Kọ́ Ọmọ Rẹ
Ráhábù Fi Ohun Tó Gbọ́ Sọ́kàn
JẸ́ KÁ sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn la wà. A wà nílùú Jẹ́ríkò nílẹ̀ Kénáánì. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù ń gbé nílùú yìí. Wọ́n bí i lẹ́yìn tí Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, tí wọ́n sì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá nínú Òkun Pupa! Kò sí rédíò, tẹlifíṣọ̀n tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà yẹn, síbẹ̀ Ráhábù mọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tí nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀ jìnnà síbi tó ń gbé. Ṣó o mọ bó ṣe gbọ́ nípa rẹ̀?—a
Ó dájú pé àwọn arìnrìn-àjò ti ní láti sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fáwọn èèyàn. Bí Ráhábù ṣe ń dàgbà, ó rántí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó tún wá gbọ́ àwọn nǹkan míì tó yani lẹ́nu nípa wọn. Lẹ́yìn ogójì [40] ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lò nínú aginjù, wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì. Ọlọ́run sì ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun gbogbo àwọn tó ń gbéjà kò wọ́n. Ní báyìí, Ráhábù gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pàgọ́ sí òdìkejì Odò Jọ́dánì nítòsí ìlú Jẹ́ríkò!
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, àwọn àlejò méjì wá sọ́dọ̀ Ráhábù torí wọ́n mọ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ níbi táwọn àlejò lè dé sí. Torí náà, ó gbà wọ́n sílé. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ọba ìlú Jẹ́ríkò gbọ́ pé àwọn amí láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti wọ ìlú Jẹ́ríkò àti pé ilé tí Ráhábù ti ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n dé sí. Lọba bá rán àwọn èèyàn sí Ráhábù pé kó mú àwọn ọkùnrin tó dé sọ́dọ̀ rẹ̀ jáde. Ṣó o mohun tí Ráhábù ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ àtohun tó ti ṣe nípa rẹ̀?—
Káwọn tí ọba rán tó dé, Ráhábù ti mọ̀ pé amí láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì làwọn àlejò tóun gbà yìí. Torí náà, ó tọ́jú wọn sókè àjà ilé, ó wá sọ fáwọn tí ọba rán pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi . . . Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí àkókò ti ń tó láti ti ẹnubodè nígbà tí ilẹ̀ ṣú ni àwọn ọkùnrin náà jáde lọ.” Ráhábù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ tètè lépa wọn.”
Kí lo rò pé ó mú kí Ráhábù tọ́jú àwọn amí yẹn?— Ó ṣàlàyé ìdí tó fi tọ́jú wọn, nígbà tó sọ fáwọn amí yẹn pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín dájúdájú . . . Nítorí a ti gbọ́ bí Jèhófà ti gbẹ omi Òkun Pupa táútáú kúrò níwájú yín nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì.” Ó tún ti gbọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì borí àwọn ọ̀tá míì tó gbéjà kò wọ́n.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nínú ìwé Hébérù 11:31 pé inú Jèhófà dùn pé Ráhábù fàwọn amí yẹn pa mọ́. Inú Ọlọ́run tún dùn sóhun tí Ráhábù béèrè lọ́wọ́ àwọn amí náà pé: ‘Mo lo inú rere onífẹ̀ẹ́ sí yín, torí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ búra fún mi pé nígbà tẹ́ ẹ bá gba Jẹ́ríkò, ẹ máa dá baba mi, ìyá mi, àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi sí.’ Àwọn amí yẹn ṣèlérí pé àwọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀ tí Ráhábù bá tẹ̀ lé ìtọ́ni táwọn máa fún un. Ṣó o mohun tí wọ́n ní kó ṣe?—
Àwọn amí yẹn sọ pé: ‘Gba okùn pupa yìí, kó o sì so ó mọ́ fèrèsé ilé rẹ, kó o sì kó gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ sínú ilé rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó bá wà níbẹ̀ ló máa yè é.’ Ráhábù ṣe gbogbo nǹkan táwọn amí náà sọ pé kó ṣe. Ṣó o mohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?—
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé sí Jẹ́ríkò, wọ́n sì wà lẹ́yìn ògiri ìlú náà. Fún odindi ọjọ́ mẹ́fà, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn yí ìlú náà ká ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Àmọ́ lọ́jọ́ keje, wọ́n rìn yí ìlú náà ká fúngbà méje, lẹ́yìn náà wọ́n pariwo gan-an. Ni ògiri gbogbo ìlú náà bá wó lulẹ̀, àyàfi ilé tí wọ́n so aṣọ pupa mọ́ ojú fèrèsé rẹ̀! Kò sóhun tó ṣe Ráhábù àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀.—Jóṣúà 2:1-24; 6:1-5, 14, 15, 20-25.
Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tí Ráhábù ṣe?— Ráhábù ò kàn gbọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, àmọ́ ó tún ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tó láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé Ráhábù yàn láti sin Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì! Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?— Àdúrà wa ni pé kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kọ́mọ náà sọ tinú ẹ̀.
Ìbéèrè:
○ Àwọn ìròyìn pàtàkì wo ni Ráhábù gbọ́ nígbà tó wà lọ́mọdé?
○ Báwo ló ṣe ṣe sáwọn amí tó wá láti Ísírẹ́lì, kí sì nìdí?
○ Ìlérí wo ni Ráhábù ní káwọn amí yẹn ṣe fóun?
○ Báwo la ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà dùn sí Ráhábù, báwo lo sì ṣe lè fìwà jọ Ráhábù?