Ẹ Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà
“Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.”—SÁÀMÙ 27:14.
1. Ọ̀pọ̀ ìbùkún wo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn?
INÚ párádísè tẹ̀mí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé. (Aísáyà 11:6-9) Nínú ayé tí wàhálà kúnnú rẹ̀ yìí, àwọn àtàwọn yòókù tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ń gbé nínú àyíká tẹ̀mí kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn àwọn tó wà lálàáfíà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara wọn. (Sáàmù 29:11; Aísáyà 54:13) Párádísè tẹ̀mí tí wọ́n wà nínú rẹ̀ náà sí túbọ̀ ń gbòòrò sí i. Gbogbo àwọn tó ń ‘ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn’ ló ń mú kó túbọ̀ máa gbòòrò sí i. (Éfésù 6:6) Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Wọ́n ń ṣe é nípa gbígbé ìgbésí ayé lọ́nà tó bá ìlànà Bíbélì mu àti nípa kíkọ́ àwọn èèyàn láti máa ṣe ohun kan náà, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ pè wọ́n láti wá gbádùn lára ọ̀pọ̀ ìbùkún párádísè tẹ̀mí náà.—Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 15:8.
2, 3. Kí làwọn nǹkan tí Kristẹni tòótọ́ ń fara dà?
2 Àmọ́ ṣá o, gbígbé tá à ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí kò túmọ̀ sí pé a ò ní rí àdánwò. Aláìpé ṣì ni wá, à ń ṣàìsàn, à ń darúgbó, a sì ń kú. Láfikún sí i, à ń fojú ara wa rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn, ìyàn àtàwọn ìṣòro lílekoko mìíràn ń pọ́n aráyé lójú, wọ́n sì ń pọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pẹ̀lú.—Máàkù 13:3-10; Lúùkù 21:10, 11.
3 Yàtọ̀ sí gbogbo ìyẹn, a mọ̀ dájú pé bí párádísè tẹ̀mí tá a wà tilẹ̀ jẹ́ ibi ààbò, àwọn tí kò sí nínú rẹ̀ ṣì máa ń ṣàtakò sí wa. Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín. Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn, pé, Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:18-21) Bó ṣe rí gan-an lónìí nìyẹn. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ni kò lóye ọ̀nà ìjọsìn wa, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ò kà á sí. Àwọn kan máa ń ṣe àríwísí wa, wọ́n ń fi wá ṣẹ̀sín, àní wọ́n tiẹ̀ kórìíra wa gẹ́gẹ́ bí Jésù ti kìlọ̀ fún wa tẹ́lẹ̀. (Mátíù 10:22) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń dìídì lo iléeṣẹ́ ìròyìn láti parọ́ mọ́ wa àti láti bà wá lórúkọ jẹ́. (Sáàmù 109:1-3) Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo wa là ń dojú kọ ipò tó ṣòro, àwọn kan lára wa sì lè bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì. Báwo la ṣe lè máa fara dà á?
4. Ta ni à ń retí pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa fara dà á?
4 Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́. Ọlọ́run mí sí onísáàmù náà láti kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.” (Sáàmù 34:19; 1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọ̀pọ̀ nínú wa ló lè jẹ́rìí sí i pé nígbà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lè Jèhófà tọkàntọkàn, ó máa ń fún wa lókun láti fara da ìpọ́njú èyíkéyìí. Ìfẹ́ tá a ní fún un àti ayọ̀ tá a gbé síwájú wa yóò jẹ́ ká lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbẹ̀rù. (Hébérù 12:2) Nípa bẹ́ẹ̀, láìka ìṣòro yòówù tá a lè ní sí, a óò máa fara dà á.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún Jeremáyà Lókun
5, 6. (a) Àpẹẹrẹ àwọn olùjọsìn tòótọ́ tó fara dà á wo la rí? (b) Báwo ni Jeremáyà ṣe ṣe nígbà tó gbọ́ ìpè láti wá ṣe wòlíì?
5 Jálẹ̀ ìtàn aráyé ni àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń láyọ̀ bí wọ́n tilẹ̀ wà nípò tí kò rọgbọ. Àwọn kan lára wọn gbé láyé láwọn àkókò ìdájọ́, ìyẹn ìgbà tí Jèhófà bínú sáwọn aláìṣòótọ́. Lára àwọn olóòótọ́ olùjọsìn náà ni Jeremáyà àti díẹ̀ lára àwọn tí ń bẹ nígbà ayé rẹ̀, títí kan àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Káwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn bàa lè jẹ́ ìṣírí fún wa la ṣe kọ wọ́n sínú Bíbélì, a sì lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ tá a bá kà wọ́n. (Róòmù 15:4) Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tó ṣelẹ̀ sí Jeremáyà yẹ̀ wò.
6 Nígbà tí Jeremáyà ṣì kéré, ó gbọ́ ìpè láti sìn gẹ́gẹ́ bí wòlíì ní Júdà. Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yẹn o. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jọ́sìn ọlọ́run èké nígbà náà lọ́hùn-ún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ni Jòsáyà, tó jẹ́ ọba nígbà tí Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, gbogbo àwọn tó jọba lẹ́yìn rẹ̀ ló jẹ́ aláìṣòótọ́ àti pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó yẹ kó máa kọ́ àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn wòlíì àtàwọn àlùfáà ló jẹ́ aláìṣòótọ́. (Jeremáyà 1:1, 2; 6:13; 23:11) Báwo ló ṣe rí lára Jeremáyà nígbà tí Jèhófà ní kó wá ṣe wòlíì? Ẹ̀rù bà á! (Jeremáyà 1:8, 17) Jeremáyà rántí bí ọ̀ràn náà ṣe kọ́kọ́ rí lára òun, ó ní: “Mo wí pé: ‘Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.’”—Jeremáyà 1:6.
7. Báwo ni àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ Jeremáyà ṣe ṣe sí iṣẹ́ rẹ̀, kí ló sì ṣe?
7 Àwọn tó pọ̀ jù lọ ní ìpínlẹ̀ tí Jeremáyà ti ń ṣiṣẹ́ ni kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ń bá àtakò lílekoko pàdé. Lákòókò kan báyìí, Páṣúrì àlùfáà lu Jeremáyà, ó sì fí i sínú àbà. Jeremáyà sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára òun lákòókò náà, ó ní: “Mo sì wí pé: ‘Èmi kì yóò mẹ́nu kàn án [Jèhófà], èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.’” Ó ti lè ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀ rí, kó ṣe ọ́ bí ẹni pé kó o pa iṣẹ́ ọ̀hún tì. Kíyè sí ohun tó ran Jeremáyà lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. Ó sọ pé: “Nínú ọkàn-àyà mi, ó [ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] sì wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra sú mi, èmi kò sì lè fara dà á.” (Jeremáyà 20:9) Ṣé bí ipá tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lórí ìwọ náà ṣe rí nìyẹn?
Àwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Jeremáyà
8, 9. (a) Kí ni wòlíì Úríjà ṣe tó kù díẹ̀ káàtó, kí ni èyí sì yọrí sí? (b) Kí nìdí tí Bárúkù fi rẹ̀wẹ̀sì, báwo la sì ṣe ràn án lọ́wọ́?
8 Jeremáyà nìkan kọ́ ló ń ṣe iṣẹ́ wòlíì o. Àwọn mìíràn tún wà tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ọ̀hún, ó sì dájú pé ìṣírí lèyí máa jẹ́ fún un. Àmọ́ ṣá o, ìgbà míì wà táwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kò hùwà ọgbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ọwọ́ wòlíì ẹgbẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Úríjà di nínú iṣẹ́ kíkéde ìkìlọ̀ fún Jerúsálẹ́mù àti Júdà “ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ Jeremáyà.” Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jèhóákímù Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa wòlíì Úríjà, ńṣe ló sá lọ sí Íjíbítì nítorí ìbẹ̀rù. Àmọ́, ìyẹn ò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú o. Àwọn ọkùnrin tí ọba máa ń rán níṣẹ sá tẹ̀ lé e, wọ́n sì mú un padà wá sí Jerúsálẹ́mù níbi tí wọ́n ti gbẹ̀mí rẹ̀. Èyí á mà ba Jeremáyà nínú jẹ́ gan-an o!—Jeremáyà 26:20-23.
9 Ẹlòmíràn tó tún jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Jeremáyà ni Bárúkù, akọ̀wé rẹ̀. Alátìlẹyìn rere ni Bárúkù jẹ́ fún Jeremáyà, àmọ́ lákòókò kan òun náà ò fi ojú tẹ̀mí wo ipò rẹ̀ mọ́. Ó wá ń ráhùn pé: “Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.” Ìrẹ̀wẹ̀sì bá Bárúkù, ìmọrírì tó ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí sì dín kù. Síbẹ̀, Jèhófà fún Bárúkù nímọ̀ràn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, ó sì tún èrò rẹ̀ ṣe. Ó mú kó dá a lójú pé yóò la ìparun tó ń bọ̀ sórí Jerúsálẹ́mù já. (Jeremáyà 45:1-5) Ìṣírí ńlá gbáà lèyí mà jẹ́ fún Jeremáyà o nígbà tí Bárúkù kọ́fẹ padà nípa tẹ̀mí!
Jèhófà Dúró Ti Wòlíì Rẹ̀
10. Ìlérí ìtìlẹ́yìn wo ní Jèhófà ṣe fún Jeremáyà?
10 Pàtàkì ọ̀rọ̀ náà ni pé, Jèhófà ò fi Jeremáyà sílẹ̀. Ó mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wòlíì rẹ̀, ó sì fún un ní okun àti ìtìlẹ́yìn tí ó nílò. Bí àpẹẹrẹ, níbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jeremáyà, ó rò pé bóyá lòun tóótun fún iṣẹ́ náà, àmọ́ Jèhófà sọ fún un pé: “Má fòyà nítorí ojú wọn, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè,’ ni àsọjáde Jèhófà.” Lẹ́yìn tí Jèhófà fún wòlíì rẹ̀ yìí ní ìsọfúnni nípa iṣẹ́ tó rán an, ó wá sọ fún un pé: “Ó . . . dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’” (Jeremáyà 1:8, 19) Ìlérí yìí mà túni lára o! Jèhófà sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
11. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà mú ìlérí tó ṣe fún Jeremáyà pé òun yóò dúró tì í ṣẹ?
11 Abájọ tí Jeremáyà fi sọ̀rọ̀ tìgboyàtìgboyà lẹ́yìn tí wọ́n fi í sínú àbà, tí wọ́n tún fi ṣẹ̀sín níwájú gbogbo èèyàn, ó sọ pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú mi bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà. Ìdí nìyẹn tí àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi yóò fi kọsẹ̀, wọn kì yóò sì borí. Dájúdájú, ìtìjú púpọ̀ yóò bá wọn.” (Jeremáyà 20:11) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà táwọn èèyàn ń wá ọ̀nà láti pa Jeremáyà, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé bíi ti Bárúkù, Jeremáyà la ìparun Jerúsálẹ́mù já lálàáfíà ara, àmọ́ wọ́n pa àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí i àtàwọn tí ò kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fipá kó àwọn tí wọ́n ò pa lọ́ sí Bábílónì.
12. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì wà, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?
12 Bíi ti Jeremáyà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ló ń fara da ìpọ́njú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, àìpé wa ló fa díẹ̀ lára àwọn ìpọ́njú yìí, ipò burúkú tí ayé yìí wà ló sì fa àwọn mìíràn, nígbà tó jẹ́ pé àwọn tó ń ta ko iṣẹ́ wa ló ń fa àwọn kan. Irú ìpọ́njú báwọ̀nyí lè múni rẹ̀wẹ̀sì. Bíi ti Jeremáyà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé bóyá la lè máa bá iṣẹ́ náà lọ. Lóòótọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì lè wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ńṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú wa fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sílẹ̀ bíi ti Úríjà. Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jeremáyà, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò dúró tì wá.
Bá A Ṣe Lè Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
13. Ọ̀nà wo la lè gbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà àti ti Dáfídì?
13 Gbogbo ìgbà ni Jeremáyà máa ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó máa ń sọ gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ fún un, ó sì máa ń bẹ̀bẹ̀ fún okun. Àpẹẹrẹ rere kan nìyẹn tá a lè tẹ̀ lé. Dáfídì tó gbé láyé ìgbàanì, tóun náà máa ń gba okun láti Orísun kan náà yìí kọ̀wé pé: “Fi etí sí àwọn àsọjáde mi, Jèhófà; lóye ìmí ẹ̀dùn mi. Fetí sí ìró igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ Ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí pé ìwọ ni mo ń gbàdúrà sí.” (Sáàmù 5:1, 2) Àkọsílẹ̀ onímìísí nípa ìgbésí ayé Dáfídì jẹ́ ká mọ̀ pé àìmọye ìgbà ni Jèhófà dáhùn àdúrà tí Dáfídì gbà fún ìrànlọ́wọ́. (Sáàmù 18:1, 2; 21:1-5) Lọ́nà kan náà, tí pákáǹleke tàbí ìṣòro tá a ní bá fẹ́ jú agbára wa lọ, yóò jẹ́ ohun ìtùnú gan-an láti gbàdúrà sí Jèhófà ká sí sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un. (Fílípì 4:6, 7; 1 Tẹsalóníkà 5:16-18) Jèhófà kò ní ṣàìgbọ́ wa. Dípò ìyẹn, ó mú kó dá wa lójú pé ‘òun bìkítà fún wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Àmọ́ ṣá o, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mú pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì wá máa ṣàìgbọràn sí i?
14. Ipa wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ní lórí Jeremáyà?
14 Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń bá wa sọ̀rọ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé bó ṣe bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ yẹ̀ wò. Nítorí pé Jeremáyà jẹ́ wòlíì, Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Jeremáyà ṣàpèjúwe ipa tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lórí ọkàn òun, ó ní: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (Jeremáyà 15:16) Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Jeremáyà dùn nítorí pé à ń pe orúkọ Ọlọ́run mọ́ ọn lára, àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sì jẹ́ iyebíye lójú wòlíì yìí. Nítorí náà, bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Jeremáyà ṣe tán láti máa polongo iṣẹ́ tá a fi síkàáwọ́ rẹ̀.—Róòmù 1:15, 16.
15. Báwo lá ṣe lè gbin ọ̀rọ̀ Jèhófà sínú ọkàn ara wa, àwọn nǹkan wo la lè gbé yẹ̀ wò tí kò ní mú ká panu mọ́?
15 Lóde òní, Jèhófà kì í bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Nítorí náà, tá a bá jẹ́ kó jẹ wá lógún láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tá a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò di “ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀” ọkàn wa. Yóò sì múnú wa dùn pé orúkọ Jèhófà ń bá wa lọ, bá a ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fáwọn èèyàn. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láé pé kò sẹ́lòmíràn lórí ilẹ̀ ayé lónìí tó ń polongo orúkọ Jèhófà. Àwa Ẹlẹ́rìí rẹ̀ nìkan ṣoṣo là ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀, àti pé àwa nìkan là ń kọ àwọn ọlọ́kàn tútù lẹ́kọ̀ọ́ kí wọn lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. (Mátíù 28:19, 20) Àǹfààní ńlá gbáà lèyí mà jẹ́ fún wa o! Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ ká panu mọ́ tí a bá ro gbogbo nǹkan ti Jèhófà fi síkàáwọ́ wa yìí?
Ẹ Jẹ́ Ká Ṣọ́ra Fáwọn Tá À Ń Bá Kẹ́gbẹ́
16, 17. Kí ni èrò Jeremáyà nípa ẹgbẹ́ kíkó, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
16 Jeremáyà sọ ohun mìíràn tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà. Ó sọ pé: “Èmi kò jókòó ní àwùjọ tímọ́tímọ́ àwọn tí ń ṣe àwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ ayọ̀ ńláǹlà. Nítorí ọwọ́ rẹ, ṣe ni mo dá jókòó ní èmi nìkan, nítorí o ti fi ìdálẹ́bi kún inú mi.” (Jeremáyà 15:17) Jeremáyà gbà kóun dá wà ju pé káwọn ọ̀rẹ́ burúkú wá kéèràn ran òun. Lónìí, bí àwa náà ṣe rí ọ̀rọ̀ náà nìyẹn. A ò gbàgbé ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́,” àní á bá ìwà rere tá a ti ń hù fún ọ̀pọ̀ ọdún jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 15:33.
17 Ẹgbẹ́ búburú lè mú kí ẹ̀mí ayé yìí ṣàkóbá fún ìrònú wa. (1 Kọ́ríńtì 2:12; Éfésù 2:2; Jákọ́bù 4:4) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká kọ agbára ìwòye wa láti mọ ẹgbẹ́ búburú ká sì yẹra fún wọn pátápátá. (Hébérù 5:14) Ká ni Pọ́ọ̀lù ń bẹ láyé lónìí, kí lo rò pé ó máa sọ fún Kristẹni kan tó ń wo eré oníṣekúṣe tàbí eré oníwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá? Ìmọ̀ràn wo ló máa fún arákùnrin tó ń bá àwọn tí kò mọ̀ rí kẹ́gbẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Irú èèyàn wo ló máa pé Kristẹni kan tó ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nídìí eré orí fídíò tàbí ti tẹlifíṣọ̀n àmọ́ tí kò ráyè ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jíire?—2 Kọ́ríńtì 6:14b; Éfésù 5:3-5, 15, 16.
Má Ṣe Kúrò Nínú Párádísè Tẹ̀mí
18. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí?
18 A mọyì párádísè tẹ̀mí wa. Kò síbì kankan lórí ilẹ̀ ayé lónìí tá a lè fi wé e. Kódà, àwọn aláìgbàgbọ́ pàápàá máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́, ìgbatẹnirò àti inú rere tí àwa Kristẹni ní fún ara wa. (Éfésù 4:31, 32) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ní láti sapá láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Alábàákẹ́gbẹ́ rere, àdúrà àti ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jíire lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti dúró ṣán-ún nípa tẹ̀mí. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn yóò fún wa lókun láti kojú àdánwò èyíkéyìí bí a ti ní ìgbékẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 4:7, 8.
19, 20. (a) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà? (b) Àwọn wo ni àpilẹ̀kọ tó kàn yóò bá sọ̀rọ̀, àwọn wo ni yóò sí tún jàǹfààní nínú rẹ̀?
19 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì láyè láti dẹ́rù bà wá, kí wọ́n sì mú kí iná ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Bíi ti àwọn ọ̀tá tó ṣe inúnibíni sí Jeremáyà, ńṣe làwọn tó ń bá wa jà ń bá Ọlọ́run jà. Kò sì sí bí wọ́n ṣe lè borí. Jèhófà, tó lágbára ju àwọn ọ̀tá wa lọ fíìfíì, sọ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.” (Sáàmù 27:14) Bí ìrètí tá a ní nínú Jèhófà ṣe wà lọ́kàn wa digbí yìí, ẹ jẹ́ ká pinnu láti má ṣe dáwọ́ rere ṣíṣe dúró. Kó dá wa lójú pé, bíi ti Jeremáyà àti Bárúkù, a óò kórè rẹ̀ bí a kò bá ṣàárẹ̀.—Gálátíà 6:9.
20 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́, wọ́n tún ní àwọn àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín wa ni àpilẹ̀kọ tó kan darí ọ̀rọ̀ sí ní tààràtà. Àwọn òbí àtàwọn àgbà to ti ṣèyàsímímọ́ nínú ìjọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní nínú àpilẹ̀kọ náà, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n lè tipa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, àpẹẹrẹ wọn àti nípa ìtìlẹ́yìn mìíràn ran àwọn èwe tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká retí pé ipò tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bani lè yọjú, ta sì lẹ́ni tó yẹ ká máa wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀?
• Báwo ni Jeremáyà ṣe borí ìrẹ̀wẹ̀sì láìfi ìṣòro tó bá pàdé nídìí iṣẹ́ rẹ̀ pè?
• Kí ni yóò mú ọkàn wa ní ‘ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀’ àní bá a tiẹ̀ níṣòro?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jeremáyà rò pé òun ti kéré jù àti pé òun ò nírìírí tó láti ṣe iṣẹ́ wòlíì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àní nígbà táwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí Jeremáyà, ó mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun “bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà”