Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
“Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”
RÚÙTÙ àti Náómì jọ ń rìn ní ojú ọ̀nà tó gba àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ẹ̀fúùfù ti máa ń rọ́ yìì. Àwọn méjèèjì péré ló kù tó ń dá rìnrìn àjò lọ láàárín pápá gbalasa kan tó lọ salalu. O lè fojú inú wo Rúùtù bó ṣe ṣàkíyèsí pé ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ báyìí, tó sì wá ń wo ìyá ọkọ rẹ̀ pé ó yẹ kí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tí àwọn máa sùn mọ́jú. Ó fẹ́ràn Náómì dọ́kàn, ó sì ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti tọ́jú rẹ̀.
Àwọn méjèèjì ni ọ̀fọ̀ ńláǹlà ṣẹ̀. Ọjọ́ ti pẹ́ tí Náómì ti di opó, àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó tún ń ṣọ̀fọ̀ ikú ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Kílíónì àti Málónì. Rúùtù pàápàá ń ṣọ̀fọ̀. Torí pé ọkọ rẹ̀ ni Málónì tó kú. Òun àti Náómì wá jọ ń lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àmọ́ ṣá, ìyàtọ̀ wà nínú ìrìn àjò àwọn méjèèjì. Ilé ni Náómì ń pa dà sí ní tiẹ̀. Àmọ́ ní ti Rúùtù, ilẹ̀ àjèjì tí kò mọ̀ rí ni ibi tí wọ́n ń lọ yìí jẹ́, ó sì ń lọ láìmọ ibi tí ọ̀rọ̀ òun lè já sí. Ṣe ló tún ń fi ẹbí, ọ̀rẹ́, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo àṣà ibẹ̀, títí kan àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ lọ.—Rúùtù 1:3-6.
Kí ló fà á tí ọ̀dọ́bìnrin yìí fi ṣe irú ìyípadà ńlá bẹ́ẹ̀? Ọ̀nà wo ni Rúùtù máa gbé e gbà táá fi lè máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àti ti Náómì? Tí a bá mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a ó rí i pé àpẹẹrẹ ńláǹlà ni ìgbàgbọ́ Rúùtù ara Móábù yẹn jẹ́ fún wa. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó fà á tí obìnrin méjèèjì fi gbéra ìrìn àjò jíjìn yìí lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
Ìdílé Kan Tí Àjálù Ńláǹlà Dé Bá
Ìlú Móábù ni Rúùtù gbé dàgbà, ìyẹn orílẹ̀-èdè kékeré kan tó wà ní ìlà oòrùn ibi tí Òkun Òkú wà. Gbogbo àgbègbè náà jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbalasa tó wà láàárín ibi gíga tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní igi, tí àwọn àfonífojì jíjìn sì là láàárín. “Àwọn pápá Móábù” jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí nǹkan ọ̀gbìn ti máa ń ṣe dáadáa, kódà ní gbogbo ìgbà tí ìyàn mú gan-an nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìyẹn gan-an ló kọ́kọ́ jẹ́ kí Rúùtù pàdé Málónì àti ìdílé rẹ̀.—Rúùtù 1:1.
Ìyàn tó mú nílẹ̀ Ísírẹ́lì ló jẹ́ kí Elimélékì ọkọ Náómì pinnu láti kó aya rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì kúrò nílùú ìbílẹ̀ wọn, tó lọ ń gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì nílẹ̀ Móábù. Ìgbésẹ̀ tó gbé yìí máa fa ìdánwò ìgbàgbọ́ bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn déédéé ní ibi mímọ́ tí Jèhófà ti yàn fún wọn. (Diutarónómì 16:16, 17) Náómì sapá gidigidi tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò fi yẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú, ìbànújẹ́ ńlá bá a.—Rúùtù 1:2, 3.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì ṣe lọ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Móábù kó ẹ̀dùn ọkàn ńlá bá a. (Rúùtù 1:4) Náómì mọ̀ pé ṣe ni Ábúráhámù baba ńlá orílẹ̀-èdè wọn sápá gidigidi láti rí i pé àárín àwọn èèyàn òun tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ni òun ti lọ fẹ́ ìyàwó fún Ísákì ọmọ òun. (Jẹ́nẹ́sísì 24:3, 4) Nígbà tó yá, Ọlọ́run wá kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè pé àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn kò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn àjèjì torí wọ́n lè mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà.—Diutarónómì 7:3, 4.a
Síbẹ̀síbẹ̀, obìnrin ọmọ Móábù ni Málónì àti Kílíónì fẹ́. Tí inú Náómì kò bá tiẹ̀ dùn sí ohun tí wọ́n ṣe yẹn tàbí pé kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ẹ̀rí fi hàn pé ó fi inú rere àti ìfẹ́ hàn sí Rúùtù àti Ópà, ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. Ó ṣeé ṣe kó ronú pé lọ́jọ́ kan àwọn náà lè dẹni tó ń sin Jèhófà bíi ti òun. Lọ́rọ̀ kan ṣá, Rúùtù àti Ópà fẹ́ràn Náómì gidigidi. Bí àárín wọn ṣe wọ̀ dáadáa yìí ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an nígbà àjálù tó dé bá wọn. Ọ̀dọ́bìnrin méjèèjì kò tíì bímọ kankan tí wọ́n fi di opó ọ̀sán gangan.—Rúùtù 1:5.
Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tí Rúùtù ń ṣe látilẹ̀ wá ti jẹ́ kó mọ ohun tó lè ṣe bí irú àjálù bẹ́ẹ̀ bá wáyé? Kò jọ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn ọmọ Móábù máa ń bọ ọ̀pọ̀ òrìṣà, Kémóṣì sì ni olórí òrìṣà wọn. (Númérì 21:29) Ó jọ pé gbogbo ìwà ìkà àti àwọn nǹkan burúkú tó wọ́pọ̀ láyé ìgbà yẹn, títí kan fífi àwọn ọmọdé rúbọ, náà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn ọmọ Móábù. Ó dájú pé àwọn nǹkan tí Rúùtù rí kọ́ lọ́dọ̀ Málónì tàbí ọ̀dọ̀ Náómì nípa Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àánú jẹ́ kó rí i pé ìjọsìn Jèhófà yàtọ̀ pátápátá. Ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣàkóso kì í da jìnnìjìnnì boni. (Diutarónómì 6:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ní àsìkò tí Rúùtù ń ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀ tó kú, ó túbọ̀ fà mọ́ Náómì, ó sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí obìnrin àgbàlagbà yìí ń sọ fún un nípa Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú sí àwọn èèyàn rẹ̀.
Ní ti Náómì, ó máa ń tẹ́tí léko láti mọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ́hùn-ún. Lọ́jọ́ kan, ó wá gbọ́, bóyá látẹnu oníṣòwò kan tó ń rìnrìn àjò, pé kò sí ìyàn mọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́. Oúnjẹ tún ti pọ̀ ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tó fi hàn pé orúkọ ìlú náà tó túmọ̀ sí “Ilé Búrẹ́dì” ti wá pa dà ń rò ó. Ni Náómì bá pinnu láti pa dà sí ìlú rẹ̀.—Rúùtù 1:6.
Kí wá ni Rúùtù àti Ópà máa ṣe báyìí? (Rúùtù 1:7) Gbogbo ohun tí àwọn àti Náómì ti jọ là kọjá ti mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ra gan-an. Ó jọ pé ohun tó tún mú kí Rúùtù túbọ̀ fà mọ́ Náómì ni inú rere rẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ni àwọn opó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wá gbéra, wọ́n ń lọ sí Júdà.
Ìtàn Rúùtù yìí máa ń jẹ́ ká rántí pé àtèèyàn rere àtèèyàn burúkú, kò sẹ́ni tí aburú kò lè ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:2, 11) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé tí àdánù ńláǹlà bá dé báni, dípò kí á bò ó mọ́ra, ó bọ́gbọ́n mu pé ká gba ìtùnú lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, pàápàá àwọn tí wọ́n ń gbára lé ààbò Jèhófà, ìyẹn Ọlọ́run tí Náómì sìn.—Òwe 17:17.
Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Tí Rúùtù Ní
Nígbà tí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ń rìn jìnnà, Náómì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa nǹkan kan. Ó ń ronú nípa àwọn ọ̀dọ́bìnrin méjèèjì tí wọ́n jọ ń lọ àti bí wọ́n ṣe fi ìfẹ́ hàn sí òun àti ọmọkùnrin òun méjèèjì. Kò fẹ́ kó jẹ́ pé òun ló tún máa dá kún ìṣòro wọn wàyí. Tí wọ́n bá wá fi ìlú tiwọn sílẹ̀, tí wọ́n sì tẹ̀ lé òun, ọ̀nà wo ni òun fẹ́ gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù?
Níkẹyìn, Náómì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ padà, olúkúlùkù sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Jèhófà ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe é sí àwọn ọkùnrin tí ó ti kú àti sí èmi.” Ó tún sọ fún wọn pé òun nírètí pé Jèhófà yóò pèsè ọkọ míì fún wọn láti fi san wọ́n ní ẹ̀san, yóò sì jẹ́ kí ayé wọn dáa. Ìtàn yẹn wá sọ pé: “Ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún.” Abájọ tí ọkàn Rúùtù àti Ópà fi fà mọ́ obìnrin onínúure tó ṣènìyàn gan-an yìí. Àmọ́, àwọn méjèèjì ò ṣáà gbà. Wọ́n ń sọ fún un pé: “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò bá ọ padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”—Rúùtù 1:8-10.
Ṣùgbọ́n Náómì kò gbà sí wọn lẹ́nu. Ó sọ ojú abẹ níkòó fún wọn pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí òun lè rí ṣe fún wọn nílẹ̀ Ísírẹ́lì tí òun ń lọ, torí pé òun kò ní ọkọ tó máa gbọ́ bùkátà òun, òun kò ní ọmọkùnrin kankan tí wọ́n lè fẹ́, pé kò sì sí ìrètí pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè wáyé mọ́. Ó jẹ́ kó yé wọn pé bí òun kò ṣe lágbára láti ràn wọ́n lọ́wọ́ jẹ ẹ̀dùn ọkàn fún òun.—Rúùtù 1:11-13.
Ópà gbà pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Náómì sọ yìí. Ó ṣe tán òun ṣì ni ẹbí ní Móábù, ìyá òun wà níbẹ̀, ilé sì tún wà tí òun máa gbé. Ó gbà pé á dáa kí òun yáa dúró sí ilẹ̀ Móábù. Torí náà, Ópà fi tẹ̀dùntẹ̀dùn fẹnu ko Náómì lẹ́nu láti kí i pé ó dìgbóṣe, ó yísẹ̀ pa dà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.—Rúùtù 1:14.
Rúùtù wá ńkọ́? Ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ kan òun náà. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ní ti Rúùtù, ó fà mọ́ ọn.” Bóyá Náómì ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ kó tó tún wá rí i pé Rúùtù ń tẹ̀ lé òun bọ̀ lẹ́yìn. Ló bá tún tẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn létí pé: “Wò ó! aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀. Bá aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó padà.” (Rúùtù 1:15) Ohun tí Náómì sọ yìí jẹ́ kí àwọn tó bá ń ka ìtàn yìí rí kókó pàtàkì kan. Kókó náà ni pé kì í ṣe pé Ópà pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ nìkan, ó tún pa dà sọ́dọ̀ “àwọn ọlọ́run rẹ̀.” Ó tẹ́ ẹ lọ́rùn láti máa bọ òrìṣà Kémóṣì àti àwọn òòṣà míì nìṣó. Ǹjẹ́ ohun tí Rúùtù náà fẹ́ ṣe nìyẹn?
Bí Rúùtù ṣe ń wo Náómì nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà tó dá páropáro yẹn, kò sí ìyè méjì kankan lọ́kàn rẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ṣe. Ó nífẹ̀ẹ́ Náómì jinlẹ̀-jinlẹ̀ látọkàn wá àti Ọlọ́run tí Náómì ń sìn. Ìyẹn ló ṣe sọ fún Náómì pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, láti padà lẹ́yìn rẹ; nítorí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni ibi tí a ó sin mí sí. Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì fi kún un, bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá ya èmi àti ìwọ.”—Rúùtù 1:16, 17.
Ọ̀rọ̀ tí Rúùtù sọ yẹn fa kíki gan-an débi pé àwọn èèyàn ṣì ń rántí rẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta [3,000] sẹ́yìn tó ti kú. Ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Rúùtù níwà kan tó fani mọ́ra gan-an, ìyẹn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Okùn ìfẹ́ yẹn yi, ó sì lágbára gan-an débi pé ibikíbi tí Náómì bá ń lọ Rúùtù yóò bá a débẹ̀. Ikú nìkan ló lè yà wọ́n. Ní báyìí, àwọn èèyàn Náómì ni yóò di èèyàn rẹ̀, torí Rúùtù ti múra tán láti fi gbogbo ohun tó mọ̀ ní Móábù sílẹ̀, títí kan àwọn òrìṣà ilẹ̀ Móábù. Rúùtù kò dà bí Ópà, torí tọkàntọkàn ló fi sọ pé Jèhófà, ìyẹn Ọlọ́run tí Náómì ń sìn, ni Ọlọ́run ti òun náà fẹ́ máa sìn.b
Bí àwọn méjèèjì ṣe ń bá ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn wọn lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nìyẹn. Ìwádìí kan fi hàn pé ìrìn àjò yẹn máa gbà tó ọ̀sẹ̀ kan. Àmọ́ ó dájú pé bí àwọn méjèèjì tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe jọ ń lọ, wọ́n á máa fi ìyẹn tu ara wọn nínú.
Ìbànújẹ́ pọ̀ jọjọ nínú ayé yìí. Ní àkókò tá a wà yìí, èyí tí Bíbélì pè ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” onírúurú aburú tó ń fà ẹ̀dùn ọkàn ló ń dé báni. (2 Tímótì 3:1) Torí náà, irú ìwà tí Rúùtù ní yìí ṣe pàtàkì fún wa gan-an nísinsìnyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ lábẹ́ ipòkípò, ni yóò mú ká máa sapá gidigidi láti ṣe rere nínú ayé tó túbọ̀ ń burú sí i yìí. A nílò ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yìí nínú ìgbéyàwó wa, nínú ìdílé wa, láàárín àwa àti ọ̀rẹ́ wa, a sì tún nílò rẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Bá a ṣe ń rí i pé a ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí Rúùtù fi lélẹ̀.
Ìgbé Ayé Rúùtù àti Náómì Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn sọ pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ọ̀tọ̀ sì ni pé kéèyàn fi ṣèwà hù. Rúùtù ti wá ní àǹfààní láti fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni òun ní sì Náómì àti sí Jèhófà, Ọlọ́run tí òun ti yàn láti máa sìn.
Níkẹyìn, obìnrin méjèèjì yìí dé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, abúlé kan tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá níhà gúúsù Jerúsálẹ́mù. Ó jọ pé ìdílé Náómì jẹ́ ìdílé tó gbajúmọ̀ ní ìlú kékeré yìí, torí ṣe ni ìròyìn pé Náómì ti pa dà dé gba gbogbo ìlú náà. Àwọn obìnrin ìlú wá ń yọjú wò ó, wọ́n á ní, “Ṣé Náómì nìyí?” Ó hàn pé ilẹ̀ Móábù tí wọ́n lọ gbé ti mú kí ara rẹ̀ yí pa dà gan-an, torí ìrísí ojú rẹ̀ àti bó ṣe rí ní ìdúró fi hàn pé ọwọ́ ìyà àti ìpọ́njú ti bà á.—Rúùtù 1:19.
Náómì sọ ohun tójú rẹ̀ ti rí àti bí nǹkan ṣe korò fún un tó fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ obìnrin àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ àtijọ́ yẹn. Kódà ó tiẹ̀ wò ó pé dípò tí àwọn èèyàn á fi máa pe òun ní Náómì tó túmọ̀ sí “Adùn,” Márà tó túmọ̀ sí “Ìkorò” ni kí wọ́n máa pe òun. Ojú Náómì mà ti rí nǹkan o! Bíi ti Jóòbù tó gbé ayé ṣáájú rẹ̀ náà ni Náómì ṣe rò pé Jèhófà Ọlọ́run ló mú àwọn àjálù wọ̀nyẹn bá òun.—Rúùtù 1:20, 21; Jóòbù 2:10; 13:24-26.
Bí obìnrin méjèèjì yìí ṣe wá fìdí kalẹ̀ ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù bẹ̀rẹ̀ sí í ro bí òun ṣe máa rí ọ̀nà tó dáa jù tí òun lè gbà tọ́jú ara òun àti Náómì. Ó ti gbọ́ pé ètò onífẹ̀ẹ́ kan wà fún àwọn tálákà nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Òfin yẹn sọ pé wọ́n lè lọ sí oko nígbà ìkórè, kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn tó ń kórè lẹ́yìn ní pápá láti máa pèéṣẹ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa ṣa àwọn irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀, wọ́n sì tún lè máa kárúgbìn eteetí oko.c—Léfítíkù 19:9, 10; Diutarónómì 24:19-21.
Ìgbà yẹn jẹ́ ìgbà ìkórè ọkà báálì, èyí tó máa bọ́ sí oṣù April ní ayé òde òní. Rúùtù wá jáde lọ sí pápá bóyá òun á rí ẹni gba òun láyè kí òun pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀. Àfi bó ṣe di pé oko ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Bóásì ló ti ráyè pèéṣẹ́, Bóásì sì jẹ́ mọ̀lẹ́bí Elimélékì ọkọ Náómì tó ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lábẹ́ òfin, Rúùtù lẹ́tọ̀ọ́ láti pèéṣẹ́, síbẹ̀ kò kàn wọnú oko olóko, ṣe ló kọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tó ń kó àwọn olùkórè ṣiṣẹ́. Ọkùnrin náà gbà á láyè, Rúùtù sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Rúùtù 1:22–2:3, 7.
Fojú inú wo Rúùtù bó ṣe ń tẹ̀ lé àwọn olùkórè yẹn lẹ́yìn. Bí wọ́n ṣe ń fi dòjé mímú wọn gé ọkà báálì, yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti ṣa èyí tó bá já bọ́ tàbí èyí tí wọ́n fi sílẹ̀ fún un, yóò dì wọ́n sí ìtí. Lẹ́yìn náà yóò wá kó o lọ sí ibi tó ti máa gún un láti lè yọ àwọn ọkà ara rẹ̀. Iṣẹ́ tó gba sùúrù ni, bí ọ̀sán bá sì ṣe ń pọ́n sí i ló ṣe máa ń nira sí i. Síbẹ̀ Rúùtù ń bá iṣẹ́ náà lọ, àfi ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tó bá dáwọ́ dúró láti nu òógùn ojú rẹ̀ tàbí láti fi nǹkan ráńpẹ́ panu “nínú ilé,” èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ahéré tí wọ́n kàn pa fún àwọn òṣìṣẹ́.
Bóyá ni Rúùtù fi máa rò pé ẹnì kankan máa ṣàkíyèsí òun, síbẹ̀ ẹnì kan kíyè sí. Bóásì rí i, ó sì béèrè nípa rẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tó ń kó àwọn olùkórè ṣiṣẹ́. Bóásì tó jẹ́ ọkùnrin kan tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, máa ń fi ọ̀yàyà kí àwọn alágbàṣe òòjọ́ tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń bá a ṣiṣẹ́ pàápàá, yóò sọ pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Àwọn náà yóò sì dá a lóhùn pa dà. Ọkùnrin àgbàlagbà olóòótọ́ yìí ṣe bíi baba sí Rúùtù.—Rúùtù 2:4-7.
Bóásì pè é ní “ọmọbìnrin mi,” ó sì gbà á nímọ̀ràn pé pápá òun ni kó máa wá láti pèéṣẹ́, pé kó má sì jìnnà sí àwọn ọmọbìnrin ilé òun kí èyíkéyìí lára àwọn ọkùnrin tó ń bá òun ṣiṣẹ́ má bàa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́. Ó tún rí i dájú pé Rúùtù rí oúnjẹ jẹ ní àkókò oúnjẹ ọ̀sán. Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó yìn ín, ó sì gbà á níyànjú. Lọ́nà wo?—Rúùtù 2:8, 9, 14.
Nígbà tí Rúùtù bi Bóásì léèrè ìdí tí ó fi ṣe òun ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní oore ńlá bẹ́ẹ̀, Bóásì dá a lóhùn pé òun ti gbọ́ nípa gbogbo ohun tó ṣe fún Náómì ìyá ọkọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Bóásì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa Rúùtù tí Náómì ti sọ fún àwọn obìnrin ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Bóásì tún mọ̀ pé Rúùtù ti di olùjọsìn Jèhófà, torí ó sọ pé: “Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà, kí owó ọ̀yà pípé sì wà fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lábẹ́ ìyẹ́ apá ẹni tí ìwọ wá láti wá ìsádi.”—Rúùtù 2:12.
Ìṣírí gbáà ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn máa jẹ́ fún Rúùtù! Òótọ́ sì ni pé Rúùtù ti wá sábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà Ọlọ́run láti fi ṣe ibi ìsádi rẹ̀, bí ọmọ ẹyẹ ṣe máa ń wá ààbò lábẹ́ ìyẹ́ apá ìyá rẹ̀. Rúùtù dúpẹ́ lọ́wọ́ Bóásì bó ṣe bá òun sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń fini lọ́kàn bálẹ̀. Ó sì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ títí di ìrọ̀lẹ́.—Rúùtù 2:13, 17.
Bí Rúùtù ṣe fi iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ fún gbogbo wa lóde òní tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún, pàápàá lásìkò tí ọ̀rọ̀ ajé ò fara rọ yìí. Kò ronú pé àwọn nǹkan kan wà tó tọ́ sí òun látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni. Torí náà, ó mọrírì gbogbo ohun tí wọ́n bá ṣe fún un. Kò tì í lójú láti ṣiṣẹ́ àṣekára fún ìgbà pípẹ́ láti lè gbọ́ bùkátà Náómì, kódà bí iṣẹ́ yẹn tiẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ tó rẹlẹ̀. Tinútinú ló fi gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un nípa bí ó ṣe lè ṣiṣẹ́ ní ibi tí kò séwu, kó sì jẹ́ láàárín àwọn èèyàn dáadáa, ó sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò fìgbà kankan gbàgbé ibi ìsádi rẹ̀ tó dájú, pé Baba wa ọ̀run ni, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.
Tí àwa náà bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ bíi tí Rúùtù, tí a tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, tí a jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára bíi tirẹ̀, tí a tún ní ẹ̀mí ìmoore bíi tirẹ̀, a ó rí i pé àwa náà yóò di àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ta yọ fún àwọn ẹlòmíì. Báwo wá ni Jèhófà ṣe pèsè ohun tí Rúùtù àti Náómì nílò? A máa jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀ nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ́ náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé—Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Pàṣẹ fún Àwọn Olùjọsìn Rẹ̀ Láti Fẹ́ Kìkì Àwọn Tí Wọ́n Jọ Ń Jọ́sìn Òun?” ní ojú ìwé 29.
b Ó wúni lórí láti rí i pé Rúùtù kò kàn lo orúkọ òye náà “Ọlọ́run” nìkan bí ọ̀pọ̀ àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè ṣe sábà máa ń ṣe. Ó tún lo orúkọ Ọlọ́run gan-an, ìyẹn Jèhófà. Ìwé náà,The Interpreter’s Bible sọ pé: “Òǹkọ̀wé Bíbélì yẹn wá jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run tòótọ́ ni ará ilẹ̀ òkèèrè yìí ń sìn.”
c Òfin náà máa jọ Rúùtù lójú gan-an, torí kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Móábù tó ti wá. Láyé ìgbà yẹn, ní apá Ìlà Oòrùn, wọ́n máa ń fìyà jẹ àwọn opó. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Tí ọkọ obìnrin kan bá ti kú, àwọn ọmọkùnrin tí opó náà bí ló máa ń tọ́jú rẹ̀, tí kò bá sì ní ọmọkùnrin kankan, ó lè jẹ́ pé ṣe ló máa ní láti ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú tàbí kó di aṣẹ́wó tàbí kó kú.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìwé Kékeré Kan Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Fa Kíki
Àwọn èèyàn ṣàpèjúwe ìwé Rúùtù bí ìṣúra iyebíye, àní ìwé kékeré kan tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fa kíki. Lóòótọ́, kò ní ọ̀pọ̀ ìtàn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gba àkókò gígùn bíi ti ìwé Àwọn Onídàájọ́ tí wọ́n kọ ṣáájú rẹ̀, èyí tó jẹ́ ká mọ ìgbà tí ìtàn inú ìwé Rúùtù ṣẹlẹ̀. (Rúùtù 1:1) Ẹ̀rí fi hàn pé wòlíì Sámúẹ́lì ló kọ ìwé méjèèjì. Ó dájú pé wàá gbà lóòótọ́ pé ibi tí wọ́n fi ìwé Rúùtù sí láàárín àwọn ìwé Bíbélì bá a mu gan-an ni. Lẹ́yìn tó o bá kà nípa àwọn ogun àti bí àwọn onísùnmọ̀mí ṣe ń gbógun wá ja àwọn èèyàn àti bí àwọn míì ṣe gba ara wọn sílẹ̀, tó o sì wá ka ìwé kékeré yìí, wàá gbà pé Jèhófà kì í gbàgbé èèyàn aláàfíà tí ìṣòrò ìgbésí ayé ń bá fínra. Ìtàn ráńpẹ́ tó wà nínú ìwé yìí tó dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé kan, kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ àtàtà nípa ìfẹ́, ikú èèyàn ẹni, ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Rúùtù hùwà ọlọ́gbọ́n, ó fà mọ́ Náómì nígbà ọ̀fọ̀ àti ìbànújẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
“Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Rúùtù múra tán láti ṣe iṣẹ́ àṣekára, tó jẹ́ iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ torí kó lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àti ti Náómì