Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Máa Ń Pẹ́ Láyé Gan-an Ní Àkókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì?
OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Jeanne Louise Calment kú ní August 4, ọdún 1997, ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Faransé. Ẹni ọdún méjì lé ní ọgọ́fà [122] ni nígbà tó kú!
Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, nínú ìtọ́jú ara àti nínú àwọn iṣẹ́ míì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn lónìí láti máa pẹ́ láyé. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé. Ìyẹn lè jẹ́ ìdí tí wọ́n fi máa ń gbé ọ̀rọ̀ àwọn tó pẹ́ láyé jáde nínú ìròyìn nígbà míì, bó ti rí nínú ọ̀ràn Ìyáàfin Calment.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn èèyàn máa ń pẹ́ láyé gan-an ní ìgbàanì, kódà, àwọn kan fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ẹgbẹ̀rún ọdún láyé. Ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Ṣé àwọn tó gbé láyé ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì pẹ́ láyé lóòótọ́? Àti pé àǹfààní wo ni ìyẹn máa ṣe fún wa lónìí?
Àwọn Èèyàn Tí Wọ́n Pẹ́ Láyé
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì inú Bíbélì sọ nípa àwọn ọkùnrin méje tí wọ́n lo ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] ọdún láyé, wọ́n sì ti bí gbogbo wọn ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Orúkọ wọn ni Ádámù, Sẹ́ẹ̀tì, Énọ́ṣì, Kénánù, Járédì, Mètúsélà àti Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 5:5-27; 9:29) Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lè má mọ àwọn kan lára àwọn ọkùnrin yìí, àmọ́ gbogbo wọn ló wà lára ìran mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú ìtàn aráyé. Àwọn èèyàn mọ Mètúsélà dáadáa, torí òun ló pẹ́ láyé jù lọ, ó lo òjì dín lẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́sàn-án [969] ọdún!
Bíbélì tún jẹ́ ká mọ àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n míì tí wọ́n lò kọjá ọdún táwọn èèyàn sábà máa ń lò lóde òní. Àwọn kan lára wọn lo ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún, irínwó [400] ọdún, àní àwọn kan tiẹ̀ lo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé. (Jẹ́nẹ́sísì 5:28-31; 11:10-25) Àmọ́ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ìtàn àròsọ ni ohun tí Bíbélì sọ pé àwọn kan pẹ́ láyé. Ṣé ìtàn àròsọ ni lóòótọ́?
Ṣé Òótọ́ ni àbí Ìtàn Àròsọ?
Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan látọwọ́ Àjọ Max Planck tó ń rí sí ọ̀ràn ọjọ́ orí nílẹ̀ Jámánì ti sọ, àwọn aṣèwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni iye ọjọ́ orí Ìyáàfin Calment tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Látinú àkójọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n gbọ́ láti ẹnu ìyá náà ni wọ́n ti fìdí èyí múlẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn jẹ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé. Wọ́n wá fi ọ̀rọ̀ tí ìyá yìí sọ wé ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ ìlú, ohun táwọn amòfin sọ àti àkọsílẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, títí kan àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn àtàwọn àkọsílẹ̀ ìkànìyàn. Òótọ́ ni pé kò ṣeé ṣe láti mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ àwọn ẹ̀rí tó ṣe tààràtà àtèyí tí kò ṣe tààràtà tí wọ́n rí kó jọ jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mọ ọjọ́ orí ìyá náà gan-an.
Ọjọ́ orí àwọn tó pẹ́ láyé tí Bíbélì sọ ńkọ́? Ṣé òótọ́ ni pé wọ́n pẹ́ láyé tó ìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé ìtàn tó wà láyé kò tíì lè fìdí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀rí tó wà múlẹ̀, léraléra ni ìtàn, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìṣirò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ fi hàn pé ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ òótọ́.a Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run máa ń sọ òtítọ́, àní bí gbogbo èèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ òpùrọ́.” (Róòmù 3:4, Bíbélì Contemporary English Version) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì jẹ́ ìwé tí “Ọlọ́run mí sí,” nítorí náà kò sí ìtàn àròsọ nínú rẹ̀.—2 Tímótì 3:16.
Mósè ni Jèhófà Ọlọ́run darí láti kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ inú Bíbélì, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún jù lọ nínú ìtàn aráyé. Àwọn Júù kà á sí olùkọ́ tó ju olùkọ́ lọ láàárín àwọn Júù. Àwọn Mùsùlùmí kà á sí ọ̀kan lára àwọn wòlíì wọn tó tóbi jù lọ. Àwọn Kristẹni sì ka Mósè sí àpẹẹrẹ irú ẹni tí Jésù Kristi máa jẹ́. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti rò pé ìwé tí irú ẹni pàtàkì nínú ìtàn aráyé bẹ́ẹ̀ kọ kò jẹ́ òótọ́?
Ṣé Bí Wọ́n Ṣe Ń Ka Ọdún Nígbà Yẹn Yàtọ̀?
Ohun táwọn kan sọ ni pé, bí wọ́n ṣe ń ka ọdún ní ayé ìgbàanì yàtọ̀ àti pé ohun tí wọ́n ń pè ní ọdún kan nígbà yẹn jẹ́ oṣù kan. Àmọ́ téèyàn bá ṣàgbéyẹ̀wò ìwé Jẹ́nẹ́sísì dáadáa, kò sí iyè méjì pé ọ̀nà kan náà làwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn àti ti òde òní gbà ń ka ọdún. Gbé àpẹẹrẹ méjì yìí yẹ̀ wò. A kà nínú ìtàn Ìkún Omi pé, Àkúnya Omi náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Nóà jẹ́ ẹni ẹgbẹ̀ta [600] ọdún, “ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù.” Ìtàn náà ń bá a nìṣó pé, omi bo ayé mọ́lẹ̀ fún àádọ́jọ [150] ọjọ́ àti pé “ní oṣù keje, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù, áàkì náà sì wá gúnlẹ̀ sórí òkè ńlá Árárátì.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 24; 8:4) Nítorí náà, oṣù márùn-ún gbáko, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje ọdún yẹn, ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ àádọ́jọ ọjọ́. Ó fi hàn kedere pé ohun tí wọ́n sọ pé ọdún kan jẹ́ oṣù kan kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.
Jẹ́ ká wá gbé àpẹẹrẹ kejì yẹ̀ wò. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 5:15-18, jẹ́ ká mọ̀ pé Máhálálélì bímọ nígbà tó wà lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65], ó wà láàyè fún ọgbọ̀n lé lẹ́gbẹ̀rin [830] ọdún lẹ́yìn náà, ó sì kú lẹ́ni ọdún márùn-ún dín lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [895]. Énọ́kù tó jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀ náà bímọ nígbà tó wà lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65]. (Jẹ́nẹ́sísì 5:21) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni pé oṣù kan jẹ́ ọdún kan, ó fi hàn pé ọmọ ọdún márùn-ún làwọn ọkùnrin méjèèjì yìí wà nígbà tí wọ́n bímọ. Ṣé ìyẹn bọ́gbọ́n mu?
Àwọn awalẹ̀pìtàn náà tún mú ẹ̀rí wá, àwọn ẹ̀rí wọn bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé àwọn èèyàn pẹ́ láyé gan-an. Bíbélì sọ pé, ìlú Úrì ni Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wá, nígbà tó yá, ó gbé ní ìlú Háránì, ó tún gbé ní agbègbè Kénáánì àti pé ó bá Kedoláómà Ọba Élámù jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31; 12:5; 14:13-17) Àwọn àwárí táwọn èèyàn ṣe fi hàn pé ìlú àtàwọn èèyàn yìí wà lóòótọ́. Àwárí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe tún jẹ́ ká lóye bí ìlú náà ṣe rí àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù. Tí àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ yìí nípa Ábúráhámù bá jẹ́ òótọ́, ṣé ó yẹ kéèyàn máa ṣe iyè méjì pé Ábúráhámù lo ọdún márùn-ún lé ní àádọ́sàn-án [175] láyé?—Jẹ́nẹ́sísì 25:7.
Nítorí náà, kò sí ìdí láti máa ṣe iyè méjì lórí ohun tí Bíbélì sọ pé àwọn kan láyé ìgbàanì pẹ́ láyé lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, o lè bi ara rẹ pé, ‘Àǹfààní wo ni ìyẹn máa ṣe mí bóyá àwọn èèyàn kan pẹ́ láyé tàbí wọn kò pẹ́?’
O Lè Pẹ́ Láyé Ju Bó O Ṣe Rò Lọ!
Pípẹ́ tí àwọn ọkùnrin tó gbé láyé ṣáájú Ìkún Omi pẹ́ láyé gan-an fi hàn pé ara èèyàn lágbára àrà ọ̀tọ̀ láti máa gbé lọ fún àkókò gígùn. Àwọn ẹ̀rọ táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣàyẹ̀wò ara èèyàn àti ọ̀nà àgbàyanu tí Ọlọ́run gbà dá a, títí kan agbára ńlá tó ní láti máa pààrọ̀ ara rẹ̀ kó sì máa wo ara rẹ̀ sàn. Kí ni ohun tí wọ́n sọ? Wọ́n ní, èèyàn lè máa wà láàyè títí lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Tom Kirkwood, tó jẹ́ Onímọ̀ Ìṣègùn sọ pé: “Dídarúgbó ṣì jẹ́ àwámáàrídìí gan-an nínú ìmọ̀ ìṣègùn.”
Àmọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run, dídarúgbó kì í ṣe àwámáàrídìí tàbí ìṣòro tí kò ní ojútùú. Ó dá Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ ní pípé, ó sì fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbé títí láé. Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù pinnu láti kọ ẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, ó sì di aláìpé. Àlàyé tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ́ mọ̀ ni pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé la ṣe ń ṣàìsàn, tí a ń darúgbó tí a sì ń kú.
Àmọ́, ohun tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ní lọ́kàn kò tíì yí pa dà. Láti fi èyí hàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ó fi Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà, èyí tó lè mú ká di èèyàn pípé, ká sì máa wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Àwọn èèyàn tó gbé láyé ṣáájú Ìkún Omi sún mọ́ ìjẹ́pípé jù wá lọ, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pẹ́ láyé gan-an ju ti àkókò wa yìí lọ. Àmọ́ a ti túbọ̀ sún mọ́ àkókò tí ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ. Láìpẹ́, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé bó ti wù kó kéré mọ máa pòórá, àwọn èèyàn kò sì ní darúgbó mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní kú mọ́.—Aísáyà 33:24; Títù 1:2.
Báwo lo ṣe lè jàǹfààní ìbùkún yìí? Má ṣe rò pé ìlérí Ọlọ́run kò lè ṣẹ. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 5:24) Nítorí náà, kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fi ohun tó o kọ́ sílò. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó fetí sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù èyí tó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:19) Mọ̀ dájú pé Ọlọ́run tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn kan nínú Bíbélì láti pẹ́ láyé gan-an lè mú kó ṣeé ṣe fún ìwọ náà láti wà láàyè títí láé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ka ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Graph tó wà ní ojú ìwé 12]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
1000
969 MÈTÚSÉLÀ
950 NÓÀ
930 ÁDÁMÙ
900
800
700
600
500
400
300
200
100 ÀWỌN ÈÈYÀN ÒDE ÒNÍ
ỌJỌ́ ORÍ