Kọ́ Ọmọ Rẹ
Ọlọ́run Fẹ́ràn Rẹ̀, Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ sì Fẹ́ràn Rẹ̀
KÒ SÍ ẹni tó mọ orúkọ ọmọbìnrin náà lóde òní. Orúkọ bàbá rẹ̀, Jẹ́fútà nìkan la fi mọ̀ ọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ, kí á sì kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn méjèèjì. A máa rí i pé Ọlọ́run fẹ́ràn ọmọbìnrin Jẹ́fútà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà sì fẹ́ràn rẹ̀.
A lè kà nípa Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ orí 11 nínú Bíbélì. Nítorí pé Jẹ́fútà jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kò sí àní-àní pé á máa kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ látinú Ìwé Mímọ́ déédéé.
Jẹ́fútà gbé láyé ṣáájú ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì béèrè pé àwọn fẹ́ kí ọba máa ṣàkóso àwọn. Jẹ́fútà ní agbára láti jà. Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kó ṣáájú àwọn lọ gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí wọn, tó ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.
Jẹ́fútà fẹ́ kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì, nítorí náà, ó ṣe ìlérí kan. Jẹ́fútà sọ pé tí Jèhófà bá jẹ́ kí òun ṣẹ́gun, òun á fi ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde látinú ilé òun nígbà tóun bá pa dà dé fún Jèhófà. Ẹni náà á máa fi ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀ sìn nínú àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ jáde wá?—a
Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ni! Inú Jẹ́fútà bà jẹ́ gan-an ni. Ọmọ kan ṣoṣo péré ló ní. Àmọ́, ó ti ṣèlérí fún Jèhófà, ó sì gbọ́dọ̀ mú un ṣẹ. Lójú ẹsẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sọ pé: “Baba mi, bí o bá ti la ẹnu rẹ sí Jèhófà, ṣe sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ti ẹnu rẹ jáde.” Lẹ́yìn náà, ọmọbìnrin yìí ní kí wọ́n fi òun nìkan sílẹ̀ fún oṣù méjì kí òun lè lọ sórí òkè láti lọ sunkún. Kí nìdí tí inú rẹ̀ fi bà jẹ́? Ìdí ni pé tí ó bá mú ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ ṣẹ, kò ní lé ní ọkọ, kò sì ní bímọ. Síbẹ̀ náà, kò ka ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀. Ó fẹ́ láti ṣègbọràn sí bàbá rẹ̀, ó sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ǹjẹ́ o rò pé ó múnú Jèhófà àti bàbá rẹ̀ dùn?—
Nítorí náà, Jẹ́fútà jẹ́ kí ọmọbìnrin rẹ̀ àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n ń bá a kẹ́gbẹ́ lọ fún oṣù méjì. Nígbà tó pa dà dé, bàbá rẹ̀ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ nípa ríràn an lọ sí àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ní Ṣílò láti lọ lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ níbẹ̀. Ọdọọdún ni àwọn ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa ń lọ sí Ṣílò láti fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà ní ìṣírí.
Ǹjẹ́ o mọ àwọn ọmọ tí wọ́n ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?— Ó dára láti túbọ̀ mọ àwọn ọmọ yẹn dáadáa, kí o sì di ọ̀rẹ́ wọn. Tó o bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọmọbìnrin Jẹ́fútà, tí o sì jẹ́ onígbọràn àti olóòótọ́, wàá ní àwọn ọ̀rẹ́ rere. Wàá múnú àwọn òbí rẹ dùn, Jèhófà á sì fẹ́ràn rẹ.
Kà á nínú Bíbélì rẹ
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.