Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ọ̀nà tí Jésù gbà bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ níbi àsè ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà fi hàn pé kò bọ̀wọ̀ fún ìyá rẹ̀?—Jòhánù 2:4.
Kété lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi ni wọ́n pé òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ síbi àsè ìgbéyàwó kan tó wáyé ní Kánà. Ìyá rẹ̀ náà wà níbẹ̀. Nígbà tí wáìnì wọn ò tó, Màríà sọ fún Jésù pé: “Wọn kò ní wáìnì kankan.” Jésù wá dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin? Wákàtí mi kò tíì dé síbẹ̀.”—Jòhánù 2:1-4.
Lóde òní, àìfi ọ̀wọ̀ hàn tàbí ìwà àrífín làwọn èèyàn máa kà á sí, tẹ́nì kan bá pe ìyá rẹ̀ ní “obìnrin” tó sì tún sọ fún un pé, “kí ni pa tèmi tìrẹ pọ̀?” Àmọ́, tẹ́nì kan bá sọ pé Jésù ò fi ọ̀wọ̀ hàn tàbí pé ó hùwà àrífín sí ìyá rẹ̀ nítorí ohun tó sọ yẹn, a jẹ́ pé onítọ̀hún gbójú fo àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà lo èdè wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ nìyẹn. Lílóye ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà lo irú gbólóhùn yìí lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì yóò ṣèrànwọ́.
Ní ti ọ̀rọ̀ náà “obìnrin,” ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words, èyí tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, sọ pé: “Bí wọ́n bá pe obìnrin kan lọ́nà yìí, kò túmọ̀ sí ìbáwí rárá, kò sì túmọ̀ sí pé wọ́n kanra mọ́ ọn, àmọ́ ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún ẹni ọ̀wọ́n kan tàbí ẹni téèyàn bọ̀wọ̀ fún gan-an.” Àwọn ìwé mìíràn fara mọ́ ohun tí ìwé yìí sọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì The Anchor Bible sọ pé: “Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìbáwí, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ àrífín tàbí ọ̀rọ̀ tí kò fìfẹ́ hàn . . . Bí Jésù ṣe sábà máa ń pe àwọn obìnrin tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nìyẹn.” Ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ The New International Dictionary of New Testament Theology ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà “jẹ́ èyí tí wọ́n máa ń lò láti bá èèyàn sọ̀rọ̀ láìsí pé wọ́n fàbùkù kan onítọ̀hún.” Bákan náà, ìwé atúmọ̀ èdè Theological Dictionary of the New Testament tí Gerhard Kittel ṣe jáde sọ pé, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ “kì í ṣe èyí tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn tàbí èyí tó ń tàbùkù ẹni rárá.” Nítorí náà, kò yẹ ká sọ pé Jésù ṣàfojúdi tàbí pé ó ṣe ohun tí kò dáa sí ìyá rẹ̀ nítorí pé ó pè é ní “obìnrin.”—Mátíù 15:28; Lúùkù 13:12; Jòhánù 4:21; 19:26; 20:13, 15.
Gbólóhùn tó sọ yẹn wá ń kọ́, tó ní “Kí ni pa tèmi tìrẹ pọ̀?” Èyí jẹ́ àkànlò èdè kan tó wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn Júù, wọ́n sì lò ó láwọn ibi mélòó kan nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nínú 2 Sámúẹ́lì 16:10, Dáfídì ò gbà rárá pé kí Ábíṣáì pa Ṣíméì, ó ní: “Kí ní pa tèmi tiyín pọ̀, ẹ̀yin ọmọ Seruáyà? Ẹ jẹ́ kí ó máa pe ibi sọ̀ kalẹ̀, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ fún un pé, ‘Pe ibi wá sórí Dáfídì!’” Bákan náà la tún rí i kà nínú 1 Àwọn Ọba 17:18 pé nígbà tí opó Sáréfátì rí i pé ọmọ òun ti kú, ó sọ fún Èlíjà pé: “Kí ní pa tèmi tìrẹ pọ̀, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣe ni o tọ̀ mí wá láti mú ìṣìnà mi wá sí ìrántí àti láti fi ikú pa ọmọkùnrin mi.”
Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wọ̀nyí jẹ́ ká rí i pé gbólóhun náà, “kí ni pa tèmi tirẹ̀ pọ̀?” jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń sọ látìgbàdégbà. Kì í ṣe pé wọ́n fi ń pẹ̀gàn ẹnì kan kì í sì í ṣe pé ẹni tó sọ ọ́ lẹ́mìí ìgbéraga, àmọ́ ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń wáyé nígbà téèyàn ò bá fẹ́ ṣe ohun tẹ́nì kan ń dámọ̀ràn fún un pé kó ṣe. Èyí tí Jésù sọ sí Màríà yẹn wá ńkọ́?
Nígbà tí Màríà sọ fún Jésù pé: “Wọn kò ní wáìnì kankan,” ó hàn gbangba pé kì í ṣe pé ó kàn fẹ́ kí Jésù mọ̀ pé kò sí wáìnì mọ́, àmọ́ ńṣe ló ń fọgbọ́n sọ pé kí Jésù ṣe nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà ni. Jésù lo àkànlò èdè tí wọ́n sábà máa ń lò yẹn láti jẹ́ kí Màríà mọ̀ pé òun ò fẹ́ ṣe ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ pé kóun ṣe yẹn. Ọ̀rọ̀ tí Jésù fi kún un pé, “Wákàtí mi kò tíì dé síbẹ̀,” ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀.
Látìgbà tí Jésù ti ṣèrìbọmi tí Ọlọ́run sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, ló ti mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà tá a ṣèlérí ni pé kóun jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí yóò wá yọrí sí ikú, àjíǹde àti ìṣelógo fún òun nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Bí àkókò ikú rẹ̀ ti ń sún mọ́lé, Jésù la ọ̀rọ̀ yìí yé àwọn èèyàn yékéyéké, ó sọ pé: “Wákàtí náà ti dé.” (Jòhánù 12:1, 23; 13:1) Abájọ tí Jésù fi sọ nínú àdúrà tó gbà lálẹ́ ọjọ́ tí ikú rẹ̀ ku ọ̀la yẹn pé: “Baba, wákàtí náà ti dé; ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo.” (Jòhánù 17:1) Nígbà táwọn èèyànkéèyàn tó wá mú Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì sì dé níkẹyìn, ó jí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lójú oorun, ó sọ pé: “Wákàtí náà ti dé! Wò ó! A fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.”—Máàkù 14:41.
Àmọ́, níbi àsè ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà yẹn, Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà ni, “wákàtí” rẹ̀ kò sì tíì dé. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí rẹ̀ ni pé kó ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ lọ́nà tí Bàbá rẹ̀ là sílẹ̀ fún un, kó ṣe é lákòókò tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe é, kò sì sẹ́ni tó lè ṣèdíwọ́ fún ohun tó ti pinnu láti ṣe yìí. Èyí lóhun tí Jésù ń jẹ́ kí màmá rẹ̀ mọ̀ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn, kì í ṣe pé kò fi ọ̀wọ̀ hàn tàbí pé ó ń tàbùkù ìyá rẹ̀. Màríà pàápàá kò bínú, kò sì sọ pé ọmọ òun tàbùkù òun. Kódà, Màríà lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn dáadáa, ìdí nìyẹn tó fi sọ fáwọn tó ń ṣe ìránṣẹ́ níbi àsè náà pé: “Ohun yòówù tí ó bá sọ fún yín, ẹ ṣe é.” Dípò kí Jésù kó ọ̀rọ̀ ìyá rẹ̀ dà nù, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ tó fi han pé òun ni Mèsáyà nípa sísọ omi di ojúlówó ọtí wáìnì. Ó wá tipa báyìí ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀, kò sì ṣàìka ọ̀rọ̀ ìyá rẹ̀ sí.—Jòhánù 2:5-11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jésù bọ̀wọ̀ fún ìyá rẹ̀, àmọ́ ó sojú abẹ níkòó nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀