ORÍ KỌKÀNDÍNLÓGÚN
Ó Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀, Ó Pèsè fún Wọn, Ó sì Ní Ìfaradà
1, 2. (a) Àárín àwọn wo ni Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ ní láti kó lọ báyìí? (b) Ìròyìn burúkú wo ni Jósẹ́fù ní láti sọ fún aya rẹ̀?
JÓSẸ́FÙ tún gbé ẹrù míì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Fojú inú wò ó bó ṣe yíjú wo abúlé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn, tó wá fọwọ́ gbá ìdí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n di ẹrù lé pẹ́pẹ́, kó lè máa lọ. Ó dájú pé á máa ronú nípa ọ̀nà jíjìn tí wọ́n fẹ́ lọ. Ìyẹn ìyànníyàn ilẹ̀ Íjíbítì, láàárín àwọn tí òun kò mọ̀ rí, tí èdè àti àṣà wọn yàtọ̀ sí tòun! Báwo ni gbogbo ìyípadà yẹn ṣe máa bá ìdílé òun kékeré yìí lára mu?
2 Kò rọrùn fún Jósẹ́fù láti sọ ìròyìn burúkú tó fa ìrìn àjò wọn yìí fún Màríà aya rẹ̀ àtàtà lọ́jọ́ tó sọ ọ́, àmọ́ ó ṣọkàn akin, ó sì sọ ọ́. Ó sọ fún un pé áńgẹ́lì kan wá jíṣẹ́ Ọlọ́run fún òun lójú àlá pé Hẹ́rọ́dù Ọba fẹ́ gbẹ̀mí Jésù, ọmọ wọn kékeré! Áńgẹ́lì náà wá ní kí wọ́n yáa jáde kúrò nínú ìlú yẹn kíákíá! (Ka Mátíù 2:13, 14.) Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú ọkàn bá Màríà gan-an. Á máa rò ó pé, kí ló dé tí ẹnì kan á fi fẹ́ gbẹ̀mí ọmọ òun jòjòló tí kò tíì dá nǹkan kan mọ̀? Màríà àti Jósẹ́fù kò mọ ohun tó lè fà á. Àmọ́ wọ́n ṣáà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì múra láti lọ.
3. Ṣàlàyé bí Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ ṣe fi Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sílẹ̀. (Tún wo àwòrán.)
3 Nígbà tí àwọn èèyàn ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣì ń sùn, láìmọ ohun tí Hẹ́rọ́dù fẹ́ ṣe, Jósẹ́fù mú Màríà àti Jésù, wọ́n rọra yọ́ jáde kúrò nílùú lóru. Bí Jósẹ́fù ṣe ń mú wọn lọ sí Íjíbítì níhà gúúsù, tí ilẹ̀ sì ń mọ́ bọ̀ ní ìlà oòrùn, ó ṣeé ṣe kó máa ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí fún àwọn ní Íjíbítì. Á máa rò ó pé, ‘Báwo ni òun káfíńtà lásánlàsàn ṣe fẹ́ dàábò bo ìdílé òun kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó lágbára gan-an yìí? Ṣé òun á lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé òun báyìí? Ṣé òun yóò lè ṣe gbogbo nǹkan tó bá gbà láti ṣe iṣẹ́ ńlá tí Jèhófà Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́, pé kí òun tọ́ ọmọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí dàgbà?’ Ó dájú pé ojúṣe ńláǹlà ń bẹ níwájú Jósẹ́fù láti ṣe. Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò bí Jósẹ́fù ṣe ṣe àwọn ojúṣe rẹ̀ yanjú, a óò rí ìdí tó fi yẹ kí àwọn bàbá àti gbogbo wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù.
Jósẹ́fù Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ̀
4, 5. (a) Báwo ni ìgbésí ayé Jósẹ́fù ṣe yí pa dà pátápátá? (b) Kí ni áńgẹ́lì kan sọ fún Jósẹ́fù tó jẹ́ kó lè tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ńlá tí Ọlọ́run ní kó ṣe?
4 Ohun tó lé lọ́dún kan sẹ́yìn ni ìgbésí ayé Jósẹ́fù ti yí pa dà pátápátá ní Násárétì ìlú rẹ̀. Òun àti Màríà ọmọ Hélì jọ ń fẹ́ra sọ́nà nígbà yẹn. Jósẹ́fù mọ̀ pé Màríà jẹ́ oníwà mímọ́, tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run. Àfi bó ṣe gbọ́ pé ó ti lóyún! Jósẹ́fù fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ kí àwọn èèyàn máa bàa kàn án lábùkù.a Àmọ́ áńgẹ́lì kan bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ lójú àlá, pé oyún tí Màríà ní jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ó sì ní ọmọ tí Màríà máa bí ni yóò “gba àwọn èèyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Ó fi Jósẹ́fù lọ́kàn balẹ̀ pé: “Má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé.”—Mát. 1:18-21.
5 Ohun tí Jósẹ́fù ọkùnrin olódodo àti onígbọràn yìí sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ìyẹn ni pé kó tọ́ ọmọ tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀ yìí, àmọ́ tó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run, dàgbà. Nígbà tó yá, òun àti aya rẹ̀ tó lóyún náà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti wá forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú ọba ṣe pa á láṣẹ. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yìí ló bí ọmọ rẹ̀ sí.
6-8. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló jẹ́ kí ìgbésí ayé Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ yí pa dà? (b) Kí ló fi hàn pé Sátánì ló rán ohun tí wọ́n pè ní ìràwọ̀ náà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Jósẹ́fù kò mú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ pa dà lọ sí Násárétì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí kò ju ibùsọ̀ mélòó kan sí Jerúsálẹ́mù ni wọ́n tẹ̀ dó sí. Tálákà ni wọ́n, àmọ́ Jósẹ́fù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rí i pé ìyà kò jẹ Màríà àti Jésù. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú ilé kékeré kan. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jésù ti kúrò ní ìkókó, bóyá tó ti di ọmọ ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìgbésí ayé wọn tún ṣàdédé yí pa dà.
7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọkùnrin kan tó jẹ́ awòràwọ̀ dé láti Ìlà Oòrùn, bóyá láti iyànníyàn Bábílónì, láti wá kí wọn. Ìràwọ̀ kan ni wọ́n sọ pé ó dárí àwọn wá sílé Jósẹ́fù àti Màríà, wọ́n ní ọmọ tó máa di ọba àwọn Júù ni wọ́n ń wá. Àwọn awòràwọ̀ yìí sì bọ̀wọ̀ fún Jósẹ́fù àti Màríà gan-an.
8 Bóyá àwọn awòràwọ̀ yẹn mọ̀ àbí wọn kò mọ̀, ṣe ni wíwá tí wọ́n wá yìí kó Jésù, ọmọ kékeré náà sínú ewu ńlá. Ìdí ni pé Jerúsálẹ́mù ni ohun tí wọ́n pè ní ìràwọ̀ yẹn kọ́kọ́ darí wọn lọ, kó tó darí wọn wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.b Ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sọ fún Hẹ́rọ́dù ọba búburú pé àwọn ń wá ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tí yóò di ọba àwọn Júù. Ohun tí wọ́n sọ yìí sì ti mú kí orí òjòwú ọba yẹn kanrin.
9-11. (a) Kí ló fi hàn pé agbára tó ju ti Hẹ́rọ́dù àti Sátánì lọ ló ń darí ọ̀rọ̀ ọmọ náà? (b) Báwo ni ìrìn àjò ìdílé Jósẹ́fù sí Íjíbítì ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ìtàn àròṣọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu inú ìwé àpókírífà sọ?
9 Àmọ́, ó dùn mọ́ni pé agbára tó ju ti Hẹ́rọ́dù àti Sátánì lọ ló ń dáàbò bo ọmọ náà. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nígbà tí àwọn ọkùnrin yẹn dé ilé tí Jésù wà, tí wọ́n sì rí i lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀, wọ́n fi àwọn ẹ̀bùn kan ta wọ́n lọ́rẹ. Ẹ ò rí i pé ó máa ya Jósẹ́fù àti Màríà lẹ́nu pé àwọn kàn dẹni tó ní “wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá” tó jẹ́ àwọn nǹkan olówó iyebíye! Àwọn awòràwọ̀ yìí wá fẹ́ pa dà lọ sọ ibi tí wọ́n ti rí ọmọ náà fún Hẹ́rọ́dù Ọba. Ṣùgbọ́n Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó pàṣẹ fún àwọn awòràwọ̀ yẹn lójú àlá pé kí wọ́n gba ọ̀nà míì pa dà lọ sí ìlú wọn.—Ka Mátíù 2:1-12.
10 Láìpẹ́ lẹ́yìn tí àwọn awòràwọ̀ náà kọrí sílé, áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o sì dúró níbẹ̀ títí èmi yóò fi bá ọ sọ̀rọ̀; nítorí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà káàkiri láti pa á run.” (Mát. 2:13) Jósẹ́fù ṣègbọràn kíá bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ààbò ọmọ rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún jù. Torí náà, ó kó ìdílé rẹ̀ gba ilẹ̀ Íjíbítì lọ. Àmọ́ nítorí pé àwọn awòràwọ̀ tó jẹ́ abọ̀rìṣà náà fi àwọn ẹ̀bùn iyebíye ta ìdílé náà lọ́rẹ, Jósẹ́fù tipa bẹ́ẹ̀ ní ohun tó lè lò láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ ní àkókò tí wọ́n fi máa wà ní ilẹ̀ Íjíbítì.
11 Nígbà tó yá, àwọn tó kọ ìtàn àròṣọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu sínú ìwé àpókírífà ṣe àbùmọ́ lóríṣiríṣi nípa ìrìn àjò wọn lọ sí Íjíbítì yìí. Wọ́n ní Jésù ọmọ kékeré náà ṣe iṣẹ́ ìyanu tó mú kí ìrìn àjò wọn sí Íjíbítì kúrú sí i àti pé kò jẹ́ kí àwọn ọlọ́ṣà tí wọ́n pàdé lọ́nà rí wọn gbé ṣe, pé ó tiẹ̀ mú kí igi ọ̀pẹ déètì tẹrí wálẹ̀ kí ìyá rẹ̀ lé ká lára èso rẹ̀.c Àmọ́ o, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ìrìn àjò tí wọ́n rìn yẹn jìnnà, kò sì rọrùn àti pé wọn kò tiẹ̀ mọ ibi tí ìrìn àjò náà lè já sí.
Jósẹ́fù pa ìdẹ̀ra rẹ̀ tì nítorí ire ìdílé rẹ̀
12. Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn òbí tó ń tọ́mọ nínú ayé eléwu yìí lè rí kọ́ lára Jósẹ́fù?
12 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni àwọn òbí lè rí kọ́ lára Jósẹ́fù. Kò lọ́ tìkọ̀ láti pa iṣẹ́ àti ìdẹ̀ra rẹ̀ tì kó lè dáàbò bo ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ ewu. Ó ṣe kedere pé ó ka ìdílé rẹ̀ sí ohun pàtàkì tí Jèhófà dìídì fi síkàáwọ́ rẹ̀. Lónìí, inú ayé eléwu làwọn òbí ti ń tọ́ ọmọ wọn, ìyẹn ayé tó kún fún onírúurú nǹkan tó ń wu àwọn ọmọ léwu, tó fẹ́ kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n tàbí kó tiẹ̀ bayé wọn jẹ́ pátápátá. Ó máa ń dára gan-an ni tí àwọn ìyá àti bàbá bá tètè ń gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́ bíi ti Jósẹ́fù, tí wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ irú àwọn ohun tó lè pa wọ́n lára bẹ́ẹ̀.
Jósẹ́fù Pèsè fún Ìdílé Rẹ̀
13, 14. Báwo ló ṣe jẹ́ pé ìlú Násárétì ni Jósẹ́fù àti Màríà ti tọ́ àwọn ọmọ wọn?
13 Ó jọ pé Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ kò dúró pẹ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ Íjíbítì, torí kò pẹ́ tí áńgẹ́lì tún fi sọ fún un pé Hẹ́rọ́dù ti kú. Jósẹ́fù sì kó ìdílé rẹ̀ pa dà sí orílẹ̀-èdè wọn. Tipẹ́tipẹ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ kan ti sọ pé Jèhófà yóò pe ọmọkùnrin rẹ̀ “láti Íjíbítì.” (Mát. 2:15) Jósẹ́fù ti kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, àmọ́ ìlú wo ló máa wá kó ìdílé rẹ̀ lọ báyìí?
14 Jósẹ́fù jẹ́ ẹni tó ń ṣọ́ra gan-an. Ó bẹ̀rù ohun tí Ákíláọ́sì tó jọba lẹ́yìn Hẹ́rọ́dù lè ṣe. Ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu, torí Ákíláọ́sì náà jẹ́ ìkà àti apànìyàn bíi ti Hẹ́rọ́dù. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run darí Jósẹ́fù pé kí ó kó ìdílé rẹ̀ pa dà lọ sí Násárétì ìlú rẹ̀ tó wà ní Gálílì níhà àríwá, èyí tó jìnnà sí Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ètekéte àwọn tó wà níbẹ̀. Ibẹ̀ ni òun àti Màríà ti tọ́ àwọn ọmọ wọn.—Ka Mátíù 2:19-23.
15, 16. Kí lo lè sọ nípa iṣẹ́ Jósẹ́fù, àwọn irinṣẹ́ wo ló sì ṣeé ṣe kó máa lò?
15 Ìdílé tálákà ni ìdílé wọn, torí náà nǹkan ò rọrùn fún wọn. Nígbà tí Bíbélì pe Jósẹ́fù ní káfíńtà, ó lo ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí ẹni tó ń ṣe onírúurú iṣẹ́ tí wọ́n ń fi igi ṣe. Irú bíi gígé igi gẹdú, gbígbé wọn lọ síbi tí wọ́n ti máa lò ó, títọ́jú rẹ̀ láti jẹ́ kó gbẹ lọ́nà tó fi máa ṣeé là láti fi kọ́ ilé, láti fi ṣe ọkọ̀ ojú omi, afárá, kẹ̀kẹ́ ẹrù, àgbá kẹ̀kẹ́, àjàgà àti onírúurú àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ oko. (Mát. 13:55) Iṣẹ́ tó gba agbára gan-an ni iṣẹ́ yìí. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, káfíńtà sábà máa ń ṣiṣẹ́ lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ilé kékeré tó ń gbé tàbí ní ṣọ́ọ̀bù tó bá kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé rẹ̀.
16 Oríṣiríṣi irinṣẹ́ ni Jósẹ́fù á máa lò, bóyá títí kan èyí tó jogún lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó lo irin kọdọrọ, okùn ìwọ̀n, ẹfun láti fi fa ìlà, àáké tí wọ́n fi ń bó èèpo igi, ayùn, àáké, òòlù onírin, òòlù onígi, àwọn ohun tí wọ́n fi ń gbẹ́ nǹkan, irin tí yóò máa fi okùn ọrun yí bírí láti fi lu ihò sára igi, àti onírúurú àtè àti bóyá àwọn ìṣó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó rẹ̀ wọ́n gan-an nígbà yẹn.
17, 18. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jésù kọ́ lọ́dọ̀ bàbá tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi ní láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára?
17 Fojú inú wo bí Jésù tó jẹ́ ọmọdé yóò ṣe máa wo bàbá tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ yìí bó ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣe ló máa tẹjú mọ́ bí Jósẹ́fù ṣe ń ṣe àwọn nǹkan. Bó ṣe ń wo èjìká Jósẹ́fù, á máa wù ú pé ó jẹ́ ẹni tó lágbára. Á tún kíyè sí bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ dárà àti bó ṣe ń fi ojú ọnà wo nǹkan. Bóyá Jósẹ́fù wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré yìí ní bí yóò ṣe máa ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, irú bó ṣe lè fi awọ ẹja tó ti gbẹ ha ara igi títí igi náà fi máa dán. Ó ṣeé ṣe kó tún fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín oríṣiríṣi àwọn igi tó lè lò hàn án, irú bí igi síkámórè, igi óákù àti igi ólífì.
18 Jésù á tún mọ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ alágbára tó fi ń gé àwọn igi, tó fi ń la igi, tó sì fi ń gbá igi wọnú ara wọn, náà ló fi ń gbá òun mọ́ra tó sì fi ń tu òun, ìyá òun àtàwọn àbúrò òun nínú. Ní báyìí, ìdílé Jósẹ́fù àti Màríà ti di ìdílé ńlá, torí ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n bí ọmọ mẹ́fà míì yàtọ̀ sí Jésù. (Mát. 13:55, 56) Jósẹ́fù sì ní láti túbọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti lè bojú tó gbogbo wọn kó sì máa bọ́ wọn.
Jósẹ́fù mọ̀ pé bí òun ṣe máa bójú tó ìdílé òun nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù
19. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe bójú tó ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí?
19 Àmọ́ ṣá o, Jósẹ́fù mọ̀ pé bí òun ṣe máa bójú tó ìdílé òun nípa tẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù. Torí náà, ó ń fara balẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn òfin rẹ̀. Òun àti Màríà tún máa ń kó àwọn ọmọ wọn lọ sí sínágọ́gù déédéé, kí wọ́n lọ gbọ́ òfin Ọlọ́run tí wọ́n ń kà, tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni Jésù á máa béèrè tí wọ́n bá kúrò níbẹ̀, tí Jósẹ́fù á sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun dáhùn gbogbo ohun tí ọmọ náà fẹ́ mọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run. Jósẹ́fù tún máa ń kó ìdílé rẹ̀ lọ síbi àwọn àjọ̀dún ìsìn ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà àjọ̀dún Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún níbẹ̀, ó lè gba Jósẹ́fù ní ọ̀sẹ̀ méjì kí òun àti ìdílé rẹ̀ tó lè rin ìrìn àjò àlọ àtàbọ̀ tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́fà kìlómítà [120] láti lọ ṣe àjọ̀dún yẹn, kí wọ́n sì pa dà.
20. Báwo ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù?
20 Ohun tí àwọn Kristẹni tó jẹ́ olórí ìdílé máa ń ṣe lónìí náà nìyẹn. Wọ́n máa ń wá àyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn gan-an, wọ́n sì máa ń fi títọ́ wọn lọ́nà Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo, títí kan níní nǹkan amáyédẹrùn. Wọ́n ń rí i dájú pé àwọn ń ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé àti pé àwọn ń mú àwọn ọmọ lọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni, yálà ìpàdé ìjọ tàbí àwọn àpéjọ. Wọ́n mọ̀ bíi ti Jósẹ́fù, pé kò tún sí ogún míì tí wọ́n lè fún àwọn ọmọ wọn tó dáa tó kí wọ́n máa ṣe nǹkan wọ̀nyí.
“Nínú Ìdààmú-Ọkàn”
21. Kí ni ìdílé Jósẹ́fù máa ń ṣe nígbà ìrékọjá? Ìgbà wo ni Jósẹ́fù àti Màríà rí i pé Jésù ti dàwátì?
21 Nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá, Jósẹ́fù kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù bó ṣe sábà máa ń ṣe nígbà Ìrékọjá. Lákòókò àjọ̀dún yìí, ṣe ni ìdílé rẹ̀ àtàwọn ìdílé púpọ̀ jọ máa ń kọ́wọ̀ọ́rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù lásìkò ìrúwé tí ewéko pápá máa ń tutù yọ̀yọ̀. Tí wọ́n bá dé àgbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ewéko níbi àtigòkè wọ ìlú Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀ nínú wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn orin ìgòkè tó wà nínú ìwé Sáàmù. (Sm. 120-134) Ó jọ pé ṣe ni èrò máa ń kún ìlú Jerúsálẹ́mù bámúbámú. Lẹ́yìn àjọ̀dún yìí, àwọn ìdílé àti gbogbo èrò tí wọ́n jọ wá yóò tún kọrí sọ́nà ìlú wọn pa dà. Bóyá bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe ń bọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan míì gbàfiyèsí wọn, tí wọ́n wá rò pé Jésù wà lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láàárín àwọn èrò tí wọ́n jọ ń bọ̀. Ẹ̀yìn tí wọ́n ti rin ìrìn àjò odindi ọjọ́ kan kúrò ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ wá rí i pé ọ̀ràn ńlá ti ṣẹlẹ̀! Jésù ti dàwátì!—Lúùkù 2:41-44.
22, 23. Kí ni Jósẹ́fù àti Màríà ṣe nígbà tí wọ́n rí i pé ọmọ wọn ti dàwátì, kí sì ni Màríà sọ nígbà tí wọ́n wá rí i?
22 Nínú ìdààmú, wọ́n tún rin gbogbo ibi tí wọ́n ti gbà kọjá pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Fojú inú wo bí gbogbo ìlú yẹn yóò ṣe dá páropáro lójú wọn bí wọ́n ṣe ń gba àárín ìgboro lọ, tí wọ́n sì ń pe orúkọ ọmọ wọn tí wọ́n ń wá. Wọ́n á máa rò ó pé ibo lọmọ yìí lè wà? Nígbà tó máa fi di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti ń wá a, ṣé Jósẹ́fù kò ti ní máa rò ó pé, kí la ti ń gbọ́ irú èyí sí, pé òun kò lè bójú tó ọmọ tí Jèhófà dìídì fi sí ìkáwọ́ òun? Níkẹyìn, wọ́n kọrí sí tẹ́ńpìlì. Wọ́n ń wá a kiri títí wọ́n fi kan yàrá ńlá kan tí àwọn ọ̀mọ̀wé tó mọ tinú tòde Òfin Mósè kóra jọ sí. Wọ́n wá rí Jésù láàárín wọn níbẹ̀! Ẹ wo bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe máa mí kanlẹ̀, tí ara á sì tù wọ́n!—Lúùkù 2:45, 46.
23 Jésù jókòó sáàárín wọn ní tiẹ̀, ó ń gbọ́ ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé yẹn ń sọ, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Ẹnu ya àwọn ọkùnrin náà sí òye rẹ̀ àti bó ṣe ń dá wọn lóhùn. Ìyàlẹ́nu gbáà ni èyí jẹ́ fún Màríà àti Jósẹ́fù. Lóòótọ́ Bíbélì kò sọ pé Jósẹ́fù sọ ohunkóhun, àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn àwọn méjèèjì. Ó ní: “Ọmọ, èé ṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yìí? Kíyè sí i, baba rẹ àti èmi ti ń wá ọ nínú ìdààmú-ọkàn.”—Lúùkù 2:47, 48.
24. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká rí ohun tójú àwọn òbí máa ń rí lórí ọmọ títọ́?
24 Bí Bíbélì ṣe fi ìwọ̀nba gbólóhùn mélòó kan ṣàpèjúwe ohun tójú àwọn òbí máa ń rí lórí ọmọ títọ́ nìyẹn. Wàhálà ọmọ títọ́ máa ń pọ̀ gan-an, kódà tí ọmọ yẹn bá jẹ́ ẹni pípé pàápàá! Ọmọ títọ́ nínú ayé eléwu tá a wà lónìí lè fa “ìdààmú-ọkàn” bá àwọn òbí gan-an ni. Àmọ́ ìtùnú ló máa jẹ́ fún àwọn bàbá àti ìyá tí wọ́n bá ń fi sọ́kàn pé Bíbélì ti fi hàn pé àwọn òbí máa ń ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀.
25, 26. Báwo ni Jésù ṣe dá àwọn òbí rẹ̀ lóhùn, báwo sì ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣe máa rí lára Jósẹ́fù?
25 Ní ti Jésù, ṣe ló dúró síbì kan ṣoṣo láyé yìí tó rí pé òun ti sún mọ́ Jèhófà Baba òun tó wà lọ́run jù lọ, tó ń kọ́ gbogbo ohun tó lè rí kọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá àwọn òbí rẹ̀ lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”—Lúùkù 2:49.
26 Ó dájú pé Jósẹ́fù máa ro ọ̀rọ̀ yẹn ní àròtúnrò. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó wú u lórí gan-an. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ akitiyan lá ti ṣe láti lè gbin irú èrò bẹ́ẹ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run sínú ọmọ tó jẹ́ alágbàtọ́ fún yìí. Nígbà ọmọdé tí Jésù wà yẹn, ó ti mọ bí ìfẹ́ “baba” ṣe máa ń rí lára ọmọ, pàápàá látinú ọwọ́ tí Jósẹ́fù fi mú ọ̀rọ̀ tòun.
27. Tó o bá jẹ́ bàbá, àǹfààní wo lo ní, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o máa rántí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù?
27 Tó bá jẹ́ pé bàbá ni ìwọ náà, ǹjẹ́ o rí i pé àǹfààní ńlá lo ní láti tọ́jú ọmọ rẹ bó ṣe yẹ, kó lè lóye ohun tó túmọ̀ sí láti ní bàbá onífẹ̀ẹ́ tó ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀? Bákan náà, tó bá jẹ́ pé ìwọ kọ́ lo bí ọmọ tí ò ń tọ́ tàbí o jẹ́ alágbàtọ́, rántí àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, kó o mọ̀ pé ọmọ yàtọ̀ sí ọmọ, kí o sì ka olúkúlùkù wọn sí ọmọ àtàtà. Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wọn ọ̀run.—Ka Éfésù 6:4.
Jósẹ́fù Ní Ìfaradà
28, 29. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Lúùkù 2:51, 52 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jósẹ́fù? (b) Ipa wo ni Jósẹ́fù kó nínú bí ọmọ rẹ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ọgbọ́n?
28 Lẹ́yìn èyí, ìwọ̀nba nǹkan díẹ̀ ni Bíbélì tún mẹ́nu kàn nípa ìgbésí ayé Jósẹ́fù. Ṣùgbọ́n ó yẹ́ ká fún ohun tó sọ ní àfiyèsí gidigidi. Bíbélì sọ pé Jésù “sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn,” ìyẹn àwọn òbí rẹ̀. A tún rí i kà pé “Jésù sì ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n àti ní ìdàgbàsókè ti ara-ìyára àti ní níní ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.” (Ka Lúùkù 2:51, 52.) Kí ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jósẹ́fù? Ohun púpọ̀ ni wọ́n jẹ́ ká mọ̀. Ara wọn ni pé Jósẹ́fù ń bá a lọ láti mú ipò iwájú nínú agbo ilé rẹ̀, torí Jésù ọmọ pípé bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Jósẹ́fù bàbá rẹ̀, ó sì fi ara rẹ̀ sábẹ́ rẹ̀.
29 Bíbélì tún sọ pé Jésù ń tẹ̀ síwájú nínú ọgbọ́n. Ó dájú pé Jósẹ́fù á ti ṣe gudugudu méje nínú ìtẹ̀síwájú tí ọmọ rẹ̀ ń ní yìí. Láyé ìgbà yẹn, òwe kan wà tipẹ́tipẹ́ láàárín àwọn Júù. Èèyàn tiẹ̀ ṣì lè rí òwe náà kà nínú ìwé lónìí. Wọ́n máa ń sọ pé àwọn ọkùnrin tí ayé bá dẹ̀ lọ́rùn ló lè di ọlọ́gbọ́n èèyàn, pé àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ bíi káfíńtà, àgbẹ̀ àti alágbẹ̀dẹ “kò lè mọ ẹ̀tọ́ àti ìdájọ́ òdodo; wọn kò sì gbọ́dọ̀ mí fín níbi tí àwọn èèyàn bá ti ń pòwe.” Àmọ́ nígbà tí Jésù dàgbà, ó fi hàn pé àṣìpa òwe gbáà ni. Torí kékeré ni Jésù ti ń gbọ́ tí bàbá tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ yìí ti ń kọ́ agbo ilé rẹ̀ nípa “ẹ̀tọ́ àti ìdájọ́ òdodo” Jèhófà lọ́nà tó jáfáfá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé káfíńtà lásán ni. Ó dájú pé àìmọye ìgbà ni Jósẹ́fù kọ́ wọn.
30. Àpẹẹrẹ rere wo ni Jósẹ́fù fi lélẹ̀ fún àwọn olórí ìdílé lóde òní?
30 A tún lè rí ipa tí Jósẹ́fù kó nínú ìdàgbàsókè Jésù. Ó tọ́jú Jésù dáadáa, débi pé ó dàgbà di géńdé ọkùnrin tí ara rẹ̀ le koko. Yàtọ̀ síyẹn, Jósẹ́fù kọ́ ọmọ rẹ̀ ní iṣẹ́ ọwọ́ títí tó fi mọ iṣẹ́ náà dáadáa. Kì í ṣe ọmọ káfíńtà nìkan ni àwọn èèyàn mọ Jésù sí, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “káfíńtà náà.” (Máàkù 6:3) Torí náà, Jósẹ́fù tọ́ Jésù ní àtọ́yanjú. Ńṣe ló yẹ kí àwọn olórí ìdílé náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, kí wọ́n tọ́jú àwọn ọmọ wọn dáadáa, kí wọ́n sì tọ́ wọn débi tí wọ́n á fi lè gbọ́ bùkátà ara wọn.
31. (a) Ìgbà wo ló jọ pé Jósẹ́fù kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn? (Tún wo àlàyé tó wà nínú àpótí.) (b) Àwọn nǹkan wo ni Jósẹ́fù ṣe tó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
31 Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ ìtàn Jésù débi pé ó ṣe ìrìbọmi ní nǹkan bí ọmọ ọgbọ̀n ọdún, Bíbélì kò tún sọ nǹkan kan mọ́ nípa Jósẹ́fù. Ẹ̀rí fi hàn pé Màríà ti di opó nígbà tí Jésù fi máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Wo àpótí náà “Ìgbà Wo Ni Jósẹ́fù Kú?”) Síbẹ̀, Jósẹ́fù ti ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà. Ó ti fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ti bí èèyàn ṣe ń jẹ́ bàbá tó dáàbò bo ìdílé rẹ̀, tó ń pèsè fún wọn, tó sì fi ìfaradà ṣe ojúṣe rẹ̀ dópin. Ohun tó ti dára jù ni pé kí gbogbo bàbá, olórí ìdílé, àní gbogbo Kristẹni pátá, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù.
a Láyé ìgbà yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojú ẹni tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n fi ń wo àwọn tó bá ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà.
b Kì í ṣe ọ̀kan lára ìràwọ̀ ojú ọ̀run ló tan ìtànṣán àrà ọ̀tọ̀ náà, Ọlọ́run kọ́ ló sì rán ohun tí wọ́n pè ní ìràwọ̀ yẹn. Ó dájú pé Sátánì ló gbé nǹkan àràmàǹdà yìí yọ gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ ibi rẹ̀ tó fẹ́ fi pa Jésù.
c Bíbélì fi hàn pé ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi ló ṣe iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, pé ìyẹn sì ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀.”—Jòh. 2:1-11.