Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó “Ń Bá A Lọ Ní Dídàgbà Lọ́dọ̀ Jèhófà”
SÁMÚẸ́LÌ wo ojú àwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà kóra jọ sí ìlú Gílígálì. Ọkùnrin olóòótọ́ yìí tó ti ṣe wòlíì àti onídàájọ́ wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún ló pè wọ́n jọ síbẹ̀. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti bẹ̀rẹ̀ lákòókò náà, oṣù May tàbí June ni àkókò náà bọ́ sí nínú kàlẹ́ńdà òde òní. Àlìkámà tó wà nínú pápá ní agbègbè náà ti gbó fún kíkórè. Kẹ́kẹ́ pa bí àwọn èèyàn náà ṣe dúró. Báwo ni ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì ṣe máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn?
Àwọn èèyàn náà kò mọ bí ipò wọn ti burú tó. Wọ́n fi dandan lé e pé àwọn ń fẹ́ èèyàn tó máa jẹ́ ọba táá máa ṣàkóso lé àwọn lórí. Wọn kò mọ̀ pé àwọn kò bọ̀wọ̀ rárá fún Jèhófà Ọlọ́run wọn àti fún wòlíì rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n tipa báyìí kọ Jèhófà ní Ọba wọn! Kí ni Sámúẹ́lì máa ṣe káwọn èèyàn yìí lè ronú pìwà dà?
Sámúẹ́lì sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pé, “Mo ti darúgbó.” Ewú orí rẹ̀ mú kí ọ̀rọ̀ tó sọ lágbára sí i. Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Èmi sì ti rìn níwájú yín láti ìgbà èwe mi títí di òní yìí.” (1 Sámúẹ́lì 11:14, 15; 12:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì ti darúgbó, kò gbàgbé ìgbà èwe rẹ̀. Ó ṣì ń rántí rẹ̀ dáadáa. Àwọn ìpinnu tó ṣe nígbà tó wà léwe ti mú kó lo ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó fi ìgbàgbọ́ hàn nínú Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀, ó sì tún mú kó jẹ́ olùfọkànsìn.
Léraléra ni Sámúẹ́lì ń mú kí ìgbàgbọ́ tó ní máa lágbára sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn tí kò nígbàgbọ́ tí wọ́n sì jẹ́ aláìdúróṣinṣin ló ń gbé. Lónìí, ó ṣòro láti ní ìgbàgbọ́ nítorí à ń gbé nínú ayé aláìnígbàgbọ́ tó ti bàjẹ́ bàlùmọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tó ti wà lọ́mọdé.
Ó “Ń Ṣe Ìránṣẹ́ Níwájú Jèhófà, Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọdékùnrin”
Ìgbà èwe Sámúẹ́lì ṣàrà ọ̀tọ̀. Kété lẹ́yìn tí wọ́n já a lẹ́nu ọmú, bóyá ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ìsìn ní àgọ́ ìjọsìn mímọ́ Jèhófà tó wà ní Ṣílò, ìyẹn sì fi nǹkan tó lé ní ọgbọ̀n kìlómítà jìn sí ilé rẹ̀ ní Rámà. Ẹlikénà àti Hánà tí wọ́n jẹ́ òbí rẹ̀ ya ọmọ wọn sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn kan, pé kó jẹ́ Násírì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.a Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn òbí Sámúẹ́lì pa á tì, tí wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn ni?
Rárá o! Wọ́n mọ̀ pé ọmọ wọn á rí ìtọ́jú ní Ṣílò. Kò sí àní-àní pé Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà bójú tó ọ̀ràn náà, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni Sámúẹ́lì ti ṣiṣẹ́. Àwọn obìnrin kan tún wà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìjọsìn, tó sì dájú pé ètò wà fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.—Ẹ́kísódù 38:8.
Síwájú sí i, Hánà àti Ẹlikénà kò jẹ́ gbàgbé ààyò ọmọ tó jẹ́ àkọ́bí wọn yìí, ẹni tó jẹ́ pé òun ni Ọlọ́run fi dáhùn àdúrà wọn. Nígbà kan, Hánà bẹ Ọlọ́run pé kó fún òun ní ọmọkùnrin kan, ó sì ṣèlérí pé òun á yọ̀ǹda ọmọ náà fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Lọ́dọọdún tí Hánà bá lọ sí àgọ́ ìjọsìn, ó máa ń mú aṣọ tí kò lápá tó hun lọ fún Sámúẹ́lì kó lè máa fi ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìjọsìn. Ó dájú pé ọmọdékùnrin yìí mọrírì bí màmá rẹ̀ ṣe máa ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìṣírí onífẹ̀ẹ́ àti ìtọ́sọ́nà àwọn òbí rẹ̀ ti ràn án lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó bí wọ́n ti kọ́ ọ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti sin Jèhófà ní ibi tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.
Lónìí, àwọn òbí lè kọ́ ohun púpọ̀ lára Hánà àti Ẹlikénà. Ohun táwọn òbí máa ń gbájú mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ àwọn ọmọ ni bí wọ́n ṣe máa pèsè ohun ìní tara fún wọn, tí wọ́n á sì wá pa ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tì. Ṣùgbọ́n ìjọsìn Ọlọ́run làwọn òbí Sámúẹ́lì fi ṣe ohun àkọ́kọ́, ìyẹn sì kó ipa pàtàkì lórí irú ẹni tí ọmọ wọn dà nígbà tó dàgbà.—Òwe 22:6.
Ẹ fojú inú wo bí ọmọdékùnrin náà ṣe ń dàgbà, tó sì ń lọ káàkiri àwọn òkè kéékèèké tó wà lágbègbè Ṣílò. Bí ó ti ń wo ìlú àtàwọn àlàfo tó wà láàárín àwọn òkè, ó ṣeé ṣe kí inú rẹ̀ máa dùn gan-an nígbà tó rí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ó sì ń fi yangàn. Ibi mímọ́ ni àgọ́ ìjọsìn jẹ́.b Nǹkan bí irinwó [400] ọdún ni wọ́n ti kọ́ ilé yìí lábẹ́ ìdarí Mósè, òun sì ni ojúkò ìjọsìn mímọ́ Jèhófà ní gbogbo ayé.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni Sámúẹ́lì, ó wá fẹ́ràn àgọ́ ìjọsìn gan-an. Nígbà tó yá, nínú ìwé tí Sámúẹ́lì kọ, ó sọ pé: “Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin kan, ó sán éfódì aṣọ ọ̀gbọ̀.” (1 Sámúẹ́lì 2:18) Láìsí àní-àní, aṣọ tí kò lápá tí Sámúẹ́lì máa ń wọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ó ń ran àwọn àlùfáà lọ́wọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì kì í ṣe àlùfáà, lára iṣẹ́ rẹ̀ ni pé kó ṣí ilẹ̀kùn àgbàlá àgọ́ ìjọsìn ní òwúrọ̀, kó sì ṣèránṣẹ́ fún Élì tó ti dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gbádùn àǹfààní yìí, àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdààmú ọkàn. Ohun burúkú kan ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé Jèhófà.
Ó Jẹ́ Oníwàmímọ́ Láìka Ìwà Ìbàjẹ́ Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Sí
Nígbà tó wà lọ́mọdé, Sámúẹ́lì rí bí ìwà ìkà àti ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń hù ti pọ̀ tó. Élì ní ọmọkùnrin méjì, orúkọ wọn ni Hófínì àti Fíníhásì. Nínú ìwé tí Sámúẹ́lì kọ, ó sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ aláìdára fún ohunkóhun; wọn kò ka Jèhófà sí.” (1 Sámúẹ́lì 2:12) Kókó méjì wà nínú ẹsẹ yìí tó tan mọ́ra wọn. Hófínì àti Fíníhásì jẹ́ “aláìdára fún ohunkóhun,” tó túmọ̀ sí “àwọn ọmọ tí kò wúlò fún nǹkan kan” nítorí wọn kò ka Jèhófà sí rárá. Wọn kì í ronú nípa ìlànà òdodo Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́. Èyí ló fa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yòókù tí wọ́n dá.
Òfin Ọlọ́run sọ ojúṣe àwọn àlùfáà ní pàtó àti ọ̀nà tí wọ́n á gbà máa rú ẹbọ nínú àgọ́ ìjọsìn. Ìyẹn sì yẹ bẹ́ẹ̀! Àwọn ẹbọ wọ̀nyẹn dúró fún àwọn ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn kí wọ́n bàa lè mọ́ lójú Ọlọ́run, kí wọ́n sì lè rí ìbùkún àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ṣùgbọ́n Hófínì àti Fíníhásì kó àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà ṣìnà, gbogbo wọn sì ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọrẹ ẹbọ.c
Fojú inú wo Sámúẹ́lì tó ń wo irú ìwà burúkú yẹn, tí ẹnì kankan kò sì ṣàtúnṣe rẹ̀. Ẹ wo bí iye àwọn èèyàn tó rí ti pọ̀ tó, tó fi mọ́ àwọn tálákà, àwọn ẹni rírẹlẹ̀, àwọn ẹni tójú ń pọ́n, tí wọ́n ń wá sí àgọ́ ìjọsìn mímọ́ kí wọ́n lè rí ìtura àti okun tẹ̀mí gbà, àmọ́ tó jẹ́ pé ìjákulẹ̀, ìpalára tàbí ìfojú-ẹni-gbolẹ̀ ni wọ́n ń bá kúrò níbẹ̀! Báwo ló sì ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé Hófínì àti Fíníhásì tún ṣàìbọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn kan lára àwọn obìnrin tí wọ́n ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn lò pọ̀? (1 Sámúẹ́lì 2:22) Ó ṣeé ṣe kó máa retí pé kí Élì ṣe ohun kan nípa ọ̀ràn náà.
Élì ló yẹ kó bójú tó ìṣòro tó ń peléke sí i yìí. Nítorí pé òun ni àlùfáà àgbà, òun ló máa dáhùn fún ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ìjọsìn náà. Òun ni bàbá àwọn ọmọ náà, òun ló sì yẹ kó tọ́ wọn sọ́nà. Ó ṣe tán, wọ́n ń pa ara wọn lára, wọ́n sì tún ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn míì lára ní ilẹ̀ náà. Àmọ́, Élì kò ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá àti àlùfáà àgbà. Ńṣe ló kàn bá wọn wí lọ́nà yọ̀bọ́kẹ́. (1 Sámúẹ́lì 2:23-25) Àmọ́ ìbáwí tó le gan-an ni àwọn ọmọ náà nílò. Ẹ̀ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú ni wọ́n ń dá!
Ọ̀ràn burú débi tí Jèhófà fi rán “èèyàn Ọlọ́run,” ìyẹn wòlíì kan tí a kò dárúkọ rẹ̀ pé kó lọ jíṣẹ́ ìdájọ́ tó lágbára fún Élì. Jèhófà sọ fún Élì pé: “O . . . ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí.” Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ kan náà làwọn ọmọ burúkú tí Élì bí máa kú àti pé ìdílé Élì yóò jìyà gan-an, wọn á tún pàdánù àǹfààní jíjẹ́ àlùfáà. Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ tó lágbára yìí mú kí nǹkan yí pa dà nínú ìdílé náà? Ìtàn náà sọ pé wọn kò yí ọkàn wọn pa dà.—1 Sámúẹ́lì 2:27–3:1.
Ipa wo làwọn ìwà ìbàjẹ́ yìí ní lórí Sámúẹ́lì? Láìka bí ìtàn yìí ti bani nínú jẹ́ tó, ìròyìn rere nípa bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà tó sì ń tẹ̀ síwájú ń fúnni láyọ̀. Rántí pé ní 1 Sámúẹ́lì 2:18, a kà nípa Sámúẹ́lì pé ó fi ìṣòtítọ́ “ṣe ìránṣẹ́ níwájú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin.” Àní bí Sámúẹ́lì ṣe kéré tó yẹn, ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ohun kan tó túbọ̀ ń mú ọkàn yọ̀ wà ní orí kan náà yẹn, ní ẹsẹ 21, ó ní: “Ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì sì ń bá a lọ ní dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà.” Bó ṣe ń dàgbà, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ ọ̀run ń lágbára sí i. Àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà yìí ló jẹ́ ààbò tó lágbára jù lọ tí kò jẹ́ kí ìwà ìbàjẹ́ èyíkéyìí ní ipa kankan lórí rẹ̀.
Ì bá rọrùn fún Sámúẹ́lì láti sọ pé bí àlùfáà àgbà àtàwọn ọmọ rẹ̀ bá jọ̀wọ́ ara wọn fún ẹ̀ṣẹ̀, òun náà lè ṣe ohun tó wu òun. Àmọ́, ìwà ìbàjẹ́ àwọn èèyàn, títí kan àwọn tó wà nípò àṣẹ, kì í ṣe àwáwí láti dẹ́sẹ̀. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn èwe Kristẹni ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì, tí wọ́n sì ń bá a lọ ní “dídàgbà lọ́dọ̀ Jèhófà,” kódà nígbà táwọn tó yí wọn ká kò fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.
Báwo ni ọ̀nà tí Sámúẹ́lì tọ̀ ṣe jẹ́ kó ṣàṣeyọrí? A kà pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” (1 Sámúẹ́lì 2:26) Nítorí náà, wọ́n fẹ́ràn Sámúẹ́lì gan-an, ó kéré tán, àwọn tó wà nípò àṣẹ. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ọmọdékùnrin yìí nítorí pé ó ń ṣe ohun tó tọ́. Sámúẹ́lì sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run yóò ṣe nǹkan kan sí ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ṣílò, àmọ́ ó lè máa ṣe kàyéfì pé, ìgbà wo ló máa jẹ́?
“Sọ̀rọ̀, Nítorí Tí Ìránṣẹ́ Rẹ Ń Fetí Sílẹ̀”
Lálẹ́ ọjọ́ kan, Sámúẹ́lì rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn rẹ̀. Ilẹ̀ tí fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́, iná fìtílà ńlá tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn náà ṣì ń jó lọ́úlọ́ú. Bí gbogbo nǹkan ṣe pa rọ́rọ́, Sámúẹ́lì gbọ́ ohùn kan tó ń pe orúkọ rẹ̀. Ó rò pé Élì tó ti darúgbó tí ojú rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ríran mọ́ ló ń pe òun. Sámúẹ́lì dìde, ó sì “sáré lọ” bá bàbá arúgbó yìí. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ọmọ yìí ṣe ń sáré lọ láì wọ bàtà kó lè lọ wo ohun tí Élì nílò? Ó dùn mọ́ni nínú pé Sámúẹ́lì fi ọ̀wọ̀ àti inú rere bá Élì lò. Láìka gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Élì ṣẹ̀ sí, òun ṣì ni wòlíì àgbà fún Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 3:2-5.
Sámúẹ́lì jí Élì, ó sọ pé: “Èmi nìyí, nítorí tí ìwọ pè mí.” Àmọ́ Élì sọ pé òun kò pè é, ó sì ní kí ọmọdékùnrin náà pa dà lọ sùn. Síbẹ̀, léraléra ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀! Níkẹyìn, Élì mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Nígbà yẹn, ó ṣọ̀wọ́n kí Jèhófà ṣí ìran tàbí àsọtẹ́lẹ̀ payá fún àwọn èèyàn rẹ̀, ìdí tí ìyẹn sì fi rí bẹ́ẹ̀ kò fara sin. Àmọ́ ní báyìí, Élì mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ́ ṣí nǹkan payá, ọmọdékùnrin yìí ló sì fẹ́ sọ nǹkan náà fún! Élì sọ fún Sámúẹ́lì pé, kó pa dà lọ sùn, ó sì kọ́ ọ bó ṣe máa dáhùn lọ́nà tó yẹ. Sámúẹ́lì ṣègbọràn. Kò sì pẹ́ tó fi gbọ́ ohùn náà tó ń ké sí i pé: “Sámúẹ́lì, Sámúẹ́lì!” Ọmọdékùnrin náà dáhùn pé: “Sọ̀rọ̀, nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 3:1, 5-10.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà ní ìránṣẹ́ kan ní Ṣílò tó ń fetí sílẹ̀. Sámúẹ́lì sì wá dẹni tó ń fetí sí ohùn Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ṣé ìwọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀? A kò nílò pé kí ohùn kan bá wa sọ̀rọ̀ láti ọ̀run ní òru. Lónìí, ìgbà gbogbo ni ohùn Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀. Ó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bá a bá ṣe ń fetí sí Ọlọ́run tó, tí a sì ń ṣègbọràn, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa á ṣe máa pọ̀ sí i. Bó ṣe rí fún Sámúẹ́lì nìyẹn.
Alẹ́ ọjọ́ yẹn ní Ṣílò jẹ́ àkókò pàtàkì nínú ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, nítorí láti ọjọ́ yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà, tó sì wá di wòlíì Ọlọ́run àti agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ọmọdékùnrin yìí ń bẹ̀rù láti jíṣẹ́ Jèhófà fún Élì, nítorí ohun tó fẹ́ sọ jẹ́ ìkéde pé àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí ìdílé náà máa tó ní ìmúṣẹ. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì lo ìgboyà, Élì náà sì fìrẹ̀lẹ̀ gba ìdájọ́ Ọlọ́run láìjanpata. Kò pẹ́ kò jìnnà, tí gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fi ṣẹ pátá. Àwọn Filísínì gbógun ja àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì pa Hófínì àti Fíníhásì lọ́jọ́ kan náà. Élì náà sì kú nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti gba Àpótí mímọ́ ti Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 3:10-18; 4:1-18.
Àmọ́, ńṣe láwọn èèyàn túbọ̀ ń mọ Sámúẹ́lì sí i gẹ́gẹ́ bíi wòlíì olóòótọ́. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,” ó tún sọ pé, Jèhófà sì rí sí i pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Sámúẹ́lì sọ ló ní ìmúṣẹ.—1 Sámúẹ́lì 3:19.
“Sámúẹ́lì Ké Pe Jèhófà”
Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì tó jẹ́ aṣáájú wọn, tí wọ́n sì di olóòótọ́ èèyàn tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run? Rárá o. Nígbà tó yá, wọ́n pinnu pé àwọn kò fẹ́ kí wòlíì máa ṣe onídàájọ́ àwọn. Wọ́n fẹ́ kí èèyàn tó jẹ́ ọba máa ṣàkóso lé àwọn lórí bíi tàwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Sámúẹ́lì gbà fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe darí ọ̀ràn náà. Àmọ́, ó ní láti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti lágbára tó. Jèhófà gan-an ni wọ́n kọ̀, kì í ṣe ẹni tó ń ṣojú fún un! Nítorí náà, ó pe àwọn èèyàn náà jọ sí Gílígálì.
Ẹ jẹ́ ká dara pọ̀ mọ́ Sámúẹ́lì nínú ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ tó fẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ní Gílígálì. Ibẹ̀ ni Sámúẹ́lì tó ti darúgbó ti rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí bó ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lákòókò iṣẹ́ ìsìn tó fi ìṣòtítọ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, a kà pé: “Sámúẹ́lì ké pe Jèhófà.” Ó sì ní kí Jèhófà jẹ́ kí ààrá sán.—1 Sámúẹ́lì 12:17, 18.
Ààrá kẹ̀? Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn? Họ́wù, a kò gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí! Bí àwọn èèyàn náà bá tiẹ̀ rò pé nǹkan tí ò lè ṣẹlẹ̀ ni tàbí tí wọ́n bá ń ṣe yẹ̀yẹ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Lójijì, ojú ọ̀run ṣú. Afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́, ó sì gbé àwọn àlìkámà ṣubú nínú pápá. Ààrá san lọ́nà tó rinlẹ̀. Òjò sì rọ̀. Kí ni àwọn èèyàn náà ṣe? “Àwọn ènìyàn náà . . . bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti burú tó.—1 Sámúẹ́lì 12:18, 19.
Jèhófà Ọlọ́run Sámúẹ́lì ló ṣe ohun tó wọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí lọ́kàn kì í ṣe Sámúẹ́lì. Láti ìgbà èwe Sámúẹ́lì títí di ìgbà tó darúgbó ló fi ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run rẹ̀. Jèhófà sì san èrè fún un. Títí dòní, Jèhófà kò yí pa dà. Ó ṣì jẹ́ alátìlẹyìn àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Sámúẹ́lì.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ara ẹ̀jẹ́ tí àwọn Násírì máa ń jẹ́ ni pé, àwọn kò ní mu ọtí èyíkéyìí, àwọn kò sì ní gé irun àwọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí fún sáà àkókò kan, àmọ́ gbogbo ọjọ́ ayé wọn làwọn kan bíi Sámúsìnì, Sámúẹ́lì àti Jòhánù Oníbatisí fi jẹ́ Násírì.
b Ibùjọsìn jẹ́ àgọ́ ńlá tó ní igun mẹ́rin, igi ni wọ́n fi gbé e ró. Àmọ́, àwọn ohun èlò bí awọ séálì, àwọn aṣọ tí wọ́n kó iṣẹ́ ọ̀nà sí àtàwọn igi olówó gọbọi tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà bò ni wọ́n fi ṣe é. Ibùjọsìn náà wà láàárín àgbàlá onígun mẹ́rin, pẹpẹ ìrúbọ kan tó gbàfiyèsí sì wà níbẹ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n kọ́ àwọn yàrá míì sí ẹ̀gbẹ́ àgọ́ ìjọsìn náà fún ìlò àwọn àlùfáà. Ó jọ pé ọ̀kan lára àwọn yàrá yẹn ni Sámúẹ́lì ń sùn.
c Ìtàn yìí jẹ́ ká mọ ìwà àìlọ́wọ̀ méjì tí wọ́n hù. Àkọ́kọ́ ni pé, Òfin sọ ní pàtó ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn àlùfáà lára ọrẹ ẹbọ. (Diutarónómì 18:3) Àmọ́ ní àgọ́ ìjọsìn náà, àwọn àlùfáà burúkú ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó yàtọ̀. Ńṣe ni wọ́n máa ń sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé kí wọ́n ki àmúga bọ ẹran tó ń hó lọ́wọ́ nínú ìkòkò, tí wọ́n á sì mú èyí tí ó bá gbé jáde! Ohun kejì ni pé, nígbà táwọn èèyàn bá mú ẹbọ tí wọ́n fẹ́ sun lórí pẹpẹ wá, àwọn àlùfáà burúkú náà á ní káwọn ìránṣẹ́ àwọn fúngun mọ́ àwọn tó mú ohun ìrúbọ wá, pé kí wọ́n fún àwọn ní ẹran tútù, kí wọ́n tiẹ̀ tó fi ọ̀rá rúbọ sí Jèhófà pàápàá.—Léfítíkù 3:3-5; 1 Sámúẹ́lì 2:13-17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Láìka ẹ̀rù tó ń ba Sámúẹ́lì sí, ó ṣì fi ìṣòtítọ́ sọ ìdájọ́ Jèhófà fún Élì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Sámúẹ́lì fí ìgbàgbọ́ gbàdúrà, Jèhófà sì fi ààrá dá a lóhùn