Ámósì Ṣé Ẹni Tí Ń Ká Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Ni àbí Ẹni Tí Ń Rẹ́ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Lára?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Amasááyà tó jẹ́ ìkà èèyàn, tó sì tún jẹ́ àlùfáà ìjọsìn ère ọmọ màlúù, pa á láṣẹ fún Ámósì pé kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ mọ́ ní Ísírẹ́lì. Ámósì kọ̀, ó ní: “Olùṣọ́ agbo ẹran ni mí àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè. Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti mú mi kúrò lẹ́nu títọ agbo ẹran lẹ́yìn, Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé, ‘Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì.’” (Ámósì 7:14, 15) Jèhófà ló yan Ámósì ní wòlíì, òun kọ́ ló yan ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni Ámósì ní lọ́kàn bó ṣe sọ pé “olùrẹ́” ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè lòun?
Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “olùrẹ́” fara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun. Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì mìíràn lo “ẹni tí ń kó èso jọ,” “aroko,” “olùtọ́jú,” tàbí “olùṣọ̀gbìn,” dípò “olùrẹ́” ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè. Bó ti wù kó rí, ìwé àtìgbàdégbà kan tó ń jẹ́ Economic Botany sọ pé “olùrẹ́” èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ló máa bá a mu jù láti lò fún ìtúmọ̀ yẹn, nítorí pé ó ń tọ́ka sí iṣẹ́ pàtàkì kan tí olùtọ́jú ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè máa ń ṣe.
Àṣà rírẹ́ èso ọ̀pọ̀tọ́, ìyẹn fífi nǹkan gún èso ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ kì í ṣe nǹkan àjèjì fáwọn ará Íjíbítì àtàwọn ará Kípírọ́sì ìgbà àtijọ́. Àmọ́, àṣà fífi nǹkan gún èso ọ̀pọ̀tọ́ tàbí rírẹ́ ẹ kò sí mọ́ báyìí ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, nítorí pé onírúurú èso ọ̀pọ̀tọ́ ni wọ́n ń gbìn báyìí. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Ámósì máa ń rẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ wọn nítorí pé ilẹ̀ Íjíbítì ni wọ́n ti mú àwọn igi síkámórè tí wọ́n ń gbìn nígbà yẹn lọ́hùn-ún wá.
Ó jọ pé, rírẹ́ tí wọ́n ń rẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ lára máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lómi dáadáa. Ó tún máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ kan báyìí tá a mọ̀ sí ethylene pọ̀ sí i, èyí tó máa ń jẹ́ kí èso tètè pọ́n táá sì jẹ́ kí èso náà túbọ̀ tóbi sí i kó sì dùn bí oyin. Yàtọ̀ síyẹn, kòkòrò kò ní lè ba èso náà jẹ́, níwọ̀n bó ti máa ń tètè pọ́n.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ olùṣọ́ agbo ẹran àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ tí Ámósì ń ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ gan-an, síbẹ̀ Ámósì ò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá òun kóun láyà jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgboyà ló fi kéde ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ ò ríi pé àpẹẹrẹ lèyí jẹ́ fún àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí, bá a tí ń kéde iṣẹ́ kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò kọbi ará sí!— Mátíù 5:11, 12; 10:22.