Ìgbéyàwó Táwọn Èèyàn Ò Retí Wáyé Láàárín Bóásì àti Rúùtù
ÌGBÒKÈGBODÒ ń lọ lọ́tùn-ún lósì nílẹ̀ ìpakà tó wà nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Wọ́n ti ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Òórùn títasánsán tó ń wá látinú ọkà tútù tí wọ́n ń sun ló jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ tébi ti ń pa mọ̀ pé àkókò oúnjẹ ti tó. Olúkúlùkù ni yóò gbádùn èrè iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.
Bóásì, baálé ilé tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni, ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkà tí wọ́n kó jọ gegere, ó ń jẹ ó ń mu, ó sì ń ṣe yọ̀tọ̀mì. Nígbà tó yá, ìkórè ọjọ́ yẹn parí, olúkúlùkù sì wá ibi tó tura láti sinmi sí. Bóásì, tọ́kàn rẹ̀ balẹ̀ bíi ti tòlótòló wá faṣọ bo ara rẹ̀ wàyí, ó sì sùn lọ fọnfọn.
Ìpàdé Bòókẹ́lẹ́
Ní ọ̀gànjọ́ òru, Bóásì ta jí, òtútù ń mú un, ó sì ń gbọ̀n rìrì. Háà, wọ́n ti mọ̀ọ́mọ̀ ṣí aṣọ kúrò lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ẹnì kan sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀! Nítorí pé kò mọ ẹni tónítọ̀hún jẹ́ nínú òkùnkùn, ó béèrè pé: “Ta ni ọ́?” Ó sì gbọ́ ohun obìnrin kan tó fèsì pé: “Èmi ni Rúùtù ẹrúbìnrin rẹ, kí o sì na apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ bo ẹrúbìnrin rẹ, nítorí ìwọ jẹ́ olùtúnnirà.”—Rúùtù 3:1-9.
Àwọn méjèèjì sì ń sọ̀rọ̀ nínú òkùnkùn láìsí ẹlòmíràn níbẹ̀. Àwọn obìnrin kì í ṣe báyìí wá sí ilẹ̀ ìpakà. (Rúùtù 3:14) Àmọ́, nítorí pé Bóásì ò bínú sí i, Rúùtù wá dùbúlẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, kó sì tó di pé ọ̀yẹ̀ là, Rúùtù dìde ó sì lọ kó má bàa sí pé ẹnikẹ́ni bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ò ṣẹlẹ̀.
Ṣé ìpàdé eléré ìfẹ́ lèyí? Ǹjẹ́ Rúùtù, ọ̀dọ́bìnrin opó tó tálákà bí nǹkan míì, tó sì wá láti orílẹ̀-èdè kèfèrí yẹn fọgbọ́n àrékérekè sún bàbá àgbàlagbà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ yìí dẹ́ṣẹ̀? Àbí ṣé Bóásì lo àǹfààní ipò tí Rúùtù wà àti bó ṣe dá nìkan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lóru ọjọ́ yẹn láti fi kó o nífà jẹ? Ìdúróṣinṣin àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run ni ìdáhùn gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí. Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ sì wúni lórí gan-an.
Ta ni Rúùtù? Kí ló ní lọ́kàn gan-an? Ta sì ni Bóásì, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí?
“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
Ìyàn ńlá kan mú ní Júdà ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́rin kan ní Ísírẹ́lì—ìyẹn Elimélékì; Náómì, ìyàwó rẹ̀; àtàwọn ọmọkùnrin wọn méjì, ìyẹn Málónì àti Kílíónì—gbéra, wọ́n sì forí lé ilẹ̀ Móábù tó lọ́ràá dáadáa. Àwọn ọmọkùnrin náà gbé àwọn ọmọbìnrin Móábù méjì tórúkọ wọ́n ń jẹ́ Rúùtù àti Ópà níyàwó. Lẹ́yìn táwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú nílẹ̀ Móábù ni àwọn obìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wá gbọ́ pé ipò nǹkan ti ṣẹnuure ní Ísírẹ́lì. Nítorí náà, Náómì—tó ti di opó báyìí, tí ọkàn rẹ̀ sí gbọgbẹ́, láìní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ—wá pinnu láti padà sí ìlú rẹ̀.—Rúùtù 1:1-14.
Bí wọ́n ṣe mú ìrìn àjò wọn pọ̀n, tí wọ́n ń lọ sí Ísírẹ́lì ni Náómì rọ Ópà pé kó padà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Náómì wá sọ fún Rúùtù pé: “Wò ó! aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀. Bá aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó padà.” Àmọ́ Rúùtù sọ pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, . . . nítorí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ . . . Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni ibi tí a ó sin mí sí.” (Rúùtù 1:15-17) Bí àwọn opó méjèèjì tí wọn ò ní gá tí wọn ò ní go yìí ṣe padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nìyẹn. Bí Rúùtù ṣe nífẹ̀ẹ́ ìyá ọkọ rẹ̀ tó sì ń tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀ wú àwọn aládùúgbò wọn lórí gan-an, débi tí wọ́n fi kà á sí “ẹni tí ó sàn fún [Náómì] ju ọmọkùnrin méje lọ.” Àwọn mìíràn sì ń pè é ní “obìnrin títayọ lọ́lá.”—Rúùtù 3:11; 4:15.
Nígbà tí ìkórè ọkà báálì bẹ̀rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù sọ fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí pápá, kí n sì pèéṣẹ́ lára ṣírí ọkà ní títẹ̀lé ẹnì yòówù kí ó jẹ́ tí mo bá lè rí ojú rere lójú rẹ̀.”—Rúùtù 2:2.
Lọ́nà kan ṣáá, oko Bóásì, tó jẹ́ ìbátan Elimélékì, baba ọkọ rẹ̀ ló lọ. Ó bẹ ẹni tó jẹ́ alábòójútó ibẹ̀ pé kó jọ̀ọ́ kó jẹ́ kí òun pèéṣẹ́. Ọ̀nà tó gbà ń fi aápọn pèéṣẹ́ ta yọ̀ lọ́lá, alábòójútó náà sì ròyìn iṣẹ́ rẹ̀ ní rere fún Bóásì.—Rúùtù 1:22–2:7.
Aláàbò àti Olóore Ẹni
Ẹni tí ń jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn ni Bóásì. Àràárọ̀ ni Bóásì máa ń kí àwọn olùkórè rẹ̀ pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín,” àwọn náà á sì fèsì pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.” (Rúùtù 2:4) Lẹ́yìn tí Bóásì kíyè sí bí Rúùtù ṣe jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́, tó sì gbọ́ nípa bó ṣe dúró ti Náómì gbágbáágbá, ó fún Rúùtù láǹfààní pípèéṣẹ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ní ṣókí, ó sọ fún un pé: ‘Dúró nínú pápá mi; má wulẹ̀ lọ sínú pápá mìíràn. Rìn sún mọ́ àwọn ọmọbìnrin mi; ohunkóhun ò sì ní ṣe ọ́ lọ́dọ̀ wọn. Mo ti pàṣẹ fáwọn ọ̀dọ́kùnrin láti má ṣe fọwọ́ kàn ọ́. Nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ ọ́, wọ́n á pọnmi fún ọ.’—Rúùtù 2:8, 9.
Rúùtù wá tẹrí ba, ó sì wí pé: ‘Báwo ni ó ti jẹ́ tí mo fi rí ojú rere lójú rẹ, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?’ Bóásì dáhùn pé: ‘Mo ti gbọ́ ìròyìn ní kíkún nípa gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ—bí o ṣe fi baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀ láti máa gbé láàárín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà. Kí ó sì fún ọ ní owó ọ̀yà pípé.’—Rúùtù 2:10-12.
Kì í ṣe pé Bóásì ń wá bóun ṣe máa fa ojú rẹ̀ mọ́ra o. Tinútinú ló fi gbóríyìn fún un. Tọkàntọkàn ní Rúùtù náà fi dojú bolẹ̀, tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún bó ṣe fi í lọ́kàn balẹ̀. Ó kà á sí oore àìlẹ́tọ̀ọ́sí ó sì túbọ̀ múra síṣẹ́. Nígbà tó yá, tí àkókò oúnjẹ tó, Bóásì pe Rúùtù, ó sì sọ fún un pé: ‘Sún mọ́ ìhín, jẹ lára oúnjẹ, kí o sì tẹ èyí tí o bù bọ inú ọtí kíkan.’ Ó jẹ oúnjẹ àjẹyó ó sì mú oúnjẹ lọ́wọ́ lọ sílé fún Náómì.—Rúùtù 2:14.
Nígbà tí iṣẹ́ ọjọ́ yẹn fi máa parí, Rúùtù ti pèéṣẹ́ nǹkan bíi lítà méjìlélógún ìwọ̀n ọkà báálì. Ó gbé ọkà báálì náà àti oúnjẹ tó ṣẹ́ kù lọ sílé fún Náómì. (Rúùtù 2:15-18) Bó ṣe kó ohun púpọ̀ wálé múnú Náómì dùn gan-an, ó sì béèrè pé: “Ibo ni o ti pèéṣẹ́ lónìí? . . . Kí ẹni tí ó kíyè sí ọ di alábùkún.” Nígbà tí Náómì gbọ́ pé Bóásì ni, ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tí kò dẹ́kun inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí àwọn alààyè àti àwọn òkú. . . . Ọkùnrin náà bá wa tan. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùtúnnirà wa.”—Rúùtù 2:19, 20.
Wíwá “Ibi Ìsinmi”
Nítorí pé Náómì fẹ́ wá “ibi ìsinmi” tàbí ilé, fún aya ọmọ rẹ̀, ó lo àǹfààní bí nǹkan ṣe rí yìí láti ṣètò fún wíwá olùtúnnirà, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ọlọ́run. (Léfítíkù 25:25; Diutarónómì 25:5, 6) Wàyí o, Náómì wá kọ́ Rúùtù lọ́nà tó gbéṣẹ́ jù lọ, àní ọ̀nà pípabanbarì tó máa gbà—ìyẹn ọ̀nà kan tí Bóásì á fi gba tiẹ̀. Pẹ̀lú ìmúratán àti ìtọ́ni tó ti gbà, ọ̀gànjọ́ òru ni Rúùtù forí lé ilẹ̀ ìpakà Bóásì. Ó bá a tó ń sùn. Ó ṣí aṣọ kúrò lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì dúró dìgbà tó máa jí.—Rúùtù 3:1-7.
Nígbà tí Bóásì jí, kò sí àní-àní pé ọ̀nà tí Rúùtù gbà fàmì ṣàpèjúwe ti jẹ́ kó lóye ìdí tó fi bẹ̀ ẹ́ pé kó ‘na apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ bo ẹrúbìnrin rẹ̀.’ Ohun tí Rúùtù ṣe yìí wá jẹ́ kí bàbá àgbàlagbà ará Jùdíà náà mọ ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùtúnnirà, nítorí pé mọ̀lẹ́bí Málónì, tó jẹ́ ọkọ Rúùtù tẹ́lẹ̀ ni.—Rúùtù 3:9.
Kò retí wíwá tí Rúùtù wá lóru yìí rárá. Síbẹ̀, ohun tí Bóásì ṣe kò fi hàn pé wíwá tí Rúùtù ń wá ẹni tó máa jẹ́ olùtúnnirà jẹ́ ohun àjèjì. Bóásì sì fẹ́ wá nǹkan ṣe sí ohun tí Rúùtù béèrè.
Ohùn Rúùtù ti ní láti fi hàn pé ọ̀ràn náà ká a lára, èyí sì mú kí Bóásì fi i lọ́kàn balẹ̀ pé: “Wàyí o, ọmọbìnrin mi, má fòyà. Gbogbo ohun tí o sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ, nítorí gbogbo ẹni tí ó wà ní ẹnubodè àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin títayọ lọ́lá.”—Rúùtù 3:11.
Pé Bóásì ka ìgbésẹ̀ tí Rúùtù gbé yìí sí ìwà ọmọlúwàbí látòkèdélẹ̀ hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Alábùkún ni ìwọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ọmọbìnrin mi. Ìwọ ti fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ hàn lọ́nà tí ó dára ní ìgbà ìkẹyìn ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ.” (Rúùtù 3:10) Ní ìgbà àkọ́kọ́, Rúùtù fi inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ dídúróṣinṣin hàn sí Náómì. Ti ìgbà ìkẹyìn ni bó ṣe fi àìmọtara ẹni nìkan sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún Bóásì, tó dàgbà jù ú fíìfíì, nítorí pé ó jẹ́ olùtúnnirà. Ó múra tán láti bí ọmọ ní orúkọ Málónì, ọkọ rẹ̀ tó ti dolóògbé, àti fún Náómì.
Olùtúnnirà Kan Kọ̀ Jálẹ̀
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Bóásì pe ìbátan kan, tá a pè ní “Lágbájá,” tó bá Náómì tan ju bí Bóásì ṣe bá a tan lọ. Níṣojú àwọn aráàlú àti àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá náà, Bóásì sọ pé: ‘Mo ronú pé ó yẹ kí n sọ ọ́ di mímọ̀ fún ọ pé o lẹ́tọ̀ọ́ láti tún abá pápá kan tó jẹ́ ti Elimélékì ọkọ Náómì rà lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé obìnrin náà gbọ́dọ̀ tà á.’ Bóásì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: ‘Ṣé wàá tún un rà? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò tún un rà nígbà náà.’ Látàrí èyí, Lágbájá sọ pé òun yóò tún un rà.—Rúùtù 4:1-4.
Àmọ́ Lágbájá ò mọ̀ pé ohun tó wà lẹ́yìn ọ̀fà ju òje lọ! Bóásì wá sọ lójú gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé: “Ní ọjọ́ tí o bá ra pápá náà lọ́wọ́ Náómì, ọwọ́ Rúùtù ọmọbìnrin Móábù, aya ọkùnrin tí ó kú, ni ìwọ yóò ti rà á pẹ̀lú, láti lè gbé orúkọ ọkùnrin tí ó kú dìde lórí ogún rẹ̀.” Nítorí ìbẹ̀rù pé òun lè ba ogún ti ara òun jẹ́, Olùtúnnirà yìí pàdánù ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe àtúnrà nípa sísọ pé: “Èmi kò lè ṣe àtúnrà náà.”—Rúùtù 4:5, 6.
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ọkùnrin tó kọ̀ láti ṣe àtúnrà náà ní láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀ kó sì kó o fún ẹnì kejì rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí olùtúnnirà náà sọ fún Bóásì pé, “Rà á fún ara rẹ,” ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sálúbàtà rẹ̀. Bóásì wá sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin àti gbogbo ènìyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Élímélékì àti gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Kílíónì àti Málónì láti ọwọ́ Náómì. Àti pẹ̀lú, Rúùtù ọmọbìnrin Móábù, aya Málónì, ni mo rà fún ara mi gẹ́gẹ́ bí aya láti gbé orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà dìde lórí ogún rẹ̀ . . . Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”—Rúùtù 4:7-10.
Gbogbo ènìyàn tó wà ní ẹnubodè náà sì sọ fún Bóásì pé: “Kí Jèhófà yọ̀ǹda kí aya tí ń bọ̀ wá sínú ilé rẹ dà bí Rákélì àti bí Léà, àwọn méjèèjì tí wọ́n kọ́ ilé Ísírẹ́lì; kí ìwọ sì fi ẹ̀rí ìníyelórí rẹ hàn ní Éfúrátà, kí o sì ṣe orúkọ tí ó gba àfiyèsí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”—Rúùtù 4:11, 12.
Pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe súre yẹn, Bóásì mú Rúùtù ṣaya. Ó bí ọmọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Óbédì fún un, Rúùtù àti Bóásì sì tipa bẹ́ẹ̀ di baba ńlá àti ìyá ńlá fún Dáfídì Ọba àti fún Jésù Kristi níkẹyìn.—Rúùtù 4:13-17; Mátíù 1:5, 6, 16.
“Owó Ọ̀yà Pípé”
Látìbẹ̀rẹ̀ dópin ìtàn náà, látorí bó ṣe máa ń kọ́kọ́ fi inúure kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ títí dórí bó ṣe tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ ṣíṣàì jẹ́ kí orúkọ ìdílé Elimélékì pa rẹ́ ni Bóásì fẹ̀rí hàn pé ọkùnrin títayọ lọ́lá lòun—akíkanjú ọkùnrin táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi. Bákan náà, ó jẹ́ ọkùnrin tó ní ìkóra ẹni níjàánu, tó nígbàgbọ́, tó sì pa ìwà títọ́ mọ́. Bóásì tún jẹ́ ọ̀làwọ́, onínúure, oníwà mímọ́, ó sì ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà láìkù síbì kankan.
Rúùtù náà ta yọ nínú ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà, nínú ìfẹ́ ìdúróṣinṣin tó ní fún Náómì, àti bó ṣe jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn àti onírẹ̀lẹ̀. Abájọ táwọn èèyàn fi kà á sí “obìnrin títayọ lọ́lá.” Kó jẹ “oúnjẹ ìmẹ́lẹ́,” iṣẹ́ àṣekára tó ṣe sì jẹ́ kó láǹfààní láti pèsè fún ìyá ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìní. (Òwe 31:27, 31) Bí Rúùtù ṣe tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ títọ́jú Náómì yẹn ti ní láti jẹ́ kó rí ayọ̀ tó ń wá látinú fífúnni.—Ìṣe 20:35; 1 Tímótì 5:4, 8.
Àwọn àpẹẹrẹ rere mà pọ̀ nínú ìwé Rúùtù inú Bíbélì o! Jèhófà ò gbàgbé Náómì. Rúùtù gba “owó ọ̀yà pípé” gẹ́gẹ́ bí ìyá ńlá Jésù Kristi. A fi “obìnrin títayọ lọ́lá” jíǹkí Bóásì. Àwa náà rí àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tá a lè tẹ̀ lé lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ó Fúnni Nírètí
Tó o bá ti fìgbà kan ronú pé àwọn àkókò àìláyọ̀ lò ń gbé, ìtàn Rúùtù lè fún ọ nírètí. Ó ta yọ gẹ́gẹ́ bí ìtàn pàtàkì tó kẹ́yìn ìwé Àwọn Onídàájọ́. Ìwé Rúùtù sọ nípa bí Jèhófà ṣe lo opó rírẹlẹ̀ kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Móábù tó jẹ́ ilẹ̀ òkèèrè nínú mímú ọba kan jáde fún àwọn èèyàn rẹ̀. Pẹ̀lú báwọn ìtàn inú ìwé Àwọn Onídàájọ́ ṣe rí, ńṣe ni ìgbàgbọ́ Rúùtù tàn bí ìmọ́lẹ̀ sànmánì yẹn.
Nípa kíka ìtàn Rúùtù, o lè ní ìdánilójú pé bó ti wù kí ipò nǹkan le koko fún èèyàn tó, Ọlọ́run máa ń bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ.