ORÍ KÌÍNÍ
“Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi Sí Ẹnu Rẹ”
1, 2. Kí nìdí tó o fi lè gba gbogbo ohun tó o bá kà nínú Bíbélì gbọ́?
“Ọ̀RẸ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) Ǹjẹ́ o ti ní irú ọ̀rẹ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yìí rí? Tí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ bá sọ nǹkan kan fún ọ, bóyá ni wàá ṣiyè méjì nípa rẹ̀. Tó bá sọ pé nǹkan kan dáa tàbí ó sọ ohun tóun máa ṣe, o máa ń gbà á gbọ́. Tó bá sọ pé kó o ṣàtúnṣe lórí ohun kan, bóyá ni wàá kọ̀ sí i lẹ́nu. Ìdí ni pé ó jẹ́ ẹni tó o ti mọ̀ látìgbà pípẹ́ pé ire rẹ jẹ ẹ́ lógún, àní tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe ló ń bá ọ wí lórí ohun kan. Bí nǹkan ṣe máa dáa fún ọ ló ń wá. Ìwọ náà sì ń wá bí nǹkan ṣe máa dáa fún un, kẹ́ ẹ lè jọ máa bá ọ̀rẹ́ yín lọ.
2 Ẹ̀rí fi hàn pé irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn tí Ọlọ́run lò láti kọ àwọn ìwé inú Bíbélì jẹ́ sí wa. Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún wa la lè gbà gbọ́. Ó dájú pé ohunkóhun tí wọ́n bá sọ máa ṣe wá láǹfààní. Irú ojú yẹn ló sì yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà àtijọ́ fi wo “àwọn ènìyàn [tí wọ́n] sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pét. 1:20, 21) Ara àwọn tó kọ Bíbélì ni Jeremáyà, ẹni tí Ọlọ́run mú kí ó kọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó gùn jù lọ, ìyẹn ìwé Jeremáyà, òun náà ló kọ ìwé Ìdárò àti ìwé méjì míì nínú Bíbélì.
3, 4. Kí ni èrò àwọn kan nípa ìwé Jeremáyà àti Ìdárò, àmọ́ kí nìdí tí èrò wọn yìí kò fi tọ̀nà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
3 Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí pé àwọn kan lára àwọn tó ń ka Bíbélì kì í fẹ́ ka àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ nítorí wọ́n sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò bá àwọn lára mu. Bóyá èrò wọn ni pé àwọn ìkìlọ̀ nípa àjálù àti àsọtẹ́lẹ̀ tó ń bani nínú jẹ́ nìkan ló kún inú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò.a Àmọ́ ṣé bí ìwé Jeremáyà àti Ìdárò ṣe rí nìyẹn lóòótọ́?
4 Òótọ́ ni pé ìbáwí àti ìkìlọ̀ tó ṣe ṣàkó wà nínú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ, àmọ́ bí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ṣe máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nígbà míì náà nìyẹn. Jésù pàápàá kò pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn àpọ́sítélì, nígbà tí wọ́n hùwà tí kò dáa, ó bá wọn wí gidigidi. (Máàkù 9:33-37) Síbẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ Jésù ló kún fún ẹ̀kọ́. Ó ń kọ́ni béèyàn ṣe lè rí ojú rere Ọlọ́run kéèyàn sì jẹ́ ara àwọn aláyọ̀ tó máa jogún Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 5:3-10, 43-45) Bí àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ ṣe rí náà nìyẹn, torí wọ́n jẹ́ ara “gbogbo Ìwé Mímọ́” tó ṣàǹfààní fún “mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tím. 3:16) Lóòótọ́, Jeremáyà kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Jèhófà àmọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni tó yẹ kó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìrètí tó sì ń jẹ́ ká mọ bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa dára ló wà nínú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò. Jeremáyà tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ń bọ̀ wá ṣe fún àwọn èèyàn Rẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì kàn wá lóde òní. Yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ tó tuni nínú tó sì gbéni ró tún wà nínú ìwé méjèèjì yìí.—Ka Jeremáyà 31:13, 33; 33:10, 11; Ìdárò 3:22, 23.
5. Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ látinú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ?
5 Láti lè láyọ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run kí á sì nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, a ní láti tẹ̀ lé ohun tí Jeremáyà kọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí kárí ayé. Àwọn ohun tó kọ yóò mú ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìṣọ̀kan yẹn túbọ̀ lágbára sí i, á sì jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, èyí tó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, ní gbígba ìtọ́sọ́nàpadà, ní gbígba ìtùnú, ní ríronú ní ìfohùnṣọ̀kan, ní gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà; Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (2 Kọ́r. 13:11) Ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ tún dà bí ohun táwa náà ń wàásù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn fáwọn èèyàn, tá a sì ń kìlọ̀ fún wọn nípa òpin ayé tó sún mọ́lé, ìhìn tó ń múnú ẹni dùn tó sì ń fúnni nírètí ni ìwàásù wa dá lé. Yàtọ̀ sí èyí, ohun tí Jeremáyà kọ wúlò fún wa gan-an nígbèésí ayé. A rí ọ̀pọ̀ ohun tó jọra pẹ̀lú tiwa nínú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i àtàwọn nǹkan tó sọ. Ká lè lóye ohun tá à ń sọ yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ìgbésí ayé àti iṣẹ́ ìsìn wòlíì àwòfiṣàpẹẹrẹ yìí ṣe rí látilẹ̀ wá. Òun ni Ọlọ́run sọ fún pé: “Kíyè sí i, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ.”—Jer. 1:9.
6, 7. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí Jeremáyà, báwo sì ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n bí i?
6 Ìgbà gbogbo ni aya kan tó lóyún àti ọkọ rẹ̀ sábà máa ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la ọmọ tí wọ́n máa bí ṣe máa rí. Irú èèyàn wo ló máa jẹ́, kí ló máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, ìyẹn ohun tó máa nífẹ̀ẹ́ sí, iṣẹ́ tó máa ṣe nígbèésí ayé àti ohun tó máa gbé ṣe láyé? Àwọn òbí tìrẹ náà á ti ro irú nǹkan báwọ̀nyí rí. Irú ohun táwọn òbí Jeremáyà náà á sì ti ṣe nìyẹn. Àmọ́, ọ̀ràn tiẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run dìídì nífẹ̀ẹ́ sí ìgbésí ayé Jeremáyà àtàwọn ìgbòkègbodò rẹ̀.—Ka Jeremáyà 1:5.
7 Àní kí wọ́n tó bí Jeremáyà, Ọlọ́run tó mọ ọjọ́ iwájú ti rí i pé ó jẹ́ ẹni tó máa lè ṣe wòlíì. Ó dìídì nífẹ̀ẹ́ sí ọmọkùnrin yìí tí wọ́n máa bí sínú ìdílé àlùfáà kan tó ń gbé ní àríwá ìlú Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn sì jẹ́ ní àárín ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí nǹkan ò fara rọ ní Júdà nítorí ìṣàkóso Mánásè Ọba burúkú. (Wo ojú ìwé 19.) Ohun tó burú lójú Jèhófà ni Mánásè ń ṣe ní èyí tó pọ̀ jù nínú ọdún márùndínlọ́gọ́ta tó fi ṣàkóso. Ìwà kan náà ni Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ hù. (2 Ọba 21:1-9, 19-26) Àmọ́, àyípadà ńlá dé nígbà tí ọba míì jẹ ní Júdà, ìyẹn Jòsáyà. Jòsáyà Ọba yìí wá Jèhófà ní tiẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún kejìdínlógún ìjọba Jòsáyà, ó ti mú kí ìbọ̀rìṣà kásẹ̀ nílẹ̀ ní Júdà. Ó dájú pé èyí á dùn mọ́ àwọn òbí Jeremáyà nínú gan-an. Ìgbà ìṣàkóso Jòsáyà yìí ni Ọlọ́run sọ ọmọ wọn di wòlíì.—2 Kíró. 34:3-8.
Kí nìdí tó fi yẹ kó wù ọ́ láti ṣàyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti Ìdárò?
ỌLỌ́RUN YAN AGBỌ̀RỌ̀SỌ KAN
8. Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run yàn fún Jeremáyà, báwo ló sì ṣe rí lára Jeremáyà?
8 A ò mọ ọjọ́ orí Jeremáyà nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé: “Wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè ni mo fi ọ́ ṣe.” Bóyá yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ìyẹn ọdún táwọn àlùfáà kọ́kọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn. (Núm. 8:24) Àmọ́, ohun tí Jeremáyà fi fèsì ni pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” (Jer. 1:6) Jeremáyà lọ́ tìkọ̀, torí ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé òun kéré sí ẹni tó ń ṣe irú iṣẹ́ ńlá yẹn àti pé òun ò tún lágbaja àtimáa báwùjọ èèyàn sọ̀rọ̀ bí àwọn wòlíì ṣe máa ń ṣe.
9, 10. Báwo ni nǹkan ṣe rí lákòókò tí Jeremáyà di wòlíì, àmọ́ kí nìdí tí iṣẹ́ náà fi gba ìgboyà nígbà tó yá?
9 Àkókò tí Jòsáyà Ọba ń fòpin sí ìbọ̀rìṣà tó sì ń mú kí ìjọsìn tòótọ́ gbilẹ̀ ni Ọlọ́run sọ Jeremáyà di wòlíì. A ò mọ bí àjọṣe láàárín Jeremáyà àti Jòsáyà ṣe pọ̀ tó, àmọ́ ó dájú pé ó rọrùn fún ẹni tó bá jẹ́ wòlíì Ọlọ́run láti ṣiṣẹ́ rẹ̀ ní gbogbo àkókò náà. Sefanáyà àti Náhúmù náà jẹ́ wòlíì ní Júdà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jòsáyà.b Ìgbà ìjọba Jòsáyà náà ni obìnrin náà Húlídà jẹ́ wòlíì, àmọ́ àjálù tó ń bọ̀ wá sórí àwọn èèyàn Júdà ló sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo àjálù náà sì ṣojú Jeremáyà. (2 Ki. 22:14) Kódà, nígbà yẹn àwọn ọ̀rẹ́ Jeremáyà bí Ebedi-mélékì àti Bárúkù ló ń kó Jeremáyà yọ, yálà níbi tí ì bá kú sí tàbí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó fẹ́ hàn án léèmọ̀.
10 Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí Ọlọ́run bá sọ pé òun dìídì yàn ọ́ ṣe wòlíì láti lọ jẹ́ iṣẹ́ kan tó le? (Ka Jeremáyà 1:10.) Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀kan lára iṣẹ́ tí Jeremáyà ní láti kéde. Lọ́dún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Bábílónì ti ń ṣígun bọ̀ wá bá Jerúsálẹ́mù jà. Sedekáyà Ọba wá fẹ́ ti ẹnu Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ ìdùnnú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, ohun tí Ọlọ́run ní kó sọ fún ọba yẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìdùnnú rárá.—Ka Jeremáyà 21:4-7, 10.
ÈÈYÀN ẸLẸ́RAN ARA BÍI TIWA NI
11. Kí nìdí tí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà lọ jẹ́ fi lè nira, àmọ́ kí ló jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó?
11 Ẹ jẹ́ ká fojú inú wò ó pé àwa ni Jeremáyà tí Ọlọ́run ní kó máa kéde ìbáwí àti ìdájọ́ tó le koko sórí àwọn ọba tó rorò, àwọn àlùfáà oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn wòlíì èké. Kò ní sídìí fún wa láti bẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run yóò wà lẹ́yìn wa bó ṣe wà lẹ́yìn Jeremáyà. (Jer. 1:7-9) Ní ti Jeremáyà ọ̀dọ́, Ọlọ́run gbà pé ó lè ṣe iṣẹ́ náà, ó wá ki í láyà pé: “Mo ti sọ ìwọ di ìlú ńlá olódi àti ọwọ̀n irin àti ògiri bàbà lòdì sí gbogbo ilẹ̀ náà, sí àwọn ọba Júdà, sí àwọn ọmọ aládé rẹ̀, sí àwọn àlùfáà rẹ̀ àti sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’”—Jer. 1:18, 19.
12. Àwọn ìdí wo la fi lè sọ pé ipò àwa àti Jeremáyà jọra?
12 Ká má ṣe rò pé àkàndá èèyàn ni Jeremáyà o. Èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ìgbà ti Jeremáyà yàtọ̀ sí tiwa, irú ipò tó bá pàdé làwa náà ń bá pàdé lóde òní. Bí nǹkan ṣe da Jeremáyà àti onírúurú èèyàn pọ̀ nígbà tiẹ̀ náà ni nǹkan ṣe ń da àwa àti onírúurú èèyàn pọ̀ nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, títí kan èyí tó jẹ mọ́ ti ìjọsìn wa. Nítorí náà, a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Jeremáyà, ẹni tó dà bíi wòlíì Èlíjà tó jẹ́ “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Ják. 5:17) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ nínú àwọn ohun tá a lè rí kọ́ lára Jeremáyà.
13, 14. Báwo ni ipò àwọn Kristẹni kan ṣe lè dà bíi ti Jeremáyà nígbà tí Páṣúrì fìyà jẹ ẹ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àwòrán tó wà lójú ìwé 10?
13 Láìsí àní-àní, wàá ti ní àwọn ìgbà tí nǹkan dùn àtàwọn ìgbà tí nǹkan ò fara rọ. Bó ṣe rí fún Jeremáyà náà nìyẹn. Nígbà kan, Páṣúrì, àlùfáà tẹ́nu rẹ̀ tólẹ̀ lu Jeremáyà, ó sì ní kí wọ́n fi í sínú àbà. Ọ̀pọ̀ wákàtí ló lò nínú igi àbà tí wọ́n ti ọwọ́, ẹsẹ àti ọrùn rẹ̀ bọ̀, èyí táá jẹ́ kí ẹ̀yìn àti ọrùn rẹ̀ ká kò. Yàtọ̀ sí ìrora tó ń jẹ nínú àbà tó wà, ńṣe ni àwọn alátakò tún ń fi ṣẹlẹ́yà. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Jeremáyà tí wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n lù, tí wọ́n tiẹ̀ tún fi sínú àbà, ṣé wàá lè fara dà á?—Jer. 20:1-4.
14 Abájọ tí ọ̀rọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lẹ́nu Jeremáyà nígbà tí nǹkan dójú ẹ̀ fún un, tó ní: “Ègún ni fún ọjọ́ tí a bí mi! . . . Èé ti ṣe tí mo fi jáde wá láti inú ilé ọlẹ̀ náà láti rí iṣẹ́ àṣekára àti ẹ̀dùn-ọkàn, kí àwọn ọjọ́ mi sì wá sí òpin wọn nínú ìtìjú lásán-làsàn?” (Jer. 20:14-18) Ayé sú u lóòótọ́! Ṣé nǹkan tíì tojú sú ọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ débi tó fi dà bíi pé gbogbo nǹkan kò lójútùú, tó dà bí ẹni pé o ò ríkan-ṣèkan, bóyá tó o tiẹ̀ wá ro ara rẹ pin? Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti nírú èrò yìí rí máa jàǹfààní gan-an tí wọ́n bá mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà àti ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọrí sí.
Kí ló wù ẹ́ nínú bí Jèhófà ṣe sọ Jeremáyà di wòlíì? Kí nìdí tó o fi lè sọ pé ipò tiwa àti ti Jeremáyà jọra?
15. Kí nìdí tá a fi máa jàǹfààní tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó fà á tínú Jeremáyà fi dédé bà jẹ́ lẹ́yìn tínú rẹ̀ dùn?
15 Kété lẹ́yìn tí wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀ nípa kíkọrin sí Jèhófà, àti pé ká yìn ín lógo ló gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ tá a fà yọ nínú Jeremáyà 20:14-18, èyí tó fi hàn pé wọ́n ti fayé sú u. (Ka Jeremáyà 20:12, 13.) Ǹjẹ́ ìwọ náà ti ṣàkíyèsí pé nígbà míì inú rẹ máa ń dùn dáadáa àmọ́ tí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn á tún dédé bá ọ lẹ́yìn náà? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa la máa jàǹfààní tá a bá gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà yẹ̀ wò. Kò sí àní-àní pé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa ló ṣe rí lára òun náà. Torí náà, a máa jàǹfààní gan-an tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Jeremáyà, tí Ẹlẹ́dàá lò gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀ lọ́nà tó pabanbarì, ṣe.—2 Kíró. 36:12, 21, 22; Ẹ́sírà 1:1.
16. Àwọn wo ló lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú bí Jeremáyà kò ṣe ní aya?
16 Ìdí mìíràn tí ipò àwọn kan fi jọ ti Jeremáyà ni bí kò ṣe ní aya. Ọlọ́run fún Jeremáyà ní ìtọ́ni àrà ọ̀tọ̀ kan tó lè ṣòro láti fara mọ́, ó ní kò gbọ́dọ̀ fẹ́ aya. (Ka Jeremáyà 16:2.) Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ bẹ́ẹ̀ fún Jeremáyà, ipa wo ni èyí sì ní lórí rẹ̀? Kí ló ṣeé ṣe kó jọra nínú ipò ti Jeremáyà àti tàwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n fúnra wọn yàn láti má ṣe ní ọkọ tàbí aya, tàbí àwọn tó kàn bára wọn nínú ipò yẹn? Ǹjẹ́ nǹkan kan tiẹ̀ wà nínú ohun tí Ọlọ́run bá Jeremáyà sọ tó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ tọkọtaya lóde òní? Ṣé àwọn tọkọtaya tí wọn ò ní “àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin” náà lè rí ẹ̀kọ́ kọ́? Báwo ni àwọn ìwé tí Jeremáyà kọ ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?
17. Àpẹẹrẹ wo ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ nínú Jeremáyà 38:20 lè mú ká ronú nípa rẹ̀?
17 Ó tún ṣẹlẹ̀ pé nígbà tọ́rọ̀ débì kan, Jeremáyà gba ọba tó ń ṣàkóso ní Júdà nímọ̀ràn pé: “Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà nínú ohun tí mo ń sọ fún ọ, nǹkan yóò lọ dáadáa fún ọ, ọkàn rẹ yóò sì máa wà láàyè nìṣó.” (Jer. 38:20) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ pàtàkì fún wa nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan máa rí láàárín àwa àtàwọn èèyàn. Kódà, èyí kan àwọn tí kò tíì di ìránṣẹ́ Jèhófà, àmọ́ tí wọ́n jẹ́ àwọn tá a lè ràn lọ́wọ́. Bákan náà, ọwọ́ tí Jeremáyà fi mú àwọn tó ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lónìí. Ká sóòótọ́, ẹ̀kọ́ ńlá la lè rí kọ́ lára Jeremáyà.
Ẹ̀KỌ́ WO LA MÁA KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ?
18, 19. Onírúurú ọ̀nà wo la lè gbà ṣàyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti Ìdárò?
18 Ìwé yìí máa jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti Ìdárò, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú wọn. Lọ́nà wo? Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16) Ìwé Jeremáyà àti Ìdárò wà lára àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí.
19 Onírúurú ọ̀nà ni èèyàn lè gbà ṣàyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti ìwé Ìdárò téèyàn á fi jàǹfààní nínú wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣàyẹ̀wò ìwé méjèèjì ní ẹsẹ-ẹsẹ láti fi mọ bí ọ̀rọ̀ inú wọn ṣe tan mọ́ra látìbẹ̀rẹ̀ tàbí láti lè mọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Èèyàn sì lè máa wá ibi táwọn èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé wọ̀nyẹn ti bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní mu. (Fi wé Jeremáyà 24:6, 7; 1 Kọ́ríńtì 3:6.) Èèyàn sì tún lè fẹ́ mọ ìtàn ohun tó fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé méjèèjì. (Jer. 39:1-9) Àmọ́ ṣá, ọ̀nà tó pé jù lọ tá a lè gbà ṣàyẹ̀wò ìwé Jeremáyà àti Ìdárò ká sì jàǹfààní nínú rẹ̀ ni pé ká lo àwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu kàn yìí pa pọ̀ dé ìwọ̀n àyè kan. Ìdí nìyẹn tá a fi lo Orí Kejì tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run ní ‘Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́,’” láti fi ṣe àkópọ̀ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jeremáyà gbé láyé àti bí Ọlọ́run ṣe darí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àsìkò náà.
20. Kí ni a fẹ́ fi ìwé yìí ṣe nípa ìwé Jeremáyà àti Ìdárò?
20 Àmọ́ ìdí pàtàkì tá a fi ṣe ìwé yìí yàtọ̀ sí àwọn ohun tá a sọ yìí. Ńṣe la fi ìwé yìí ṣàlàyé bí ìwé Jeremáyà àti Ìdárò ṣe jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èyí tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé ìgbé ayé Kristẹni lóde òní. (Títù 2:12) Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọfúnni tó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni” ló wà nínú ìwé méjèèjì yìí. Wọ́n fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn àti àpẹẹrẹ tó wúlò gan-an táá jẹ́ ká lè pegedé, ká sì gbára dì láti lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí tá a bá bá pàdé nígbèésí ayé. Èyí ò sì yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, yálà a láya tàbí a kò ní, yálà a lọ́kọ tàbí a kò ní, yálà a jẹ́ alàgbà, aṣáájú-ọ̀nà, ẹni tó ń gbé bùkátà ìdílé, ìyàwó ilé tàbí ọmọ iléèwé. Olúkúlùkù wa máa rí i pé Ọlọ́run ti pèsè ìrànlọ́wọ́ tó máa “mú [wa] gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo” sínú ìwé méjèèjì yìí.—2 Tím. 3:17.
21. Kí lo máa rí kọ́ nínú ìwé yìí?
21 Bó o ṣe ń gbé àkòrí kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò nínú ìwé yìí, máa fọkàn sí àwọn kókó tó o máa lò. Ó dájú pé ìwé Jeremáyà àti Ìdárò máa jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé òótọ́ ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò, èyí tó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́?
a Láwọn èdè kan, wọ́n ní ọ̀nà àkànlò tí wọ́n máa ń gbà lo orúkọ náà Jeremáyà táá mú kó túmọ̀ sí “ẹni tó ń fìkanra báni wí” tàbí “ẹni tó ń fìbínú sọ̀rọ̀.” Ìwé ìròyìn Washington Post tiẹ̀ fi ọ̀rọ̀ yẹn ṣàpèjúwe fíìmù kan tó dá lórí bí ojú ọjọ́, ewéko àtàwọn ohun abẹ̀mí yòókù ṣe ń bà jẹ́ sí i.
b Nígbà tó yá, àwọn míì bíi, Hábákúkù, Ọbadáyà, Dáníẹ́lì àti Ìsíkíẹ́lì náà di wòlíì bí Jeremáyà ṣe ń bá iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ lọ. Ogójì ọdún lẹ́yìn tí Jeremáyà ti ń ṣe wòlíì ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lẹ́yìn ìgbà yẹn ó sì tún lò ju ogún ọdún lọ láyé.