Ẹ̀KỌ́ 50
Jèhófà Gbèjà Jèhóṣáfátì
Jèhóṣáfátì ọba Júdà wó gbogbo pẹpẹ tí àwọn èèyàn ti ń bọ òrìṣà Báálì ní ilẹ̀ náà. Ó fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òfin Jèhófà, torí náà ó rán àwọn ọmọ aládé àti àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n máa kọ́ gbogbo àwọn èèyàn Júdà ní òfin Jèhófà.
Torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà, ẹ̀rù máa ń ba àwọn ọ̀tá láti wá gbéjà kò wọ́n. Kódà, ńṣe ni wọ́n máa ń kó ẹ̀bùn wá fún Jèhóṣáfátì Ọba. Àmọ́, àwọn ọmọ Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn kan láti àgbègbè Séírì wá bá àwọn èèyàn Júdà jagun. Jèhóṣáfátì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè ran àwọn lọ́wọ́. Ó wá pe gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin àti àwọn ọmọ kékeré pé kí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù. Òun náà wá dúró síwájú wọn, ó sì bẹ̀rẹ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: ‘Jèhófà, láìjẹ́ pé ó ràn wá lọ́wọ́, a kò lè borí àwọn èèyàn yìí. Jọ̀wọ́ sọ ohun tá a máa ṣe fún wa.’
Jèhófà wá dahùn àdúrà wọn, ó ní: ‘Ẹ má fòyà. Màá ràn yín lọ́wọ́. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí i bí màá ṣe gbà yín là.’ Báwo ni Jèhófà ṣe gbà wọ́n?
Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ kejì, Jèhóṣáfátì yan àwọn akọrin, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa kọrin lọ níwájú àwọn ọmọ ogun. Báwọn ọmọ ogun ṣe ń yan tẹ̀ lé wọn nìyẹn títí wọ́n fi dé ojú ogun níbì kan tí wọ́n ń pè ní Tékóà.
Ńṣe ni ohùn àwọn akọrin ń dún gan-an bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà, Jèhófà sì gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. Ó da àárín àwọn ọmọ ogun Ámónì àti Móábù rú débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ra wọn jà, tí wọ́n sì pa ara wọn tán pátápátá. Àmọ́ Jèhófà dáàbò bo àwọn èèyàn Júdà, àwọn ọmọ ogun wọn àti àwọn àlùfáà. Gbogbo àwọn ìlú tó wà ní àgbègbè wọn ló gbọ́ nípa ohun tí Jèhófà ṣe, èyí jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà ló ń gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ là? Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń ṣe. Àmọ́ Jèhófà kò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.
“Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí. Ẹ mú ìdúró yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà fún yín.”—2 Kíróníkà 20:17