Ẹ̀KỌ́ 28
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] ọdún nínú aginjù. Wọ́n ti ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ ìlú tó lágbára. Ní báyìí, ilẹ̀ Móábù ni wọ́n wà nítòsí Odò Jọ́dánì, ó ti ń tó àsìkò fún wọn láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ̀rù ń ba Bálákì ọba Móábù pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tó gba ilẹ̀ òun mọ́ òun lọ́wọ́. Torí náà, ó ní kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Báláámù wá sí Móábù láti wá ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Báláámù pé: ‘O kò gbọ́dọ̀ ṣépè fún wọn.’ Fún ìdí yìí, Báláámù kò lọ. Ọba Bálákì tún pe Báláámù nígbà kejì, ó sì ṣèlérí láti fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. Síbẹ̀, Báláámù kọ̀ jálẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ọlọ́run sọ fún Báláámù pé: ‘Lọ, àmọ́ ohun tí mo bá sọ fún ẹ ni kí o sọ.’
Báláámù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì kọrí sí Móábù. Ó fẹ́ lọ ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Áńgẹ́lì kan yọ sí i lẹ́ẹ̀mẹta lójú ọ̀nà. Báláámù kò rí áńgẹ́lì náà, àmọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ rí i. Nígbà àkọ́kọ́, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn sá kúrò lójú ọ̀nà, ó sáré gba orí koríko tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Nígbà kejì, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí tún fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri kan débi pé ẹsẹ̀ Báláámù náà fún mọ́ ògiri yìí. Nígbà kẹta, ńṣe ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà kúkú takú, tó sì dùbúlẹ̀ sí àárín ọ̀nà. Ìgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì ni Báláámù ń fi igi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.
Nígbà kẹta, Jèhófà jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí sọ̀rọ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà bi Báláámù pé: ‘Kí ló dé tí o fi ń lù mí ṣáá?’ Báláámù dáhùn pé: ‘O ti múnú bí mi gan-an. Tó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, màá ti pa ẹ́.’ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sọ pé: ‘Ọ̀pọ̀ ọdún lo ti fi ń gùn mí. Ṣé mo ti ṣe báyìí sí ẹ rí?’
Ní báyìí, Jèhófà jẹ́ kí Báláámù rí áńgẹ́lì náà. Áńgẹ́lì yìí wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà kìlọ̀ fún ẹ pé kí o má lọ ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’ Báláámù sọ pé: ‘Mo ti ṣe ohun tí kò dára. Mo máa pa dà lọ sílé.’ Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Máa lọ síbi tí ò ń lọ ní Móábù, àmọ́ ohun ti Jèhófà bá ní kí o sọ nìkan ni kí o sọ.’
Ṣé Báláámù kọ́gbọ́n látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Rárá o. Torí pé lẹ́yìn tó rí áńgẹ́lì yẹn, Báláámù ṣì gbìyànjú láti lọ ṣépè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbà mẹ́ta, àmọ́ kàkà kó ṣépè, Jèhófà jẹ́ kó gbàdúrà fún wọn nígbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá ìlú Móábù jà, Báláámù sì kú nínú ogun náà. Tó bá jẹ́ pé Báláámù ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un, ṣé ó máa kú sógun?
“Kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”—Lúùkù 12:15