjà pẹ̀lú àìpé tìrẹ fúnra rẹ àti ọkàn-àyà tó ṣe àdàkàdekè. (Jer. 17:9; Éfé. 2:3) Síbẹ̀, Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ja àjàṣẹ́gun. Má sì gbàgbé pé, ní gbogbo ìgbà tó o bá yàn láti ṣe ohun tó tọ́, ohun rere méjì ló máa yọrí sí. Èkíní, wàá mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Èkejì, bí “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” bá ṣe túbọ̀ ń sọ ẹ́ di òmìnira, bẹ́ẹ̀ náà ni ìpinnu rẹ láti máa tọ ‘ọ̀nà tóóró’ tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun á máa lágbára sí i. Tó bá yá, wàá wá gbádùn òmìnira ńláǹlà èyí tí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Jèhófà ń fojú sọ́nà fún.—Ják. 1:25; Mát. 7:13, 14.
17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tí àìpé bá mú wa ṣe àṣìṣe, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?
17 Àmọ́ ṣá o, gbogbo wa la máa ń ṣe àṣìṣe láwọn ìgbà míì. (Oníw. 7:20) Bó o bá ṣe àṣìṣe, má ṣe wo ara rẹ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, má sì ṣe jẹ́ kí ìbànújẹ́ sorí rẹ kodò. Béèyàn bá ṣubú ńṣe ló máa ń dìde. Torí náà, tó bá gba pé kó o tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ, ṣe bẹ́ẹ̀ kó o sì ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Àdúrà ìgbàgbọ́” wọn “yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.” (Ják. 5:15) Má ṣe gbàgbé pé òótọ́ ni Ọlọ́run jẹ́ aláàánú àti pé ó rí ohun tó dára lára rẹ ni ó fi fà ẹ́ wá sínú ìjọ. (Ka Sáàmù 103:8, 9.) Torí náà, tí o bá ń bá a nìṣó láti máa fi ọkàn pípé sin Jèhófà, kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé.—1 Kíró. 28:9.
18. Kí ló yẹ ká ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Jésù tó wà nínú Jòhánù 17:15?
18 Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní alẹ́ tó lò kẹ́yìn láyé, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan nípa wọn. Ó ní: “Máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòh. 17:15) Ọ̀ràn àwọn àpọ́sítélì Jésù nìkan kọ́ ló jẹ ẹ́ lógún, ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pátá ló jẹ ẹ́ lógún. Torí náà, ó lè dá wa lójú pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà Jésù nípa fífi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa ní àwọn àkókò lílekoko yìí. “[Jèhófà] jẹ́ apata fún àwọn tí ń rìn nínú ìwà títọ́ . . . Yóò sì máa ṣọ́ ọ̀nà àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (Òwe 2:7, 8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn láti máa pa ìwà títọ́ mọ́, àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ló lè mú kéèyàn jèrè ìyè àìnípẹ̀kun kó sì ní ojúlówó òmìnira. (Róòmù 8:21) Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ẹ̀tàn fà ẹ́ kúrò lójú ọ̀nà náà!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn tí Dáfídì ti bí Ábúsálómù ni Ọlọ́run tó ṣèlérí fún un pé “irú ọmọ” rẹ̀ kan máa jogún ìtẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, ó ti yẹ kí Ábúsálómù mọ̀ pé Jèhófà kò yan òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó máa gorí ìtẹ́ lẹ́yìn Dáfídì.—2 Sám. 3:3; 7:12.
b Àwọn àpẹẹrẹ tó dára wà nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti ṣàpèjúwe ìfẹ́, àti Sáàmù 19:7-11, tó ṣàlàyé ọ̀pọ̀ ìbùkún téèyàn lè rí gbà tó bá ń ṣègbọràn sí àwọn òfin Jèhófà.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Báwo la ṣe lè dá àwọn tó fìwà jọ Ábúsálómù mọ̀ lóde òní ká sì yẹra fún wọn?