A Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Wa
“Kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”—1 PÉT. 1:15.
1, 2. (a) Irú ìwà wo ló yẹ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa hù? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn?
JÈHÓFÀ mí sí àpọ́sítélì Pétérù láti sọ bí ìjẹ́mímọ́ tí ìwé Léfítíkù tẹnu mọ́ ṣe kan jíjẹ́ tí àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa. (Ka 1 Pétérù 1:14-16.) “Ẹni Mímọ́” náà, Jèhófà, retí pé kí àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” máa sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wọn, kì í wulẹ̀ ṣe nínú díẹ̀ lára ìwà wọn.—Jòh. 10:16.
2 A máa jàǹfààní tó pọ̀ gan-an tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó wà nínú ìwé Léfítíkù síwájú sí i, tá a bá sì fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ nínú gbogbo ìwà wa. A máa jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Ojú wo ló yẹ ká fi wo ṣíṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run? Kí ni ìwé Léfítíkù kọ́ wa tó jẹ́ ká lè máa fi hàn pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run? Kí la máa rí kọ́ nínú ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rú?
MÁ ṢE OHUN TÓ LÒDÌ SÍ ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN
3, 4. (a) Kí nìdí tí àwọn Kristẹni kò fi gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí àwọn òfin àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì? (b) Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí a di kùnrùngbùn?
3 Tá a bá fẹ́ wu Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀, ká má ṣe lọ́wọ́ nínú ìwà àìmọ́, ká má sì ṣe ohun tó lòdì sáwọn òfin àti ìlànà náà. Lóòótọ́ a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ àwọn ohun tí òfin náà sọ jẹ́ ká lóye ohun tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà àti ohun tí kò tẹ́wọ́ gbà. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ. Èmi ni Jèhófà.”—Léf. 19:18.
4 Jèhófà ò fẹ́ ká máa gbẹ̀san, kò sì fẹ́ ká máa di kùnrùngbùn. (Róòmù 12:19) Tá a bá pa àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run tì, inú Èṣù máa dùn, a sì lè kó ẹ̀gàn bá Jèhófà. Kódà, bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ mú wa bínú, ẹ má ṣe jẹ́ ká sọ ara wa di ohun èlò ìbínú, ìyẹn ìkòkò tí a kó ìbínú sí. Ọlọ́run ti fún wa láǹfààní láti jẹ́ “àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe” níbi tí a kó ohun ìṣúra sí, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Kọ́r. 4:1, 7) Torí náà, kò yẹ ká bá ìkùnsínú tó dà bí ásíìdì olóró nínú àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀.
5. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa Áárónì àti ikú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 Ìwé Léfítíkù 10:1-11 sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ba ìdílé Áárónì lọ́kàn jẹ́. Ọkàn wọn á ti dà rú gan-an nígbà tí iná wá láti ọ̀run tó sì jó àwọn ọmọ Áárónì, ìyẹn Nádábù àti Ábíhù, run níbi àgọ́ ìjọsìn. Ẹ wo bí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe dán ìgbàgbọ́ Áárónì àti ìdílé rẹ̀ wò torí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣọ̀fọ̀ àwọn ìbátan wọn tó kú náà! Ǹjẹ́ ìwọ náà ń fi hàn pé o jẹ́ mímọ́ tó bá dọ̀rọ̀ pé ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ìbátan tàbí ẹlòmíràn tá a yọ lẹ́gbẹ́?—Ka 1 Kọ́ríńtì 5:11.
6, 7. (a) Tá a bá fẹ́ pinnu bóyá ó yẹ ká lọ síbi ìgbéyàwó kan tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì, kókó pàtàkì wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo la ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ìbátan wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nípa ìgbéyàwó tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì?
6 A lè má dojú kọ ìdánwò tó le koko tó ti Áárónì àti ìdílé rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá pè wá síbi ìgbéyàwó ìbátan wa kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fẹ́ ṣe ní ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sì retí pé ká lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ náà ńkọ́? Kò síbi tí Ìwé Mímọ́ ti pàṣẹ ní tààràtà pé a kò gbọ́dọ̀ lọ sí irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀, àmọ́ ṣé àwọn ìlànà Bíbélì kan wà tá a lè fi ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀?a
7 Tá a bá pinnu pé a máa jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà nínú ọ̀ràn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí, ó lè ya àwọn ìbátan wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu. (1 Pét. 4:3, 4) Lóòótọ́, a ò ní fẹ́ ṣẹ̀ wọ́n, àmọ́ ohun tó dára jù lọ ni pé ká sojú abẹ níkòó, síbẹ̀ ká fi pẹ̀lẹ́tù ṣe é. A sì lè bá wọn sọ̀rọ̀ náà nígbà tí ọjọ́ ayẹyẹ náà ṣì jìn. A lè dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn ká sì sọ pé inú wa dùn pé wọ́n ní ká wá síbi ìgbéyàwó náà. Lẹ́yìn náà, a lè wá sọ pé torí pé ọ̀rọ̀ ìjọsìn ti wọ̀ ọ́, tá a bá wà níbẹ̀, nǹkan tá a máa ṣe kò ní dùn mọ́ wọn nínú lọ́jọ́ ẹ̀yẹ wọn, ó sì lè kó ìtìjú bá wọn àti àwọn míì tí wọ́n pè wá síbẹ̀. Ọ̀nà kan nìyí tá ò fi ní ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wa.
MÁA FI HÀN PÉ JÈHÓFÀ NI ỌBA ALÁṢẸ AYÉ ÀTỌ̀RUN
8. Báwo ni ìwé Léfítíkù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ?
8 Ìwé Léfítíkù jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ. Ó fi hàn ní ìgbà tó ju ọgbọ̀n [30] lọ pé Jèhófà ló fúnni láwọn òfin tó wà nínú ìwé Léfítíkù. Mósè mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. (Léf. 8:4, 5) Bíi ti Mósè, ó yẹ kí àwa náà máa ṣe ohun tí Jèhófà, Ọba Aláṣẹ wa fẹ́ ká máa ṣe. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ètò Ọlọ́run á máa tì wá lẹ́yìn. Àmọ́ ṣá o, bí Èṣù ṣe dán Jésù wò nínú aginjù, a lè dán ìgbàgbọ́ tiwa náà wò nígbà tá a bá dá wà. (Lúùkù 4:1-13) Tá a bá pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba aláṣẹ tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ẹnikẹ́ni ò ní lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́, ìbẹ̀rù ò sì ní mú wa kó sínú ìdẹkùn.—Òwe 29:25.
9. Kí nìdí tí wọ́n fi kórìíra àwa èèyàn Ọlọ́run ní gbogbo orílẹ̀-èdè?
9 Torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi àti Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, wọ́n ń ṣenúnibíni sí wa láwọn orílẹ̀-èdè yíká ayé. A retí pé kó rí bẹ́ẹ̀, torí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Àmọ́, láìka ìkórìíra bẹ́ẹ̀ sí, à ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run a sì ń jẹ́ mímọ́ nìṣó lójú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ olóòótọ́, tí a kì í lọ́wọ́ sí ìwà pálapàla, tá a sì tún ń pa òfin mọ́, kí wá nìdí náà gan-an táwọn èèyàn fi kórìíra wa? (Róòmù 13:1-7) Ìdí ni pé Jèhófà la gbà pé ó jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ wa! “Òun nìkan ṣoṣo” là ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún, a ò sì ní ṣe ohun tó lòdì sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ láé.—Mát. 4:10.
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí arákùnrin kan gbà láti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun?
10 Yàtọ̀ síyẹn, a “kì í ṣe apá kan ayé.” Torí náà, a kì í dá sí ogun àti ọ̀ràn òṣèlú ayé. (Ka Jòhánù 15:18-21; Aísáyà 2:4.) Àwọn kan tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run ti dá sí ọ̀ràn ogun. Ọ̀pọ̀ lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ti ronú pìwà dà wọ́n sì ti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run tó jẹ́ aláàánú. (Sm. 51:17) Ṣùgbọ́n, àwọn díẹ̀ lára wọn kò ronú pìwà dà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn aláṣẹ kó ọgọ́jọ [160] lára àwọn arákùnrin wá jáde látinú gbogbo ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi wọ́n sí láìbófinmu lórílẹ̀-èdè Hungary, wọ́n sì kó wọn jọ sínú ìlú kan. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn arákùnrin yìí tó tíì pé ọmọ ọdún márùndínláàádọ́ta [45]. Wọ́n wá pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wọṣẹ́ ológun. Àwọn arákùnrin olóòótọ́ kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní wọṣẹ́ ológun, àmọ́ mẹ́sàn-án lára wọ́n gbà láti wọṣẹ́ ológun, wọ́n ṣe ìbúra fún wọn, wọ́n sì gbé aṣọ ogun wọ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn tó gbà láti wọṣẹ́ ológun náà wà lára àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ní kí wọn yìnbọn pa àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olóòótọ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ọmọ ìyá rẹ̀ wà lára àwọn arákùnrin náà! Àmọ́, wọ́n kàn halẹ̀ mọ́ wọn lásán ni, wọn ò pa wọ́n.
OHUN TÓ DÁRA JÙ LỌ NI KÓ O FI RÚBỌ SÍ JÈHÓFÀ
11, 12. Kí làwa Kristẹni òde òní rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà rúbọ láyé àtijọ́?
11 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa rú oríṣiríṣi ẹbọ. (Léf. 9:1-4, 15-21) Àwọn ẹbọ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí kò lábàwọ́n torí pé wọ́n ṣàpẹẹrẹ ẹbọ pípé tí Jésù fi ara rẹ̀ rú. Síwájú sí i, ìlànà pàtó wà fún irú ọrẹ tí wọ́n fẹ́ mú wá tàbí irú ẹbọ tí wọ́n fẹ́ rú. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tí Ọlọ́run ní kí ìyá kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ mú wá. Ìwé Léfítíkù 12:6 sọ pé: “Ní ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí fún ọmọbìnrin bá pé, òun yóò mú ẹgbọrọ àgbò tí ó wà ní ọdún rẹ̀ àkọ́kọ́ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọrẹ ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí oriri fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, fún àlùfáà.” Ó ní àwọn nǹkan pàtó tí Ọlọ́run ń béèrè, àmọ́ bó ṣe ń fìfẹ́ gba tẹni rò fara hàn kedere nínú Òfin náà. Bí ìyá náà kò bá ní lọ́wọ́, tí kò sì lè mú àgùntàn wá, Ọlọ́run yọ̀ǹda pé kó mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá. (Léf. 12:8) Bí olùjọ́sìn bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ jẹ́ òtòṣì, Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ̀ ó sì mọyì rẹ̀ bó ṣe mọyì àwọn tó mú ọrẹ olówó ńlá wá. Kí la rí kọ́ nínú èyí?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n máa rú “ẹbọ ìyìn” sí Ọlọ́run. (Héb. 13:15) A gbọ́dọ̀ máa fi ètè wa polongo orúkọ mímọ́ Jèhófà. Àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ adití máa ń lo èdè àwọn adití láti fi irú ìyìn bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run. Àwọn ará wa tí wọn ò lè jáde nílé mọ́ máa ń yìn ín nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ, fífi fóònù jẹ́rìí àti wíwàásù fún àwọn tó ń tọ́jú wọn àti àwọn tó ń bẹ̀ wọ́n wò. Ohun tí ìlera wa àti agbára wa gbé ló máa pinnu bí ẹbọ ìyìn wa ṣe máa pọ̀ tó, ìyẹn ìyìn tá à ń fún Jèhófà nígbà tá a bá ń sọ orúkọ rẹ̀ fáwọn èèyàn tá a sì ń polongo ìhìn rere náà. Ohun tó dára jù lọ ló yẹ kó jẹ́.—Róòmù 12:1; 2 Tím. 2:15.
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa?
13 Àwọn ẹbọ ìyìn wa jẹ́ àwọn ohun tá à ń fínnú fíndọ̀ fún Ọlọ́run torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mát. 22:37, 38) Ṣùgbọ́n a ti sọ fún wa pé ká máa ròyìn ohun tá a ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ìṣètò yìí? Ìròyìn tá à ń fi sílẹ̀ lóṣooṣù jẹ́ ara ìfọkànsìn wa sí Ọlọ́run. (2 Pét. 1:7) Àmọ́, kò sídìí fún ẹnikẹ́ni láti rò pé òun gbọ́dọ̀ fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣe iṣẹ́ ìwàásù torí kí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá òun bàa lè pọ̀ gan-an. Torí rẹ̀ gan-an ló fi jẹ́ pé akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà nílé àwọn arúgbó tàbí ẹni tó jẹ́ aláìlera lè ròyìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù kan dípò kó ròyìn odindi wákàtí. Jèhófà mọyì àwọn ìṣẹ́jú tí akéde Ìjọba Ọlọ́run yẹn fi wàásù, ó gbà pé ọrẹ ẹbọ tó dára jù lọ tí akéde náà lè mú wá nìyẹn, ó gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó mọyì àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tó ní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí òun. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ohun tí agbára wọn gbé ní wọ́n lè fi rúbọ sí Jèhófà dípò ẹbọ olówó ńlá, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá tí agbára wọ́n gbé. Ìròyìn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá bá fi sílẹ̀ ló ń para pọ̀ di ìròyìn kárí ayé, èyí tó ń mú kó ṣeé ṣe fún ètò Ọlọ́run láti wéwèé àwọn ohun tá a máa nílò fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Torí náà, ṣé ìnira ni láti ròyìn ohun tá a bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ WA NÍ Í ṢE PẸ̀LÚ ẸBỌ ÌYÌN WA
14. Ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ọ̀nà tá à ń gbà kẹ́kọ̀ọ́?
14 Lẹ́yìn tá a ti gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó wà nínú ìwé Léfítíkù, o lè wá ronú pé, ‘Mo ti wá túbọ̀ lóye ìdí tí Ọlọ́run fi mú kí ìwé yìí wà lára Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí.’ (2 Tím. 3:16) Ní báyìí, ìpinnu rẹ á túbọ̀ lágbára pé wàá máa jẹ́ mímọ́, kì í ṣe torí pé Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́ mímọ́ nìkan ni, àmọ́ torí pé òun ló yẹ kó o fi gbogbo agbára rẹ̀ sìn. Ó sì ṣeé ṣe kí ohun tó o ti kọ́ nípa ìwé Léfítíkù nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí ti mú kó túbọ̀ wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. (Ka Òwe 2:1-5.) Máa kíyè sí ọ̀nà tó ò ń gbà kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. Ó dájú pé wàá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà ẹbọ ìyìn rẹ. Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, géèmù fídíò, àwọn eré ìdárayá tàbí àwọn eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ ti ń pín ọkàn rẹ níyà, tí wọn ò sì jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní pé kó o ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé Hébérù.
15, 16. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ojú abẹ níkòó nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni?
15 Pọ́ọ̀lù sọ ojú abẹ níkòó nígbà tó kọ̀wé sí àwọn Hébérù tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. (Ka Hébérù 5:7, 11-14.) Àpọ́sítélì náà ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Ó sọ fún wọn pé etí wọn ti “yigbì.” Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀ lọ́nà ṣàkó bẹ́ẹ̀? Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fi hàn pé, bíi ti Jèhófà, òun nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ pé wàrà tẹ̀mí nìkan ni wọ́n fẹ́ láti máa mu, òun sì ń ṣàníyàn nípa wọn. Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú ẹ̀kọ́ Kristẹni. Àmọ́, wọ́n nílò “oúnjẹ líle” tó máa jẹ́ kí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀.
16 Dípò tí àwọn Hébérù yẹn ì bá fi máa tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíì, wọ́n ṣì nílò ẹnì kan táá máa kọ́ wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n kì í jẹ “oúnjẹ líle.” O lè wá bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ èmi náà ń fẹ́ láti máa jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí? Ṣé mo sì máa ń jẹ ẹ́? Àbí kì í yá mi lára láti máa gbàdúrà, tí mi ò sì kì í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣó lè jẹ́ pé ọ̀nà tí mò ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ wà lára ìṣòro náà?’ Kì í ṣe pé ká wàásù fáwọn èèyàn nìkan, àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ kọ́ wọn ká sì sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 28:19, 20.
17, 18. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa jẹ́ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí déédéé? (b) Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìpàdé ìjọ, ojú wo ló yẹ ká fi wo mímu ọtí?
17 Ó lè má rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wa láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kì í fi ẹ̀rí ọkàn wa dá wa lẹ́bì torí ká lè máa kẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, yálà a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀ ọdún tàbí kò tíì pẹ́ tá a ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí déédéé. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́ nìṣó.
18 Ká lè máa jẹ́ mímọ́, a gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yẹ̀ wò ká sì máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Ronú nípa àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù, tí wọ́n kú torí pé wọn rú “ẹbọ tí kò bá ìlànà mu,” bóyá nítorí pé wọ́n ti mutí yó. (Léf. 10:1, 2) Kíyè sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Áárónì lẹ́yìn náà. (Ka Léfítíkù 10:8-11.) Ṣé ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ ni pé a kò gbọ́dọ̀ mu ọtí ká tó lọ sí ìpàdé ìjọ? Àwọn kókó tó o máa ronú lé lórí rèé: A kò sí lábẹ́ Òfin Mósè. (Róòmù 10:4) Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni máa ń mu ọtí níwọ̀nba tí wọ́n bá ń jẹun kí wọ́n tó lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ife wáìnì mẹ́rin ni wọ́n máa ń lò níbi àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó ní kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mu wáìnì tó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Mát. 26:27) Bíbélì sọ pé ọtí àmujù àti àmupara kò dára. (1 Kọ́r. 6:10; 1 Tím. 3:8) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni sì wà tó jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọn mú kí wọ́n pinnu pé àwọn ò ní mutí rárá táwọn bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ èyíkéyìí. Àmọ́, bí ipò nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí bó ṣe rí ní orílẹ̀-èdè míì àti pé ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí àwọn Kristẹni máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́” kí wọ́n lè máa hùwà mímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́.
19. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá di ọ̀rọ̀ ìjọsìn ìdílé àti ìdákẹ́kọ̀ọ́? (b) Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe kó o lè máa jẹ́ mímọ́?
19 O ṣì lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Máa lo àwọn ohun èlò ìwádìí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti mú ìjọsìn ìdílé yín àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ sunwọ̀n sí i. Túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. (Ják. 4:8) Gbàdúrà sí Ọlọ́run bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “La ojú mi, kí n lè máa wo àwọn ohun àgbàyanu láti inú òfin rẹ.” (Sm. 119:18) Rí i pé o kì í ṣe ohun tó lòdì sí àwọn òfin àti ìlànà inú Bíbélì. Máa fínnú fíndọ̀ tẹ̀ lé òfin gíga jù lọ tí Jèhófà, “Ẹni Mímọ́” fún wa, kó o sì máa fìtara ṣe “iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run.” (1 Pét. 1:15; Róòmù 15:16) Máa jẹ́ mímọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó kún fún wàhálà yìí. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa jẹ́ oníwà mímọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fi hàn pé Jèhófà, Ọlọ́run wa mímọ́, ni ọba aláṣẹ ayé àtọrun.
a Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2002.