“Àwọn Ìránnilétí Rẹ Ni Mo Ní Ìfẹ́ni Fún”
“Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa.”—RÓÒMÙ 15:4.
1. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń fún wa ní ìránnilétí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa fiyè sí wọn?
JÈHÓFÀ máa ń pèsè ìránnilétí fún àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nípa àwọn ìṣòro tó wà láwọn àkókò tó le koko tí à ń gbé yìí. Ìgbà tá a bá ń ka Bíbélì tàbí tá à ń gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn ará wa bá ń sọ látorí pèpéle tàbí látorí ìjókòó wọn nípàdé la máa ń gbọ́ ìránnilétí wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kì í ṣe tuntun sí wa. Ó ṣeé ṣe ká ti gbọ́ tàbí ká ti kà nípa wọn nígbà kan sẹ́yìn. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwa ẹ̀dá aláìpé máa ń gbàgbé nǹkan, ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa gbé àwọn òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà, àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe lọ́jọ́ iwájú yẹ̀ wò. Ó yẹ ká mọrírì àwọn ìránnilétí Ọlọ́run. Wọ́n ń fún wa lókun ní ti pé wọ́n ń jẹ́ ká máa rántí ìdí tá a fi pinnu láti máa gbé ìgbé ayé tí inú Ọlọ́run dùn sí. Abájọ tí onísáàmù fi kọrin sí Jèhófà pé: “Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún.”—Sáàmù 119:24.
2, 3. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi rí sí i pé ìtàn àwọn tó wà nínú Bíbélì ṣì wà títí dọjọ́ òní? (b) Àwọn ìtàn Bíbélì wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára gan-an bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti kọ ọ́. (Hébérù 4:12) Bíbélì sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn kan tó gbé láyé ìgbàanì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà àwọn èèyàn àti ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan ti yàtọ̀ gan-an sí ti ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, àwọn ìṣòro tá a sábà máa ń ní lóde òní kò yàtọ̀ sí tayé ìgbà yẹn. Ọ̀pọ̀ ìtàn tó wà nínú Bíbélì fún àǹfààní wa jẹ́ ìtàn alárinrin nípa àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì sìn ín tọkàntọkàn bí wọ́n tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àwọn ìtàn míì sì jẹ́ ká mọ irú ìwà tí Ọlọ́run kórìíra. Jèhófà rí sí i pé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn yìí, àtèyí tó dára àtèyí tí kò dára, ló wà nínú Bíbélì láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí, ó ní: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
3 Ẹ jẹ́ ká jíròrò ìtàn mẹ́ta nínú Bíbélì, ìyẹn ìtàn Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù, ìtàn Ananíà àti Sáfírà, àti ìtàn Jósẹ́fù òun ìyàwó Pọ́tífárì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtàn wọ̀nyí ló kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì.
Dídúró Ti Ètò Tí Ọlọ́run Ṣe
4, 5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín Sọ́ọ̀lù Ọba àti Dáfídì? (b) Kí ni Dáfídì ṣe pẹ̀lú gbogbo bí Sọ́ọ̀lù ṣe kórìíra rẹ̀?
4 Sọ́ọ̀lù Ọba hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà, èyí ò sì jẹ́ kó kúnjú ìwọ̀n mọ́ láti máa ṣàkóso àwọn èèyàn Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi kọ̀ ọ́, tó sì sọ fún Sámúẹ́lì wòlíì pé kó lọ fòróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Dáfídì ṣe ohun tó fi hàn pé ó jẹ́ akọni lógún ogun táwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí i yìn ín, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí i wò ó gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń bá òun du ipò ọba. Àìmọye ìgbà ni Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa á. Ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà tí Sọ́ọ̀lù gbìyànjú rẹ̀ ni Dáfídì yè bọ́ torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 18:6-12, 25; 19:10, 11.
5 Ọ̀pọ̀ ọdún ni Dáfídì fi ń sá kiri kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́. Láwọn ìgbà kan tí Dáfídì láǹfààní láti pa Sọ́ọ̀lù, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ sọ pé kó pa á, wọ́n ní Jèhófà ti fi ọ̀tá rẹ̀ lé e lọ́wọ́. Àmọ́, Dáfídì ò gbà sí wọn lẹ́nu. Ìdí tí Dáfídì kò ṣe pa Sọ́ọ̀lù ni pé Dáfídì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó sì bọ̀wọ̀ fun Sọ́ọ̀lù torí pé òun ni ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn láti ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀. Jèhófà ló ṣáà yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì, àbí òun kọ́? Jèhófà náà ni yóò tún mú un kúrò nípò ọba bí àkókò bá tó. Dáfídì wò ó pé òun ò lẹ́tọ̀ọ́ láti dá sí ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú kí inú Sọ́ọ̀lù yọ́ sóun, ó sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò mú ìyọnu àgbálù bá a; tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò dé tí yóò sì ní láti kú, tàbí yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìjà ogun, a ó sì gbá a lọ dájúdájú. Kò ṣeé ronú kàn, níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, láti na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Jèhófà!”—1 Sámúẹ́lì 24:3-15; 26:7-20.
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé ìtàn Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù yẹ̀ wò?
6 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tá a lè rí kọ́ látinú ìtàn yìí. Nígbà míì, ǹjẹ́ o máa ń ṣàníyàn nípa ìdí táwọn ìṣòro kan fi wà nínú ìjọ? Ó lè jẹ́ pé ohun tí kò bójú mu lẹnì kan ń ṣe sí ọ. Nǹkan ọ̀hún lè má jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ńlá o, síbẹ̀ ó lè máa dùn ọ́. Kí wá ló yẹ kó o ṣe? Nítorí ìfẹ́ tó o ní sí onítọ̀hún àti nítorí pé o fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ńṣe ló yẹ kó o lọ bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù nítorí àtilè jèrè arákùnrin rẹ. Àmọ́, bí ìṣòro náà ò bá yanjú ńkọ́? Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, o lè fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Ohun tí Dáfídì ṣe nìyẹn.
7. Báwo la ṣe lè fìwà jọ Dáfídì bí àwọn kan bá ń hùwà àìdáa sí wa tàbí tí wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú sí wa?
7 Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ pé àwọn kan ń hùwà àìdáa sí ọ tàbí wọ́n ń ṣe ẹ̀tanú sí ọ nítorí ìsìn rẹ. Ó lè máà sí nǹkan kan tó o lè ṣe sí ìṣòro náà nísinsìnyí. Òótọ́ ni pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè má rọrùn láti fara dà, àmọ́ ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń hùwà àìdáa sí i kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan. Téèyàn bá ka àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ nígbà tó wà nínú ìṣòro, àánú á ṣèèyàn. Kì í ṣe àdúrà àtọkànwá tó gbà sí Ọlọ́run pé kó má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù tẹ òun nìkan ló wà nínú àwọn sáàmù wọ̀nyí, àmọ́ ó tún kọ̀wé nípa ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Jèhófà àti bó ṣe ń wù ú tó pé káwọn èèyàn gbé orúkọ Ọlọ́run ga. (Sáàmù 18:1-6, 25-27, 30-32, 48-50; 57:1-11) Dáfídì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Sọ́ọ̀lù fi hùwà àìdáa sí i. Àwa náà ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti ètò rẹ̀ bí àwọn èèyàn tiẹ̀ ń hùwà àìdáa tàbí tí wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan míì sí wa. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà.—Sáàmù 86:2.
8. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ilẹ̀ Mòsáńbíìkì ṣe nígbà tí àwọn ìṣòro kan dán ìdúróṣinṣin wọn sí Jèhófà wò?
8 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà ìdánwò tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn lónìí ni àwọn ará wa ní Mòsáńbíìkì. Lọ́dún 1984, àìmọye ìgbà làwọn ọmọ ogún ọlọ̀tẹ̀ kan lọ gbógun jà wọ́n lábúlé wọn. Bí wọ́n ṣe ń ja àwọn èèyàn lólè ni wọ́n ń dáná sun ilé wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn mìíràn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyí lè ṣe láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà ò fi àwọn tó ń gbé lágbègbè náà lọ́rùn sílẹ̀ rárá, wọ́n ní àfi kí wọ́n dára pọ̀ mọ́ àwọn tàbí kí wọ́n ṣàtìlẹ́yìn fún àwọn láwọn ọ̀nà mìíràn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì mọ̀ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lòdì sí ìlànà Kristẹni tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbè sẹ́yìn ẹnì kankan. Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ yìí mú kí orí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà gbóná. Nǹkan bí ọgbọ̀n Ẹlẹ́rìí ni wọ́n pa lákòókò tí gbogbo nǹkan gbóná girigiri yẹn, síbẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ò juwọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú gbogbo bí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe láwọn máa pa wọ́n.a Wọ́n fara da ìwà àìdáa tí wọ́n ń hù sí wọn bíi ti Dáfídì, wọ́n sì borí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Ìránnilétí Tó Jẹ́ Ìkìlọ̀ fún Wa
9, 10. (a) Báwo làwọn ìtàn kan nínú Ìwé Mímọ́ ṣe lè ṣe wá láǹfààní? (b) Kí ló burú nínú ohun tí Ananíà àti Sáfírà ṣe?
9 Ìtàn àwọn kan lára àwọn tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa wọn jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa nípa irú ìwà tó yẹ ká jìnnà sí. Ìtàn àwọn tó ṣe ohun tí kò dáa tí wọ́n sì jìyà ẹ̀ pọ̀ gan-an nínú Bíbélì, kódà àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wà lára wọn. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ọ̀kan lára irú ìtàn bẹ́ẹ̀ ni ti Ananíà àti Sáfírà, tọkọtaya kan tí wọ́n wà nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nílùú Jerúsálẹ́mù.
10 Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi rí i pé ó yẹ kí àwọn fi nǹkan ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n dúró sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n bàa lè jàǹfààní látinú ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì. Àwọn kan nínú ìjọ ta àwọn ohun ìní wọn kí wọ́n lè fowó rẹ̀ ṣètìlẹyìn fáwọn èèyàn nínú ìjọ kó má bàa sí ẹni tó ṣe aláìní. (Ìṣe 2:41-45) Ananíà àti Sáfírà ta ilẹ̀ kan àmọ́ apá kan ni wọ́n mú wá fáwọn àpọ́sítélì lára iye tí wọ́n tà á, wọ́n ní gbogbo iye tí àwọn rí lórí ilẹ̀ tí àwọn tà làwọn mú wá yẹn. Iyekíye tó bá wu Ananíà àti Sáfírà ni wọ́n lè fi sílẹ̀, ṣùgbọ́n èròkerò ló wà lọ́kàn wọn, wọn ò sì ṣòótọ́. Ńṣe ni wọ́n fẹ́ ṣe ohun táwọn ọmọlẹ́yìn yòókù yóò fi máa fojú ọ̀làwọ́ gidi wò wọ́n. Ẹ̀mí mímọ́ wá ran àpọ́sítélì Pétérù lọ́wọ́ láti tú ìwà àìṣòótọ́ àti àgàbàgebè wọn fó, Jèhófà sì fikú pa wọ́n.—Ìṣe 5:1-10.
11, 12. (a) Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣítí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́? (b) Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ tá a bá jẹ́ olóòótọ́?
11 Bó bá ń ṣe wá bíi pé ká parọ́ torí káwọn èèyàn lè kà wá sí èèyàn dáadáa, ẹ jẹ́ ká rántí ìtàn Ananíà àti Sáfírà o. Tá a bá tiẹ̀ rí àwọn èèyàn tàn jẹ, a ò lè tan Jèhófà jẹ. (Hébérù 4:13) Ọ̀pọ̀ ibi ni Ìwé Mímọ́ ti rọ̀ wá pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí ara wa torí pé àwọn òpùrọ́ ò ní sí nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, níbi tí kò ti ní sí ìwà àìṣòdodo. (Òwe 14:2; Ìṣípayá 21:8; 22:15) Ó yẹ ká mọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀. Ìdí ọ̀hún ni pé Sátánì Èṣù ló ń fa gbogbo ìwà àìṣòótọ́.—Jòhánù 8:44.
12 Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, àǹfààní kékeré kọ́ la máa jẹ o. Lára wọn ni pé a ó ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a ó sì jẹ́ ẹni táwọn èèyàn fọkàn tán. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló jẹ́ pé jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ló mú kí wọ́n ríṣẹ́, òun ni ò sì jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn míì. Àmọ́, àǹfààní tó ga jù lọ tá a máa jẹ ni pé, a óò jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè.—Sáàmù 15:1, 2.
Jíjẹ́ Oníwà Mímọ́
13. Inú ipò wo ni Jósẹ́fù bá ara rẹ̀, kí ló sì ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀?
13 Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Jósẹ́fù ọmọ Jákọ́bù baba ńlá ìgbàanì kan nígbà tí wọ́n tà á sóko ẹrú. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó bára ẹ̀ nílé Pọ́tífárì tó jẹ́ ìjòyè kan láàfin ọba ilẹ̀ Íjíbítì. Ṣùgbọ́n ìyàwó Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ ò fi í lọ́rùn sílẹ̀, ó fẹ́ kí Jósẹ́fù tó rẹwà lọ́kùnrin ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun. Ojoojúmọ́ ló máa ń sọ fún Jósẹ́fù pé: “Sùn tì mí.” Ọ̀nà Jósẹ́fù jìn síbi táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ wà, kò sì sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n nílẹ̀ Íjíbítì. Bó bá tiẹ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin yìí, ẹnikẹ́ni lè má mọ̀. Àmọ́ nígbà tí ara ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ò gbà á mọ́, ló bá di Jósẹ́fù mú, Jósẹ́fù sì já ara rẹ̀ gbà ó fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 37:2, 18-28; 39:1-12.
14, 15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé ìtàn Jósẹ́fù yẹ̀ wò? (b) Kí nìdí tí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni fi dúpẹ́ pé òun kọbi ara sí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run?
14 Inú agboolé àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni wọ́n ti tọ́ Jósẹ́fù dàgbà, ó sì mọ̀ pé kò tọ̀nà káwọn tí kì í ṣe tọkọtaya ní ìbálòpọ̀. Ó bi obìnrin náà pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Bóyá ohun tó mú kó ronú bẹ́ẹ̀ ni pé ó mọ̀ nípa ìlànà ọkọ-kan aya-kan tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá èèyàn ní ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ tí wọ́n bá ronú nípa ohun tí Jósẹ́fù ṣe nínú ipò tó wà yẹn. Láwọn àgbègbè kan, àwọn èèyàn ò ka ìṣekúṣe sí ohun tó burú rárá, àní ńṣe ni wọ́n máa ń dá yẹ̀yẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí kò bá bá wọn ṣèṣekúṣe. Ìwà panṣágà tún wọ́pọ̀ láàárín àwọn àgbàlagbà. Nítorí náà, ìránnilétí ni ìtàn Jósẹ́fù jẹ́ fún wa lónìí. Òfin tí Ọlọ́run ṣe pé ẹ̀ṣẹ̀ ni panṣágà àti àgbèrè ṣì wà fún wa lóde òní. (Hébérù 13:4) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣèṣekúṣe gbà pé kò tiẹ̀ yẹ kéèyàn ṣe é rárá. Lára ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ ni pé àwọn èèyàn lè máa fini ṣẹ̀sín, kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi, owú jíjẹ, oyún àti àìsàn tí ìṣekúṣe ń fà. Èyí bá ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ mu pé ńṣe lẹni tó “bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 5:9-12; 6:18; Òwe 6:23-29, 32.
15 Obìnrin kan tí kò lọ́kọ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jennyb tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúpẹ́ pé òun kọbi ara sí àwọn ìránnilétí Jèhófà. Níbi iṣẹ́ rẹ̀, ọkùnrin kan tó lẹ́wà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ fẹ́ máa bá a tage. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jenny ò gbà fún un, síbẹ̀ ọkùnrin náà kò fi í lọ́rùn sílẹ̀. Jenny sọ pé: “Mo wá rí i pé ó túbọ̀ ń nira fún mi láti pa ara mi mọ́ torí pé kò sí ọmọbìnrin tí orí rẹ̀ ò ní wú tí ọmọkùnrin kan bá ń gba tiẹ̀.” Síbẹ̀, Jenny mọ̀ pé ńṣe ló kàn fẹ́ bá òun ṣèṣekúṣe bíi tàwọn tó ti bá ṣe irú ẹ̀. Nígbà tí Jenny wá ń kíyè sí i pé òun ti fẹ́ juwọ́ sílẹ̀, ó fi taratara bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí òun lè jẹ́ olóòótọ́. Jenny rí i pé ńṣe làwọn ohun tí òun kọ́ nígbà tí òun ṣèwádìí nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run tẹ̀ dà bí ìránnilétí àtìgbàdégbà tó ń ta òun jí kí òun lè wà lójúfò. Ọ̀kan lára irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀ ni ìtàn Jósẹ́fù àti ìyàwó Pọ́tífárì. Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ti lè máa rán ara mi létí bí mo ṣe fẹ́ràn Jèhófà tó, mi ò ní máa bẹ̀rù pé màá ṣe ohun tó burú jáì yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.”
Máa Kọbi Ara Sáwọn Ìránnilétí Ọlọ́run!
16. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá ń gbé ìtàn àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn yẹ̀ wò tá a sì ń ṣàṣàrò lórí irú ìtàn bẹ́ẹ̀?
16 Tí gbogbo wa bá gbìyànjú láti mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣètò pé káwọn ìtàn kan wà nínú Bíbélì fún wa, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n ń kọ́ wa? Kí làwọn ìṣesí tàbí ìwà táwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn hù tó yẹ ká fara wé tàbí tó yẹ ká ṣọ́ra fún? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ni ìtàn wọn wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìtọ́ni Ọlọ́run yóò jàǹfààní tí wọ́n bá ń wá bí wọ́n á ṣe ní ọgbọ́n tí ń fúnni ní ìyè, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tí Jèhófà jẹ́ kó wà lákọọ́lẹ̀ fún wa. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sábà máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tá a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé wọn. O ò ṣe máa wá àyè láti gbé àwọn ìtàn wọ̀nyí yẹ̀ wò?
17. Ojú wo lo fi ń wo àwọn ìránnilétí Jèhófà, kí sì nìdí?
17 A mà dúpẹ́ o fún ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sáwọn tó ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀! Lóòótọ́, a kì í ṣe ẹni pípé àní gẹ́gẹ́ báwọn ọkùnrin àtobìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn kì í ti í ṣe ẹni pípé. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ohun tí wọ́n ṣe wúlò gan-an fún wa. Tá a bá ń kọbi ara sí àwọn ìránnilétí Jèhófà, a ò ní ṣe àṣìṣe tó burú gan-an, yóò sì ṣeé ṣe fún wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n rìn ní ọ̀nà òdodo. Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè sọ bíi ti onísáàmù tó kọrin pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí [Jèhófà] mọ́; wọ́n ń fi gbogbo ọkàn-àyà wá a. Ọkàn mi ti pa àwọn ìránnilétí rẹ mọ́, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́nà tí ó peléke.”—Sáàmù 119:2, 167.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 1996, ojú ìwé 160 sí 162.
b A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìwà Dáfídì sí Sọ́ọ̀lù?
• Kí ni ìtàn Ananíà àti Sáfírà kọ́ wa?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù yẹ̀ wò lónìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kí nìdí tí Dáfídì ò ṣe jẹ́ kí wọ́n pa Sọ́ọ̀lù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ẹ̀kọ́ wo ni ìtàn Ananíà àti Sáfírà kọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kí nìdí tí Jósẹ́fù ò fi gbà láti ṣèṣekúṣe?